ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 15
ORIN 30 Bàbá Mi, Ọlọ́run Mi àti Ọ̀rẹ́ Mi
“Sísúnmọ́ Ọlọ́run Dára” fún Wa!
“Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.”—SM. 73:28.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bá a ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti àǹfààní tá a máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀.
1-2. (a) Kí lèèyàn máa ṣe kó tó lè di ọ̀rẹ́ ẹnì kan? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
ṢÉ O ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan? Báwo lẹ ṣe dọ̀rẹ́? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ jọ máa ń wà pa pọ̀, o mọ àwọn ohun tó fẹ́ àtohun tí ò fẹ́, kódà o mọ ìṣòro ẹ̀. O tún mọ àwọn ìwà ẹ̀ tó wù ẹ́ kó o fara wé. Àwọn nǹkan yẹn ló sì jẹ́ kó o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.
2 Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá kéèyàn tó lè di ọ̀rẹ́ ẹnì kan. Ohun kan náà la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Jèhófà. Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tá a máa rí tá a bá sún mọ́ Jèhófà, ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n.
3. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa àǹfààní tá a máa rí tá a bá sún mọ́ Jèhófà? Sọ àpèjúwe kan.
3 Gbogbo wa la gbà pé tá a bá sún mọ́ Jèhófà, á ṣe wá láǹfààní. Àmọ́ téèyàn bá ń ronú nípa àǹfààní yẹn, á túbọ̀ wù ú láti sún mọ́ Ọlọ́run. (Sm. 63:6-8) Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé tá a bá ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore, tá à ń ṣeré ìmárale, tá à ń sùn dáadáa, tá a sì ń mu omi dáadáa, ara wa máa le. Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ò ka nǹkan wọ̀nyí sí, wọn kì í sì í tọ́jú ara wọn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bá a bá ṣe ń ronú nípa àǹfààní tá a máa rí tára wa bá le, bẹ́ẹ̀ lá máa wù wá láti ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kára wa túbọ̀ jí pépé. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ronú nípa àǹfààní tá a máa rí tá a bá sún mọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ lá máa wù wá láti ṣohun táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n yìí.—Sm. 119:27-30.
4. Kí ni onísáàmù kan sọ ní Sáàmù 73:28?
4 Ka Sáàmù 73:28. Ọmọ Léfì lẹni tó kọ Sáàmù 73, ó sì wà lára àwọn akọrin nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó ti máa sin Jèhófà tipẹ́. Síbẹ̀, ó rí i pé ó yẹ kóun rán ara òun àtàwọn míì létí pé “sísúnmọ́ Ọlọ́run dára.” Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run?
TÁ A BÁ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN, A MÁA LÁYỌ̀
5. (a) Kí nìdí tá a fi sọ pé a máa láyọ̀ tá a bá sún mọ́ Jèhófà? (b) Bó ṣe wà ní Òwe 2:6-16, sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé ọgbọ́n Jèhófà lè dáàbò bò ẹ́, ó sì lè ṣe ẹ́ láǹfààní.
5 Bá a bá ṣe ń sún mọ́ Jèhófà, bẹ́ẹ̀ làá túbọ̀ máa láyọ̀. (Sm. 65:4) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí. Ìdí ni pé tá a bá ń fi àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì sílò, ó máa ṣe wá láǹfààní. Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n náà máa ń dáàbò bò wá, kì í sì í jẹ́ ká hùwàkiwà. (Ka Òwe 2:6-16.) Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tó wá ọgbọ́n rí àti ẹni tó ní òye.”—Òwe 3:13.
