ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 45
Ẹ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn sí Ara Yín
“Kí ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín má yẹ̀, kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín.”—SEK. 7:9.
ORIN 107 Ìfẹ́ Ọlọ́run Jẹ́ Àpẹẹrẹ fún Wa
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1-2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ara wa?
Ọ̀PỌ̀ nǹkan ló wà tó fi yẹ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ara wa. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára wọn. Ẹ kíyè sí ohun tí àwọn ẹsẹ Bíbélì inú ìwé Òwe yìí sọ nípa wọn: “Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́ fi ọ́ sílẹ̀. . . . Nígbà náà, wàá rí ojú rere àti òye tó jinlẹ̀ gan-an lójú Ọlọ́run àti èèyàn.” “Ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní.” “Ẹni tó bá ń wá òdodo àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ yóò rí ìyè.”—Òwe 3:3, 4; 11:17, àlàyé ìsàlẹ̀; 21:21.
2 Àwọn ẹsẹ Bíbélì inú ìwé Òwe yìí mẹ́nu kan nǹkan mẹ́ta tó fi yẹ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. Àkọ́kọ́, tá a bá ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, Ọlọ́run máa mọyì wa. Ìkejì, tá a bá ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, a máa ṣe ara wa láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, àjọṣe tó wà láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ máa wà pẹ́ títí. Ìkẹta, tá ò bá jẹ́ kó sú wa láti máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, a máa gba èrè tó pọ̀ lọ́jọ́ iwájú títí kan ìyè àìnípẹ̀kun. Ká sòótọ́, ó yẹ káwọn nǹkan yìí mú ká máa fi ìmọ̀ràn Jèhófà yìí sọ́kàn pé: “Kí ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín má yẹ̀, kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín.”—Sek. 7:9.
3. Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́rin. Àwọn wo ló yẹ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí? Kí la lè rí kọ́ nínú ìwé Rúùtù nípa bó ṣe yẹ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn? Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn lóde òní? Tá a bá ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn, àǹfààní wo la máa rí?
ÀWỌN WO LÓ YẸ KÁ MÁA FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN SÍ?
4. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà tó bá dọ̀rọ̀ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn? (Máàkù 10:29, 30)
4 Bá a ṣe kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń fòótọ́ jọ́sìn rẹ̀ nìkan ló máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí. (Dán. 9:4) Ó yẹ ká “máa fara wé Ọlọ́run, bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ.” (Éfé. 5:1) Torí náà, ó yẹ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú ìjọ.—Ka Máàkù 10:29, 30.
5-6. Kí ló ń fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ ‘adúróṣinṣin’?
5 Tá a bá mọ ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́, ó dájú pé ìyẹn á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fi ìfẹ́ yìí hàn sáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà. Ká lè túbọ̀ lóye ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́, ẹ jẹ́ ká fi wé ọ̀rọ̀ náà ìdúróṣinṣin. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò.
6 Tí ẹnì kan bá ti ń bá ilé iṣẹ́ kan ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, a lè sọ pé ẹni náà jẹ́ adúróṣinṣin. Síbẹ̀, látìgbà tó ti wà nílé iṣẹ́ yẹn, ó lè má tíì rí àwọn tó ni ilé iṣẹ́ náà rí. Ó lè má fara mọ́ gbogbo ìpinnu táwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ yẹn bá ṣe, ó sì lè má nífẹ̀ẹ́ ilé iṣẹ́ náà. Àmọ́, inú ẹ̀ ń dùn pé òun ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láti rówó gbọ́ bùkátà. Á ṣì máa rọ́jú ṣiṣẹ́ nílé iṣẹ́ yẹn títí táá fi fẹ̀yìn tì, àfi tó bá ríṣẹ́ tó dáa jùyẹn lọ sílé iṣẹ́ míì.
7-8. (a) Kí ló ń mú kí ẹnì kan fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn? (b) Kí nìdí tá a fẹ́ fi gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan yẹ̀ wò nínú ìwé Rúùtù?
