ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w21 November ojú ìwé 2-7
  • Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ṣe Ń Ṣe Ọ́ Láǹfààní?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ṣe Ń Ṣe Ọ́ Láǹfààní?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘ÌFẸ́ JÈHÓFÀ TÍ KÌ Í YẸ̀ PỌ̀ GIDIGIDI’
  • ÀWỌN WO NI JÈHÓFÀ MÁA Ń FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN SÍ?
  • BÁWO LA ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ ÌFẸ́ JÈHÓFÀ TÍ KÌ Í YẸ̀?
  • Ó DÁJÚ PÉ ỌLỌ́RUN Á MÁA FI ÌFẸ́ RẸ̀ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN SÍ WA
  • Ṣé Inú Rẹ Máa Ń Dùn sí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Bíi Ti Jèhófà?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Máa Fìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Bíi Ti Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Mà Pọ̀ O!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Jẹ́ Adúróṣinṣin
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
w21 November ojú ìwé 2-7

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 44

Báwo Ni Ìfẹ́ Jèhófà Tí Kì Í Yẹ̀ Ṣe Ń Ṣe Ọ́ Láǹfààní?

“Ìfẹ́ [Jèhófà] tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”​—SM. 136:1.

ORIN 108 Ìfẹ́ Ọlọ́run Tí Kì Í Yẹ̀

OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa

1. Kí ni Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe?

INÚ Jèhófà máa ń dùn láti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. (Hós. 6:6) Ó sì rọ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ pé ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Míkà sọ fún wa pé ká “fẹ́ràn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.” (Míkà 6:8, àlàyé ìsàlẹ̀) Torí náà, ó hàn gbangba pé ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́.

2. Kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀?

2 Kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Gbólóhùn náà “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀” fara hàn nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgbọ̀n (230) ìgbà. Àmọ́ kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Bí “Àlàyé Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì” yìí ṣe sọ, ó ń tọ́ka sí “ìfẹ́ tí ẹni tó ṣeé fọkàn tán, tó jẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin àti adúrótini ní sáwọn èèyàn. Bíbélì sábà máa ń lò ó fún ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwa èèyàn, àmọ́ ó tún jẹ́ ìfẹ́ táwa èèyàn ní sí èèyàn bíi tiwa.” Jèhófà ni àpẹẹrẹ tó dáa jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ ká fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò bí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwa èèyàn. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a máa jíròrò bí àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe lè tè lé àpẹẹrẹ rẹ̀, ká sì máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn.

‘ÌFẸ́ JÈHÓFÀ TÍ KÌ Í YẸ̀ PỌ̀ GIDIGIDI’

3. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí Mósè mọ irú ẹni tóun jẹ́?

3 Kò pẹ́ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, Jèhófà sọ orúkọ rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ fún Mósè. Ó sọ pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini.” (Ẹ́kís. 34:6, 7) Àwọn ànímọ́ tí Jèhófà sọ fún Mósè pé òun ní yìí jẹ́ kó mọ̀ pé Ọlọ́run tí ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀ lòun jẹ́. Torí náà, kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀?

4-5. (a) Irú ẹni wo ni Jèhófà sọ pé òun jẹ́? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

4 Nígbà tí Jèhófà ń sọ irú ẹni tí òun jẹ́, kò kàn sọ pé òun ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ nìkan, àmọ́ ohun tó sọ ni pé ‘ìfẹ́ òun tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi.’ Gbólóhùn yìí tún fara hàn níbi mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì. (Nọ́ń. 14:18; Neh. 9:17; Sm. 86:15; 103:8; Jóẹ́lì 2:13; Jónà 4:2) Kò sẹ́ni tá a máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún àfi Jèhófà nìkan ṣoṣo. Ẹ ò rí i pé bí Jèhófà ṣe tẹnu mọ́ ànímọ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run tí ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀ lòun jẹ́. Torí náà, ó dájú pé ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì lójú ẹ̀.b Abájọ tí Ọba Dáfídì fi sọ nípa Jèhófà pé: “Jèhófà, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga dé ọ̀run . . . Ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ mà ṣeyebíye o, Ọlọ́run! Abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ ni àwọn ọmọ èèyàn fi ṣe ibi ààbò.” (Sm. 36:5, 7) Bíi ti Dáfídì, ṣé àwa náà mọyì ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀?

