ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 35
ORIN 121 A Nílò Ìkóra-Ẹni-Níjàánu
Bó O Ṣe Lè Borí Èrò Tí Kò Tọ́
“Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa jọba lọ nínú ara kíkú yín, tí ẹ ó fi máa ṣe ìfẹ́ ti ara.”—RÓÒMÙ 6:12.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bó o ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì, kó o sì sá fún ìdẹwò.
1. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa torí a jẹ́ aláìpé?
ṢÉ ÌGBÀ kan wà tó wù ẹ́ gan-an láti ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má rò pé ohun tó ń ṣe ẹ́ yẹn ò ṣe àwọn ẹlòmíì. Bíbélì sọ pé: “Kò sí àdánwò kankan tó ti bá yín àfi èyí tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn.” (1 Kọ́r. 10:13)a Ohun tá à ń sọ ni pé bí èrò tí kò dáa ṣe ń wá sọ́kàn ẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló ń wá sọ́kàn àwọn ẹlòmíì. Ìwọ nìkan kọ́ lo nírú ìṣòro yìí, Jèhófà sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí ẹ̀.
2. Àwọn nǹkan wo ló máa ń dẹ àwọn Kristẹni kan àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ wò? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
2 Bíbélì tún sọ pé: “Àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.” (Jém. 1:14) Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tó ń dẹ ẹnì kan wò lè yàtọ̀ sóhun tó ń dẹ ẹlòmíì wò. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa wu àwọn Kristẹni kan láti ṣèṣekúṣe, àmọ́ ó lè máa wu àwọn míì kí wọ́n bá ọkùnrin bíi tiwọn tàbí obìnrin bíi tiwọn ṣèṣekúṣe. Bákan náà, ó lè máa wu àwọn tó ti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán tàbí fíìmù ìṣekúṣe láti pa dà wò ó. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró tàbí ọtí àmujù lè fẹ́ pa dà sídìí ẹ̀. Díẹ̀ nìyí lára ohun táwọn Kristẹni kan àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń bá yí. Nígbà míì, ó lè ṣe gbogbo wa bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.”—Róòmù 7:21.
Ìgbàkigbà ni ìdẹwò lè dé, ibikíbi ló sì ti lè ṣẹlẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 2)d
3. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tí èrò tí kò tọ́ bá ń wá sọ́kàn ẹ léraléra?
3 Tí èrò tí kò tọ́ bá ń wá sọ́kàn ẹ léraléra, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò lè borí ẹ̀. Ó tún lè máa ṣe ẹ́ bíi pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà ẹ́ torí pé o ní èrò tí kò tọ́. Jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀ torí pé ọ̀rọ̀ ò rí bó o ṣe rò! Ká lè mọ ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀, a máa dáhùn ìbéèrè méjì nínú àpilẹ̀kọ yìí. (1) Ta ló máa ń mú ká rò pé a ò lè borí èrò tí kò tọ́ àti pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá? (2) Báwo la ṣe lè borí èrò tí kò tọ́?
OHUN TÍ SÁTÁNÌ FẸ́ KÁ MÁA RÒ
4. (a) Kí nìdí tí Sátánì fi fẹ́ ká gbà pé a ò lè borí ìdẹwò? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbà pé a lè borí ìdẹwò?
4 Sátánì fẹ́ ká gbà pé a ò lè borí ìdẹwò. Jésù náà mọ̀ pé ohun tí Sátánì ń rò nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi ní káwa ọmọlẹ́yìn ẹ̀ máa gbàdúrà pé: ‘Má mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.’ (Mát. 6:13) Sátánì sọ pé àwa èèyàn ò ní ṣègbọràn sí Jèhófà tí nǹkan kan bá dán wa wò. (Jóòbù 2:4, 5) Kí nìdí tí Sátánì fi sọ bẹ́ẹ̀? Sátánì lẹni tó kọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ nítorí ìfẹ́ ọkàn ẹ̀, kò sì jólóòótọ́ sí Jèhófà. Torí náà, ìdí tó fi sọ pé a ò ní ṣègbọràn sí Jèhófà ni pé ó rò pé a máa fara wé òun, a sì máa pa Jèhófà tì nígbà àdánwò. Kódà Sátánì rò pé Jésù Ọmọ Ọlọ́run tó tún jẹ́ ẹni pípé máa ṣàìgbọràn sí Jèhófà tí àdánwò bá dé bá a! (Mát. 4:8, 9) Àmọ́, ṣóòótọ́ ni pé a ò lè borí èròkerò? Rárá o, a lè borí ẹ̀! A gbà pé òótọ́ lohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.”—Fílí. 4:13.
