ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 20
ORIN 7 Jèhófà Ni Agbára Wa
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Pé Ó Máa Tù Ẹ́ Nínú
“Ìyìn ni fún . . . Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 KỌ́R. 1:3.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe tu àwọn Júù tó lọ sígbèkùn nínú.
1. Ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí fáwọn Júù tó lọ sígbèkùn.
Ẹ FOJÚ inú wo bí nǹkan ṣe rí fáwọn Júù tó lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Ìṣojú wọn ni wọ́n ṣe pa ìlú wọn run. Torí ìwà burúkú táwọn àtàwọn baba ńlá wọn hù, wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ sílẹ̀ àjèjì. (2 Kíró. 36:15, 16, 20, 21) Lóòótọ́, àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì lómìnira láti ṣe àwọn nǹkan kan. (Jer. 29:4-7) Síbẹ̀, nǹkan ò rọrùn fún wọn rárá, kì í sì í ṣe irú ìgbésí ayé tí wọ́n fẹ́ nìyẹn. Àmọ́ báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn? Ẹ gbọ́ ohun tí ọ̀kan lára àwọn olóòótọ́ tó wà nígbèkùn náà sọ, ó ní: “Létí àwọn odò Bábílónì, ibẹ̀ la jókòó sí. A sunkún nígbà tí a rántí Síónì.” (Sm. 137:1) Àwọn tó wà nígbèkùn yìí ń fẹ́ ìtùnú, àmọ́ ta ló máa tù wọ́n nínú?
2-3. (a) Kí ni Jèhófà ṣe fáwọn Júù tó lọ sígbèkùn? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Jèhófà ni “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́r. 1:3) Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, ó máa ń tu gbogbo àwọn tó bá jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú. Jèhófà mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn tó lọ sígbèkùn yẹn máa ronú pìwà dà, wọ́n sì máa pa dà sọ́dọ̀ òun. (Àìsá. 59:20) Torí náà, ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ṣáájú kí wọ́n tó lọ sígbèkùn, Jèhófà fẹ̀mí ẹ̀ darí wòlíì Àìsáyà pé kó kọ ìwé Bíbélì kan. Orúkọ ìwé náà ni Àìsáyà. Kí nìdí tí Jèhófà fi ní kó kọ ìwé Bíbélì náà? Àìsáyà sọ ìdí náà, ó ní: “‘Ẹ tu àwọn èèyàn mi nínú, ẹ tù wọ́n nínú,’ ni Ọlọ́run yín wí.” (Àìsá. 40:1) Torí náà, ohun tí wòlíì Àìsáyà kọ yìí ni Jèhófà fi tu àwọn Júù tó wà nígbèkùn nínú.
3 Bíi tàwọn Júù tó lọ sígbèkùn yẹn, àwa náà nílò ìtùnú látìgbàdégbà. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò nǹkan mẹ́ta tí Jèhófà ṣe láti tu àwọn Júù yẹn nínú: (1) Ó ṣèlérí pé òun máa dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà, (2) ó jẹ́ káwọn èèyàn ẹ̀ nírètí, (3) ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Bá a ṣe ń jíròrò àwọn nǹkan yìí, kíyè sí àǹfààní tá a máa rí nínú bí Jèhófà ṣe ń fi ọ̀rọ̀ ẹ̀ tù wá nínú.
ALÁÀÁNÚ NI JÈHÓFÀ, Ó SÌ MÁA Ń DÁRÍ JINI
4. Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé aláàánú ni òun? (Àìsáyà 55:7)
4 “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” ni Jèhófà. (2 Kọ́r. 1:3) Ó sì fi hàn pé aláàánú lòun nígbà tó ṣèlérí pé òun máa dárí ji àwọn Júù tó ronú pìwà dà. (Ka Àìsáyà 55:7.) Ó sọ pé: “Màá ṣàánú rẹ nítorí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, tó wà títí láé.” (Àìsá. 54:8) Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe máa ṣàánú wọn? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù yìí ṣì gbọ́dọ̀ jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Jèhófà ṣèlérí pé òun ò ní gbàgbé wọn sí Bábílónì. Àsìkò díẹ̀ ni wọ́n máa fi wà nígbèkùn. (Àìsá. 40:2) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yẹn máa tu àwọn tó bá ronú pìwà dà nínú!