5 Ká lè túbọ̀ lóye ohun tí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè méjì yìí yẹ̀ wò: Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí? Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀?

ÀWỌN WO NI JÈHÓFÀ MÁA Ń FI ÌFẸ́ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN SÍ?

6. Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí?

6 Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí? Bíbélì sọ pé ọ̀pọ̀ nǹkan la lè nífẹ̀ẹ́, irú bí “iṣẹ́ àgbẹ̀,” “wáìnì àti òróró,” “ẹ̀kọ́,” “ìmọ̀,” “ọgbọ́n” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (2 Kíró. 26:10; Òwe 12:1; 21:17; 29:3) Àmọ́ ṣá o, a kì í ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sáwọn nǹkan yìí, àwa èèyàn nìkan ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ yìí hàn sí àfi àwọn tó bá ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Torí náà, Ọlọ́run máa ń jẹ́ olóòótọ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn ohun rere kan wà tó fẹ́ ṣe fún wọn, ìgbà gbogbo lá sì máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn.

Àwọn èèyàn lọ́mọdé lágbà láti ibi gbogbo láyé. Fọ́tò: Ohun tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. 1. Oòrùn àti òjò. 2. Òdòdó, ewéko àti igi. 3. Ó fún wa ní Jèsù ọmọ rẹ̀ tó kú nítorí wa.

Jèhófà ń pèsè ọ̀pọ̀ ohun rere fún aráyé títí kan àwọn tí kò jọ́sìn rẹ̀(Wo ìpínrọ̀ 7)c

7. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn?

7 Gbogbo aráyé ni Jèhófà ti fi ìfẹ́ hàn sí. Jésù sọ fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nikodémù pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ [aráyé] gan-an débi pé ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí gbogbo ẹni tó bá ń ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”​—Jòh. 3:1, 16; Mát. 5:44, 45.

Fọ́tò: 1. Ọba Dáfídì ń fi háàpù kọrin. 2. Wòlíì Dáníẹ́lì ṣí àkájọ ìwé, ó sì ń kà á.

Àwọn ohun tí Ọba Dáfídì àti wòlíì Dáníẹ́lì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé ìdí tí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ (Wo ìpínrọ̀ 8-9)

8-9. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

8 Bá a ṣe sọ níṣàájú, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nìkan ló máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí. Ohun tí Ọba Dáfídì àti wòlíì Dáníẹ́lì sọ jẹ́ ká mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé: “Máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn nìṣó sí àwọn tó mọ̀ ọ́.” “Àmọ́ ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wà títí ayé sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.” Dáníẹ́lì ní tiẹ̀ sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, [ẹni tó] ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (Sm. 36:10; 103:17; Dán. 9:4) Bí àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, ìdí tí Jèhófà ṣe ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni pé wọ́n mọ̀ ọ́n, wọ́n bẹ̀rù rẹ̀, wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Torí náà, àwọn tó bá ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó tọ́ nìkan ló máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí.

9 Kó tó di pé a di ìránṣẹ́ Jèhófà la ti ń gbádùn ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí aráyé. (Sm. 104:14) Àmọ́, lẹ́yìn tá a di ìránṣẹ́ rẹ̀, a wá ń gbádùn ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Kódà, Jèhófà fi dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú pé: “Ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ.” (Àìsá. 54:10) Dáfídì rí bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ yìí hàn sí òun, ó sọ pé: “Jèhófà máa ṣìkẹ́ ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀.” (Sm. 4:3) Torí náà, kí ló yẹ ká ṣe bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń bójú tó wa lọ́nà àrà ọ̀tọ̀? Onísáàmù sọ pé: “Ẹni tó bá gbọ́n yóò kíyè sí àwọn nǹkan yìí, yóò sì fara balẹ̀ kíyè sí àwọn ohun tí Jèhófà ṣe nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.” (Sm. 107:43) Jèhófà fẹ́ ká fi ìmọ̀ràn yìí sọ́kàn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò ọ̀nà mẹ́ta táwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbà ń jàǹfààní ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.