5. Báwo la ṣe mọ̀ pé ó dá Jèhófà lójú pé a lè borí èrò tí kò tọ́?
5 Jèhófà ò dà bíi Sátánì torí ó dá Jèhófà lójú pé a lè borí èrò tí kò tọ́. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ máa la ìpọ́njú ńlá já. Rò ó wò ná. Jèhófà, ẹni tí kò lè parọ́ sọ pé kì í ṣe èèyàn díẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun ló máa wọnú ayé tuntun torí “wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìfi. 7:9, 13, 14) Torí náà, ó dájú pé Jèhófà mọ̀ pé a lè borí èrò tí kò tọ́.
6-7. Kí nìdí tí Sátánì fi fẹ́ ká rò pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá?
6 Yàtọ̀ sí pé Sátánì fẹ́ ká rò pé a ò lè borí èrò tí kò tọ́, ó tún fẹ́ ká máa rò pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá. Ó fẹ́ ká gbà pé tá a bá ní èrò tí kò tọ́ pẹ́nrẹ́n, Jèhófà máa dá wa lẹ́bi ni. Ẹ jẹ́ ká tún wò ó báyìí ná. Sátánì ni Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà, kò sì ní jẹ́ kó jogún ìyè àìnípẹ̀kun. (Jẹ́n. 3:15; Ìfi. 20:10) Ó hàn gbangba pé Sátánì ń jowú wa, kò sì fẹ́ kí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wá torí ó mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun tó ti bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́. Àmọ́ irọ́ ló pa, Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà wá. Kódà, Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́, kò sì ní dá wa lẹ́bi. Jèhófà “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà.”—2 Pét. 3:9.
7 Tá a bá fara mọ́ èrò Sátánì pẹ́nrẹ́n, tá a sì gbà pé a ò lè borí èrò tí kò tọ́ àti pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá, a ti bọ́ sọ́wọ́ Èṣù nìyẹn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a máa kọjú ìjà sí Èṣù ní gbogbo ọ̀nà.—1 Pét. 5:8, 9.
KÍ NI Ẹ̀ṢẸ̀ LÈ MÚ KÁ MÁA RÒ?
8. Yàtọ̀ sí kéèyàn hùwà tí kò dáa, kí ni Bíbélì tún pè ní ẹ̀ṣẹ̀? (Sáàmù 51:5) (Tún wo “Àlàyé Ọ̀rọ̀.”)
8 Yàtọ̀ sí Sátánì, nǹkan míì wà tó máa ń jẹ́ ká rò pé a ò lè borí èrò tí kò tọ́ àti pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá. Kí ni nǹkan náà? Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ni.b—Jóòbù 14:4; ka Sáàmù 51:5.
9-10. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Ádámù àti Éfà lẹ́yìn tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí wa torí pé a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀?
9 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ádámù àti Éfà nígbà tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣàìgbọràn sí Jèhófà, wọ́n lọ fara pa mọ́, wọ́n sì fi nǹkan bo ara wọn. Ìwé Insight on the Scriptures sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti Éfà mú kí nǹkan mẹ́rin yìí ṣẹlẹ̀ sí wọn: “Ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ kí ọkàn wọn dá wọn lẹ́bi, kí wọ́n máa ṣàníyàn, kí ọkàn wọn má balẹ̀, kí ojú sì máa tì wọ́n.” A lè fi àwọn nǹkan mẹ́rin yìí wé yàrá mẹ́rin tó wà nínú ilé kan tí wọ́n ti Ádámù àti Éfà mọ́. Wọ́n lè lọ láti yàrá kan sí òmíì, àmọ́ wọn ò lè jáde kúrò nínú ilé náà. Torí náà, wọn ò lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn nǹkan tí ẹ̀ṣẹ̀ náà fà.