5. Kí nìdí tá a fi mọyì bí Jèhófà ṣe ń dárí jini ju báwọn Júù ṣe mọyì ẹ̀ lọ?
5 Kí la kọ́? Jèhófà ṣe tán láti dárí ji àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ pátápátá. Lónìí, a mọyì bí Jèhófà ṣe ń dárí jì wá ju báwọn Júù ṣe mọyì ẹ̀ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé a mọ nǹkan ńlá tí Jèhófà ṣe kó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méje (700) lẹ́yìn tí Àìsáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dárí jini, Jèhófà rán Ọmọ ẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé láti san ìràpadà nítorí gbogbo ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Ìràpadà yìí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ‘pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́’ pátápátá. (Ìṣe 3:19; Àìsá. 1:18; Éfé. 1:7) Ẹ ò rí i pé aláàánú ni Ọlọ́run tá à ń sìn!
6. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọlọ́run aláàánú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
6 Tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi torí àṣìṣe tá a ṣe, ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Àìsáyà 55:7 máa tù wá nínú. Àwọn kan lè máa dá ara wọn lẹ́bi torí àṣìṣe tí wọ́n ṣe kódà lẹ́yìn tí wọ́n ti ronú pìwà dà. Ẹni náà ṣì lè máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi tó bá rí i pé òun ṣì ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ òun. Àmọ́, ó dá wa lójú pé tá a bá ti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, tá a sì ti ṣàtúnṣe, Jèhófà ti dárí jì wá nìyẹn. Tí Jèhófà bá sì ti dárí jì wá, kì í rántí ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́. (Fi wé Jeremáyà 31:34.) Torí náà, tí Jèhófà bá ti gbàgbé àwọn àṣìṣe tá a ṣe sẹ́yìn, ó yẹ káwa náà gbàgbé ẹ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà làwọn nǹkan tá à ń ṣe báyìí, kì í ṣe àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn. (Ìsík. 33:14-16) Láìpẹ́, Jèhófà Baba wa aláàánú máa fòpin sí gbogbo ìyà tá à ń jẹ nítorí àṣìṣe wa.
Àwọn nǹkan tá à ń ṣe báyìí ló ṣe pàtàkì jù lójú Jèhófà, kì í ṣe àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn (Wo ìpínrọ̀ 6)
7. Tá a bá dẹ́ṣẹ̀ ńlá, àmọ́ tá à ń bò ó mọ́lẹ̀, kí ló máa jẹ́ ká jẹ́wọ́?
7 Kí ló yẹ ká ṣe tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi torí ẹ̀ṣẹ̀ tá à ń bò mọ́lẹ̀? Bíbélì sọ pé ká lọ bá àwọn alàgbà kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. (Jém. 5:14, 15) Síbẹ̀, ó lè má rọrùn fún wa láti gbà pé a ṣàṣìṣe. Àmọ́, ó máa rọrùn fún wa láti lọ bá àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yẹn tá a bá ti ronú pìwà dà, tá a sì ń rántí pé Jèhófà àtàwọn ọkùnrin tó yàn yìí máa fàánú hàn sí wa. Ẹ jẹ́ ká wo bí Jèhófà ṣe fàánú hàn sí Arákùnrin Arthura tí ọkàn ẹ̀ ń dá lẹ́bi ṣáá torí àṣìṣe tó ṣe. Ó sọ pé: “Nǹkan bí ọdún kan ni mo fi ń wo àwòrán ìṣekúṣe. Àmọ́ lẹ́yìn tí mo gbọ́ àsọyé kan tó dá lórí ẹ̀rí ọkàn, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ìyàwó mi àtàwọn alàgbà. Lẹ́yìn ìyẹn, ara tù mí, àmọ́ mo ṣì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn torí àṣìṣe tí mo ṣe. Àwọn alàgbà rán mi létí pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ mi, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa ló sì ṣe ń bá wa wí. Ọ̀rọ̀ ìtùnú tí wọ́n sọ yìí wọ̀ mí lọ́kàn, ó sì jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà ti dárí jì mí.” Ní báyìí, Arákùnrin Arthur ti di aṣáájú-ọ̀nà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ ò rí i pé ara tù wá gan-an bá a ṣe mọ̀ pé Jèhófà máa ń fàánú hàn sí wa tá a bá ronú pìwà dà!
