ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Sámúẹ́lì

      • Àwọn tí Dáfídì ṣẹ́gun (1-14)

      • Ìjọba Dáfídì (15-18)

2 Sámúẹ́lì 8:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:2, 3; 2Sa 21:15
  • +1Kr 18:1

2 Sámúẹ́lì 8:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “owó òde.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 24:17; Ond 3:29; 1Sa 14:47; Sm 60:8
  • +Di 23:3-6
  • +2Ọb 3:4; 1Kr 18:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2005, ojú ìwé 17

2 Sámúẹ́lì 8:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 10:6; 1Ọb 11:23; Sm 60:àkọlé
  • +Jẹ 15:18; Ẹk 23:31; 1Ọb 4:21; 1Kr 18:3, 4

2 Sámúẹ́lì 8:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pátì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:16; Sm 20:7; 33:17

2 Sámúẹ́lì 8:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 7:8
  • +1Kr 18:5, 6

2 Sámúẹ́lì 8:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “owó òde.”

  • *

    Tàbí “gba Dáfídì là.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:24; 2Sa 8:14

2 Sámúẹ́lì 8:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “apata ribiti.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 18:7, 8

2 Sámúẹ́lì 8:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 14:28
  • +1Kr 18:9-11

2 Sámúẹ́lì 8:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 6:19; 1Ọb 7:51; 1Kr 22:14; 26:27

2 Sámúẹ́lì 8:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 8:2
  • +2Sa 8:1
  • +1Sa 30:18
  • +2Sa 8:7

2 Sámúẹ́lì 8:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 18:12, 13; Sm 60:àkọlé

2 Sámúẹ́lì 8:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gba Dáfídì là.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:23, 26; 27:29, 37; Nọ 24:18
  • +Sm 60:12

2 Sámúẹ́lì 8:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:3, 5
  • +1Ọb 3:6
  • +1Kr 18:14-17

2 Sámúẹ́lì 8:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 20:23; 1Kr 11:6
  • +2Sa 20:24; 1Ọb 4:3

2 Sámúẹ́lì 8:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:27; 1Kr 6:8; 24:3

2 Sámúẹ́lì 8:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àlùfáà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 23:20; 1Ọb 1:44; 2:35
  • +2Sa 15:18; 20:7

Àwọn míì

2 Sám. 8:1Joṣ 13:2, 3; 2Sa 21:15
2 Sám. 8:11Kr 18:1
2 Sám. 8:2Nọ 24:17; Ond 3:29; 1Sa 14:47; Sm 60:8
2 Sám. 8:2Di 23:3-6
2 Sám. 8:22Ọb 3:4; 1Kr 18:2
2 Sám. 8:32Sa 10:6; 1Ọb 11:23; Sm 60:àkọlé
2 Sám. 8:3Jẹ 15:18; Ẹk 23:31; 1Ọb 4:21; 1Kr 18:3, 4
2 Sám. 8:4Di 17:16; Sm 20:7; 33:17
2 Sám. 8:5Ais 7:8
2 Sám. 8:51Kr 18:5, 6
2 Sám. 8:6Di 7:24; 2Sa 8:14
2 Sám. 8:71Kr 18:7, 8
2 Sám. 8:92Ọb 14:28
2 Sám. 8:91Kr 18:9-11
2 Sám. 8:11Joṣ 6:19; 1Ọb 7:51; 1Kr 22:14; 26:27
2 Sám. 8:122Sa 8:2
2 Sám. 8:122Sa 8:1
2 Sám. 8:121Sa 30:18
2 Sám. 8:122Sa 8:7
2 Sám. 8:131Kr 18:12, 13; Sm 60:àkọlé
2 Sám. 8:14Jẹ 25:23, 26; 27:29, 37; Nọ 24:18
2 Sám. 8:14Sm 60:12
2 Sám. 8:152Sa 5:3, 5
2 Sám. 8:151Ọb 3:6
2 Sám. 8:151Kr 18:14-17
2 Sám. 8:162Sa 20:23; 1Kr 11:6
2 Sám. 8:162Sa 20:24; 1Ọb 4:3
2 Sám. 8:172Sa 15:27; 1Kr 6:8; 24:3
2 Sám. 8:182Sa 23:20; 1Ọb 1:44; 2:35
2 Sám. 8:182Sa 15:18; 20:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Sámúẹ́lì 8:1-18

