ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 43
ORIN 90 Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
Bó O Ṣe Lè Borí Èrò Tí Ò Tọ́
“Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú.” —1 TẸS. 5:21.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè borí èrò tí ò tọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà.
1-2. (a) Èrò tí ò tọ́ wo làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lè ní? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
LẸ́Ẹ̀KỌ̀Ọ̀KAN, gbogbo wa la máa ń ní èrò tí ò tọ́,a yálà ọmọdé ni wá àbí àgbàlagbà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lè máa rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ òun. Ìyẹn lè jẹ́ kó sọ pé òun ò ní ṣèrìbọmi. Ẹ jẹ́ ká tún wo arákùnrin kan tó gbájú mọ́ iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run láti kékeré dípò kó máa wá bó ṣe máa lówó rẹpẹtẹ. Ní báyìí tó ti ní ìdílé tiẹ̀, tí ò sì fi bẹ́ẹ̀ lówó láti gbọ́ bùkátà wọn, ó lè máa rò pé ìpinnu tóun ṣe nígbà tóun wà lọ́dọ̀ọ́ yẹn ò dáa. Àpẹẹrẹ míì ni arábìnrin àgbàlagbà kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ lókun mọ́. Inú ẹ̀ lè má dùn torí kò lè ṣe tó bó ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ṣé o ti bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí rí: ‘Ṣé Jèhófà tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi? Ṣé ó tiẹ̀ yẹ kí n fi nǹkan tó lè jẹ́ kí n dolówó sílẹ̀ torí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ṣé mo ṣì wúlò fún Jèhófà?’
2 Ó yẹ ká dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè mú ká má sin Jèhófà mọ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń rò pé (1) Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ wa, (2) pé àwọn ìpinnu tí ò dáa la ṣe tàbí (3) pé a ò wúlò fún Jèhófà mọ́.
BÁ A ṢE LÈ MÚ ÈRÒ TÍ Ò TỌ́ KÚRÒ LỌ́KÀN
3. Kí la lè ṣe láti mú èrò tí ò tọ́ kúrò lọ́kàn?
3 Ohun táá jẹ́ ká mú èrò tí ò tọ́ kúrò lọ́kàn ni pé ká máa yẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wò ká lè rí ìdáhùn àwọn nǹkan tó ń jẹ wá lọ́kàn. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á lágbára sí i, àá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àá sì lè “dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.”—1 Kọ́r. 16:13.
4. Báwo la ṣe lè “máa wádìí ohun gbogbo dájú”? (1 Tẹsalóníkà 5:21)
4 Ka 1 Tẹsalóníkà 5:21. Kíyè sí pé Bíbélì rọ̀ wá pé ká “máa wádìí ohun gbogbo dájú.” Báwo la ṣe máa ṣe é? Tí ohun tá a gbà gbọ́ ò bá dá wa lójú, ó yẹ ká ṣèwádìí ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́ tó rò pé Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ òun. Ṣé ó yẹ kó gbà pé èrò yẹn tọ́? Rárá, ó yẹ kó “wádìí ohun gbogbo dájú,” ìyẹn ni pé kó mọ ohun tí Jèhófà sọ nípa ọ̀rọ̀ náà.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àwọn ìbéèrè wa?
5 Tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ṣe ló máa ń dà bíi pé Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀ tààràtà. Tá a bá kàn ka Bíbélì lásán, a ò lè mọ èrò Jèhófà nípa ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn, ó gba pé ká ṣe àwọn nǹkan kan. Torí náà, àwọn ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tó ń jẹ wá lọ́kàn ló yẹ ká kà. A lè lo àwọn ìwé àti fídíò tí ètò Ọlọ́run ṣe láti ṣèwádìí nípa ẹ̀. (Òwe 2:3-6) Ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, ká lè rí ìdáhùn nínú ìwádìí tá a fẹ́ ṣe. Lẹ́yìn náà, ká wo àwọn ìlànà Bíbélì àtàwọn ìsọfúnni tó máa ràn wá lọ́wọ́. Ohun míì tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká ka ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ìgbà àtijọ́ tọ́rọ̀ wa jọra.
6. Báwo làwọn ìpàdé wa ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú èrò tí ò tọ́ kúrò lọ́kàn?
6 Jèhófà tún máa ń bá wa sọ̀rọ̀ nípàdé. Tá a bá ń wá sípàdé déédéé, a lè gbọ́ ọ̀rọ̀ kan nínú àsọyé tàbí ohun tẹ́nì kan sọ nígbà tó ń dáhùn, ó sì lè jẹ́ ohun tó sọ yẹn ló máa jẹ́ ká mú èrò tí ò tọ́ kúrò lọ́kàn. (Òwe 27:17) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa èrò mẹ́ta tí ò tọ́, tó yẹ ká mú kúrò lọ́kàn.
