ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 16
ORIN 87 Ẹ Wá Gba Ìtura
A Máa Jàǹfààní Tá A Bá Sún Mọ́ Àwọn Ará
“Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o pé kí àwọn ará máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan!”—SM. 133:1.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká rí àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa àtàwọn àǹfààní tá a máa rí tá a bá mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́.
1-2. Kí ló ṣe pàtàkì jù lójú Jèhófà, kí ló sì fẹ́ ká ṣe?
BÁ A ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn ṣe pàtàkì gan-an lójú Jèhófà, kódà ó ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan míì tá à ń ṣe nínú ìjọsìn ẹ̀ lọ. Jésù kọ́ wa pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wa. (Mát. 22:37-39) Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tí Jésù ní ká nífẹ̀ẹ́. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, à ń fara wé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn èèyàn burúkú àtàwọn èèyàn rere, ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.”—Mát. 5:45.
2 Lóòótọ́, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, àmọ́ inú ẹ̀ máa ń dùn gan-an sáwọn tó ń ṣe ohun tó fẹ́. (Jòh. 14:21) Ó fẹ́ ká fara wé òun. Ó rọ̀ wá pé ká ní “ìfẹ́ tó jinlẹ̀” sáwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, ká sì máa fi “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” hàn sí wọn. (1 Pét. 4:8; Róòmù 12:10) Tá a bá ń fi irú ìfẹ́ yìí hàn sẹ́nì kan, ìyẹn lè jẹ́ ká máa wo ẹni náà bíi mọ̀lẹ́bí wa tàbí ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n.
3. Kí la lè fi ìfẹ́ wé, kí sì nìdí?
3 A lè fi ìfẹ́ wé irúgbìn tá a gbìn. Bó ṣe jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ tọ́jú ẹ̀ kó lè dàgbà dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ ká túbọ̀ fìfẹ́ hàn sáwọn ará. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ túbọ̀ máa ní ìfẹ́ ará.” (Héb. 13:1) Jèhófà fẹ́ ká máa fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sáwọn èèyàn. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn ará wa àti bá ò ṣe ní jẹ́ kó sú wa láti máa nífẹ̀ẹ́ wọn.
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ÀWỌN ARÁ
4. Bí Sáàmù 133:1 ṣe sọ, kí la lè ṣe táá fi hàn pé a mọyì àwọn ará wa, a sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
4 Ka Sáàmù 133:1. Àwa náà gbà pẹ̀lú onísáàmù tó sọ pé ó “dára,” ó sì “dùn” bí àwa àtàwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Àmọ́ o, tá ò bá ṣọ́ra, a lè má mọyì ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa. Ṣe ló dà bí ìgbà tí igi ńlá kan ò jọni lójú mọ́ torí pé a máa ń rí i lójoojúmọ́. Òótọ́ ni pé gbogbo ìgbà là ń rí àwọn ará wa. Ṣùgbọ́n, tá a bá fẹ́ túbọ̀ mọyì wọn, ká sì nífẹ̀ẹ́ wọn, ó yẹ ká máa ronú nípa iṣẹ́ tí kálukú wọn ń ṣe nínú ìjọ àti bí wọ́n ṣe ń ràn wá lọ́wọ́.
Rí i pé o mọyì ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa ará (Wo ìpínrọ̀ 4)
5. Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn tí wọ́n bá rí i pé a nífẹ̀ẹ́ ara wa?
5 Tí àwọn tó wá sípàdé wa nígbà àkọ́kọ́ bá rí ìfẹ́ tó wà láàárín wa, ó máa ń wú wọn lórí gan-an. Ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó dá wọn lójú pé àwọn ti rí ẹ̀sìn tòótọ́. Jésù sọ pé: “Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.” (Jòh. 13:35) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tó ń jẹ́ Chaithra. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì ni, ó sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n pè é wá sí àpéjọ agbègbè wa, ó sì gbà láti wá. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́, ó sọ fún ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ pé: “Àwọn òbí mi ò gbá mi mọ́ra rí. Àmọ́ ní àpéjọ yìí, èèyàn méjìléláàádọ́ta (52) ló ti gbá mi mọ́ra lónìí! Ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi. Èmi náà fẹ́ máa sin Jèhófà bíi tiyín.” Chaithra ò dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ dúró, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2024. Tí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé bá rí i pé a níwà tó dáa, a sì nífẹ̀ẹ́ ara wa, ìyẹn lè mú kí wọ́n pinnu pé àwọn máa sin Jèhófà.—Mát. 5:16.
6. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá sún mọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa?
6 Tá a bá sún mọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa, a máa jàǹfààní. Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ máa fún ara yín níṣìírí lójoojúmọ́ . . . kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ìkankan nínú yín di ọlọ́kàn líle.” (Héb. 3:13) Tí nǹkan bá tojú sú wa, tó sì nira fún wa láti ṣohun tó tọ́, Jèhófà lè lo arákùnrin tàbí arábìnrin kan láti ràn wá lọ́wọ́. (Sm. 73:2, 17, 23) Ọ̀rọ̀ ìṣírí tẹ́ni náà bá sọ fún wa máa ṣe wá láǹfààní gan-an.
7. Báwo ni ìfẹ́ ṣe ń jẹ́ ká wà níṣọ̀kan? (Kólósè 3:13, 14)
7 A wà láàárín àwọn ará tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti fìfẹ́ hàn síra wọn, a sì ń jàǹfààní tó pọ̀ gan-an. (1 Jòh. 4:11) Bí àpẹẹrẹ, ìfẹ́ ló ń jẹ́ ká “máa fara dà á fún ara” wa, ìyẹn ló sì ń jẹ́ ká wà níṣọ̀kan. (Ka Kólósè 3:13, 14; Éfé. 4:2-6) Torí náà, tá a bá wà láwọn ìpàdé wa, ara máa ń tù wá gan-an, ọkàn wa sì máa ń balẹ̀. Ká sòótọ́, kò síbòmíì téèyàn ti lè rí irú ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan yìí.
Ẹ MÁA BỌLÁ FÚN ARA YÍN
8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè wà níṣọ̀kan?
8 Ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa èèyàn Jèhófà kárí ayé jọni lójú gan-an. Ìdí sì ni pé kò ṣeé ṣe fáwa èèyàn aláìpé láti mú kírú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ wà, àmọ́ Jèhófà mú kó ṣeé ṣe. (1 Kọ́r. 12:25) Bíbélì sọ pé ‘Ọlọ́run ti kọ́ wa láti máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.’ (1 Tẹs. 4:9) Ohun tá à ń sọ ni pé, Jèhófà ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ ohun tó yẹ ká ṣe ká lè wà níṣọ̀kan. Torí náà, tá a bá ń fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì ń ṣe ohun tó sọ, ìyẹn á fi hàn pé ‘Ọlọ́run ló ń kọ́ wa.’ (Héb. 4:12; Jém. 1:25) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti fi ohun tá à ń kọ́ sílò.
9. Kí la kọ́ nínú Róòmù 12:9-13 nípa bó ṣe yẹ ká máa bọlá fún ara wa?
9 Kí la kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra wa? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí nínú Róòmù 12:9-13. (Kà á.) Lára ohun pàtàkì tó sọ ni pé “nínú bíbu ọlá fún ara yín, ẹ mú ipò iwájú.” Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Ohun tó ń sọ ni pé àwa ló yẹ ká kọ́kọ́ máa fi “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” hàn sáwọn èèyàn. Lára nǹkan tá a lè ṣe ni pé ká máa dárí ji àwọn èèyàn, ká máa gbà wọ́n lálejò, ká sì máa ṣoore fún wọn. (Éfé. 4:32) Torí náà, kò yẹ ká dúró dìgbà táwọn ará bá kọ́kọ́ wá bá wa. Àwa ló yẹ ká “mú ipò iwájú” láti sún mọ́ wọn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá rí i pé òótọ́ lohun tí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
10. Báwo la ṣe lè ṣiṣẹ́ kára ká lè máa ‘bọlá fáwọn ará wa?’ (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Ẹ kíyè sí pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ pé ká máa bọlá fáwọn ará, ó sọ pé ká ‘máa ṣiṣẹ́ kára, ká má ṣọ̀lẹ.’ Ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára kì í fiṣẹ́ ṣeré, kì í sì í ṣèmẹ́lẹ́. Tí wọ́n bá ní kó ṣiṣẹ́ kan, ó máa ń rí i pé òun ṣe é dáadáa. Òwe 3:27, 28 rọ̀ wá pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn tó yẹ kí o ṣe é fún tó bá wà níkàáwọ́ rẹ láti ṣe é.” Torí náà, tá a bá rí i pé ó yẹ ká ran ẹnì kan lọ́wọ́, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́. Kò yẹ ká fọ̀rọ̀ náà falẹ̀, kò sì yẹ ká ronú pé táwa ò bá ṣe é, ẹlòmíì á kúkú ṣe é.—1 Jòh. 3:17, 18.
