ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 March ojú ìwé 26-31
  • Ọwọ́ Jèhófà Ò Kúrú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọwọ́ Jèhófà Ò Kúrú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍNÚ ÀṢÌṢE TÍ MÓSÈ ÀTÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ ṢE
  • TÁ Ò BÁ LÓWÓ LÁTI GBỌ́ BÙKÁTÀ
  • MÚRA SÍLẸ̀ DE ỌJỌ́ IWÁJÚ
  • Kí La Kọ́ Nínú Ohun Táwọn Ọkùnrin Olóòótọ́ Sọ Kí Wọ́n Tó Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Rántí Pé Jèhófà Ni “Ọlọ́run Alààyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 March ojú ìwé 26-31

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 13

ORIN 4 “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”

Ọwọ́ Jèhófà Ò Kúrú

“Ṣé ọwọ́ Jèhófà kúrú ni?”—NỌ́Ń. 11:23.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Bá a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á pèsè ohun tá a nílò, ká sì fọkàn tán an pé á ràn wá lọ́wọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.

1. Báwo ni Mósè ṣe fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nínú Jèhófà nígbà tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní Íjíbítì?

ÌWÉ Hébérù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ọ̀kan lára àwọn tó nígbàgbọ́ tó lágbára tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni Mósè. (Héb. 3:2-5; 11:23-25) Ó fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nígbà tó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde ní Íjíbítì. Kò jẹ́ kí Fáráò àtàwọn ọmọ ogun ẹ̀ kó jìnnìjìnnì bá òun. Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó kó wọn la Òkun Pupa já àti nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù. (Héb. 11:27-29) Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà mọ́ pé ó lè bójú tó àwọn, àmọ́ Mósè ṣì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ọlọ́run ò já Mósè kulẹ̀ torí òun ló pèsè oúnjẹ àti omi fáwọn èèyàn náà lọ́nà ìyanu nínú aginjù.a—Ẹ́kís. 15:22-25; Sm. 78:23-25.

2. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi bi Mósè pé: “Ṣé ọwọ́ Jèhófà kúrú ni”? (Nọ́ńbà 11:21-23)

2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Mósè nígbàgbọ́ tó lágbára, ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí Jèhófà dá wọn sílẹ̀ lọ́nà ìyanu, ó béèrè ìbéèrè tó fi hàn pé kò gbà pé Jèhófà lè ṣe ohun tó sọ. Ó sọ pé, ṣé lóòótọ́ ni Jèhófà máa lè pèsè ẹran fún gbogbo àwọn èèyàn náà bó ṣe sọ? Mósè ò mọ bí Jèhófà ṣe máa pèsè ẹran fáwọn èèyàn rẹpẹtẹ tó wà nínú aginjù tó dá páropáro yẹn. Jèhófà wá dá a lóhùn pé: “Ṣé ọwọ́ Jèhófà kúrú ni?” (Ka Nọ́ńbà 11:21-23.) Nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, “ọwọ́ Jèhófà” ni ẹ̀mí mímọ́ tàbí agbára tó fi ń ṣiṣẹ́. Lédè míì, ohun tí Jèhófà ń bi Mósè ni pé, ‘Ṣé o rò pé mi ò ní lè ṣe ohun tí mo sọ ni?’

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

3 Ǹjẹ́ o ti bi ara ẹ rí pé, ṣé Jèhófà máa pèsè ohun tí èmi tàbí ìdílé mi nílò? Bóyá o ti bi ara ẹ rí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọn ò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó lè pèsè fáwọn. Àwọn ìlànà Bíbélì tá a máa jíròrò báyìí máa jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ọwọ́ ẹ̀ ò kúrú rárá láti bójú tó wa.

KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍNÚ ÀṢÌṢE TÍ MÓSÈ ÀTÀWỌN ỌMỌ ÍSÍRẸ́LÌ ṢE

4. Kí ló ṣeé ṣe kó mú káwọn èèyàn náà máa ṣiyèméjì pé Jèhófà lè pèsè fáwọn?

4 Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ń ṣiyèméjì pé Jèhófà máa pèsè fáwọn? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti “oríṣiríṣi èèyàn tó pọ̀ rẹpẹtẹ” tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò láti Íjíbítì lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Ẹ́kís. 12:38; Diu. 8:15) Àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ń ráhùn pé mánà ti sú àwọn, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì dara pọ̀ mọ́ wọn. (Nọ́ń. 11:4-6) Àwọn èèyàn náà sọ pé oúnjẹ táwọn ń jẹ ní Íjíbítì ló wu àwọn jẹ. Báwọn èèyàn náà ṣe ń fúngun mọ́ Mósè mú kó rò pé òun ló yẹ kóun pèsè oúnjẹ fún wọn.—Nọ́ń. 11:13, 14.