TÓ BÁ Ń ṢE Ẹ́ BÍI PÉ JÈHÓFÀ Ò NÍFẸ̀Ẹ́ Ẹ
7. Ìbéèrè wo làwọn kan máa ń bi ara wọn?
7 Ṣé o ti bi ara ẹ rí pé, ‘Ṣé Jèhófà tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi?’ Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò já mọ́ nǹkan kan, ó lè jẹ́ kó o máa rò pé o ò lè di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run. Ó ṣeé ṣe kí Ọba Dáfídì ti nírú èrò yẹn rí. Ó yà á lẹ́nu pé bí Jèhófà ṣe tóbi tó, ó ń kíyè sí àwa èèyàn tí ò já mọ́ nǹkan kan, ìyẹn ló jẹ́ kó bi Jèhófà pé: “Jèhófà, kí ni èèyàn jẹ́, tí o fi ń kíyè sí i àti ọmọ ẹni kíkú, tí o fi ń fiyè sí i?” (Sm. 144:3) Ibo la ti wá lè rí ìdáhùn ìbéèrè náà, “Ṣé Jèhófà tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi?”
8. Bí 1 Sámúẹ́lì 16:6, 7, 10-12 ṣe sọ, kí ni Jèhófà máa ń kíyè sí lára wa?
8 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń kíyè sí ẹni táwọn èèyàn ń fojú pa rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Jèhófà ní kí Sámúẹ́lì lọ sílé Jésè pé kó lọ yan ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀ láti di ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú. Nígbà tó débẹ̀, Jésè pe méje lára àwọn ọmọkùnrin ẹ̀ mẹ́jọ, àmọ́ Dáfídì tó kéré jù ò sí níbẹ̀.b Síbẹ̀, Dáfídì ni Jèhófà yàn. (Ka 1 Sámúẹ́lì 16:6, 7, 10-12.) Jèhófà mọ Dáfídì dáadáa, ó sì mọ̀ pé ọ̀dọ́kùnrin náà nífẹ̀ẹ́ òun gan-an.
9. Kí ló jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ẹ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ tó fi hàn pé ó ń rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe. Ó ń fún ẹ nímọ̀ràn tó dáa, tó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Sm. 32:8) Torí pé Jèhófà mọ̀ ẹ́ dunjú ló jẹ́ kó lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Sm. 139:1) Tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà, tó o sì rí àǹfààní tó wà níbẹ̀, á jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó nífẹ̀ẹ́ ẹ. (1 Kíró. 28:9; Ìṣe 17:26, 27) Jèhófà ń rí bó o ṣe ń sìn ín, tó o sì ń ṣègbọràn. Ó rí àwọn ìwà tó dáa tó o ní, ó sì ṣe tán láti di ọ̀rẹ́ ẹ. (Jer. 17:10) Inú ẹ̀ sì máa dùn gan-an tíwọ náà bá di ọ̀rẹ́ ẹ̀.—1 Jòh. 4:19.
“Tí o bá wá [Jèhófà], á jẹ́ kí o rí òun.”—1 Kíró. 28:9 (Wo ìpínrọ̀ 9)c
TÓ O BÁ Ń KÁBÀÁMỌ̀ ÀWỌN ÌPINNU TÓ O TI ṢE
10. Tá a bá ń ronú nípa ìpinnu tá a ti ṣe sẹ́yìn, àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa?
10 Nígbà míì, àwọn kan máa ń ronú nípa ìpinnu tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, á sì máa ṣe wọ́n bíi pé wọn ò ṣe ìpinnu tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ti fi àwọn nǹkan tó lè jẹ́ kí wọ́n di olówó sílẹ̀ torí kí wọ́n lè túbọ̀ ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n lè wá máa rí àwọn tí wọ́n mọ̀, tí wọ́n ṣèpinnu tó yàtọ̀ sí tiwọn, tí wọ́n ti dolówó, tí wọ́n sì ń jayé orí wọn. Ìyẹn lè mú kí wọ́n máa bi ara wọn pé: ‘Ṣé ó tiẹ̀ yẹ kí n fi nǹkan tó lè jẹ́ kí n dolówó sílẹ̀ torí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Ṣé àwọn nǹkan tí mo fi sílẹ̀ yẹn ò jẹ́ kí n pàdánù àwọn àǹfààní míì?’
11. Èrò tí ò tọ́ wo lẹni tó kọ Sáàmù 73 ní?