JÈHÓFÀ JẸ́ KÁ NÍRÈTÍ
8. (a) Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fáwọn tó lọ sígbèkùn? (b) Bí Àìsáyà 40:29-31 ṣe sọ, kí ni ìlérí tí Jèhófà ṣe máa mú káwọn Júù tó ronú pìwà dà ṣe?
8 Tá a bá fojú èèyàn wò ó, ó jọ pé kò sírètí kankan fáwọn Júù tó wà nígbèkùn. Ìdí sì ni pé àwọn ará Bábílónì kì í fi àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú sílẹ̀. (Àìsá. 14:17) Láìka ìyẹn sí, Jèhófà ṣèlérí kan fáwọn èèyàn ẹ̀. Ó sọ pé òun máa dá wọn sílẹ̀, kò sì sóhun tó lè dá a dúró. (Àìsá. 44:26; 55:12) Lójú Jèhófà, bí ekuru lásán làwọn èèyàn Bábílónì. (Àìsá. 40:15) Tí afẹ́fẹ́ lásán bá fẹ́, ṣe ni wọ́n máa pòórá. Báwo wá ni ìlérí Jèhófà ṣe rí lára àwọn tó wà nígbèkùn? Ó dájú pé ó tù wọ́n nínú gan-an, kódà, ó ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àìsáyà sọ pé: “Àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà máa jèrè okun pa dà.” (Ka Àìsáyà 40:29-31.) Ìlérí yìí fún wọn lágbára débi pé ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n “fi ìyẹ́ fò lọ sókè réré bí ẹyẹ idì.”
9. Kí ló mú kó dá àwọn tó wà nígbèkùn lójú pé ìlérí Jèhófà máa ṣẹ?
9 Jèhófà ṣe àwọn nǹkan tó jẹ́ kó dá àwọn tó lọ sígbèkùn lójú pé ìlérí òun máa ṣẹ. Àwọn nǹkan wo ló ṣe? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ. Wọ́n mọ̀ pé àwọn ará Ásíríà ti ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá, wọ́n sì ti kó wọn lọ sígbèkùn. (Àìsá. 8:4) Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n rí i nígbà táwọn ará Bábílónì wá pa Jerúsálẹ́mù run, tí wọ́n sì kó àwọn tó ń gbébẹ̀ lọ sígbèkùn. (Àìsá. 39:5-7) Wọ́n tún rí ìgbà tí wọ́n fọ́ ojú Ọba Sedekáyà, tí wọ́n sì rán an lọ sígbèkùn ní Bábílónì. (Jer. 39:7; Ìsík. 12:12, 13) Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ló ṣẹ. (Àìsá. 42:9; 46:10) Torí náà, àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí máa jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé ìlérí tí Jèhófà ṣe pé wọ́n máa pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn máa ṣẹ.
10. Kí ló máa jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ lágbára láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?
10 Kí la kọ́? Tá a bá rẹ̀wẹ̀sì, ìrètí tá a ní máa tù wá nínú, á sì jẹ́ ká lágbára. Àsìkò tá à ń gbé yìí nira gan-an, àwọn ọ̀tá wa sì lágbára. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kẹ́rù bà wá. Ìdí ni pé Jèhófà ti ṣèlérí àgbàyanu kan fún wa, ìlérí náà sì ni pé a máa wà láàyè títí láé níbi tí àlàáfíà àti ìfọ̀kànbalẹ̀ máa wà. Ó yẹ ká jẹ́ kí ìlérí yìí máa fún wa láyọ̀ nígbà gbogbo. Tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìrètí tá a ní ò ní dá wa lójú, ṣe ló máa dà bí ìgbà tá à ń wo ọgbà kan tó rẹwà gan-an látojú gíláàsì tó dọ̀tí. Báwo la ṣe lè “nu gíláàsì náà,” kí ìrètí wa lè lágbára? Àtìgbàdégbà ló yẹ ká máa ronú nípa bí ìgbésí ayé wa ṣe máa rí nínú ayé tuntun. A lè ka àwọn àpilẹ̀kọ, ká wo fídíò, ká sì tẹ́tí sáwọn orin tó sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tá a ní. Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ń gbàdúrà, a lè jẹ́ kí Jèhófà mọ àwọn ohun tá à ń retí nínú ayé tuntun.