7 Ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìdúróṣinṣin tá a sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ní ìpínrọ̀ kẹfà àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni ohun tó ń mú kí ẹnì kan ṣe nǹkan. Nínú Bíbélì, ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ wo ló ń mú káwọn èèyàn Ọlọ́run fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn? Ìdí tí àwọn tó fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn nínú Bíbélì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó wá látọkàn wọn, kì í ṣe pé a fipá mú wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Dáfídì. Ọkàn Dáfídì ló mú kó fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Jónátánì ọ̀rẹ́ rẹ̀ bó tiẹ̀ jẹ́ pé bàbá Jónátánì fẹ́ pa Dáfídì. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Jónátánì kú, Dáfídì ṣì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Méfíbóṣétì ọmọ Jónátánì.—1 Sám. 20:9, 14, 15; 2 Sám. 4:4; 8:15; 9:1, 6, 7.
8 Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tá a bá gbé àwọn ẹsẹ Bíbélì kan yẹ̀ wò nínú ìwé Rúùtù. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ látara àwọn èèyàn tó wà nínú ìwé Rúùtù? Báwo la ṣe lè lo àwọn ẹ̀kọ́ yìí nínú ìjọ wa?b
KÍ LA LÈ RÍ KỌ́ NÍNÚ ÌWÉ RÚÙTÙ NÍPA BÓ ṢE YẸ KÁ MÁA FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN?
9. Kí nìdí tí Náómì fi rò pé Jèhófà ti kẹ̀yìn sí òun?
9 Nínú ìwé Rúùtù, a kà nípa ìtàn Náómì, Rúùtù tó jẹ́ ìyàwó ọmọ ẹ̀ àti ọkùnrin kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí ọkọ Náómì tó ń jẹ́ Bóásì. Nígbà tí ìyàn kan mú ní Ísírẹ́lì, Náómì, ọkọ ẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn méjèèjì ṣí lọ sí Móábù. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọkọ Náómì kú. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ẹ̀ méjèèjì fẹ́ ìyàwó. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé nígbà tó yá, àwọn náà kú. (Rúùtù 1:3-5; 2:1) Àwọn àjálù yìí mú kí Náómì rẹ̀wẹ̀sì gan-an. Kódà, ìbànújẹ́ dorí ẹ̀ kodò débi tó fi sọ pé Jèhófà ti kẹ̀yìn sóun. Nígbà tó ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀, ó sọ nípa Ọlọ́run pé: “Jèhófà ti bínú sí mi.” “Olódùmarè ti mú kí ayé mi korò gan-an.” Ó tún sọ pé: “Jèhófà ló kẹ̀yìn sí mi, Olódùmarè ló sì fa àjálù tó bá mi.”—Rúùtù 1:13, 20, 21.
10. Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ?
10 Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ? Jèhófà ò jáwọ́ lọ́rọ̀ Náómì tí ọkàn ẹ̀ ti gbọgbẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà gba tiẹ̀ rò. Jèhófà mọ̀ pé “ìnilára lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bíi wèrè.” (Oníw. 7:7) Síbẹ̀, ó yẹ kí Náómì rí ìrànlọ́wọ́ gbà kó lè mọ̀ pé Jèhófà ò fi òun sílẹ̀. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Náómì lọ́wọ́? (1 Sám. 2:8) Jèhófà lo Rúùtù láti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Náómì. Rúùtù ran ìyá ọkọ ẹ̀ lọ́wọ́ látọkàn wá, ó sì tù ú nínú kó lè mọ̀ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Rúùtù?
11. Kí nìdí táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin onínúure fi máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn tíṣòro dé bá?
11 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ló ń mú ká ṣèrànwọ́ fáwọn tíṣòro dé bá. Bí Rúùtù ṣe dúró ti Náómì, bẹ́ẹ̀ náà làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin onínúure lóde òní ṣe máa ń dúró ti àwọn ará ìjọ tíṣòro dé bá. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, wọ́n sì ṣe tán láti ṣe ohunkóhun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Òwe 12:25, àlàyé ìsàlẹ̀; 24:10) Ohun tí wọ́n ṣe yìí bá ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ mu pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́, ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.”—1 Tẹs. 5:14.
Tá a bá tẹ́tí sí arákùnrin tàbí arábìnrin kan tí ìṣòro dé bá, ìyẹn á jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ràn án lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 12)
12. Ọ̀nà tó dáa jù lọ wo la lè gbà ran arákùnrin tàbí arábìnrin kan lọ́wọ́?
