ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp25 No. 1 ojú ìwé 6-8
  • Ṣé Àwa Èèyàn Lè Fòpin sí Ogun àti Rògbòdìyàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àwa Èèyàn Lè Fòpin sí Ogun àti Rògbòdìyàn?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • WỌ́N FẸ́ MÚ KÍ ỌRỌ̀ AJÉ DÁA SÍ I
  • ÀDÉHÙN ÀLÀÁFÍÀ
  • WỌ́N FẸ́ DÍN OHUN ÌJÀ KÙ
  • ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ Ń GBÈJÀ ARA WỌN
  • Will Diplomacy Bring World Peace?
    Jí!—2004
  • Kí Ló Máa Kẹ́yìn Ogun?
    Jí!—1999
  • Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà Láyé?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìgbà Wo Ni Gbogbo Ogun Yìí Máa Dópin?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
wp25 No. 1 ojú ìwé 6-8

Ṣé Àwa Èèyàn Lè Fòpin sí Ogun àti Rògbòdìyàn?

Oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń dá ìjà sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn. Àwọn olóṣèlú máa ń bára wọn jà, àwọn kan máa ń jà torí owó, àwọn míì sì máa ń jà torí pé wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn fojú pa wọ́n rẹ́ láwùjọ. Àwọn kan tún máa ń bá ara wọn jà torí ilẹ̀ àtàwọn ohun àmúṣọrọ̀ míì. Ọ̀pọ̀ ibi tí rògbòdìyàn ti ń ṣẹlẹ̀ ló jẹ́ pé ìjà ẹ̀sìn àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ló fà á, ó sì ti pẹ́ tí wọ́n ti wà lẹ́nu ẹ̀. Kí làwọn èèyàn ń ṣe kí wọ́n lè fòpin sí rògbòdìyàn àti ogun? Ṣé wọ́n máa ṣàṣeyọrí lóòótọ́?

Àjákù fọ́tò àwọn òṣìṣẹ́ tó ń kọ́lé, wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ náà.

Drazen_/​E+ via Getty Images

WỌ́N FẸ́ MÚ KÍ ỌRỌ̀ AJÉ DÁA SÍ I

Àfojúsùn: Wọ́n fẹ́ kí nǹkan túbọ̀ dáa fáwọn èèyàn. Tí wọ́n bá sì rí i ṣe, ó máa dín ìṣẹ́ àti òṣì kù tàbí kó má tiẹ̀ sí mọ́. Torí ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ tó wà láàárín àwọn tó lówó gan-an àtàwọn tálákà paraku jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó sábà máa ń fa ogun àti rògbòdìyàn.

Ìṣòro: Ìyẹn máa gba pé kí ìjọba yí àwọn nǹkan tí wọ́n ń náwó lé lórí pa dà. Bí àpẹẹrẹ lọ́dún 2022, wọ́n fojú bù ú pé ó ju bílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n owó dọ́là ilẹ̀ Amẹ́ríkà ($34.1 billion) tí wọ́n ná láti pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn fáwọn ará ìlú. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, iye tí wọ́n ná sórí ogun lọ́dún yẹn ju tírílíọ̀nù mẹ́jọ owó dọ́là ilẹ̀ Ámẹríkà ($8.525 trillion). Ẹ ò rí i pé gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ niye tí wọ́n ná sórí ogun fi ju iye tí wọ́n ná sórí ohun amáyédẹrùn lọ!

“Òbítíbitì owó là ń ná láti paná ogun àti rògbòdìyàn, wàhálà tó wà níbẹ̀ sì pọ̀ gan-an. Àmọ́, owó tá à ń ná sórí àwọn nǹkan tó máa mú káyé dẹrùn kí àlàáfíà sì jọba nílùú ò tó nǹkan rárá.”—António Guterres, akọ̀wé àgbà fún Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé.