5-6. Kí la kọ́ nínú bí àwọn tó tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe mú kí wọ́n ya aláìmoore?

5 Torí pé àwọn tó tẹ̀ lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì ò mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà pèsè, ìyẹn mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà ya aláìmoore. Tá ò bá ṣọ́ra, àwa náà lè má mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ń pèsè fún wa bíi tàwọn aláìmoore tó yí wa ká. Ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tá a ní tẹ́lẹ̀ àmọ́ tá ò ní mọ́ tàbí tá à ń jowú àwọn míì torí ohun tí wọ́n ní. Ṣùgbọ́n tí ohun tá a ní bá tẹ́ wa lọ́rùn, ó dájú pé a máa láyọ̀.

6 Ó yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rántí ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún wọn pé tí wọ́n bá dé ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n máa gbádùn ọ̀pọ̀ nǹkan rere. Ilẹ̀ Ìlérí ni Jèhófà ti máa mú ìlérí yẹn ṣẹ, kì í ṣe ìgbà tí wọ́n wà lọ́nà ní aginjù. Torí náà, dípò táwa náà á fi máa ronú nípa àwọn nǹkan tá ò lè ní nínú ayé burúkú yìí, àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa nínú ayé tuntun ló yẹ ká máa ronú nípa ẹ̀. Ó tún yẹ ká máa ronú dáadáa nípa àwọn ẹsẹ Bíbélì tó máa jẹ́ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.

7. Kí ló mú kó dá wa lójú pé ọwọ́ Jèhófà ò kúrú?

7 Síbẹ̀, o lè máa rò pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi bi Mósè pé: “Ṣé ọwọ́ Jèhófà kúrú ni?” Nígbà tí Jèhófà bi Mósè ní ìbéèrè yẹn, ó fẹ́ kó ronú nípa bí agbára òun ṣe pọ̀ tó àti pé kò sóhun tí agbára òun ò ká. Ọlọ́run lè pèsè ẹran rẹpẹtẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì bó tiẹ̀ jẹ́ pé àárín aginjù ni wọ́n wà. Torí náà, ó fi “ọwọ́ agbára àti apá tó nà jáde” ràn wọ́n lọ́wọ́. (Sm. 136:11, 12) Tá a bá níṣòro, ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣiyèméjì pé Jèhófà lè fi ọwọ́ agbára ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́.—Sm. 138:6, 7.

8. Kí ni ò ní jẹ́ ká ṣe irú àṣìṣe tí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe nínú aginjù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

8 Kò pẹ́ tí Jèhófà fi pèsè àparò rẹpẹtẹ fún wọn. Àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí iṣẹ́ ìyanu yìí. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n fi ìwàǹwára kó àparò náà, kódà tọ̀sántòru ni wọ́n fi kó o wọ̀ǹtì wọnti. Jèhófà bínú gan-an sáwọn “tó hùwà wọ̀bìà,” ó sì fìyà jẹ wọ́n. (Nọ́ń. 11:31-34) A lè kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Ó yẹ káwa náà ṣọ́ra, ká má ṣojúkòkòrò. Yálà olówó ni wá tàbí a ò fi bẹ́ẹ̀ lówó, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa to ‘ìṣúra pa mọ́ ní ọ̀run,’ a sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àti Jésù. (Mát. 6:19, 20; Lúùkù 16:9) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa pèsè fún wa.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kó àparò tó pọ̀ gan-an nínú aginjù lóru.

Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe nínú aginjù, kí la sì kọ́ nínú àṣìṣe tí wọ́n ṣe? (Wo ìpínrọ̀ 8)


9. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́?

9 Jèhófà ń fi ọwọ́ agbára ẹ̀ ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́ lónìí. Àmọ́ ìyẹn ò sọ pé gbogbo ìgbà la máa ní ohun tá a fẹ́ tàbí pé ebi ò ní pa wá rárá.b Àmọ́ ó dájú pé Jèhófà ò ní fi wá sílẹ̀. Ó máa ràn wá lọ́wọ́ láìka ìṣòro tá a ní sí. Báwo la ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa pèsè fún wa? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan méjì: (1) tá ò bá lówó láti gbọ́ bùkátà (2) tá a bá ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú.

TÁ Ò BÁ LÓWÓ LÁTI GBỌ́ BÙKÁTÀ

10. Àwọn ìṣòro àtigbọ́ bùkátà wo la lè ní?

10 Bí ayé burúkú yìí ṣe ń lọ sópin, a mọ̀ pé ìṣòro àtigbọ́ bùkátà á túbọ̀ máa le sí i. Rògbòdìyàn òṣèlú, ogun, àjálù tàbí àjàkálẹ̀ àrùn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lè mú kí nǹkan wọ́n sí i, wọ́n sì lè mú ká pàdánù iṣẹ́ wa, àwọn ohun ìní wa tàbí ilé wa pàápàá. Ó lè gba pé ká wáṣẹ́ tuntun níbi tá a wà báyìí tàbí ká ro bá a ṣe máa kó ìdílé wa lọ síbòmíì ká lè bójú tó wọn. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ọwọ́ ẹ̀ ò kúrú?

11. Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro àtigbọ́ bùkátà? (Lúùkù 12:29-31)

11 Ohun àkọ́kọ́ tó dáa jù tó o lè ṣe ni pé kó o fọ̀rọ̀ ẹ lé Jèhófà lọ́wọ́. (Òwe 16:3) Bẹ̀ ẹ́ pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n tó o máa fi ṣèpinnu tó tọ́, kí ọkàn ẹ balẹ̀, ‘kí àníyàn má sì kó ẹ lọ́kàn sókè mọ́.’ (Ka Lúùkù 12:29-31.) Rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i pé kó jẹ́ kó o nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tó o bá ti ní àwọn nǹkan kòṣeémáàní. (1 Tím. 6:7, 8) Bákan náà, ṣèwádìí nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run nípa ohun téèyàn lè ṣe láti borí ìṣòro àtigbọ́ bùkátà. Ọ̀pọ̀ ló ti jàǹfààní nínú àwọn àpilẹ̀kọ àtàwọn fídíò tó wà lórí jw.org tó sọ nípa bá a ṣe lè gbọ́ bùkátà wa.

12. Àwọn ìbéèrè wo ló máa jẹ́ kí Kristẹni kan ṣèpinnu tó dáa fún ìdílé ẹ̀?

12 Àwọn kan ti gba iṣẹ́ tó jẹ́ kí wọ́n kúrò lọ́dọ̀ ìdílé wọn lọ síbòmíì, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń rí i pé ìpinnu táwọn ṣe yẹn ò dáa. Kó o tó gbaṣẹ́ tuntun, á dáa kó o ronú nípa ìpalára tó lè ṣe fún ìjọsìn ẹ, kì í ṣe owó tó o máa rí níbẹ̀ nìkan ló yẹ kó o rò. (Lúùkù 14:28) Torí náà bi ara ẹ pé: ‘Tí mo bá fi ọkọ tàbí ìyàwó mi sílẹ̀ torí iṣẹ́ yìí, àkóbá wo ló lè ṣe fún wa? Ṣé màá lè máa lọ sípàdé déédéé, kí n máa lọ sóde ìwàásù, kí n sì máa wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin?’ Tó o bá ti bímọ, ó tún yẹ kó o bi ara ẹ láwọn ìbéèrè pàtàkì yìí: ‘Báwo ni màá ṣe fi “ìbáwí àti ìmọ̀ràn Jèhófà” tọ́ wọn tí mi ò bá sí lọ́dọ̀ wọn?’ (Éfé. 6:4) Ìlànà Bíbélì ni kó o tẹ̀ lé, má ṣe ohun táwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì fẹ́ kó o ṣe.c Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Tony tó ń gbé ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Éṣíà ríṣẹ́ tó máa mówó gọbọi wọlé lókè òkun. Àmọ́ lẹ́yìn tó gbàdúrà, tóun àtìyàwó ẹ̀ sì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ó pinnu pé òun ò ní gba ìkankan nínú àwọn iṣẹ́ náà, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló wá bó ṣe máa dín ìnáwó wọn kù. Nígbà tí Tony rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ni mo ti ràn lọ́wọ́ tí wọ́n sì ti ń sin Jèhófà báyìí. Kì í ṣèyẹn nìkan o, àwọn ọmọ wa ò fi òtítọ́ ṣeré, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Ìdílé wa ti rí i pé gbogbo ìgbà tá a bá ṣe ohun tó wà ní Mátíù 6:33, Jèhófà máa ń bójú tó wa.”

MÚRA SÍLẸ̀ DE ỌJỌ́ IWÁJÚ

13. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe báyìí ká lè rówó gbọ́ bùkátà tá a bá dàgbà?

13 A tún lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a bá ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú. Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa ṣiṣẹ́ kára ká lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú. (Òwe 6:6-11) Torí náà, ó dáa kéèyàn máa tọ́jú nǹkan pa mọ́ bí owó tó ń wọlé fún un bá ṣe tó. Lóòótọ́, owó lè dáàbò bò wá. (Oníw. 7:12) Àmọ́, kì í ṣe owó àtàwọn nǹkan tara ló yẹ ká máa fi gbogbo ayé wa lé.

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká ronú nípa ohun tó wà nínú Hébérù 13:5 tá a bá ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú?

