ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w25 July ojú ìwé 26-30
  • “Ogun Náà Jẹ́ Ti Jèhófà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ogun Náà Jẹ́ Ti Jèhófà”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ TÓ NÍTARA LÓ TỌ́ MI DÀGBÀ
  • MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN LÓRÍLÉEṢẸ́ WA
  • MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ NÍ Ẹ̀KA TÓ Ń BÓJÚ TÓ Ọ̀RỌ̀ ÒFIN
  • À Ń GBÈJÀ ÌHÌN RERE, A SÌ Ń FÌDÍ Ẹ̀ MÚLẸ̀ LỌ́NÀ ÒFIN
  • JÈHÓFÀ O ṢEUN O!
  • Bí A Ṣe Jà fún Òmìnira Láti Lè Máa Sin Jèhófà Láìsí Ìdíwọ́
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • Dídáàbò Bo Ìhìn Rere Lọ́nà Òfin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìròyìn Nípa Àwọn Ẹjọ́
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
  • Ìjọba Ọlọ́run Nìkan Ṣoṣo Là Ń Tì Lẹ́yìn
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
w25 July ojú ìwé 26-30
Philip Brumley.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Ogun Náà Jẹ́ Ti Jèhófà”

GẸ́GẸ́ BÍ PHILIP BRUMLEY ṢE SỌ Ọ́

NÍ JANUARY 28, ọdún 2010, mo lọ sílùú Strasbourg, lórílẹ̀-èdè Faransé. Àmọ́ kì í ṣe torí pé mo fẹ́ lọ gbafẹ́ ni mo ṣe lọ síbẹ̀. Mo wà lára àwọn agbẹjọ́rò tí ètò Ọlọ́run ní kó lọ gbèjà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Ohun tó gbé wa lọ síbẹ̀ ni pé ìjọba ilẹ̀ Faransé sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ wọ́n ní owó orí tó tó mílíọ̀nù mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún owó dọ́là ($89,000,000). Àmọ́ owó yẹn kọ́ ló ṣe pàtàkì jù, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni orúkọ Jèhófà, ojú táwọn èèyàn fi ń wo àwa èèyàn ẹ̀ àti bí àá ṣe máa jọ́sìn ẹ̀ láìsí ìdíwọ́ kankan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ yẹn jẹ́ ká rí i pé “ogun náà jẹ́ ti Jèhófà.” (1 Sám. 17:47) Ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún yín.

Ọdún 1999 ni àríyànjiyàn yẹn bẹ̀rẹ̀. Ìjọba orílẹ̀-èdè Faransé sọ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè náà gbọ́dọ̀ san owó orí torí owó táwọn èèyàn fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ọlọ́run láti ọdún 1993 sí 1996. A gbé ẹjọ́ náà lọ sáwọn ilé ẹjọ́ tó wà nílẹ̀ Faransé, àmọ́ pàbó ni gbogbo ẹ̀ já sí. Lẹ́yìn náà, a lọ sílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, wọ́n sì sọ pé a jẹ̀bi, ìjọba wá gbẹ́sẹ̀ lé owó tó wà nínú àkáǹtì ẹ̀ka ọ́fíísì wa, owó náà sì ju mílíọ̀nù mẹ́fà ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta dọ́là lọ ($6,300,000). Níbi tọ́rọ̀ dé yìí, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù nìkan ló lè gbà wá. Àmọ́ kí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù tó dá ẹjọ́ náà, wọ́n sọ pé kí àwọn agbẹjọ́rò wa àtàwọn agbẹjọ́rò ìjọba kọ́kọ́ jọ sọ ọ̀rọ̀ náà níṣojú ọ̀kan lára àwọn aṣojú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn bóyá a lè yanjú ọ̀rọ̀ náà.

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn rán obìnrin kan wá láti ṣojú wọn. Èrò wa ni pé aṣojú náà máa rọ̀ wá pé ká san díẹ̀ lára owó tí ìjọba ní ká san, ká lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́, a mọ̀ pé tá a bá san díẹ̀ lára owó náà, kódà kó jẹ́ yúrò kan (€1) péré la san, a ti rú òfin Ọlọ́run nìyẹn. Àwọn ará fowó ṣètìlẹ́yìn kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú, torí náà owó náà kì í ṣe ti ìjọba. (Mát. 22:21) Síbẹ̀, a lọ bá aṣojú náà ṣèpàdé ká lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ilé ẹjọ́ náà.