10 Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ tiwa yàtọ̀ sí ti Ádámù àti Éfà torí pé wọn ò lè jàǹfààní ìràpadà. Àmọ́ ìràpadà lè nu ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, ó sì ń jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́. (1 Kọ́r. 6:11) Síbẹ̀, a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. Torí náà, kò yà wá lẹ́nu pé nígbà míì ẹ̀rí ọkàn tiwa náà máa ń dá wa lẹ́bi, a máa ń ṣàníyàn, ọkàn wa kì í balẹ̀, ojú sì máa ń tì wá. Kódà, Bíbélì sọ pé ẹ̀ṣẹ̀ ń darí aráyé. Ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ “àní lórí àwọn tí kò dẹ́ṣẹ̀ bíi ti Ádámù.” (Róòmù 5:14) Àmọ́ kò yẹ ká máa rò pé torí a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀, a ò lè borí èrò tí kò tọ́ àti pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé a lè borí. Àmọ́ lọ́nà wo?
Ẹ̀ṣẹ̀ mú kí ọkàn Ádámù àti Éfà dá wọn lẹ́bi, kí wọ́n máa ṣàníyàn, kí ọkàn wọn má balẹ̀, kí ojú sì tì wọ́n (Wo ìpínrọ̀ 9)
11. Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò lè borí èrò tí kò tọ́, kí sì nìdí? (Róòmù 6:12)
11 Tó bá ń ṣe wá bíi pé a ò lè borí èrò tí kò tọ́, ṣe ló dà bí ìgbà tí ẹnì kan ń sọ fún wa pé kò sóhun tá a lè ṣe sí i. Àmọ́, kò yẹ ká gba irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì sọ pé a ò gbọ́dọ̀ “jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ máa jọba” lórí wa. (Ka Róòmù 6:12.) Ìyẹn ni pé a ò ní ṣe ohun burúkú tó ń wá sọ́kàn wa. (Gál. 5:16) Ìdí tí Jèhófà fi ní ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti borí àdánwò ni pé ó mọ̀ pé a lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Diu. 30:11-14; Róòmù 6:6; 1 Tẹs. 4:3) Ó dájú pé a lè borí èròkerò, ká sì ṣe ohun tó tọ́.
12. Kí ló yẹ ká ṣe tó bá ń ṣe wá bíi pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá, kí sì nìdí?
12 Bákan náà, tó bá ń ṣe wá bíi pé Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá torí pé a ní èrò tí kò tọ́, ṣe ló dà bí ìgbà tí àìpé wa ń “sọ” fún wa pé kò sóhun tá a lè ṣe sí i. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ fetí sí i. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá. (Sm. 103:13, 14) Jèhófà “mọ ohun gbogbo” nípa wa, títí kan gbogbo ohun tí ò dáa tá à ń ṣe torí pé a jẹ́ aláìpé. (1 Jòh. 3:19, 20) Tá a bá ṣáà ti ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa ṣe ohun burúkú tó ń wá sọ́kàn wa, Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà wá. Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú?
13-14. Ṣé tá a bá ní èrò tí kò tọ́, Jèhófà ò ní tẹ́wọ́ gbà wá? Ṣàlàyé.
13 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín kéèyàn ní èrò tí kò tọ́ àti kéèyàn ṣe ohun tí kò tọ́. Èrò tí kò tọ́ lè wá sí wa lọ́kàn nígbà míì, àmọ́ àwa la ò ní ṣe ohun tí kò tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀ làwọn Kristẹni kan níjọ Kọ́ríńtì tẹ́lẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín jẹ́ tẹ́lẹ̀ nìyẹn.” Síbẹ̀, ó ṣeé ṣe kírú èrò yẹn ṣì máa wá sí wọn lọ́kàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan torí irú ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń di bárakú. Àmọ́ Jèhófà tẹ́wọ́ gba àwọn Kristẹni tó kó ara wọn níjàánu nígbà yẹn, tí wọn ò sì ṣe ohun burúkú tó ń wá sí wọn lọ́kàn. Torí náà, Jèhófà ‘wẹ̀ wọ́n mọ́.’ (1 Kọ́r. 6:9-11) Tíwọ náà ò bá ṣe ohun burúkú tó ń wá sí ẹ lọ́kàn, mọ̀ dájú pé Jèhófà máa tẹ́wọ́ gbà ẹ́.