Ó yẹ ká máa ran àwọn ará lọ́wọ́ láìjẹ́ pé wọ́n sọ fún wa (Wo ìpínrọ̀ 10)
11. Kí lá jẹ́ ká túbọ̀ ṣe ara wa lọ́kan?
11 Nǹkan míì tá a lè ṣe táá fi hàn pé à ń bọlá fáwọn ará wa ni pé ká tètè máa dárí jì wọ́n tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá. Éfésù 4:26 sọ pé “ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ìbínú.” Kí nìdí tí ò fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹsẹ 27 sọ pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń “gba Èṣù láyè.” Léraléra ni Jèhófà sọ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé ká máa dárí ji ara wa. Bákan náà, Kólósè 3:13 rọ̀ wá pé ká “máa dárí ji ara [wa] fàlàlà.” Ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù tá a bá fẹ́ sún mọ́ àwọn ará wa ni pé ká máa gbójú fo àṣìṣe wọn, ká sì máa dárí jì wọ́n. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ ká lè “pa ìṣọ̀kan ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà.” (Éfé. 4:3) Kókó náà ni pé tá a bá ń dárí ji ara wa, àá túbọ̀ ṣe ara wa lọ́kan, àlàáfíà á sì wà láàárín wa.
12. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa dárí ji ara wa?
12 Òótọ́ ni pé ó máa ń ṣòro láti dárí ji àwọn tó ṣohun tó dùn wá. Àmọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú ká dárí jì wọ́n. Lẹ́yìn tí Bíbélì sọ pé ká “ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara [wa],” ká sì “máa ṣiṣẹ́ kára,” ó tún rọ̀ wá pé: “Kí iná ẹ̀mí máa jó nínú [wa].” Tí iná ẹ̀mí bá ń “jó” nínú ẹnì kan, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ darí òun, ìyẹn sì ń jẹ́ kó nítara tó pọ̀ gan-an. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ Róòmù 12:11 nínú nwtsty-E.) Torí náà, ẹ̀mí Ọlọ́run máa jẹ́ ká ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ká sì máa dárí ji ara wa fàlàlà. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń bẹ Jèhófà léraléra pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́.—Lúùkù 11:13.
“KÍ ÌYAPA MÁ ṢE SÍ LÁÀÁRÍN YÍN”
13. Kí ló lè fa ìyapa láàárín wa?
13 “Onírúurú èèyàn” tó wá láti ibi tó yàtọ̀ síra ló wà nínú ìjọ. (1 Tím. 2:3, 4) Tá ò bá ṣọ́ra, ìyàtọ̀ yìí lè fa ìyapa tó bá di ọ̀rọ̀ èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́, irú bí aṣọ tá a máa wọ̀, irun tá a máa ṣe tàbí tá a máa gẹ̀, ìtọ́jú tá a máa gbà tàbí eré ìnàjú tá a fẹ́. (Róòmù 14:4; 1 Kọ́r. 1:10) Torí pé Ọlọ́run ti kọ́ wa láti máa nífẹ̀ẹ́ ara wa, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má jẹ́ pé ohun tá a fẹ́ là ń dọ́gbọ́n mú káwọn ará ṣe.—Fílí. 2:3.