11. Kí ló ran arábìnrin kan tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́ tó jẹ́ kó pa dà lókun?
11 Nígbà tí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Joy ń ṣàìsàn tó le gan-an, ìrètí tó ní tù ú nínú, ó sì fún un lókun. Ó sọ pé: “Tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì, mo máa ń sọ bó ṣe ń ṣe mí fún Jèhófà torí mo mọ̀ pé ọ̀rọ̀ mi yé e. Jèhófà sì máa ń gbọ́ àdúrà mi torí ó ń fún mi ní ‘agbára tó kọjá ti ẹ̀dá.’” (2 Kọ́r. 4:7) Yàtọ̀ síyẹn, Arábìnrin Joy tún máa ń wo ara ẹ̀ bíi pé òun wà nínú ayé tuntun níbi tí kò ti ní sí “ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’” (Àìsá. 33:24) Táwa náà bá ń sọ bó ṣe ń ṣe wá fún Jèhófà, tá a sì jẹ́ kí ìrètí tá a ní dá wa lójú, a máa pa dà lókun.
12. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
12 Bí Jèhófà ṣe fi dá àwọn Júù yẹn lójú pé àwọn ìlérí òun máa ṣẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe fi dá wa lójú pé àwọn ìlérí òun máa ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ń ṣẹ báyìí. Bí àpẹẹrẹ, a rí i pé ìjọba tó ń ṣàkóso ayé báyìí ‘lágbára lápá kan, kò sì lágbára lápá kan.’ (Dán. 2:42, 43) Yàtọ̀ síyẹn, a tún ń gbọ́ nípa ‘ìmìtìtì ilẹ̀ láti ibì kan dé ibòmíì,’ a sì ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní “gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:7, 14) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí àtàwọn míì jẹ́ kọ́kàn wa túbọ̀ balẹ̀ pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń ṣẹ lónìí ń jẹ́ kó túbọ̀ dá wa lójú pé àwọn ìlérí Jèhófà máa ṣẹ (Wo ìpínrọ̀ 12)
JÈHÓFÀ MÁA Ń JẸ́ KỌ́KÀN WA BALẸ̀
13. (a) Ìṣòro wo làwọn Júù máa ní tí wọ́n bá kúrò nígbèkùn? (b) Bó ṣe wà nínú Àìsáyà 41:10-13, báwo ni Jèhófà ṣe tu àwọn Júù tó wà nígbèkùn nínú?
13 Jèhófà ṣèlérí àgbàyanu kan fáwọn Júù tó wà nígbèkùn, ìlérí yẹn sì tù wọ́n nínú, síbẹ̀ ó mọ̀ pé wọ́n máa láwọn ìṣòro kan nígbà tí wọ́n bá dá wọn sílẹ̀. Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá ku díẹ̀ kí wọ́n dá àwọn Júù tó wà nígbèkùn sílẹ̀, ọ̀gágun kan máa gbógun ja Bábílónì àtàwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká. (Àìsá. 41:2-5) Ṣé ó yẹ kíyẹn kó ìdààmú bá àwọn Júù? Jèhófà ti fi àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn nígbà tó sọ pé: “Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.” (Ka Àìsáyà 41:10-13.) Kí ni Jèhófà ń sọ nígbà tó sọ pé “Èmi ni Ọlọ́run rẹ”? Kì í ṣe pé ó ń rán wọn létí pé òun ló yẹ kí wọ́n máa jọ́sìn torí àwọn Júù yẹn mọ̀ bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé òun ò ní fi wọ́n sílẹ̀ láé.—Sm. 118:6.
14. Kí ni nǹkan míì tí Jèhófà ṣe láti fi àwọn Júù tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀?
14 Jèhófà tún fi àwọn Júù tó wà nígbèkùn lọ́kàn balẹ̀ nígbà tó jẹ́ kí wọ́n rí bí agbára àti ìmọ̀ òun ṣe pọ̀ tó. Ó ní káwọn Júù yẹn gbójú sókè wo àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run. Ó sọ fún wọn pé kì í ṣe pé òun dá àwọn ìràwọ̀ nìkan ni, òun tún mọ orúkọ gbogbo wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. (Àìsá. 40:25-28) Tó bá mọ orúkọ àwọn ìràwọ̀ yẹn lọ́kọ̀ọ̀kan, ṣé kò wá ní mọ orúkọ àwa ìránṣẹ́ ẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? Tí Jèhófà bá sì lágbára láti dá àwọn ìràwọ̀, ó dájú pé ó lágbára láti ran àwọn èèyàn ẹ̀ lọ́wọ́. Torí náà, kò sídìí kankan tó fi yẹ káwọn Júù tó wà nígbèkùn yẹn máa bẹ̀rù.
