ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp22 No. 1 ojú ìwé 8-9
  • 2 | Má Ṣe Gbẹ̀san

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2 | Má Ṣe Gbẹ̀san
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ:
  • Ohun Tó Túmọ̀ Sí:
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígbẹ̀san?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Táwọn Èèyàn Bá Ṣe Ohun Tó Dùn Ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Inú Mi Kì Í Dùn, Mo Sì Máa Ń Hùwà Ìpáǹle
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
  • Ẹ̀san Ha Ṣàìtọ́ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
wp22 No. 1 ojú ìwé 8-9
Inú ń bí àwọn ọkùnrin méjì tó jókòó sórí ẹ̀ka igi kan. Àwọn méjèèjì kọjú síra, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń gé ẹ̀ka igi tó jókòó lé.

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

2 | Má Ṣe Gbẹ̀san

Ohun Tí Bíbélì Sọ:

“Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni. . . . Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn. Ẹ má ṣe fúnra yín gbẹ̀san, . . . nítorí ó ti wà lákọsílẹ̀ pé: ‘“Tèmi ni ẹ̀san; màá gbẹ̀san,” ni Jèhófà wí.’”​—RÓÒMÙ 12:​17-19.

Ohun Tó Túmọ̀ Sí:

Ká sòótọ́, inú lè bí wa tẹ́nì kan bá ṣe ohun tí ò dáa sí wa, àmọ́ Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ ká máa mú sùúrù, torí pé kò ní pẹ́ fòpin sí ìwà ibi àti ìrẹ́jẹ.​—Sáàmù 37:​7, 10.

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:

Táwa èèyàn aláìpé bá ń gbẹ̀san, ìyẹn ò ní paná ìkórìíra ṣe lá túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Torí náà, tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ ẹ́ tàbí tó ṣàìdáa sí ẹ, má ṣe gbẹ̀san, má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà ká ẹ lára jù, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni kó o fi sùúrù bá ẹni náà sọ̀rọ̀. Nígbà míì, ohun tó máa dáa jù ni pé ká gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. (Òwe 19:11) Àmọ́, tó o bá rí i pé o ò lè gbé e kúrò lọ́kàn, o lè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà. Bí àpẹẹrẹ, táwọn ọ̀daràn bá gbéjà kò ẹ́, o lè fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá tàbí àwọn aláṣẹ míì létí.

Àkóbá kékeré kọ́ lẹni tó bá ń gbẹ̀san máa ń ṣe fún ara ẹ̀

Ká sọ pé kò sí bẹ́ ẹ ṣe lè yanjú ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí kò la ariwo lọ ńkọ́? Àbí o ti ṣe gbogbo nǹkan tó yẹ kó o ṣe láti fi sùúrù yanjú ọ̀rọ̀ náà? Má ṣe gbẹ̀san. Torí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lọ̀rọ̀ náà á wá burú sí i. Dípò tí wàá fi gbẹ̀san, ńṣe ni kó o paná ìkórìíra. Ohun tó máa dáa ni pé kó o fi ọ̀rọ̀ náà lé Ọlọ́run lọ́wọ́ kó lè bá ẹ yanjú ẹ̀. “Gbẹ́kẹ̀ lé e, yóò sì gbé ìgbésẹ̀ nítorí rẹ.”​—Sáàmù 37:​3-5.

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ẹnì Kan—ADRIÁN

Kì Í Gbẹ̀san Mọ́

Adrián.

Nígbà tí Adrián wà lọ́mọdé, ó máa ń bínú gan-an, ó sì máa ń ja ìjà ìgboro. Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ ẹ́ pẹ́rẹ́n, á rí i pé òun gbẹ̀san. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ja ìjà ìgboro, tí màá fara gbọta ìbọn, tí ẹ̀jẹ̀ á sì bò mí, débi pé ńṣe làwọn èèyàn á rò pé mo ti kú.”

Nígbà tí Adrián wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún (16), ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi lọ, mo rí i pé ó yẹ kí n ṣàwọn àyípadà kan nínú ìgbé ayé mi.” Ó yẹ kó jáwọ́ nínú ìwà ọ̀daràn kó má sì kórìíra àwọn èèyàn mọ́. Ohun tó wà ní Róòmù 12:​17-19 ló wọ̀ ọ́ lọ́kàn jù, èyí tó sọ pé ká má ṣe máa gbẹ̀san. Adrián sọ pé: “Mo wá gbà pé tí àkókò bá tó lójú Jèhófà, ó máa fòpin sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ lọ́nà tó dáa jù lọ. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo wá dẹni tó jáwọ́ nínú ìwà ọ̀daràn.”

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan táwọn àti Adrián jọ máa ń bára wọn jà tẹ́lẹ̀ gbéjà kò ó. Ọ̀gá wọn wá pariwo mọ́ ọn pé: “Ọwọ́ bà ẹ́ lónìí, ó yá jẹ́ ká jà!” Adrián sọ pé: “Ó ń ṣe mí bíi pé kí n bá wọn jà.” Àmọ́, ó fọkàn gbàdúrà pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́, ó sì kúrò níbẹ̀.

Adrián ń bá ọ̀rọ̀ ẹ̀ lọ pé: “Lọ́jọ́ kejì, èmi àti ọ̀gá wọn tún pàdé ara wa. Bí mo ṣe rí i, inú bí mi gan-an, ó sì ń ṣe mí bíi pé kí n bá a jà, àmọ́ ńṣe ni mo tún fọkàn gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n lè kó ara mi níjàánu. Ó yà mí lẹ́nu pé ńṣe ni ọ̀dọ́kùnrin náà sún mọ́ mi tó sì sọ pé: ‘Jọ̀ọ́, má bínú torí ohun tó ṣẹlẹ̀ lánàá. Wò ó, ó wù mí kí n máa hùwà bíi tìẹ. Èmi náà fẹ́ kẹ́kọ́ọ̀ Bíbélì.’ Inú mi dùn gan-an pé mi ò bá a jà lọ́jọ́ yẹn! Bá a ṣe jọ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.”

O lè ka apá tó kù nínú ìtàn Adrián nínú Ilé Ìṣọ́ No. 5 2016, ojú ìwé 14 àti 15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́