ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp25 No. 1 ojú ìwé 14-15
  • Ọkàn Ẹ Lè Balẹ̀ Láìka Ohun Tí Ogun àti Rògbòdìyàn Ti Fojú Ẹ Rí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọkàn Ẹ Lè Balẹ̀ Láìka Ohun Tí Ogun àti Rògbòdìyàn Ti Fojú Ẹ Rí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ogun Kì Í Bímọọre
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Máa Wá Àlàáfíà Tòótọ́, Kí O Sì Máa Lépa Rẹ̀!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Báwo ló ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run tó o bá ń jìyà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
wp25 No. 1 ojú ìwé 14-15
Bàbá àgbàlagbà kan tí apá ẹ̀ gé nígbà ogun jókòó sórí kẹ̀kẹ́ arọ, òun àti ìdílé ẹ̀ ń jẹun níta wọ́n sì ń gbádùn ara wọn.

Ọkàn Ẹ Lè Balẹ̀ Láìka Ohun Tí Ogun àti Rògbòdìyàn Ti Fojú Ẹ Rí

Gary tó ti fìgbà kan rí ṣiṣẹ́ ológun sọ pé: “Kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mi ò mọ ohun tó fà á tí wàhálà fi pọ̀ láyé, táwọn èèyàn fi ya ọ̀dájú, tí wọ́n sì ń fìyà jẹ aláìṣẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, ọkàn mi ti balẹ̀. Mo mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run máa tó tún ayé yìí ṣe, ọkàn gbogbo èèyàn á sì balẹ̀.”

Gary nìkan kọ́ ló nírú èrò yìí. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn míì tí Bíbélì ti ràn lọ́wọ́.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.”—Sáàmù 86:5.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: “Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kó dá mi lójú pé aláàánú ni Jèhófà. Ó ṣe tán láti dárí jini, torí náà mo mọ̀ pé kò ní fìyà jẹ mí torí àwọn nǹkan tí mo ti ṣe nígbà tí mo ṣì ń jagun.”—Wilmar, Colombia.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Mò ń dá ọ̀run tuntun àti ayé tuntun; àwọn ohun àtijọ́ ò ní wá sí ìrántí, wọn ò sì ní wá sí ọkàn.”—Àìsáyà 65:17.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: “Àwọn nǹkan ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tí mo rí nígbà ogun ṣì máa ń pa dà wá sọ́kàn mi, ìyẹn sì máa ń mú kí n ní ẹ̀dùn ọkàn tó lágbára gan-an. Àmọ́, ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ki n rí i pé láìpẹ́ Jèhófà ò ní jẹ́ káwọn èrò burúkú yìí wá sí mi lọ́kàn mọ́. Màá gbàgbé ẹ̀ pátápátá. Ìlérí yìí máa ń tù mí nínú gan-an!”—Zafirah, Amẹ́ríkà.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Ní àkókò rẹ̀, àwọn olódodo yóò gbilẹ̀, àlàáfíà yóò sì gbilẹ̀ títí òṣùpá kò fi ní sí mọ́.”—Sáàmù 72:7.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: “Mo sábà máa ń ronú nípa ẹsẹ Bíbélì yìí. Ó fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé láìpẹ́ kò ní sí ogun mọ́, tó fi mọ́ àwọn nǹkan burúkú tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà ogun. A ò sì ní máa kó ọkàn sókè pé jàǹbá lè ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn wa.”—Oleksandra, Ukraine.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Àwọn òkú rẹ máa wà láàyè. . . . Ẹ jí, ẹ sì kígbe ayọ̀, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé inú iyẹ̀pẹ̀!”—Àìsáyà 26:19.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn mọ̀lẹ́bí mi ló pa run nígbà tí ẹ̀yà Hutu ń bá ẹ̀yà Tutsi jà. Àmọ́, ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kó dá mi lójú pé mo ṣì máa pa dà rí wọn. Mò ń retí ìgbà tí Jèhófà máa jí wọn dìde, tí màá sì pa dà gbọ́ ohùn wọn!”—Marie, Rwanda.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ: “Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́ . . . Àmọ́ àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóò jogún ayé, inú wọn yóò sì máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: “Bo tiẹ̀ jẹ́ pé ogun tó ń jà nílùú wa ti parí, àwọn èèyàn burúkú ṣì ń hùwà ìkà, wọ́n sì ń rẹ́ni jẹ. Ẹsẹ Bíbélì yìí máa ń fún mi lókun gan-an. Ó jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì mọ bí nǹkan ṣe rí lára mi. Ó ṣèlérí pé láìpẹ́ àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ yìí máa dópin, a ò sì ní rántí wọn mọ́.”—Daler, Tajikistan.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú ìwé yìí wà lára ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé tí Bíbélì ti ràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Torí ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ti kọ́, wọn kì í kórìíra àwọn èèyàn torí pé orílẹ̀-èdè wọn, ẹ̀yà wọn tàbí èdè wọn yàtọ̀ sí tiwọn. (Éfésù 4:31, 32) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í lọ́wọ́ sí ogun tàbí rògbòdìyàn.—Jòhánù 18:36.

Bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí ọmọ ìyá, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ran ara wọn lọ́wọ́ kárí ayé. (Jòhánù 13:35) Àpẹẹrẹ kan ni ti Oleksandra tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. Nígbà tí ogun ń jà lórílẹ̀-èdè wọn, òun àti ẹ̀gbọ́n ẹ̀ obìnrin ní láti sá kúrò nílùú. Ó sọ pé: “Bá a ṣe ń kọjá ààlà orílẹ̀-èdè wa báyìí, bẹ́ẹ̀ la rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti ń dúró dè wá kí wọ́n lè kí wa káàbọ̀. Wọ́n jẹ́ kára tù wá, ìyẹn sì jẹ́ kára wa tètè mọlé ní orílẹ̀-èdè tuntun yìí.”

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ pé ó lè mú kí ọkàn wa balẹ̀, ká sì wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn. Tayọ̀tayọ̀ la pè ẹ́ pé kó o dara pọ̀ mọ́ wa. Lọ sórí ìkànnì jw.org kó o lè wá èyí tó sún mọ́ ẹ lára àwọn ibi tá a ti ń ṣèpàdé tàbí kó o ní kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá máa fi ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́