14. Kí ló yẹ ká máa ṣe fáwọn ará, kí sì nìdí?
14 Ohun míì tí ò ní jẹ́ kí ìyapa wà láàárín wa ni pé ká máa mára tu àwọn ará, ká sì máa gbé wọn ró ní gbogbo ìgbà. (1 Tẹs. 5:11) Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn tí ò wàásù mọ́ àtàwọn tá a ti mú kúrò nínú ìjọ ti pa dà sínú ìjọ báyìí, wọ́n sì ti ń ṣe dáadáa. Inú wa dùn pé wọ́n ti pa dà! (2 Kọ́r. 2:8) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tí ò wàásù mọ́ fún odindi ọdún mẹ́wàá (10), àmọ́ tó ti pa dà sínú ìjọ báyìí. Ó sọ pé, “Àwọn ará kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà, wọ́n sì gbá mi mọ́ra.” (Ìṣe 3:19) Báwo ni ìfẹ́ táwọn ará fi hàn sí i ṣe rí lára ẹ̀? Ó ní, “Ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà fẹ́ kí n pa dà láyọ̀.” Torí náà, tá a bá ń gbé àwọn ará ró láìya ẹnikẹ́ni sọ́tọ̀, ńṣe là ń jẹ́ kí Kristi lò wá láti mára tu àwọn “tó ń ṣe làálàá, tí a [sì] di ẹrù wọ̀ lọ́rùn.”—Mát. 11:28, 29.
15. Nǹkan míì wo la lè ṣe táá jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wa? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Nǹkan míì táá jẹ́ kí ìṣọ̀kan wà láàárín wa ni pé ká máa kíyè sí ohun tá à ń sọ. Jóòbù 12:11 sọ pé: “Ṣebí etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò, bí ahọ́n ṣe ń tọ́ oúnjẹ wò?” Bí ẹnì kan tó mọ oúnjẹ sè ṣe máa ń tọ́ ọ wò kó lè mọ̀ bóyá ó dùn kó tó bù ú fáwọn èèyàn, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ro ohun tá a fẹ́ sọ dáadáa ká tó sọ ọ́. (Sm. 141:3) Torí náà, ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún ni bí ọ̀rọ̀ wa ṣe máa gbé àwọn èèyàn ró, tó máa tù wọ́n lára, tó sì máa “ṣe àwọn tó ń gbọ́ [wa] láǹfààní.”—Éfé. 4:29.
Ronú dáadáa nípa ohun tó o fẹ́ sọ kó o tó sọ ọ́ (Wo ìpínrọ̀ 15)
16. Àwọn wo gan-an ló yẹ kó máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró?
16 Ó ṣe pàtàkì káwọn ọkọ àtàwọn òbí máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró. (Kól. 3:19, 21; Títù 2:4) Ó yẹ káwọn alàgbà náà máa sọ̀rọ̀ tó ń tuni lára, tó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣàbójútó àwọn èèyàn Jèhófà. (Àìsá. 32:1, 2; Gál. 6:1) Kódà, òwe Bíbélì kan sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ tó bọ́ sí àkókò mà dára o!’—Òwe 15:23.
Ó YẸ KÍ ÌFẸ́ WA JẸ́ “NÍ ÌṢE ÀTI ÒTÍTỌ́”
17. Kí la lè ṣe táá fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dénú?
17 Àpọ́sítélì Jòhánù gbà wá níyànjú pé “kò yẹ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ti ahọ́n, àmọ́ ó yẹ kó jẹ́ ní ìṣe àti òtítọ́.” (1 Jòh. 3:18) Ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa dénú. Báwo la ṣe lè ṣe é? Tá a bá ń sún mọ́ àwọn ará, àjọṣe àárín wa á túbọ̀ gún régé, àá sì máa nífẹ̀ẹ́ wọn. Torí náà, máa bá àwọn ará sọ̀rọ̀ nípàdé àti lóde ìwàásù. Yàtọ̀ síyẹn, máa lọ kí wọn nílé. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àá máa fi hàn pé ‘Ọlọ́run ti kọ́ wa láti máa nífẹ̀ẹ́ ara wa.’ (1 Tẹs. 4:9) Àwa náà á sì gbà pé ‘ó dára, ó sì dùn pé kí àwa ará máa gbé pọ̀ ní ìṣọ̀kan!’—Sm. 133:1.
ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú