ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 31
ORIN 111 Ohun Tó Ń Fún Wa Láyọ̀
Ṣé O Mọ Béèyàn Ṣe Ń Nítẹ̀ẹ́lọ́rùn?
“Mo ti kọ́ bí èèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tó bá ní nínú ipòkípò tí mo bá wà.”—FÍLÍ. 4:11.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kọ́ bá a ṣe lè nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tá a bá ń dúpẹ́, tá a nírẹ̀lẹ̀, tá a sì ń ronú nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.
1. Kí lẹni tó nítẹ̀ẹ́lọ́rùn máa ń ṣe, kí ni kì í sì í ṣe?
ṢÉ O nítẹ̀ẹ́lọ́rùn? Ẹni tó nítẹ̀ẹ́lọ́rùn máa ń láyọ̀, ọkàn ẹ̀ sì máa ń balẹ̀ torí ó mọyì àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe fún un. Kì í bínú tàbí banú jẹ́ torí àwọn nǹkan tí ò ní. Tẹ́nì kan bá tiẹ̀ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, kò túmọ̀ sí pé kó má ka nǹkan sí tàbí kó kàn máa ṣe bó ṣe wù ú. Bí àpẹẹrẹ, kò sóhun tó burú tí Kristẹni kan bá ń sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. (Róòmù 12:1; 1 Tím. 3:1) Síbẹ̀, á ṣì máa láyọ̀ táwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe nínú ètò Ọlọ́run ò bá tètè tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́.
2. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan ò bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn?
2 Tẹ́nì kan ò bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ó lè kó o sí wàhálà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn máa ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó kí wọ́n lè rówó ra ọ̀pọ̀ nǹkan, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn nǹkan yẹn ò pọn dandan. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn Kristẹni kan tiẹ̀ jí owó àtàwọn nǹkan míì tó wù wọ́n. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa rò pé, ‘Ó yẹ kémi náà ní in,’ ‘Mo ti ní sùúrù tó’ tàbí ‘Màá dá owó náà pa dà tó bá yá.’ Àmọ́, ó yẹ ká máa rántí pé olè lolè ń jẹ́, Jèhófà sì kórìíra ẹ̀ gan-an. (Òwe 30:9) Kódà, àwọn kan ti fi Jèhófà sílẹ̀ torí pé ọwọ́ wọn ò tẹ iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n fẹ́ nínú ètò Ọlọ́run. (Gál. 6:9) Ẹ gbọ́ ná, kí ló lè sún ìránṣẹ́ Jèhófà kan láti ṣerú ẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹni náà ò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn mọ́.
3. Kí ni Fílípì 4:11, 12 sọ tó fi wá lọ́kàn balẹ̀?
3 Gbogbo wa la lè kọ́ béèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “mo ti kọ́ bí èèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun tó bá ní nínú ipòkípò tí mo bá wà.” (Ka Fílípì 4:11, 12.) Ìgbà tó wà lẹ́wọ̀n ló sọ̀rọ̀ yẹn. Síbẹ̀, ó ṣì ń láyọ̀ torí ó ti “kọ́ àṣírí” béèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Tó bá ṣòro fún wa láti nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ máa jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ pé a lè kọ́ béèyàn ṣe ń ní in. Kò yẹ ká rò pé ó máa rọrùn fún wa láti nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká kọ́ béèyàn ṣe ń ní in. Báwo la ṣe lè ṣe é? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ànímọ́ táá jẹ́ ká mọ béèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.
MÁA DÚPẸ́
4. Tá a bá ń dúpẹ́, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn? (1 Tẹsalóníkà 5:18)
4 Táwọn èèyàn bá ṣe wá lóore tá a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn, àá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:18.) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí àwọn nǹkan kòṣeémáàní tó fún wa, a ò ní máa ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan tá a fẹ́ àmọ́ tá ò ní. Tá a bá sì mọyì àwọn iṣẹ́ ìsìn tá a láǹfààní ẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run báyìí, àá máa ronú nípa bá a ṣe lè sunwọ̀n sí i dípò ká máa ronú nípa àwọn iṣẹ́ ìsìn tá ò láǹfààní ẹ̀. Abájọ tí Bíbélì fi rọ̀ wá pé ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà. Torí náà, tá a bá ń dúpẹ́, a máa ní “àlàáfíà Ọlọ́run tó kọjá gbogbo òye.”—Fílí. 4:6, 7.
5. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa dúpẹ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n kùn sí Jèhófà pé àwọn ò rí oúnjẹ táwọn ń jẹ ní Íjíbítì jẹ mọ́. (Nọ́ń. 11:4-6) Ká sòótọ́, nǹkan ò rọrùn fún wọn nínú aginjù. Kí ni wọn ò bá ti ṣe kí wọ́n lè nítẹ̀ẹ́lọ́rùn? Wọn ò bá ti ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì, Jèhófà fi ìyọnu mẹ́wàá kọlu àwọn tó mú wọn lẹ́rú. Lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀, ‘wọ́n gba fàdákà, wúrà àti aṣọ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì.’ (Ẹ́kís. 12:35, 36) Nígbà táwọn ará Íjíbítì ń lé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n fi dé Òkun Pupa, Jèhófà pín omi náà sí méjì lọ́nà ìyanu. Bí wọ́n sì ṣe ń rìn lọ nínú aginjù, ojoojúmọ́ ni Jèhófà ń fi mánà bọ́ wọn. Kí wá nìṣòro wọn gan-an? Kì í ṣe torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní oúnjẹ ni wọn ò ṣe nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọn ò mọyì àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún wọn.
Kí ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn? (Wo ìpínrọ̀ 5)
6. Báwo la ṣe lè mọ béèyàn ṣe ń dúpẹ́?
6 Báwo la ṣe lè mọ béèyàn ṣe ń dúpẹ́? Ohun àkọ́kọ́ ni pé ká máa ronú lójoojúmọ́ nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wa. Kódà, o lè kọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún ẹ sílẹ̀, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. (Ìdárò 3:22, 23) Ìkejì, máa dúpẹ́ táwọn èèyàn bá ṣe ẹ́ lóore. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbà gbogbo. (Sm. 75:1) Ìkẹta, àwọn tó moore ni kó o mú lọ́rẹ̀ẹ́. Ìwà jọ̀wà ló ń jẹ́ ọ̀rẹ́ jọ̀rẹ́. Táwọn tá à ń bá rìn bá moore, àwa náà máa moore, àmọ́ tí wọn ò bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, àwa náà ò ní nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. (Diu. 1:26-28; 2 Tím. 3:1, 2, 5) Tó bá mọ́ wa lára láti máa dúpẹ́ oore, a ò ní di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn.
7. Kí ló ran Aci lọ́wọ́ tó jẹ́ kó mọpẹ́ dá?
7 Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Arábìnrin Aci tó ń gbé Indonéṣíà. Ó sọ pé: “Lásìkò àrùn kòrónà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi ara mi wé àwọn míì nínú ìjọ. Bó ṣe di pé mi ò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn mọ́ nìyẹn.” (Gál. 6:4) Kí ló ràn án lọ́wọ́? Aci sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ń ṣe fún mi lójoojúmọ́ àtàwọn nǹkan tí mò ń gbádùn torí pé mo wà nínú ètò Ọlọ́run. Kì í ṣèyẹn nìkan o, mo tún máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Àwọn nǹkan tí mò ń ṣe yìí ló jẹ́ kí n nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.” Táwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ bá mú kó o ní èrò tí ò tọ́, á dáa kó o ṣe bíi ti arábìnrin yìí, kó o lè mọpẹ́ dá.
NÍRẸ̀LẸ̀
8. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù?
8 Ìgbà kan wà tí Bárúkù tó jẹ́ akọ̀wé wòlíì Jeremáyà ò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn mọ́. Iṣẹ́ tí Bárúkù ṣe ò rọrùn rárá. Ó ran Jeremáyà lọ́wọ́ láti kéde ìdájọ́ Jèhófà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìmoore. Àmọ́, dípò kí Bárúkù gbájú mọ́ iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún un, ṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í wá nǹkan ńláńlá fún ara ẹ̀. Jèhófà ní kí Jeremáyà sọ fún Bárúkù pé: “Ìwọ ń wá àwọn ohun ńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.” (Jer. 45:3-5) Ohun tí Jèhófà ń sọ fún un ni pé: “Jẹ́ káwọn nǹkan tó o ní báyìí tẹ́ ẹ lọ́rùn.” Bárúkù gba ìbáwí tí Jèhófà fún un, Jèhófà sì bù kún un lọ́pọ̀lọpọ̀.