Àwa agbẹjọ́rò ètò Ọlọ́run rèé níwájú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 2010

Ọ̀kan lára àwọn yàrá tí wọ́n ti ń ṣèpàdé la lò. Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀, aṣojú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn náà sọ pé ó yẹ káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Faransé san díẹ̀ lára owó tí wọ́n bù fún wa. Àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà mú ká bi í pé, “Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé iye tó ju mílíọ̀nù mẹ́fà ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta dọ́là ($6,300,000) lára owó wa tó wà ní báǹkì?”

Ó ya obìnrin náà lẹ́nu gan-an nígbà tó gbọ́ bẹ́ẹ̀. Nígbà táwọn agbẹjọ́rò ìjọba sọ pé òótọ́ ni pé ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé owó náà, ojú tó fi ń wo ẹjọ́ náà yí pa dà pátápátá. Ó bá wọn wí gan-an, ó sì sọ pé ìpàdé náà ti parí nìyẹn. Ìgbà yẹn ni mo wá rí i pé Jèhófà ti dá sọ́rọ̀ yìí lọ́nà tá ò rò ká lè jàre ẹjọ́ náà. Inú wa dùn gan-an nígbà tá a kúrò níbẹ̀, ká sòótọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn yà wá lẹ́nu.

Ní June 30, 2011, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá wa láre. Wọ́n fagi lé owó orí tí wọ́n ní ká san, wọ́n sì ní kí ìjọba dá owó tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé pa dà fún wa, kódà wọ́n ní kí wọ́n san gbogbo èlé tó ti gorí ẹ̀! Àwọn èèyàn lórílẹ̀-èdè Faransé ò lè gbàgbé ìdájọ́ yìí láé torí ó jẹ́ káwọn èèyàn Jèhófà lómìnira láti máa jọ́sìn ẹ̀. Ìbéèrè kan ṣoṣo tá a béèrè yẹn ló yí gbogbo ìdájọ́ náà pa dà bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ̀ pé a máa bi wọ́n ní ìbéèrè yẹn. Ṣe ló dà bí òkúta tí Dáfídì sọ lu Gòláyátì lágbárí. Kí ló jẹ́ ká jàre ẹjọ́ náà? A gbà pé “Ogun náà jẹ́ ti Jèhófà” bí Dáfídì ṣe sọ fún Gòláyátì.—1 Sám. 17:45-47.

Ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa dá wa láre nílé ẹjọ́ kọ́ nìyí. Títí di báyìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn olóṣèlú tó lágbára àtàwọn ẹlẹ́sìn tó lóókọ ń ta kò wá, a ti jàre ẹjọ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (1,225) ní orílẹ̀-èdè àádọ́rin (70) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti láwọn ilé ẹjọ́ gíga lágbàáyé. Àwọn ẹjọ́ tá a jàre yìí jẹ́ ká lómìnira láti jọ́sìn Jèhófà, ká sì máa wàásù. Ó tún jẹ́ ká lómìnira láti ṣe ohun tá a ti pinnu pé a ò ní gbẹ̀jẹ̀, a ò sì ní ṣe àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè.

Kí nìdí tí wọ́n fi ní kí n wà lára àwọn agbẹjọ́rò tó lọ ṣẹjọ́ nílẹ̀ Yúróòpù nígbà tó jẹ́ pé oríléeṣẹ́ wa nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni mo ti ń sìn?

ÀWỌN MÍṢỌ́NNÁRÌ TÓ NÍTARA LÓ TỌ́ MI DÀGBÀ

George lorúkọ bàbá mi, ìyá mi sì ń jẹ́ Lucille. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejìlá (12) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Lẹ́yìn náà, ètò Ọlọ́run rán wọn lọ sórílẹ̀-èdè Etiópíà, ibẹ̀ ni wọ́n sì bí mi sí lọ́dún 1956. Wọ́n sọ mí ní Philip kí n lè máa bá Fílípì ajíhìnrere tó wà nínú Bíbélì jẹ́ orúkọ. (Ìṣe 21:8) Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ìjọba fòfin de ìjọsìn wa. Òótọ́ ni pé mo ṣì kéré nígbà yẹn, àmọ́ mo rántí bá a ṣe máa ń jọ́sìn Jèhófà ní bòókẹ́lẹ́. Bá a ṣe ń jọ́sìn ní bòókẹ́lẹ́ yẹn máa ń múnú mi dùn gan-an, àmọ́ mi ò mọ̀ pé kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀! Ó dùn wá gan-an nígbà tí ìjọba sọ pé ká kúrò nílùú yẹn lọ́dún 1960.