6. Kí ni ò jẹ́ kẹ́ni tó kọ Sáàmù 73 láyọ̀ mọ́?
6 Ká sòótọ́, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni inú àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà máa ń dùn. Ìgbà míì wà tí inú wọn máa ń bà jẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó kọ Sáàmù 73 nìyẹn, kò láyọ̀ mọ́ nígbà tó ń ronú lọ́nà tí ò tọ́. Inú ń bí i, ó sì ń jowú torí ó rò pé nǹkan ń dáa fáwọn èèyàn burúkú. Ó sọ pé àwọn tó ń hùwà ìkà àtàwọn agbéraga ń lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀, ara wọn jí pépé, ìyà ò sì jẹ wọ́n. (Sm. 73:3-7, 12) Nígbà kan, ọ̀rọ̀ náà kó ìdààmú bá a débi tó fi rò pé kò sí àǹfààní kankan nínú bóun ṣe ń sin Jèhófà. Ìyẹn ló mú kó sọ pé: “Ó dájú pé lásán ni mo pa ọkàn mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi mọ́ pé mo jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀.”—Sm. 73:13.
7. Tí inú wa bá bà jẹ́, kí la lè ṣe? (Wo àwòrán.)
7 Ẹni tó kọ sáàmù yẹn kò jẹ́ kí ìbànújẹ́ bo òun mọ́lẹ̀. Ọgbọ́n wo ló dá sí i? Ó “wọ ibi mímọ́ títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run,” Jèhófà sì tọ́ ọ sọ́nà. (Sm. 73:17-19) Torí náà, tínú wa bá bà jẹ́, Jèhófà ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wa. Tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́ wa sọ́nà, tá à ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó fún wa, tá a sì jẹ́ káwọn ará ìjọ ràn wá lọ́wọ́, àá lókun láti fara dà á. Kódà, tí àníyàn bá bò wá mọ́lẹ̀, Jèhófà máa tù wá nínú, á sì fọkàn wa balẹ̀.—Sm. 94:19.a
Ọmọ Léfì tó kọ Sáàmù 73 dúró sí “ibi mímọ́ títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run.” (Wo ìpínrọ̀ 7)
TÁ A BÁ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN, AYÉ WA MÁA DÁA
8. Àwọn àǹfààní míì wo la máa rí tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run?
8 Tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run, ayé wa máa dáa. A máa jàǹfààní ẹ̀ láwọn ọ̀nà méjì yìí. Àkọ́kọ́, ó máa jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ìkejì, ó máa jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (Jer. 29:11) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan yìí.
9. Tá a bá sún mọ́ Jèhófà, báwo ló ṣe máa jẹ́ káyé wa dáa?
9 Tá a bá sún mọ́ Jèhófà, ayé wa máa ládùn, á sì lóyin. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó sọ pé kò sí Ọlọ́run ló gbà pé asán layé àti pé gbogbo èèyàn máa pa rẹ́ lọ́jọ́ kan. Àmọ́, ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run wà àti pé kò ní gbàgbé ohun tá a bá ṣe fún un torí pé “òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.” (Héb. 11:6) Kódà lásìkò tá a wà yìí, ayé wa dáa torí à ń sin Jèhófà Baba wa ọ̀run, ohun tó sì fẹ́ ká máa ṣe nìyẹn.—Diu. 10:12, 13.
10. Kí ni Sáàmù 37:29 sọ nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
10 Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé ayé lónìí mọ̀ ò ju pé kí wọ́n ṣiṣẹ́, kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sì fowó pa mọ́ de ìgbà tí wọ́n bá dàgbà. Wọn ò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àtàwọn nǹkan rere tó fẹ́ ṣe fáráyé. Àmọ́, àwa ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀ sáwọn èèyàn yẹn torí a gbà pé Jèhófà máa bójú tó wa. (Sm. 25:3-5; 1 Tím. 6:17) A gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pé á mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. A sì mọ̀ pé àá máa sìn ín títí láé nínú Párádísè.—Ka Sáàmù 37:29.
11. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe máa rí lára Ọlọ́run?