9. Kí ni 1 Kọ́ríńtì 4:6, 7 sọ pé ó máa mú ká fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ ìsìn? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Nígbà míì, Kristẹni kan lè rò pé iṣẹ́ ìsìn kan tọ́ sóun. Ó lè ti máa sin Jèhófà tipẹ́tipẹ́, ó lè mọ àwọn nǹkan kan ṣe tàbí kó máa ṣiṣẹ́ kára, kódà ó lè mọ gbogbo nǹkan yìí ṣe. Síbẹ̀, wọ́n lè gbé iṣẹ́ ìsìn tó wù ú yẹn fún ẹlòmíì. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí ló yẹ kó ṣe? Ó yẹ kó ronú nípa ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ní 1 Kọ́ríńtì 4:6, 7. (Kà á.) Jèhófà ló fún wa láǹfààní láti ṣe gbogbo iṣẹ́ ìsìn tá à ń ṣe àti gbogbo nǹkan tá a mọ̀ ọ́n ṣe. Kì í ṣe torí pé a dáa ju àwọn yòókù lọ ni wọ́n ṣe gbé àwọn iṣẹ́ ìsìn yẹn fún wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn sí wa ló jẹ́ kó ṣeé ṣe.—Róòmù 12:3, 6; Éfé. 2:8, 9.
Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà ń fi hàn sí wa ló jẹ́ ká lè ṣe gbogbo ohun tá a mọ̀ ọ́n ṣe (Wo ìpínrọ̀ 9)b
10. Kí ló máa jẹ́ ká nírẹ̀lẹ̀?
10 Tá a bá ronú dáadáa nípa ohun tí Jésù ṣe, a máa nírẹ̀lẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì ẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Jésù mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́ àti pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun sì ń lọ, torí náà, . . . ó bẹ̀rẹ̀ sí í fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn.” (Jòh. 13:3-5) Jésù lè sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ló yẹ kó fọ ẹsẹ̀ òun. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tó wà láyé, kò ronú pé ó yẹ kóun lówó rẹpẹtẹ tàbí kóun máa gbádùn ayé òun torí pé Ọmọ Ọlọ́run lòun. (Lúùkù 9:58) Jésù nírẹ̀lẹ̀, ó sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa ló fi lélẹ̀ fún wa!—Jòh. 13:15.
11. Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀ ṣe mú kí Dennis nítẹ̀ẹ́lọ́rùn?
11 Arákùnrin Dennis tó ń gbé Netherlands ń gbìyànjú gan-an kó lè nírẹ̀lẹ̀ bíi Jésù, àmọ́ kò rọrùn fún un. Ó sọ pé: “Nígbà míì, tí wọ́n bá fún ẹnì kan láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìsìn kan, inú máa ń bí mi, mo sì máa ń rò pé èmi ló yẹ kí wọ́n gbé e fún dípò ẹni yẹn. Tí mo bá ti ń nírú èrò yẹn, mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀. Nínú JW Library® mi, mo máa ń tọ́jú àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ìrẹ̀lẹ̀ síbì kan kí n lè tètè rí wọn, màá sì kà wọ́n lákàtúnkà. Yàtọ̀ síyẹn, mo tún wa àwọn àsọyé tó sọ̀rọ̀ nípa ìrẹ̀lẹ̀ sórí fóònù mi, gbogbo ìgbà ni mo sì máa ń gbọ́ wọn.a Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn wa, Jèhófà ló yẹ ká fògo fún. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń ṣe ipa tiwa nínú iṣẹ́ náà, Jèhófà ló ń jẹ́ ká ṣàṣeyọrí.” Tínú ẹ ò bá dùn torí pé iṣẹ́ ìsìn tó wù ẹ́ ò tíì tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́, máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kó o túbọ̀ nírẹ̀lẹ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, wàá sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.—Jém. 4:6, 8.