11 Tíwọ náà bá ń bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yẹn, á dáa kó o ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó kọ Sáàmù 73. Ó rí i pé àwọn tí ò sin Jèhófà ní ìlera tó jí pépé, wọ́n ní ọrọ̀, ayé sì rọ̀ wọ́n lọ́rùn. (Sm. 73:3-5, 12) Bó ṣe ń rí i pé nǹkan ń lọ dáadáa fún wọn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé kò sí èrè kankan nínú bóun ṣe ń sin Jèhófà. Nítorí èrò tó ní yìí, ó sọ pé: “Ìdààmú bá mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.” (Sm. 73:13, 14) Àmọ́, kí ló ràn án lọ́wọ́ láti borí èrò tí ò tọ́ yìí?
12. Kí ni Sáàmù 73:16-18 sọ pé ó jẹ́ kí onísáàmù yẹn yí èrò ẹ̀ pa dà?
12 Ka Sáàmù 73:16-18. Onísáàmù náà wọ ibi mímọ́ Jèhófà. Nígbà tó débẹ̀, ó ṣeé ṣe fún un láti ronú lọ́nà tó tọ́. Ó wá rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé rọ àwọn kan lára wọn lọ́rùn, ìgbẹ̀yìn wọn ò ní dáa. Ní báyìí tó ti mọ ohun tó máa gbẹ̀yìn wọn, ọkàn ẹ̀ balẹ̀, ó wá gbà pé kéèyàn máa sin Jèhófà ló dáa jù. Torí náà, ó pinnu pé òun á máa sin Jèhófà nìṣó.—Sm. 73:23-28.
13. Kí ló máa jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ tó o bá ń kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó o ti ṣe sẹ́yìn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Tó o bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, ọkàn tìẹ náà máa balẹ̀ bíi ti onísáàmù yẹn. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ronú nípa àjọṣe tó dáa tó o ní pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn nǹkan rere tó ti ṣe fún ẹ, kó o wá fi wé ohun tó máa gbẹ̀yìn àwọn tí ò sin Jèhófà tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n ní nínú ayé yìí nìkan lèrè wọn. Wọ́n lè máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lé nǹkan tara torí wọn ò gbà pé ìrètí kankan wà fún wọn lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan rere ni Jèhófà ń ṣe fún wa báyìí, ó sì ṣèlérí pé a máa gbádùn èyí tó jùyẹn lọ lọ́jọ́ iwájú. (Sm. 145:16) Tún rò ó wò ná: Ṣé ó tiẹ̀ dá ẹ lójú pé o mọ bí ìgbésí ayé ẹ ì bá ṣe rí ká sọ pé nǹkan míì lo fayé ẹ ṣe? Torí náà, ohun tó dájú ni pé àwọn tó pinnu pé àwọn ò ní lé nǹkan tara torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ò ní kábàámọ̀ ìpinnu tí wọ́n ṣe láé, wọ́n á sì máa láyọ̀.
Máa fojú inú wo àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣèlérí lọ́jọ́ iwájú (Wo ìpínrọ̀ 13)d
TÓ O BÁ Ń RÒ PÉ O Ò WÚLÒ FÚN JÈHÓFÀ
14. Kí ló lè mú káwọn kan má lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ìbéèrè wo ni wọ́n sì lè máa bi ara wọn?
14 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan ò lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ nítorí ọjọ́ ogbó, àìsàn tàbí àwọn àìlera kan. Ìyẹn lè mú kí wọ́n máa rò pé àwọn ò ṣeyebíye lójú Jèhófà. Wọ́n lè máa bi ara wọn pé, ‘Ṣé mo ṣì wúlò fún Jèhófà báyìí?’
15. Kí ló dá ẹni tó kọ Sáàmù 71 lójú?
15 Ẹni tó kọ Sáàmù 71 náà ti bi ara ẹ̀ nírú ìbéèrè yẹn rí. Ó bẹ Jèhófà pé: “Má pa mí tì nígbà tí mi ò bá lágbára mọ́.” (Sm. 71:9, 18) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé onísáàmù yìí ti ń rẹ̀wẹ̀sì, ó dá a lójú pé tóun bá ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn, ó máa tọ́ òun sọ́nà, ó sì máa fún òun lókun. Onísáàmù yìí wá mọ̀ pé inú Jèhófà máa ń dùn sáwọn tó bá ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, láìka ìṣòro tí wọ́n ní sí.—Sm. 37:23-25.