12 Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀nà tó dáa jù lọ tá a lè gbà ran arákùnrin tàbí arábìnrin kan lọ́wọ́ ni pé ká máa tẹ́tí sí i tó bá ń sọ̀rọ̀, ká sì fi dá a lójú pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jèhófà mọyì ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tá a bá ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Sm. 41:1) Òwe 19:17 sọ pé: “Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan, á sì san án pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.”
Rúùtù wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Náómì ìyá ọkọ ẹ̀, Ọ́pà sì ń pa dà sí Móábù. Rúùtù sọ fún Náómì pé: “Ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ” (Wo ìpínrọ̀ 13)
13. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín Rúùtù àti Ọ́pà, kí sì nìdí tí ìpinnu Rúùtù fi jẹ́ ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
13 Ká lè túbọ̀ mọ ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Náómì lẹ́yìn tí ọkọ ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ méjèèjì kú. Nígbà tí Náómì gbọ́ pé “Jèhófà ti ṣíjú àánú wo àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ti ń fún wọn ní oúnjẹ,” ó pinnu pé òun máa pa dà sílé. (Rúùtù 1:6) Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò pẹ̀lú àwọn ìyàwó ọmọ ẹ̀ méjèèjì nìyẹn. Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Náómì rọ ìyàwó àwọn ọmọ ẹ̀ pé kí wọ́n pa dà sí Móábù. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Ọ́pà fi ẹnu ko ìyá ọkọ rẹ̀ lẹ́nu, ó sì pa dà. Àmọ́ Rúùtù kò fi í sílẹ̀.” (Rúùtù 1:7-14) Ọ́pà pinnu láti pa dà sí Móábù torí pé Náómì rọ̀ ọ́ pé kó pa dà. Àmọ́ Rúùtù ní tiẹ̀ ò pa dà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Rúùtù ní sí Náómì, ó pinnu láti tẹ̀ lé e. (Rúùtù 1:16, 17) Kì í ṣe dandan kí Rúùtù dúró ti Náómì, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé ó wù ú látọkàn wá. Ìpinnu tí Rúùtù ṣe yìí fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ló ní sí Náómì. Kí la rí kọ́ nínú ohun tí Rúùtù ṣe yìí?
14. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó nífẹ̀ẹ́ wa máa ń ṣe lónìí? (b) Bí Hébérù 13:16 ṣe sọ, àwọn nǹkan wo là ń ṣe tí inú Ọlọ́run ń dùn sí?
14 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ máa ń jẹ́ ká ṣe kọjá ohun táwọn èèyàn ń retí. Bíi tàwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lóde òní ti pinnu láti máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ̀ wọ́n rí. Bí àpẹẹrẹ, tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn ará máa ń fẹ́ mọ bí wọ́n ṣe máa ṣèrànwọ́. Tí nǹkan ò bá lọ dáadáa fún ẹnì kan nínú ìjọ, kíákíá làwọn ará máa ṣèrànwọ́ fún ẹni náà. Bíi tàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nílùú Makedóníà, àwọn ará wa náà máa ń ṣe kọjá ohun tá a retí. Wọ́n ń lo àkókò àti okun wọn láti ṣèrànwọ́. Kódà wọ́n ṣe “kọjá agbára wọn” kí wọ́n lè ran àwọn ará tíṣòro dé bá lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 8:3) Ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń rí i táwọn ará ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn síra wọn!—Ka Hébérù 13:16.
BÁWO LA ṢE LÈ FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN LÓDE ÒNÍ?
15-16. Báwo ni Rúùtù ò ṣe jẹ́ kó sú òun?
15 A lè kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tá a bá ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Rúùtù àti Náómì. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára wọn.
16 Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Nígbà tí Rúùtù sọ fún Náómì pé òun máa tẹ̀ lé e lọ sí Júdà, Náómì ò kọ́kọ́ gbà. Àmọ́ Rúùtù ò pa dà sílé. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí Náómì rí i pé Rúùtù kò fẹ́ fi òun sílẹ̀, kò rọ̀ ọ́ mọ́ pé kó pa dà.”—Rúùtù 1:15-18.
17. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní jẹ́ kó sú wa?
17 Ohun tá a rí kọ́: Ó gba sùúrù ká tó lè ṣèrànwọ́ fún ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́ ká má ṣe jẹ́ kó sú wa. Arábìnrin kan tó wà nínú ìṣòro lè má kọ́kọ́ gbà ká ran òun lọ́wọ́,c síbẹ̀ ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tá a ní sí i ò ní jẹ́ ká fi í sílẹ̀. (Gál. 6:2) A mọ̀ pé tó bá yá, ó máa gbà ká ran òun lọ́wọ́ kó lè borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀.
