MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Àǹfààní Tí Àtẹ Tó Ṣeé Tì Kiri Ti Ṣe Wá Kárí Ayé
Ìṣe orí karùn-ún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lọ sínú tẹ́ńpìlì, níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn wà, kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere fún wọn. (Iṣe 5:19-21, 42) Lónìí, àtẹ tó ṣeé tì kiri tá à ń lò láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn wà ti so èso rere.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀǸFÀÀNÍ TÍ ÀTẸ TÓ ṢEÉ TÌ KIRI TI ṢE WÁ KÁRÍ AYÉ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Ìgbà wo la bẹ̀rẹ̀ sí í fi àtẹ tó ṣeé tì kiri wàásù, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀?
Àwọn ọ̀nà wo ni àtẹ tó ṣeé tì kiri gbà dáa ju tábìlì tá a fi ń pàtẹ ìwé?
Kí la rí kọ́ látinú ìrírí Mi Jung You?
Báwo ni ìrírí Arákùnrin Jacob Salomé ṣe jẹ́ ká rí i pé àtẹ tó ṣeé tì kiri dára gan-an?
Kí ni ìrírí Annies àti ọkọ rẹ̀ kọ́ wa nípa bá a ṣe lè fi àtẹ tó ṣeé tì kiri wàásù lọ́nà tó gbéṣẹ́?