BÁWO LA ṢE LÈ JÀǸFÀÀNÍ ÌFẸ́ JÈHÓFÀ TÍ KÌ Í YẸ̀?

Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà dá yàtọ̀ láàárín àwọn èèyàn yòókù. Fọ́tò: Ohun tó fi hàn pé Jèhófà ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí wa. 1. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run jẹ́ ká mọ̀ pé ìfẹ́ Jèhófà wà títí láé. 2. Arábìnrin kan ń gbàdúrà kó lè rí ìdáríjì gbà. 3. Bí odi ṣe máa ń dáàbò bo ìlú kan, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà kì í jẹ́ kí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ bà jẹ́. Èyí fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn. 4. Oòrun àti òjò. 5. Òdòdó, ewéko àti igi. 6. Ìràpadà.

Jèhófà máa ń ṣe ọ̀pọ̀ ohun rere fáwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 10-16)d

10. Báwo ni ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ tó wà títí láé ṣe ń ṣe wá láǹfààní? (Sáàmù 31:7)

10 Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ wà títí láé. Ìgbà mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ni gbólóhùn náà ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ wà títí láé fara hàn nínú Sáàmù kẹrìndínlógóje (136), ìyẹn sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an. Ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú orí yìí kà pé: “Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere; ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.” (Sm. 136:1) Ní ẹsẹ kejì sí kẹrìndínlọ́gbọ̀n (26), gbólóhùn náà “nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé” fara hàn ní ẹsẹ kọ̀ọ̀kan. Bá a ṣe ń ka àwọn ẹsẹ tó kù nínú Sáàmù kẹrìndínlógóje (136) yìí, ó yà wá lẹ́nu bá a ṣe ń rí i pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn. Gbólóhùn náà “nítorí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé” fi dá wa lójú pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwa èèyàn rẹ̀ kì í yí pa dà. Ẹ ò rí i bó ṣe múnú wa dùn tó pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń nífẹ̀ẹ́ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀! Kì í fi àwọn tó ń sìn ín sílẹ̀, ńṣe ló máa ń dúró tì wọ́n pàápàá nígbà ìṣòro. Àǹfààní tó ń ṣe wá: Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ò fi wá sílẹ̀ ń jẹ́ ká máa láyọ̀, ó sì ń jẹ́ ká lókun láti máa fara da àwọn ìṣòro wa, ká sì máa rìn ní ọ̀nà ìyè.​—Ka Sáàmù 31:7.

11. Bí Sáàmù 86:5 ṣe sọ, kí ló máa ń mú kí Jèhófà dárí jini?

11 Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ló ń mú kó dárí jì wá. Tí Jèhófà bá rí i pé ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ronú pìwà dà, tí kò sì pa dà dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́, ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ máa mú kó dárí ji ẹni náà. Dáfídì sọ nípa Jèhófà pé: “Kò fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa hùwà sí wa, kò sì fi ìyà tó yẹ àṣìṣe wa jẹ wá.” (Sm. 103:8-11) Dáfídì mọ bó ṣe máa ń rí tí ìbànújẹ́ bá dorí ẹni kodò torí ẹ̀rí ọkàn tó ń dáni lẹ́bi. Àmọ́ ó tún mọ̀ pé Jèhófà “ṣe tán láti dárí jini.” Kí ló ń mú kí Jèhófà máa dárí jini? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú Sáàmù 86:5. (Kà á.) Bí Dáfídì ṣe sọ nínú àdúrà rẹ̀ ló rí, Jèhófà máa ń dárí jini torí pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí gbogbo àwọn tó ń ké pè é pọ̀ gidigidi.

12-13. Tí ẹ̀ṣẹ̀ tí o dá sẹ́yìn bá ń mú kó o máa dá ara rẹ lẹ́bi, kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

12 Tá a bá dẹ́ṣẹ̀, ó yẹ ká kábàámọ̀ ohun tá a ṣe, kò sì sóhun tó burú níbẹ̀. Ìyẹn máa jẹ́ ká ronú pìwà dà, ká sì gbégbèésẹ̀ láti ṣàtúnṣe. Àmọ́, àwọn kan lára ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣì máa ń dára wọn lẹ́bi torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá ṣẹ́yìn. Ọkàn wọn tó ṣì ń dá wọn lẹ́bi ń mú kí wọ́n rò pé Jèhófà ò lè dárí ji àwọn láé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ronú pìwà dà tí wọn ò sì dá ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. Tó bá jẹ́ pé bó ṣe rí fún ìwọ náà nìyẹn, mọ̀ dájú pé Ọlọ́run máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹ, á sì mú kó o borí èrò náà.