Lọ́dún 1959, Arákùnrin Nathan H. Knorr (lápá òsì) wá kí ìdílé wa ní Addis Ababa, Etiópíà

Nígbà tí ìdílé wa kó lọ sílùú Wichita, ní ìpínlẹ̀ Kansas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn òbí mi ṣì máa ń fìtara wàásù bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, wọ́n sì kọ́ èmi, Judy ẹ̀gbọ́n mi obìnrin àti Leslie àbúrò mi ọkùnrin ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, orílẹ̀-èdè Etiópíà ni wọ́n bí àwọn náà sí. Mo ṣèrìbọmi nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá (13). Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ìdílé wa kó lọ sílùú Arequipa, lórílẹ̀-èdè Peru níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù.

Lọ́dún 1974 nígbà tí mo ṣì wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún (18), ẹ̀ka ọ́fíìsì Peru sọ pé kí èmi àtàwọn arákùnrin mẹ́rin míì máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Wọ́n ní ká lọ wàásù níbi táwọn èèyàn ò tíì gbọ́ ìwàásù, ìyẹn láwọn orí òkè Central Andes. Lára àwọn tá a máa wàásù fún ni àwọn tó ń sọ èdè Quechua àti Aymara lágbègbè yẹn. Mọ́tò kan tó dà bí ilé la fi ń rìnrìn àjò, a pe mọ́tò náà ní Áàkì torí pé ó dà bí àpótí. Mo máa ń rántí bí mo ṣe ń fi Bíbélì ṣàlàyé fáwọn èèyàn náà pé Jèhófà ò ní pẹ́ mú òṣì, àìsàn àti ikú kúrò, ó sì máa ń múnú mi dùn gan-an. (Ìfi. 21:3, 4) Nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn náà wá sin Jèhófà.

À ń gbé mọ́tò àfiṣelé wa gba inú omi tó jìn.

Mọ́tò wa “Áàkì” tá à ń lò lọ́dún 1974

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ ÌSÌN LÓRÍLÉEṢẸ́ WA

Lọ́dún 1977, nígbà tí Arákùnrin Albert Schroeder tó wà lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí Peru, ó sọ pé kí n gba fọ́ọ̀mù Bẹ́tẹ́lì kí n lè wá sìn lóríléeṣẹ́ wa. Mo ṣe ohun tí wọ́n sọ. Torí náà ní June 17, 1977, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn. Ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́ tí mo lò níbẹ̀, ẹ̀ka Ìmọ́tótó àti Àtúnṣe ni mo ti ṣiṣẹ́.

Ọjọ́ tá a ṣègbéyàwó lọ́dún 1979

Ní June 1978, mo pàdé Arabìnrin Elizabeth Avallone níbi àpéjọ àgbáyé tá a ṣe nílùú New Orleans, ní ìpínlẹ̀ Louisiana. Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ló tọ́ òun náà dàgbà. Ọdún mẹ́rin ni Elizabeth ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà, iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ló sì fẹ́ fayé ẹ̀ ṣe. A máa ń bá ara wa sọ̀rọ̀. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ìfẹ́ ti kó sí wa lórí. A ṣègbéyàwó ní October 20, 1979, a sì jọ ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì.

Àwọn ará tá a jọ wà níjọ Brooklyn Spanish tá a kọ́kọ́ dara pọ̀ mọ́ nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ní gbogbo ọdún tá a ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa, a ti dara pọ̀ mọ́ ìjọ mẹ́ta míì, wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. A mọyì àwọn ará ìjọ wa, a tún mọyì àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìdílé wa tí wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn òbí wa tó ti dàgbà.

Philip àtàwọn ará Bẹ́tẹ́lì mí ì wà nípàdé.

Àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tá a jọ wà níjọ Brooklyn Spanish lọ́dún 1986

MO BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ NÍ Ẹ̀KA TÓ Ń BÓJÚ TÓ Ọ̀RỌ̀ ÒFIN

Ní January 1982, ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin ní Bẹ́tẹ́lì. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, wọ́n ní kí n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn amòfin kí n lè di agbẹjọ́rò. Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n kọ́ wa nílé ẹ̀kọ́ yẹn pé àwọn ẹjọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jàre wà lára ohun tí wọ́n fi ṣe òfin ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀-èdè míì ń jàǹfààní ẹ̀. A máa ń jíròrò àwọn ẹjọ́ yìí gan-an nínú kíláàsì.

Lọ́dún 1986, nígbà tí mo pé ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún, wọ́n ní kí n máa ṣe alábòójútó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin. Inú mi dùn nígbà tí wọ́n gbé iṣẹ́ yìí fún mi, àmọ́ torí pé ọ̀dọ́ ni mí, ọkàn mi ò balẹ̀ torí pé mi ò mọ bí iṣẹ́ náà ṣe máa rí.

Mo di agbẹjọ́rò lọ́dún 1988, àmọ́ mi ò mọ̀ pé ilé ìwé tí mo lọ ti jẹ́ kí àjọṣe èmi àti Jèhófà má lágbára mọ́. Ilé ẹ̀kọ́ gíga máa ń jẹ́ kéèyàn ro ara ẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn rò pé òun sàn ju àwọn ẹlòmíì torí pé òun ní ìmọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ táwọn kan ò ní. Ọpẹ́lọpẹ́ Elizabeth ìyàwó mi. Òun ló ràn mí lọ́wọ́ kí n lè pa dà máa ṣe àwọn nǹkan tí mò ń ṣe tẹ́lẹ̀ kí àjọṣe èmi àti Jèhófà lè gún régé. Ó gba àkókò díẹ̀, àmọ́ mo pa dà sún mọ́ Jèhófà. Ó wá yé mi pé kéèyàn ní ìmọ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kọ́ ló ṣe pàtàkì jù láyé yìí, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ẹ̀ dénú.

À Ń GBÈJÀ ÌHÌN RERE, A SÌ Ń FÌDÍ Ẹ̀ MÚLẸ̀ LỌ́NÀ ÒFIN

Lẹ́yìn tí mo yege nílé ẹ̀kọ́ àwọn amòfin, mò ń ṣètò ọ̀rọ̀ òfin ní Bẹ́tẹ́lì, mo sì ń gbẹjọ́ rò fún ètò Ọlọ́run kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú. Mò ń gbádùn iṣẹ́ mi, àmọ́ nǹkan ò rọrùn torí pé iṣẹ́ ń pọ̀ sí i, nǹkan sì ń yí pa dà nínú ètò Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ṣáájú ọdún 1990, a máa ń gba owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn tá a bá fún wọn níwèé wa, àmọ́ ètò Ọlọ́run ní kí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin ṣàtúnṣe ọ̀rọ̀ náà. Látìgbà yẹn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í béèrè owó lọ́wọ́ àwọn èèyàn mọ́ tá a bá fún wọn níwèé wa. Àwọn nǹkan tá a ṣe yìí jẹ́ kí iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì àti iṣẹ́ ìwàásù túbọ̀ rọrùn, ìjọba ò sì ní béèrè owó orí lọ́wọ́ wa mọ́. Àwọn kan rò pé a ò ní fi bẹ́ẹ̀ lówó mọ́ kódà a ò ní rówó tẹ̀wé mọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí ọ̀pọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Láti 1990, iye àwa tá à ń sin Jèhófà ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po méjì, àwọn èèyàn sì láǹfààní láti gba ìwé wa láìsanwó. Ọ̀pọ̀ àyípadà ló ti wáyé nínú ètò Ọlọ́run, mo sì ti rí i pé ẹ̀mí mímọ́ àti ìtọ́sọ́nà tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ ẹrú olóòótọ́ ló jẹ́ kó ṣeé ṣe.—Ẹ́kís. 15:2; Mát. 24:45.