11 Tá a bá sún mọ́ Ọlọ́run, ó máa ṣe wá láǹfààní láwọn ọ̀nà míì. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ pé òun máa dárí ji àwọn ìránṣẹ́ òun tó bá ronú pìwà dà. (Àìsá. 1:18) Torí náà, kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti dá sẹ́yìn. (Sm. 32:1-5) Yàtọ̀ síyẹn, a láǹfààní láti múnú Jèhófà dùn, ká sì mú ọkàn ẹ̀ yọ̀. (Òwe 23:15) Ó dájú pé ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Àmọ́, báwo la ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?
BÁ A ṢE LÈ TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
12. Àwọn nǹkan wo lo ti ṣe kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?
12 Tó o bá ti ṣèrìbọmi, ó dájú pé o ti sún mọ́ Jèhófà débi tó lápẹẹrẹ. O ti kọ́ ohun tó pọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù, o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ. O ti nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run, o sì ti ń ṣe ìfẹ́ ẹ̀. Àmọ́, tá a bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan yìí nìṣó.—Kól. 2:6.
13. Nǹkan mẹ́ta wo lá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
13 Kí ló máa jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run? (1) A gbọ́dọ̀ máa ka Bíbélì, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀. Òótọ́ ni pé téèyàn bá ń ka Bíbélì, ó máa mọ àwọn nǹkan kan nípa Ọlọ́run. Àmọ́, bá a ṣe ń kà á, ó tún yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe, ká sì máa tẹ̀ lé ìlànà ẹ̀. (Éfé. 5:15-17) (2) A gbọ́dọ̀ máa ṣàṣàrò lórí bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó, kí ìgbàgbọ́ wa lè lágbára. (3) A gbọ́dọ̀ kórìíra ohun tí Jèhófà ò fẹ́, ká má sì bá àwọn tó ń ṣohun tí inú ẹ̀ ò dùn sí ṣọ̀rẹ́.—Sm. 1:1; 101:3.
14. Bí 1 Kọ́ríńtì 10:31 ṣe sọ, kí ni díẹ̀ lára nǹkan tá a lè máa ṣe lójoojúmọ́ láti múnú Jèhófà dùn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Ka 1 Kọ́ríńtì 10:31. Ó ṣe pàtàkì ká máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Àwọn nǹkan tí Jèhófà fẹ́ kọjá ká máa lọ wàásù, ká sì máa lọ sípàdé. Ó tún kan àwọn ohun tá à ń ṣe lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá jólóòótọ́ nínú ohun gbogbo, tá a sì ń fáwọn èèyàn ní nǹkan, àá múnú Jèhófà dùn. (2 Kọ́r. 8:21; 9:7) Ó tún fẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ìléra wa. Tá a bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa, àá máa tọ́jú ara wa. Kò yẹ ká máa ṣàṣejù tó bá dọ̀rọ̀ oúnjẹ àti ohun mímu, àá sì máa ṣe ohun táá jẹ́ kára wa jí pépé. Tá a bá ń sapá láti ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ títí kan àwọn nǹkan tá à ń ṣe lójoojúmọ́, àá túbọ̀ sún mọ́ ọn.—Lúùkù 16:10.
Ó yẹ ká máa wa ọkọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, ká máa ṣeré ìmárale, ká máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, ká sì máa ṣaájò àwọn èèyàn. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa múnú Jèhófà dùn (Wo ìpínrọ̀ 14)
15. Báwo ni Jèhófà ṣe fẹ́ ká máa ṣe sáwọn èèyàn?
15 Jèhófà máa ń fi inúure hàn sáwọn olódodo àtàwọn aláìṣòdodo. (Mát. 5:45) Ohun tó sì fẹ́ káwa náà máa ṣe nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ‘kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ ẹnì kankan láìdáa, kò yẹ ká jẹ́ oníjà, àmọ́ ó yẹ ká jẹ́ oníwà tútù sí gbogbo èèyàn.’ (Títù 3:2) Tá a bá ń rántí àwọn nǹkan yìí, a ò ní máa fojú pa àwọn èèyàn rẹ́ torí pé wọn ò fara mọ́ ohun tá a gbà gbọ́. (2 Tím. 2:23-25) Tá a bá ń fi inúure hàn sáwọn èèyàn, tá a sì ń gba tiwọn rò, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Ó YẸ KÁ TÚBỌ̀ SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN TÁ A BÁ ṢÀṢÌṢE