18. Kí ni Náómì ṣe tó dun Rúùtù gan-an?
18 Má ṣe jẹ́ kí inú bí ẹ. Nígbà tí Náómì àti Rúùtù pa dà dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Náómì rí àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ládùúgbò tẹ́lẹ̀. Ó wá sọ fún wọn pé: “Ọwọ́ mi kún nígbà tí mo lọ, àmọ́ Jèhófà mú kí n pa dà lọ́wọ́ òfo.” (Rúùtù 1:21) Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Rúùtù nígbà tó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ yìí. Rúùtù ti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ran Náómì lọ́wọ́. Rúùtù sunkún pẹ̀lú rẹ̀, ó tù ú nínú, ọ̀pọ̀ ọjọ́ sì ni wọ́n fi jọ rìnrìn àjò pa dà sílé. Láìka gbogbo ohun tí Rúùtù ṣe yìí sí, Náómì sọ pé: “Jèhófà mú kí n pa dà lọ́wọ́ òfo.” Ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ yìí fi hàn pé kò mọyì gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí Rúùtù ṣe fún un. Ẹ wo bíyẹn ṣe máa dun Rúùtù tó. Àmọ́ kò fi Náómì sílẹ̀ rárá.
19. Kí ló máa jẹ́ ká lè dúró ti ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn?
19 Ohun tá a rí kọ́: Lónìí, arábìnrin kan tó ní ẹ̀dùn ọkàn lè sọ ohun tó dùn wá bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti ṣe ipa tiwa láti ràn án lọ́wọ́. Àmọ́, a ò ní jẹ́ kínú bí wa, ńṣe la máa dúró ti arábìnrin wa gbágbáágbá, àá sì bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè tù ú nínú.—Òwe 17:17.
Báwo làwọn alàgbà ṣe lè fara wé Bóásì lóde òní? (Wo ìpínrọ̀ 20-21)
20. Kí ló jẹ́ kí Rúùtù lè máa ran Náómì lọ́wọ́ nìṣó?
20 Máa tu àwọn èèyàn nínú lákòókò tó yẹ. Rúùtù ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí Náómì, àmọ́ ní báyìí Rúùtù náà fẹ́ kí ẹnì kan tu òun nínú. Jèhófà sì lo Bóásì láti tù ú nínú. Bóásì sọ fún Rúùtù pé: “Kí Jèhófà san ẹ̀san ohun tí o ṣe fún ọ, kí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí o wá ààbò wá sábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ sì fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí tu Rúùtù nínú gan-an. Rúùtù wá dá Bóásì lóhùn pé: “O ti tù mí nínú, ọ̀rọ̀ rẹ sì ti fi ìránṣẹ́ rẹ lọ́kàn balẹ̀.” (Rúùtù 2:12, 13) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Bóásì sọ fún Rúùtù lákòókò tó yẹ yìí fún un lókun, ìyẹn ò sì jẹ́ kí nǹkan sú u.
21. Bí Àìsáyà 32:1, 2 ṣe sọ, kí ni àwọn alàgbà tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará máa ń ṣe?
21 Ohun tá a rí kọ́: Láwọn ìgbà míì, àwọn tó máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn ń fẹ́ ká tu àwọn náà nínú. Nígbà tí Bóásì rí inúure tí Rúùtù fi hàn sí Náómì, ó jẹ́ kí Rúùtù mọ̀ pé òun mọyì ohun tó ṣe. Bákan náà lónìí, àwọn alàgbà tó lákìíyèsí máa ń fi hàn pé àwọn mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ, wọ́n sì máa ń gbóríyìn fún wọn tí wọ́n bá rí i pé wọ́n fi inúure hàn sáwọn ará. Ọ̀rọ̀ ìṣírí táwọn alàgbà ń fún irú àwọn ará bẹ́ẹ̀ lákòókò tó yẹ ń jẹ́ kí wọ́n máa lókun, kò sì jẹ́ kí nǹkan sú wọn.—Ka Àìsáyà 32:1, 2.
