ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp25 No. 1 ojú ìwé 3
  • Ogun Kì Í Bímọọre

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ogun Kì Í Bímọọre
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN SÓJÀ
  • ÀWỌN ARÁ ÌLÚ
  • Ọkàn Ẹ Lè Balẹ̀ Láìka Ohun Tí Ogun àti Rògbòdìyàn Ti Fojú Ẹ Rí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
  • Ó Ti Lé Lọ́dún Kan Tí Ogun Ti Ń Jà ní Ukraine—Kí Ni Bíbélì Sọ Pé Ọlọ́run Máa Ṣe?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Wọ́n Ti Ná Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ Owó Sórí Ogun—Kí Ni Àbárèbábọ̀ Ẹ̀?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Gbogbo Wa Ni Ogun àti Rògbòdìyàn Ń Ṣàkóbá Fún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2025
wp25 No. 1 ojú ìwé 3
Àwòrán: 1. Apá kan lára ojú sójà nínú fọ́tò kan tó ti ya. 2. Apá kan lára ojú ìyá àgbàlagbà kan nínú fọ́tò kan tó ti ya.

Ogun Kì Í Bímọọre

Àwọn tí ogun bá ti jà lójú wọn rí á gbà pé ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú jù lọ láyé nìyẹn. Kárí ayé làwọn èèyàn ti mọ̀ pé àti sójà àtàwọn ará ìlú ló máa ń fara gbá aburú tó máa ń tẹ̀yìn ogun yọ.

ÀWỌN SÓJÀ

“Téèyàn bá wà lójú ogun, oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bani lẹ́rù láá máa rí. Wàá rí àwọn tó ti fara pa yánnayànna, àwọn tí ìbọn ti bà àti òkú tó sùn lọ bẹẹrẹbẹ. Wàá wá máa bi ara ẹ pé ṣé èmi kọ́ ló kàn báyìí?”—Gary, Britain.

“Ọta ìbọn ṣe mí léṣe lẹ́yìn àti lójú, mo sì rí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé àtàgbàlagbà tó ti kú. Ńṣe ni ogun máa ń sọni di ọ̀dájú.”—Wilmar, Colombia.

“Tí wọ́n bá ti yìnbọn fẹ́nì kan lójú ẹ rí, á pẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó kúrò lọ́kàn ẹ. Ṣe ló máa dà bíi pé o ṣì ń gbọ́ bí onítọ̀hún ṣe ń jẹ̀rora, tó sì ń kígbe oró. Kò sígbà tọ́rọ̀ onítọ̀hún ò ní máa wá sí ẹ lọ́kàn.”—Zafirah, Amẹ́ríkà.

ÀWỌN ARÁ ÌLÚ

“Tí mo bá ń rántí ohun tójú mi rí nígbà ogun, ńṣe ni inú mi máa ń bà jẹ́. Bó o ṣe ń du orí ara ẹ, bẹ́ẹ̀ ni wàá máa bẹ̀rù pé kí nǹkan má ṣe àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ.”—Oleksandra, Ukraine.

“Nǹkan bíi wákàtí mọ́kànlélógún (21) ni mo fi wà lórí ìlà kí n tó lè rí oúnjẹ gbà, ọkàn mi ò sì balẹ̀ rárá torí pé ìgbàkigbà ni ọta ìbọn lè ṣèèṣì ba ẹnikẹ́ni.”—Daler, Tajikistan.

“Àwọn òbí mi ti bógun lọ. Bí mo ṣe di ọmọ aláìlóbìí nìyẹn, láìsí ẹni tó máa tù mí nínú tàbí ẹni tó máa tọ́jú mi.”—Marie, Rwanda.

Pẹ̀lú gbogbo ohun tí ogun ti fojú àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn lókè yìí rí, ọkàn wọn ti wá balẹ̀ báyìí. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti wá rí i pé ogun àti rògbòdìyàn máa dópin láìpẹ́. Ìwé yìí máa ṣàlàyé àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ nípa bó ṣe máa ṣẹlẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́