13 Àǹfààní tó ń ṣe wá: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ aláìpé, a ṣì lè máa fi ayọ̀ sin Jèhófà pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. Èyí ṣeé ṣe torí pé ‘ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.’ (1 Jòh. 1:7) Tí àwọn àṣìṣe ẹ bá ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ, rántí pé Jèhófà ṣe tán láti dárí jì ẹ́ tó o bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Wo ohun tí Dáfídì sọ tó fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ló ń mú kí Ọlọ́run dárí jini. Ó sọ pé: “Bí ọ̀run ṣe ga ju ayé, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ní sí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ ṣe ga. Bí yíyọ oòrùn ṣe jìnnà sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jìnnà sí wa.” (Sm. 103:11, 12) Ká sòótọ́, Jèhófà ṣe tán láti “dárí jini fàlàlà.”​—Àìsá. 55:7

14. Báwo ni Dáfídì ṣe ṣàlàyé bí ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ṣe ń dáàbò bò wá?

14 Ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ kò ní jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà bà jẹ́. Nínú àdúrà kan tí Dáfídì gbà sí Jèhófà, ó sọ pé: “Ìwọ ni ibi ìfarapamọ́ mi; wàá dáàbò bò mí nínú wàhálà. Wàá fi igbe ayọ̀ ìgbàlà yí mi ká. . . . Ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ yí ẹni tó gbẹ́kẹ̀ lé E ká.” (Sm. 32:7, 10) Bí wọ́n ṣe máa ń mọ odi yí ìlú kan ká láyé àtijọ́ láti dáàbò bo àwọn ará ìlú, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ yí wa ká, kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Yàtọ̀ síyẹn, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fà wá mọ́ra.​—Jer. 31:3.

15. Báwo ni ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ṣe dà bí ibi ààbò?

15 Dáfídì lo àfiwé míì láti fi ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa ń dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀. Ó sọ pé: “Ọlọ́run ni ibi ààbò mi, Ọlọ́run tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi.” Dáfídì tún sọ nípa Jèhófà pé: “Òun ni ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ àti ibi ààbò mi, ibi gíga mi tó láàbò àti olùgbàlà mi, apata mi àti Ẹni tí mo fi ṣe ibi ààbò.” (Sm. 59:17; 144:2) Kí nìdí tí Dáfídì ṣe fi ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ wé ibi ààbò àti odi ààbò? Ibi yóówù ká máa gbé láyé, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, ó máa dáàbò bò wá ní gbogbo ọ̀nà kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe tó dáa tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Ohun kan náà ni Jèhófà fi dá wa lójú nínú Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún (91). Ẹni tó kọ sáàmù yẹn sọ pé: “Màá sọ fún Jèhófà pé: ‘Ìwọ ni ibi ààbò mi àti odi ààbò mi.’ ” (Sm. 91:1-3, 9, 14) Mósè náà lo àfiwé kan tó jọ ọ́ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ibi ààbò. (Sm. 90:1, àlàyé ìsàlẹ̀) Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí àkókò ikú Mósè ti sún mọ́lé, ó lo àfiwé míì tó ń fini lọ́kàn balẹ̀. Ó ní: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ààbò láti ìgbà àtijọ́, ọwọ́ ayérayé rẹ̀ wà lábẹ́ rẹ.” (Diu. 33:27) Kí ni gbólóhùn náà “ọwọ́ ayérayé rẹ̀ wà lábẹ́ rẹ” jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?