TÁ A BÁ Ń FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN, ÀǸFÀÀNÍ WO LA MÁA RÍ?
22-23. Báwo ni Náómì ṣe yí èrò ẹ̀ pa dà, kí sì nìdí? (Sáàmù 136:23, 26)
22 Lẹ́yìn tí àkókò díẹ̀ kọjá, Bóásì fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn sí Rúùtù àti Náómì, ó pèsè oúnjẹ fún wọn. (Rúùtù 2:14-18) Nígbà tí Náómì rí ìwà ọ̀làwọ́ Bóásì, kí ló wá ṣe? Ó sọ pé: “Ìbùkún ni fún un látọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí àwọn alààyè àti òkú.” (Rúùtù 2:20a) Ẹ ò rí i pé Náómì ti yí èrò ẹ̀ pa dà! Níbẹ̀rẹ̀, ńṣe ló ń sunkún nígbà tó sọ pé: “Jèhófà ló kẹ̀yìn sí mi,” àmọ́ ní báyìí, tayọ̀tayọ̀ ló fi sọ pé: “Jèhófà . . . ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.” Kí ló jẹ́ kí Náómì yí èrò ẹ̀ pa dà?
23 Náómì bẹ̀rẹ̀ sí í rí ọwọ́ Jèhófà láyé ẹ̀. Jèhófà lo Rúùtù láti ran Náómì lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń pa dà sí Júdà. (Rúùtù 1:16) Náómì tún rí ọwọ́ Jèhófà nígbà tí Bóásì tó jẹ́ ọ̀kan lára “olùtúnrà” wọn fìfẹ́ pèsè ohun tí òun àti Rúùtù nílò.d (Rúùtù 2:19, 20b) Ó ṣeé ṣe kí Náómì sọ pé ‘Ní báyìí, ó ti wá yé mi pé Jèhófà ò fi mí sílẹ̀. Ńṣe ló dúró tì mí látìgbà tí mo ti ń kojú ìṣòro!’ (Ka Sáàmù 136:23, 26.) Ẹ wo bí inú Náómì ṣe máa dùn tó pé Rúùtù àti Bóásì ò fi òun sílẹ̀ nígbà ìṣòro! Ẹ̀yin náà ẹ fojú inú wo bí inú gbogbo wọn ṣe ń dùn pé Náómì ti wá ń fayọ̀ sin Jèhófà.
24. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn nìṣó sáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà?
24 Àwọn nǹkan wo la rí kọ́ látinú ìwé Rúùtù nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Tá a bá ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ìyẹn ò ní jẹ́ ká fi wọ́n sílẹ̀ nígbà ìṣòro. Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tún máa ń jẹ́ ká ṣe kọjá ohun táwọn ará wa retí. Ó yẹ káwọn alàgbà máa gbóríyìn fáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn tó wà nínú ìṣòro. Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá rí i pé àwọn tó wà nínú ìṣòro ti wá ń fayọ̀ sin Jèhófà. (Ìṣe 20:35) Àmọ́, kí ló máa ń jẹ́ ká fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn nìṣó sáwọn ará wa? Ohun tó ń jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà ẹni tí ‘ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi,’ a sì fẹ́ máa múnú rẹ̀ dùn.—Ẹ́kís. 34:6; Sm. 33:22.
ORIN 130 Ẹ Máa Dárí Jini
a Jèhófà fẹ́ ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nínú ìjọ. A lè túbọ̀ mọ ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́ tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan láyé àtijọ́ tí wọ́n fi ìfẹ́ yìí hàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí ohun tá a lè kọ́ lára Rúùtù, Náómì àti Bóásì.
b Kó o lè túbọ̀ lóye ẹ̀kọ́ inú àpilẹ̀kọ yìí dáadáa, a rọ̀ ẹ́ pé kó o ka Rúùtù orí kìíní àti kejì fúnra ẹ.
c Ìdí tá a fi lo àpẹẹrẹ àwọn arábìnrin nínú àpilẹ̀kọ yìí ni pé ìtàn Náómì là ń gbé yẹ̀ wò, àmọ́ ohun tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí kan àwọn arákùnrin náà.
d Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí Bóásì ṣe jẹ́ olùtúnrà, wo àpilẹ̀kọ náà, “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn—‘Obìnrin Títayọ Lọ́lá,’” nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2012, ojú ìwé 20.