MÁA RONÚ NÍPA ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ MÁA ṢE LỌ́JỌ́ IWÁJÚ
12. Àwọn nǹkan wo là ń retí tó máa jẹ́ ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn? (Àìsáyà 65:21-25)
12 A máa túbọ̀ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀rọ̀ tí wòlíì Àìsáyà kọ sílẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ń rí àwọn ìṣòro tó ń kó wa lọ́kàn sókè, ó sì ṣèlérí pé òun máa mú wọn kúrò. (Ka Àìsáyà 65:21-25.) A máa gbé inú ilé wa, ọkàn wa sì máa balẹ̀. A máa ṣiṣẹ́ tó dáa, àá sì máa jẹ oríṣiríṣi oúnjẹ aládùn tó ń ṣara lóore. Ẹ̀rù ò ní bà wá pé nǹkan burúkú lè ṣẹlẹ̀ sáwa àtàwọn ọmọ wa. (Àìsá. 32:17, 18; Ìsík. 34:25) Ó dá wa lójú pé Jèhófà máa ṣe àwọn nǹkan rere yìí fún wa.
13. Àwọn ìṣòro wo là ń bá yí, kí ló sì ń mú ká máa fara dà á?
13 Àkókò yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú. Kí nìdí? Ìdí ni pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí, gbogbo wa la sì níṣòro tó máa ń mú kí nǹkan “nira” fún wa. (2 Tím. 3:1) Ojoojúmọ́ ni Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da ìṣòro wa, ó máa ń tọ́ wa sọ́nà, ó máa ń fún wa lókun, ó sì máa ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò. (Sm. 145:14) Ohun míì tó ń jẹ́ ká lè máa fara dà á ni bá a ṣe mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Ó ṣeé ṣe kó o máa ṣiṣẹ́ kára gan-an kó o tó lè pèsè ohun tí ìdílé ẹ nílò. Ṣéyẹn wá fi hàn pé bí wàá ṣe máa forí ṣe fọrùn ṣe nìyẹn tí ò sì ní sọ́nà àbáyọ? Rárá o! Jèhófà ti ṣèlérí pé òun máa ṣe gbogbo ohun tó o fẹ́ fún ẹ nínú Párádísè, kódà ó máa ṣe kọjá ohun tó o rò. (Sm. 9:18; 72:12-14) Ní báyìí, ìrora àti ẹ̀dùn ọkàn lè máa bá ẹ fínra tàbí kó o ní àìsàn kan tó le gan-an. Ṣé o rò pé bí wàá ṣe máa jìyà lọ nìyẹn tó ò sì ní bọ́ ńbẹ̀? Rárá o. Ìdí ni pé àìsàn àti ikú ò ní sí mọ́ nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Ìfi. 21:3, 4) Àwọn nǹkan rere tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí ló jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀, tí kì í sì í jẹ́ ká bínú tá a bá níṣòro. Tí wọ́n bá rẹ́ wa jẹ, tí èèyàn wa bá kú, tá a bá ń fara da àìsàn kan tàbí àwọn ìṣòro míì, ọkàn wa ṣì lè balẹ̀, ká sì máa láyọ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé bó ti wù kí ìṣòro wa le tó, a mọ̀ pé “ìpọ́njú náà jẹ́ fún ìgbà díẹ̀,” ó sì dá wa lójú pé nínú ayé tuntun, gbogbo ìṣòro wa máa dópin.—2 Kọ́r. 4:17, 18.
14. Kí ló máa jẹ́ káwọn nǹkan tí Jèhófà ṣèlérí túbọ̀ dá wa lójú?
14 Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé àwọn nǹkan tá à ń retí máa jẹ́ ká nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn nǹkan yẹn túbọ̀ dá wa lójú? Bí ẹnì kan ṣe máa ń fi awò sójú kó lè rí ohun tó wà lókèèrè dáadáa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká máa ṣe nǹkan táá jẹ́ káwọn ohun tó máa wáyé nínú Párádísè túbọ̀ dá wa lójú. Tá a bá ń ṣàníyàn torí pé a ò lówó lọ́wọ́, a lè ronú nípa bí ayé tuntun ṣe máa rí nígbà tí ò ní sí owó mọ́, tí ẹnikẹ́ni ò ní tòṣì tàbí jẹ gbèsè mọ́. Tínú wa ò bá dùn torí pé ọwọ́ wa ò tíì tẹ ohun tá a fẹ́ ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run báyìí, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé iṣẹ́ ìsìn tọ́wọ́ wa ò tẹ̀ yẹn ò tó nǹkan kan tá a bá fi wé àwọn nnkan rere tá a máa gbádùn lẹ́yìn tá a bá di pípé, tí àá sì máa sin Jèhófà títí láé. (1 Tím. 6:19) Torí pé a máa ń ṣàníyàn nípa ọ̀pọ̀ nǹkan báyìí, ó lè má rọrùn fún wa láti ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́, tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe láìpẹ́, a ò ní máa ronú nípa àwọn ìṣòro wa ṣáá.