15. Báwo ni Jèhófà ṣe múra àwọn Júù yẹn sílẹ̀ de ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
15 Jèhófà tún múra àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Nínú ìwé Àìsáyà, Ọlọ́run sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé: “Ẹ wọnú yàrá yín tó wà ní inú, kí ẹ sì ti àwọn ilẹ̀kùn yín mọ́ ara yín. Ẹ fi ara yín pa mọ́ fúngbà díẹ̀, títí ìbínú náà fi máa kọjá lọ.” (Àìsá. 26:20) Ó jọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti kọ́kọ́ ṣẹ nígbà tí Ọba Kírúsì ṣẹ́gun Bábílónì. Òpìtàn ilẹ̀ Gíríìkì kan sọ pé nígbà tí Kírúsì wọ ilẹ̀ Bábílónì, ó ní “kí [àwọn ọmọ ogun ẹ̀] pa gbogbo àwọn tí wọ́n bá rí níta.” Ẹ wo bí jìnnìjìnnì ṣe máa bo gbogbo àwọn ará Bábílónì! Àmọ́ nǹkan kan lè má ṣe àwọn Júù tó wà nígbèkùn yẹn torí pé wọ́n ṣe ohun tí Jèhófà sọ.
16. Kí nìdí tí ò fi yẹ kí jìnnìjìnnì bò wá torí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
16 Kí la kọ́? Láìpẹ́, ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀, irú èyí tí ò tíì ṣẹlẹ̀ rí nínú ìtàn àwa èèyàn. Tó bá bẹ̀rẹ̀, jìnnìjìnnì máa bo àwọn èèyàn níbi gbogbo, wọn ò sì ní mọ ohun tí wọ́n máa ṣe. Àmọ́ ọ̀rọ̀ àwa èèyàn Jèhófà ò ní rí bẹ́ẹ̀. Ìdí sì ni pé a mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run wa. A ò ní bẹ̀rù, ọkàn wa sì máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé “ìdáǹdè [wa] ń sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:28) Kódà nígbà tí àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè bá kọ lù wá, mìmì kan ò ní mì wá. Jèhófà máa fi àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ dáàbò bò wá, ó sì tún máa sọ àwọn ohun tó máa gba ẹ̀mí wa là fún wa. Báwo ló ṣe máa sọ àwọn nǹkan yìí fún wa? A ò tíì lè sọ, àfi ká ní sùúrù dìgbà yẹn. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé inú ìjọ la ti máa gbọ́ àwọn nǹkan tá a máa ṣe. Torí náà, ìjọ wa ló máa dà bí ‘yàrá inú,’ níbi tá a ti máa rí ààbò. Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ de ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú? Ó yẹ ká sún mọ́ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ká máa ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ fún wa, ká sì jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà ló ń darí wa nínú ètò ẹ̀.—Héb. 10:24, 25; 13:17.
Tá a bá ń ronú nípa bí agbára Jèhófà ṣe pọ̀ tó láti gbà wá là, a ò ní máa gbọ̀n jìnnìjìnnì torí àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá (Wo ìpínrọ̀ 16)b
17. Tó o bá fẹ́ kí Jèhófà tù ẹ́ nínú, kí lo máa ṣe?
17 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù tó wà nígbèkùn láwọn ìṣòro kan, Jèhófà ṣe àwọn nǹkan tó tù wọ́n nínú. Ó sì dájú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwa náà. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa tù ẹ́ nínú. Torí náà, nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa fàánú hàn sí ẹ. Jẹ́ kí ìrètí tó o ní dá ẹ lójú hán-ún hán-ún. Má gbàgbé pé Jèhófà ni Ọlọ́run rẹ, ó sì máa dáàbò bò ẹ́.
ORIN 3 Agbára Wa, Ìrètí Wa, Ìgbọ́kànlé Wa
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwọn ará kan pé jọ sínú yàrá. Ọkàn wọn balẹ̀ pé Jèhófà lágbára, ó sì máa dáàbò bo àwọn èèyàn ẹ̀ láìka ibi tí wọ́n wà sí.