14 Jésù jẹ́ ká mọ̀ nínú àpèjúwe kan tó ṣe pé ìwà òmùgọ̀ ni kéèyàn kówó jọ pelemọ, kó má sì ní “ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:16-21) Ká sòótọ́, a ò mohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa lọ́la. (Òwe 23:4, 5; Jém. 4:13-15) Jésù sọ pé gbogbo àwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ “yááfì” àwọn ohun ìní wọn, ìyẹn ò sì rọrùn. (Lúùkù 14:33, àlàyé ìsàlẹ̀) Ohun táwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó ń gbé Jùdíà ṣe nìyẹn. (Héb. 10:34) Lákòókò wa yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ti pàdánù iṣẹ́ tàbí ohun ìní wọn torí pé wọn ò ti ẹgbẹ́ òṣèlú lẹ́yìn. (Ìfi. 13:16, 17) Kí ló jẹ́ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n gbà pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ nígbà tó sọ pé: “Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé, mi ò sì ní pa ọ́ tì láé.” (Ka Hébérù 13:5.) Síbẹ̀, àá sapá láti múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú, àmọ́ tóhun tá ò retí bá ṣẹlẹ̀, àá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa bójú tó wa.

15. Èrò wo ló yẹ káwọn òbí ní nípa àwọn ọmọ wọn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

15 Ní àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, àwọn tọkọtaya máa ń bímọ torí káwọn ọmọ wọn lè gbọ́ bùkátà wọn tí wọ́n bá dàgbà. Irú àwọn òbí bẹ́ẹ̀ ń rò pé àwọn ọmọ wọn ló máa bá wọn tán ìṣẹ́. Ṣùgbọ́n, Bíbélì sọ pé àwọn òbí ló yẹ kó pèsè ohun táwọn ọmọ wọn nílò. (2 Kọ́r. 12:14) Kò burú táwọn òbí bá fẹ́ káwọn ọmọ wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ táwọn bá dàgbà, inú ọ̀pọ̀ ọmọ ló sì ń dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Tím. 5:4) Àmọ́ àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni mọ̀ pé kì í ṣe ìrànlọ́wọ́ táwọn ọmọ wọn máa ṣe fún wọn ló máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀, ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n láyọ̀ ni kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ náà yanjú kí wọ́n lè sin Jèhófà.—3 Jòh. 4.

Àwọn òbí arábìnrin kan ń kí òun àti ọkọ ẹ̀ lórí ìkànnì, wọ́n sì tan fídíò wọn. Arábìnrin náà àti ọkọ ẹ̀ wọ aṣọ táwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé máa ń wọ̀.

Àwọn tọkọtaya Kristẹni máa ń ronú nípa àwọn ìlànà Bíbélì tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu nípa ọjọ́ iwájú (Wo ìpínrọ̀ 15)d


16. Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti gbọ́ bùkátà ara wọn? (Éfésù 4:28)

16 Tó o bá ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ bí wọ́n ṣe máa gbọ́ bùkátà ara wọn lọ́jọ́ iwájú, jẹ́ kí wọ́n rí i pé ìwọ náà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú àwọn ìpinnu tó ò ń ṣe. Kọ́ wọn láti kékeré pé ó yẹ kéèyàn máa ṣiṣẹ́ kára. (Òwe 29:21; ka Éfésù 4:28.) Bí wọ́n ṣe ń dàgbà, ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa ṣe dáadáa nílé ìwé. Ó yẹ kẹ́yin òbí ṣèwádìí àwọn ìlànà Bíbélì tó máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ iye ìwé tí wọ́n máa kà. Ìyẹn máa jẹ́ káwọn ọmọ yín lè gbọ́ bùkátà ara wọn, kí wọ́n sì lè ráyè máa wàásù déédéé.

17. Kí ló dá wa lójú?

17 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà gbẹ́kẹ̀ lé e pé ó lágbára láti pèsè gbogbo ohun tá a nílò. Bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ayé burúkú yìí, àwọn nǹkan kan máa dán wa wò bóyá a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àbí a ò ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá pé ó máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò. Ó dájú pé ọwọ́ agbára Jèhófà àti apá ẹ̀ tó nà jáde ò kúrú láti gbà wá.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí la kọ́ nínú àṣìṣe tí Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe?

  • Tá a bá níṣòro àtigbọ́ bùkátà, báwo la ṣe lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

  • Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe tá a bá ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ iwájú?

ORIN 150 Wá Ọlọ́run Kó O Lè Rí Ìgbàlà

a Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ October 2023.

b Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ September 15, 2014.

c Wo àpilẹ̀kọ náà, “Kò Sí Ẹni Tó Lè Sin Ọ̀gá Méjì” nínú Ilé Ìṣọ́ April 15, 2014.

d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Tọkọtaya Kristẹni kan ń bá ọmọ wọn sọ̀rọ̀. Ọmọ náà àti ọkọ ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwùjọ tó ń kọ́ Ilé Ìpàdé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́