Kì í ṣe torí pé àwọn agbẹjọ́rò wa jáfáfá nìkan la ṣe máa ń jàre nílé ẹjọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwà ọmọlúwàbí táwa èèyàn Jèhófà ní ló máa ń jẹ́ káwọn aláṣẹ dá wa láre. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1998 nígbà tí mẹ́ta lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn ìyàwó wọn wá sí àkànṣe àpéjọ tá a ṣe lórílẹ̀-èdè Cuba. Ìwà tó dáa tí wọ́n ní àti bí wọ́n ṣe ń bọ̀wọ̀ fúnni jẹ́ káwọn aláṣẹ yẹn rí i pé lóòótọ́ a kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú, ìyẹn sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn ju ọ̀rọ̀ tá a ti ń bá wọn sọ.

Àmọ́ tá ò bá lè yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kan nítùbí-ìnùbí, a máa ‘ń gbèjà ìhìn rere, a sì máa ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin’ nílé ẹjọ́. (Fílí. 1:7) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn aláṣẹ ilẹ̀ Yúróòpù àti orílẹ̀-èdè South Korea fi ẹ̀tọ́ wa dù wá nígbà tá a sọ pé a ò ní wọṣẹ́ ológun. Torí náà, àwọn arákùnrin tó tó ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún (18,000) nílẹ̀ Yúróòpù àtàwọn arákùnrin tó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún (19,000) ní South Korea ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun.

Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ní July 7, 2011, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá ẹjọ́ mánigbàgbé kan láàárín Bayatyan àti Armenia, wọ́n sì sọ pé ní gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn èèyàn lè ṣiṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ní June 28, 2018, Kóòtù Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ South Korea náà sọ pé àwọn èèyàn lè ṣiṣẹ́ àṣesìnlú. Ká sọ pé díẹ̀ lára àwọn arákùnrin wa tó jẹ́ ọ̀dọ́ yìí gbà láti wọṣẹ́ ológun ni, ì bá má ṣeé ṣe láti jàre àwọn ẹjọ́ náà.

Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin ní oríléeṣẹ́ wa àti láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kárí ayé ń ṣiṣẹ́ kára láti gbèjà ìhìn rere. Inú wa dùn pé a lè ṣojú àwọn ará wa tí ìjọba ń ta kò nílé ẹjọ́. Bóyá a jàre nílé ẹjọ́ tàbí a ò jàre, àwọn ẹjọ́ tá a pè jẹ́ ká lè jẹ́rìí fáwọn gómìnà, àwọn ọba àtàwọn orílẹ̀-èdè. (Mát. 10:18) Àwọn adájọ́, àwọn aṣojú ìjọba, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn àtàwọn ará ìlú máa ń gbọ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a fi ti ọ̀rọ̀ wa lẹ́yìn nílé ẹjọ́, wọ́n sì máa ń kà wọ́n nínú ìwé ìgbẹ́jọ́. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ máa ń mọ ẹni táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́, wọ́n sì máa ń mọ̀ pé inú Bíbélì lohun tá a gbà gbọ́ ti wá. Àwọn kan lára wọn ti ń jọ́sìn Jèhófà báyìí.

JÈHÓFÀ O ṢEUN O!

Ó ti lé lógójì (40) ọdún báyìí tí mo ti láǹfààní láti máa bá àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì ṣiṣẹ́ kárí ayé ká lè bójú tó ọ̀rọ̀ òfin, mo tún láǹfààní láti máa ṣojú àwọn ará láwọn ilé ẹjọ́ ńlá, kí n sì bá àwọn ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba sọ̀rọ̀. Mo nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Òfin ní oríléeṣẹ́ wa àti láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kárí ayé. Jèhófà ti bù kún mi gan-an, mo sì ń láyọ̀.

Philip àti Elizabeth Brumley.

Ọdún márùnlélógójì (45) ni Elizabeth ti dúró tì mí gbágbáágbá nígbà dídùn àti nígbà kíkan. Mo nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an torí pé ó máa ń ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ní àìsàn kan tó máa ń jẹ́ kó tètè rẹ̀ ẹ́.

Èmi àtìyàwó mi ti rí i pé agbára wa kọ́ la fi ń ṣe àwọn nǹkan tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà, àwọn àṣeyọrí wa kì í sì í ṣe mímọ̀ọ́ṣe wa. Bí Dáfídì ṣe sọ, àwa náà gbà pé: “Jèhófà ni agbára àwọn èèyàn rẹ̀.” (Sm. 28:8) Ká sòótọ́, “ogun náà jẹ́ ti Jèhófà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́