ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sjj orin 111
  • Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
  • “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Ayọ̀ Wa Pọ̀
    Kọrin sí Jèhófà
  • Inú Mi Ń Dùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Rẹ
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Ìdùnnú​—Ànímọ́ Rere Tí Ọlọ́run Ń Fúnni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Orísun Ayọ̀ Wa
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
Àwọn Míì
“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
sjj orin 111

ORIN 111

Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀

Bíi Ti Orí Ìwé

(Mátíù 5:12)

  1. 1. Bí a ṣe ń rí tí àwọn èèyàn

    Tó ń dara pọ̀ mọ́ wa ń pọ̀ sí i,

    Látinú gbogbo ‘rílẹ̀-èdè

    Mú káyọ̀ wa pọ̀ púpọ̀ gan-an.

    À ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́

    Tí à ń kọ́ nínú Bíbélì.

    À ń fi àwọn ẹ̀kọ́ yìí sílò;

    Èyí ń mú káyọ̀ wa pọ̀ sí i.

    Ayọ̀ ti wá kúnnú ọkàn wa,

    Ayọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà.

    Bí ‘ṣòro àtìpọ́njú bá dé,

    Jèhófà yóò fún wa lókun.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, ìwọ layọ̀ wa,

    Àwọn iṣẹ́ rẹ ń dùn mọ́ wa.

    Èrò rẹ jinlẹ̀, iṣẹ́ rẹ tóbi;

    Oore àtagbára rẹ pọ̀!

  2. 2. Ayọ̀ wa kún bá a ṣe ń ríṣẹ́ rẹ

    Lójú ọ̀run, lórí ilẹ̀;

    Omi òkun sì lọ salalu,

    A fìyìn fún ọ, Jèhófà.

    A ti bí Ìjọba Ọlọ́run,

    Ọ̀pọ̀ ìbùkún ló ń mú bọ̀.

    À ń wàásù rẹ̀ lọ bí aṣẹ́gun,

    À ń fayọ̀ kéde fáráyé.

    Ayọ̀ àìlópin wọlé dé tán,

    Ìgbà ọ̀tun sì ti dé tán.

    Ọ̀run àtayé tuntun yóò mú

    Ìdùnnú ayérayé wá.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà, ìwọ layọ̀ wa,

    Àwọn iṣẹ́ rẹ ńdùn mọ́ wa.

    Èrò rẹ jinlẹ̀, iṣẹ́ rẹ tóbi;

    Oore àtagbára rẹ pọ̀!

(Tún wo Diu. 16:15; Àìsá. 12:6; Jòh. 15:11.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́