16. Ọ̀nà méjì wo ni Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́? (Sáàmù 136:23)

16 Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa dáàbò bò wá, ọkàn wa máa balẹ̀. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ìrẹ̀wẹ̀sì lè mú wa débi tá ò fi ní lókun mọ́. Nírú àwọn àsìkò bẹ́ẹ̀, kí ni Jèhófà máa ń ṣe fún wa? (Ka Sáàmù 136:23.) Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, ó máa rọra fi apá rẹ̀ gbé wa dìde, kò sì ní jẹ́ ká rẹ̀wẹ̀sì mọ́. (Sm. 28:9; 94:18) Àǹfààní tó ń ṣe wá: Bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn máa ń jẹ́ ká rántí pé ọ̀nà méjì ló ń gbà ràn wá lọ́wọ́. Àkọ́kọ́, ibi yòówù ká máa gbé, a mọ̀ pé Jèhófà á máa dáàbò bò wá. Ìkejì, Bàbá wa ọ̀run ń fìfẹ́ bójú tó wa.

Ó DÁJÚ PÉ ỌLỌ́RUN Á MÁA FI ÌFẸ́ RẸ̀ TÍ KÌ Í YẸ̀ HÀN SÍ WA

17. Kí ló dá wa lójú nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Jèhófà fi ń hàn sí wa? (Sáàmù 33:18-22)

17 Látinú ohun tá a ti jíròrò, a ti rí i pé tá a bá kojú ìṣòro, Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ má bàa bà jẹ́. (2 Kọ́r. 4:7-9) Wòlíì Jeremáyà sọ pé: “Nítorí ìfẹ́ Jèhófà tí kì í yẹ̀ ni ò jẹ́ ká ṣègbé, nítorí àánú rẹ̀ kò ní dópin láé.” (Ìdárò 3:22) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà á máa fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa nìṣó, torí onísáàmù fi dá wa lójú pé, “ojú Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀, àwọn tó ń dúró de ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.”​—Ka Sáàmù 33:18-22.

18-19. (a) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

18 Kí lohun tó yẹ ká fi sọ́kàn? Kó tó di pé a di ìránṣẹ́ Jèhófà la ti ń gbádùn ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí aráyé. Àmọ́, lẹ́yìn tá a di ìránṣẹ́ rẹ̀, a wá ń gbádùn ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀. Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa yìí ló jẹ́ kó fà wá mọ́ra, tó sì ń mú kó máa dáàbò bò wá. Jèhófà á máa wà pẹ̀lú wa nígbà gbogbo, á sì mú àwọn ìlérí tó ṣe fún wa ṣẹ. Ẹ ò rí i pé Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ ọ̀rẹ́ òun títí láé! (Sm. 46:1, 2, 7) Torí náà, ìṣòro yòówù ká máa kojú, Jèhófà á fún wa lókun ká lè jẹ́ olóòótọ́.

19 A ti rí bí Jèhófà ṣe fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ohun tó ń fẹ́ káwa náà máa ṣe ni pé ká máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sáwọn èèyàn. Báwo la ṣe máa fi ìfẹ́ yìí hàn? A máa jíròrò kókó pàtàkì yìí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀?

  • Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn sí wa?

ORIN 136 “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Èrè” Látọ̀dọ̀ Jèhófà

a Kí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? Àwọn wo ni Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí, báwo sì ni àwọn tó fi ìfẹ́ yìí hàn sí ṣe ń jàǹfààní rẹ̀? A máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ méjì àkọ́kọ́ tá a ti máa jíròrò ànímọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí.

b Nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì míì, a tún sọ̀rọ̀ nípa bí ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ ṣe pọ̀ gidigidi.​—Wo Nehemáyà 13:22; Sáàmù 69:13; 106:7; àti Ìdárò 3:32.

c ÀWÒRÁN: Gbogbo aráyé ni Jèhófà ń fi ìfẹ́ hàn sí títí kan àwa ìránṣẹ́ rẹ̀. Àwọn àwòrán tó wà lókè àwọn èèyàn yẹn ń fi ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa hàn. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lára nǹkan tí Ọlọ́run fún wa yìí ni Jésù ọmọ rẹ̀ tó kú nítorí wa.

d ÀWÒRÁN: Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn sáwọn tó di ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Yàtọ̀ sí pé àwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbádùn ìfẹ́ tó ń fi hàn sí gbogbo aráyé, a tún ń gbádùn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ń fi hàn sí wa. Àwọn kan lára nǹkan tá à ń gbádùn ló wà nínú àwọn àwòrán yẹn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́