16. Àwọn nǹkan wo làwọn àgbàlagbà lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? (Sáàmù 92:12-15)
16 Ẹ̀yin àgbàlagbà wa ọ̀wọ́n, ojú tí Jèhófà fi ń wò yín ni kẹ́ ẹ máa fi wo ara yín. Ó máa fún yín lókun kẹ́ ẹ lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, kódà tẹ́ ò bá tiẹ̀ lágbára mọ́ torí pé ẹ ti ń dàgbà. (Ka Sáàmù 92:12-15.) Dípò kẹ́ ẹ máa ronú nípa àwọn nǹkan tẹ́ ò lè ṣe, àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè ṣe ni kẹ́ ẹ gbájú mọ́. Bí àpẹẹrẹ, táwọn ará bá rí i pé ẹ jẹ́ olóòótọ́, tẹ́ ẹ sì ń fìfẹ́ hàn sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, ó máa fún wọn níṣìírí. Ẹ lè sọ fáwọn ará nípa bí Jèhófà ṣe ń ràn yín lọ́wọ́ títí di báyìí, ẹ sì lè jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìlérí Jèhófà tẹ́ ẹ̀ ń retí lọ́jọ́ iwájú. Bákan náà, ẹ má gbàgbé láti máa gbàdúrà fáwọn ará torí pé ó máa ṣe wọ́n láǹfààní gan-an. (1 Pét. 3:12) Torí náà, bóyá a lè ṣe púpọ̀ sí i tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wa la lè ṣe ohun kan fún Jèhófà àtàwọn ará.
17. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì?
17 Tó o bá rẹ̀wẹ̀sì torí pé o ò lè ṣe tó ti tẹ́lẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, mọ̀ dájú pé ó mọyì àwọn nǹkan tó ò ń ṣe báyìí. Àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè fẹ́ máa fi ara ẹ wé àwọn ẹlòmíì. Má ṣe bẹ́ẹ̀ rárá! Kí nìdí tí ò fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà kì í fi wá wé àwọn ẹlòmíì. (Gál. 6:4) Bí àpẹẹrẹ, Màríà fún Jésù ní òróró onílọ́fínńdà tó wọ́n gan-an. (Jòh. 12:3-5) Àmọ́, opó aláìní yẹn fi ẹyọ owó kéékèèké méjì tí kò níye lórí sínú àpótí tó wà nínú tẹ́ńpìlì. (Lúùkù 21:1-4) Síbẹ̀, Jésù ò fi ohun táwọn méjèèjì ṣe wéra. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó rí i pé ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní ló mú kí wọ́n ṣe ohun tí wọ́n ṣe. Bákan náà lónìí, Jèhófà mọyì ohunkóhun tá a bá ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn ẹ̀ bó ti wù kó kéré mọ, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé torí a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ tọkàntọkàn la fi ṣe é.
18. Kí ló máa jẹ́ ká borí èrò tí ò tọ́? (Wo àpótí náà “Bíbélì Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Borí Èrò Tí Ò Tọ́.”)
18 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo wa la máa ń ní èrò tí ò tọ́. Àwọn ohun tá a ti jíròrò ti jẹ́ ká rí i pé, Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí èrò tí ò tọ́. Torí náà, tó o bá ń ní èrò tí ò tọ́, ó yẹ kó o ṣiṣẹ́ kára láti borí ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀, á sì dá ẹ lójú pé ohun tó tọ́ lò ń ṣe. Mọ̀ dájú pé Jèhófà mọ̀ ẹ́ dáadáa. Ó mọ gbogbo nǹkan tó o ti fi sílẹ̀ kó o lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn ẹ̀, ó sì máa san èrè fún ẹ. Torí náà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwa olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, á sì máa bójú tó wa.
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
a ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Nínú àpilẹ̀kọ yìí, èrò tí ò tọ́ ni ohun tó ń jẹ́ ká máa rò pé a ò ṣeyebíye lójú Jèhófà tàbí tó ń jẹ́ ká kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó dáa tá a ti ṣe sẹ́yìn. Èrò tí ò tọ́ yìí kì í ṣe iyèméjì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ pé kì í jẹ́ kéèyàn nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí tó ṣe.
b Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò sọ ọjọ́ orí Dáfídì nígbà tí Jèhófà yàn án, ó ṣeé ṣe kó má tíì pé ọmọ ogún (20) ọdún nígbà yẹn.—Wo Ilé Ìṣọ́ September 1, 2011, ojú ìwé 29, ìpínrọ̀ 2.
c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Ọ̀dọ́bìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń ka Bíbélì kí Jèhófà lè tọ́ ọ sọ́nà.
d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń ṣiṣẹ́ kára kó lè bójú tó ìdílé ẹ̀, àmọ́ ó ń ronú nípa bí ayé ṣe máa rí nínú Párádísè.