15. Kí lo kọ́ nínú ohun tí Christa sọ?
15 Níṣàájú, a sọ̀rọ̀ nípa Dennis. Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe lọ́jọ́ iwájú ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ Christa ìyàwó ẹ̀ túbọ̀ lágbára. Christa sọ pé: “Mo ní àìsàn kan tí ò jẹ́ kí iṣan ara mi ṣiṣẹ́ dáadáa, ìyẹn sì gba pé kí n máa jókòó sórí kẹ̀kẹ́ aláìlera, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì máa ń wà lórí bẹ́ẹ̀dì. Ojoojúmọ́ lara máa ń ro mí gan-an. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni dókítà mi sọ fún mi pé kò sọ́nà àbáyọ mọ́. Àmọ́ ojú ẹsẹ̀ ni mo sọ fúnra mi pé, ‘Dókítà yìí ò mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.’ Àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú ni mò ń rò, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn mi balẹ̀. Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni mò ń fara dà báyìí, àmọ́ mo mọ̀ pé màá gbádùn ara mi dọ́ba nínú ayé tuntun!”
“ÀWỌN TÓ BẸ̀RÙ RẸ̀ KÒ NÍ ṢALÁÌNÍ”
16. Kí nìdí tí Ọba Dáfídì fi sọ pé àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà “kò ní ṣaláìní”?
16 Tá a bá tiẹ̀ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, a ṣì máa ń níṣòro nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, ó kéré tán mẹ́ta lára àwọn ọmọ Ọba Dáfídì ló kú nígbà ayé ẹ̀. Wọ́n fẹ̀sùn èké kàn án, wọ́n dalẹ̀ ẹ̀, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi ń sá kiri nítorí àwọn ọ̀tá tó fẹ́ pa á. Síbẹ̀ ní gbogbo àsìkò tó ń fara da ìṣòro yẹn, ó sọ nípa Jèhófà pé: “Àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ kò ní ṣaláìní.” (Sm. 34:9, 10) Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé bá a tiẹ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, ìyẹn ò sọ pé a ò ní níṣòro kankan, àmọ́ ó dá wa lójú pé Jèhófà máa pèsè gbogbo ohun tá a nílò. (Sm. 145:16) A gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da gbogbo ìṣòro wa. Torí náà tá a bá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, àá máa fayọ̀ sin Jèhófà nìṣó.
17. Kí nìdí tó o fi pinnu pé wàá kọ́ béèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn?
17 Jèhófà fẹ́ kó o nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. (Sm. 131:1, 2) Torí náà, kọ́ béèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa dúpẹ́, tó o nírẹ̀lẹ̀, tó o sì ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà máa ṣe fún ẹ lọ́jọ́ iwájú, ìwọ náà á lè sọ pé: “Mo ti kọ́ bí èèyàn ṣe ń nítẹ̀ẹ́lọ́rùn.”—Fílí. 4:11.
ORIN 118 “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
a Bí àpẹẹrẹ, wo àwọn fídíò ìjọsìn òwúrọ̀ yìí lórí jw.org, Jèhófà Ń Bójú Tó Àwọn Tó Nírẹ̀lẹ̀ àti Ìgbéraga Ló Ń Ṣáájú Ìparun.
b ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arákùnrin kan ń tún nǹkan ṣe nínú ilé ètò Ọlọ́run, wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá arábìnrin kan tó kọ́ èdè àwọn adití lẹ́nu wò ní àpéjọ àyíká, arákùnrin kan sì ń sọ àsọyé.