16. Báwo ni nǹkan ṣe rí lára ẹni tó kọ Sáàmù 73 lẹ́yìn tó ti ń sin Jèhófà bọ̀?
16 Lẹ́yìn tó o ti ń sin Jèhófà, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ ẹ mọ́ ńkọ́? Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó kọ Sáàmù 73. Ó sọ pé: “Ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lójú ọ̀nà; díẹ̀ ló kù kí ẹsẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́.” (Sm. 73:2) Ó gbà pé ọkàn òun “korò,” òun ò sì “nírònú,” ó sọ pé òun “dà bí ẹranko tí kò ní làákàyè” níwájú Jèhófà. (Sm. 73:21, 22) Àmọ́ ṣé ohun tó ń rò ni pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ òun mọ́ torí pé òun ní èrò tí kò tọ́?
17. (a) Nígbà tí nǹkan tojú sú onísáàmù yẹn, kí ló ṣe? (b) Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí onísáàmù náà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
17 Tí onísáàmù yẹn bá rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ òun, kò pẹ́ rárá tó fi pèrò dà. Ó jọ pé nígbà tí nǹkan tojú sú u, ó rí i pé ó yẹ kóun túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó sọ pé: “Àmọ́ ní báyìí, ọ̀dọ̀ rẹ ni mo wà nígbà gbogbo [Jèhófà]; o ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. O fi ìmọ̀ràn rẹ ṣamọ̀nà mi, lẹ́yìn náà, wàá mú mi wọnú ògo.” (Sm. 73:23, 24) Ó yẹ káwa náà bẹ Jèhófà pé kó fún wa lókun tá a bá rí i pé ìgbàgbọ́ wa ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára tàbí tá a bá rẹ̀wẹ̀sì. (Sm. 73:26; 94:18) Tá a bá tiẹ̀ ṣàṣìṣe, ó yẹ ká tètè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà torí ó dá wa lójú pé ó “ṣe tán láti dárí jini.” (Sm. 86:5) Ìgbà tá a bá rẹ̀wẹ̀sì gan-an ló yẹ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.—Sm. 103:13, 14.
Tá a bá rí i pé ìgbàgbọ́ wa ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára, ó yẹ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ìyẹn ni pé ká tẹra mọ́ àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 17)
TÍTÍ LÁÉ LÀÁ MÁA SÚN MỌ́ ỌLỌ́RUN
18. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé títí láé làá máa sún mọ́ Jèhófà?
18 Títí ayé làá máa sún mọ́ Jèhófà, àá sì máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀. Bíbélì sọ pé ọ̀nà Jèhófà, ọgbọ́n ẹ̀ àti ìmọ̀ ẹ̀ “kọjá àwárí.”—Róòmù 11:33.
19. Kí ni Sáàmù sọ nípa ọjọ́ iwájú?
19 Sáàmù 79:13 sọ pé: “Àwa èèyàn rẹ àti agbo ẹran ibi ìjẹko rẹ yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé; a ó sì máa kéde ìyìn rẹ láti ìran dé ìran.” Bó o bá ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ Ọlọ́run, á dá ẹ lójú pé ó máa bù kún ẹ títí láé, wàá sì lè sọ pé: “Ọlọ́run ni àpáta ọkàn mi àti ìpín mi títí láé.”—Sm. 73:26.
ORIN 32 Dúró Ti Jèhófà!
a Ó yẹ káwọn tó ní ìrẹ̀wẹ̀sì, àníyàn àti ẹ̀dùn ọkàn tó le lọ rí dọ́kítà. Kó o lè mọ̀ sí i, wo Ilé Ìṣọ́, No. 1 2023.