Ohun tí Bíbélì sọ: Ìjọba àtàwọn àjọ kan lágbára láti ran àwọn tálákà lọ́wọ́, àmọ́ wọn ò ní lè mú ìṣẹ́ àti òṣì kúrò pátápátá.–Diutarónómì 15:11; Mátíù 26:11.

Àjákù fọ́tò àwọn méjì tó ń bọ ara wọn lọ́wọ́ lẹ́yìn àdéhùn kan.

ÀDÉHÙN ÀLÀÁFÍÀ

Àfojúsùn: Àwọn orílẹ̀-èdè kan máa ń ṣe ìpàdé kí wọ́n lè jíròrò bí wọ́n á ṣe dènà ìṣòro tàbí kí wọ́n lè yanjú ìṣòro tó wà láàárín wọn ní ìtùnbí-ìnùbí. Wọ́n á sì ṣàdéhùn lórí ohun tó máa ṣe tọ̀tún-tòsì wọn láǹfààní.

Ìṣòro: Àwọn kan lára wọn lè má wá sípàdé náà, àwọn kan lè má ṣe ohun tí wọ́n fẹnu kò lé lórí. Àwọn míì tiẹ̀ lè má tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn rárá. Ká tiẹ̀ wá sọ pé gbogbo wọn fẹnu kò, kì í pẹ́ rárá tí wọ́n fi máa ń yẹ àdéhùn.

“Àdéhùn àlàáfíà táwọn orílẹ̀-èdè máa ń ṣe kì í sábà ṣiṣẹ́. Dípò kó fòpin sí ogun, ó lè dá kún wàhálà tó wà nílẹ̀, kó sì mú kó le ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.”—Raymond F. Smith, American Diplomacy.

Ohun tí Bíbélì sọ: Bíbélì sọ pé ká “máa wá àlàáfíà.” (Sáàmù 34:14) Àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ ‘aláìṣòótọ́, kìígbọ́-kìígbà àti ọ̀dàlẹ̀.’ (2 Tímótì 3:1-4) Táwọn olóṣèlú kan tó ní èrò tó dáa lọ́kàn bá tiẹ̀ fẹ́ yanjú ìṣòro, àwọn tó ní ìwà àti ìṣe yìí ò ní jẹ́ kó ṣeé ṣe.

Àjákù fọ́tò ìbọn tó ti fọ́.

WỌ́N FẸ́ DÍN OHUN ÌJÀ KÙ

Àfojúsùn: Wọ́n fẹ́ dín àwọn ohun ìjà tó wà lọ́wọ́ kù tàbí kó má tiẹ̀ sóhun ìjà mọ́ rárá, ní pàtàkì àwọn ohun ìjà runlé-rùnnà, èyí tí wọ́n fi kẹ́míkà ṣe àtèyí tó máa ń fọ́n kòkòrò àrùn sínú afẹ́fẹ́.

Ìṣòro: Àwọn orílẹ̀-èdè kì í fẹ́ dín ohun ìjà wọn kù, wọn ò sì lè wà láìní ohun ìjà kankan. Wọ́n gbà pé táwọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ò ní lágbára mọ́, àwọn ò sì ní lè gbèjà ara wọn táwọn orílẹ̀-èdè míì bá gbógun jà wọ́n. Táwọn orílẹ̀-èdè ò bá tiẹ̀ ní ohun ìjà kankan mọ́, wọn ò lè yanjú ìṣòro tó ń mú káwọn èèyàn máa bá ara wọn jà.

“Lọ́dún 1991, àwọn orílẹ̀-èdè kan ṣèlérí pé àwọn máa kó ohun ìjà àwọn dà nù, àwọn máa ṣe ohun táá dín jàǹbá kù àti ohun tí kò ní jẹ́ káwọn orílẹ̀-èdè máa bá ara wọn jà. Wọ́n gbà pé èyí á jẹ́ kí ìlú rọgbọ, kí ara sì tu àwọn aráàlú. Àmọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ni kò mú ìlérí wọn ṣẹ.”—Ìwé “Securing Our Common Future: An Agenda for Disarmament.”

Ohun tí Bíbélì sọ: Bíbélì sọ pé káwọn èèyàn pa ohun ìjà wọn tì, kí wọ́n sì “fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀.” (Àìsáyà 2:4) Àmọ́ ìyẹn nìkan ò tó láti fòpin sí ogun, torí èrò burúkú tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn ló máa ń mú kí wọ́n bá ara wọn jà.—Mátíù 15:19.

Àjákù fọ́tò àwọn aláṣẹ ìjọba tí wọ́n jókòó yí tábílì ká. Gbogbo wọn ń fọwọ́ sí ìwé àdéhùn kan.

ÀWỌN ORÍLẸ̀-ÈDÈ Ń GBÈJÀ ARA WỌN

Àfojúsùn: Àwọn orílẹ̀-èdè kan pinnu pé àwọn máa pawọ́ pọ̀ bá àwọn ọ̀tá jà. Wọ́n gbà pé àwọn ọ̀tá ò ní fẹ́ bá wọn jà tí wọ́n bá rí i pé kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo làwọn fẹ́ bá jà.

Ìṣòro: Táwọn orílẹ̀-èdè kan bá lérí pé àwọn máa para pọ̀ dojú kọ ọ̀tá, ìyẹn ò sọ pé kí àlàáfíà jọba. Ìdí ni pé àwọn orílẹ̀-èdè kì í sábà mú ìlérí wọn ṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ wọn kì í sábà ṣọ̀kan lórí bí wọ́n ṣe máa bá àwọn ọ̀tá jà àti ìgbà tí wọ́n máa bá wọn jà.

“Òótọ́ ni pé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè àti Àjọ Ìṣọ̀kan Àgbáyé ti ṣiṣẹ́ kára láti mú káwọn orílẹ̀-èdè pawọ́ pọ̀ bá àwọn ọ̀tá jà kí wọ́n lè dín ogun kù, síbẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ṣì ń bá ara wọn jagun.”—“Encyclopedia Britannica.”

Ohun tí Bíbélì sọ: Táwọn èèyàn bá pawọ́ pọ̀ ṣe nǹkan, wọ́n sábà máa ń ṣàṣeyọrí. (Oníwàásù 4:12) Àmọ́, kò sí àjọ èyíkéyìí téèyàn dá sílẹ̀ tó lè jẹ́ kí aráyé ní àlàáfíà àti ààbò tó wà pẹ́ títí. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí tàbí lé ọmọ èèyàn, tí kò lè gbani là. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó pa dà sínú ilẹ̀; ọjọ́ yẹn gan-an ni èrò inú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:3, 4.

Àwọn orílẹ̀-èdè ń ṣiṣẹ́ kára láti mú kí àlàáfíà wà, síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣì ń jagun kárí ayé.

Ṣé àlàáfíà ti ń wà láyé báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

Àwọn kan gbà pé àlàáfíà ti ń wà láyé báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Wọ́n ní àwọn ogun tí wọ́n ń jà báyìí kì í pẹ́, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣọṣẹ́ tó ti tẹ́lẹ̀ àti pé iye àwọn tó ń kú sójú ogun ti dín kù gan-an sí ti tẹ́lẹ̀. Àmọ́ àwọn míì ò fara mọ́ èrò yìí, torí wọ́n gbà pé kì í ṣe àwọn tó kú sójú ogun nìkan ló yẹ ká fi díwọ̀n bí ogun ṣe ṣọṣẹ́ tó, ó ṣe tán ọ̀pọ̀ èèyàn ni ogun ti pa ní àpasáyé.

Ohun yòówù káwọn èèyàn sọ, òótọ́ kan ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn láyé ni ogun àti rògbòdìyàn ń ṣàkóbá fún, kódà àwọn tí ò sí níbi tí ogun ti ń jà pàápàá ń jìyà ẹ̀ láwọn ọ̀nà kan.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́