Sámúẹ́lì Kejì

8 Nígbà tó yá, Dáfídì ṣẹ́gun àwọn Filísínì,+ ó borí wọn,+ Dáfídì sì gba Metegi-ámà lọ́wọ́ àwọn Filísínì.

2 Ó ṣẹ́gun àwọn ọmọ Móábù,+ ó dá wọn dùbúlẹ̀, ó sì fi okùn wọ̀n wọ́n. Ó ní kí wọ́n pa àwọn tó wà níbi tí okùn ìwọ̀n méjì gùn dé, àmọ́ kí wọ́n dá àwọn tó wà níbi okùn ìwọ̀n kan sí.+ Àwọn ọmọ Móábù di ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀*+ wá.

3 Dáfídì ṣẹ́gun Hadadésà ọmọ Réhóbù ọba Sóbà+ bí ó ṣe ń lọ láti gba àkóso rẹ̀ pa dà ní odò Yúfírétì.+ 4 Dáfídì gba ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje (1,700) agẹṣin àti ọ̀kẹ́ kan (20,000) ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn lọ́wọ́ rẹ̀. Dáfídì sì já iṣan ẹsẹ̀* gbogbo àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ogun, àmọ́ ó dá ọgọ́rùn-ún (100) lára àwọn ẹṣin+ náà sí.

5 Nígbà tí àwọn ará Síríà tó wà ní Damásíkù+ wá ran Hadadésà ọba Sóbà lọ́wọ́, Dáfídì pa ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) lára àwọn ará Síríà+ náà. 6 Lẹ́yìn náà, Dáfídì fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Damásíkù ní Síríà, àwọn ará Síríà wá di ìránṣẹ́ Dáfídì, wọ́n sì ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá. Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+ 7 Láfikún sí i, Dáfídì gba àwọn apata* wúrà tó wà lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ Hadadésà, ó sì kó wọn wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 8 Ọba Dáfídì kó bàbà tó pọ̀ gan-an láti Bétà àti Bérótáì, àwọn ìlú Hadadésà.

9 Lásìkò yìí, Tóì ọba Hámátì+ gbọ́ pé Dáfídì ti ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadésà.+ 10 Torí náà, Tóì rán Jórámù ọmọkùnrin rẹ̀ sí Ọba Dáfídì pé kí ó lọ béèrè àlàáfíà rẹ̀, kí ó sì bá a yọ̀ torí pé ó ti bá Hadadésà jà, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ (nítorí Hadadésà ti máa ń bá Tóì jà tẹ́lẹ̀), ó sì kó àwọn ohun èlò fàdákà, ohun èlò wúrà àti ohun èlò bàbà wá. 11 Ọba Dáfídì yà wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà bó ṣe ya fàdákà àti wúrà tó kó lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣẹ́gun+ sí mímọ́: 12 ó kó wọn láti Síríà àti Móábù,+ látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, àwọn Filísínì+ àti àwọn ọmọ Ámálékì+ àti látinú ẹrù ogun Hadadésà+ ọmọ Réhóbù ọba Sóbà. 13 Òkìkí Dáfídì túbọ̀ kàn nígbà tí ó pa dà láti ibi tó ti lọ pa ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) lára àwọn ọmọ Édómù ní Àfonífojì Iyọ̀.+ 14 Ó fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí Édómù. Gbogbo Édómù ni ó fi àwọn àwùjọ ọmọ ogun àdádó sí, gbogbo àwọn ọmọ Édómù sì di ìránṣẹ́ Dáfídì.+ Jèhófà sì ń jẹ́ kí Dáfídì ṣẹ́gun* ní ibikíbi tó bá lọ.+

15 Dáfídì ń jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì,+ Dáfídì ń dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó sì ń ṣe òdodo+ sí gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀.+ 16 Jóábù+ ọmọ Seruáyà ni olórí àwọn ọmọ ogun, Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù sì ni akọ̀wé ìrántí. 17 Sádókù+ ọmọ Áhítúbù àti Áhímélékì ọmọ Ábíátárì ni àlùfáà, Seráyà sì ni akọ̀wé. 18 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ni olórí àwọn Kérétì àti àwọn Pẹ́lẹ́tì.+ Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì di olórí àwọn òjíṣẹ́.*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́