14 Kò sí bí èrò tó ń wá sí ẹ lọ́kàn ṣe lè burú tó, o lè borí ẹ̀. Tó ò bá tiẹ̀ lè gbé e kúrò lọ́kàn pátápátá, o lè kó ara ẹ níjàánu, kó o má sì ‘ṣe ohun tí ara ẹ fẹ́ àti ohun tí ọkàn ẹ ń rò.’ (Éfé. 2:3) Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè borí èrò tí kò tọ́?
BÓ O ṢE LÈ BORÍ ÈRÒ TÍ KÒ TỌ́
15. Tó o bá fẹ́ borí èrò tí kò tọ́, kí nìdí tí kò fi yẹ kó o tan ara ẹ jẹ?
15 Tó o bá fẹ́ borí èrò tí kò tọ́, àfi kó o bá ara ẹ sòótọ́ ọ̀rọ̀, kó o sì mọ ibi tó o kù sí. Á dáa kó o ṣọ́ra, kó o má bàa fi “èrò èké” tan ara ẹ jẹ. (Jém. 1:22) Má fojú kéré ìṣòro náà, kó o wá máa rò pé ‘Mi ò kì í mutí tó pọ̀, àwọn míì ṣáà máa ń mutí jù mí lọ.’ Ó sì lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá àwọn ẹlòmíì lẹ́bi, bíi kó o máa sọ pé ‘Ká sọ pé ìyàwó mi máa ń fìfẹ́ hàn sí mi ni, kò ní máa wù mí láti wo àwòrán àti fíìmù ìṣekúṣe.’ Tó o bá ń nírú èrò bẹ́ẹ̀, ó máa ṣòro fún ẹ láti borí ìdẹwò yẹn. Torí náà, rí i pé o ò ṣàwáwí kódà nínú ọkàn ẹ. Múra láti ṣe ohun tó tọ́, kó o sì gbà pé ọwọ́ ẹ lọ̀rọ̀ náà kù sí.—Gál. 6:7.
16. Kí ló máa jẹ́ kó o pinnu pé ohun tó tọ́ lo máa ṣe?
16 Yàtọ̀ sí pé kó o mọ àwọn ibi tó o kù sí, ó yẹ kó o pinnu pé o ò ní ṣe nǹkan burúkú tó ń wá sí ẹ lọ́kàn. (1 Kọ́r. 9:26, 27; 1 Tẹs. 4:4; 1 Pét. 1:15, 16) Máa kíyè sí nǹkan tó máa ń dẹ ẹ́ wò àtìgbà tó máa ń ṣẹlẹ̀. Ó lè jẹ́ ohun kan pàtó ló sábà máa ń dẹ ẹ́ wò tàbí kó jẹ́ àkókò kan pàtó ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti borí èròkerò tó bá ti rẹ̀ ẹ́ tàbí tó bá dọwọ́ alẹ́? Ronú nípa ohun tó lè dẹ ẹ́ wò, kó o sì mọ ohun tó o máa ṣe. Torí náà, á dáa kó o mọ ohun tó o máa ṣe kí ìdẹwò náà tó dé.—Òwe 22:3.
17. Kí la kọ́ lára Jósẹ́fù? (Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
17 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jósẹ́fù ṣe nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì fẹ́ kó bá òun ṣèṣekúṣe. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sọ fún un pé òun ò ṣe, kò sì yí ìpinnu náà pa dà. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9.) Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Jósẹ́fù mọ̀ pé kò yẹ kéèyàn gba ìyàwó oníyàwó, ó sì ti pinnu ohun tó máa ṣe kí ìyàwó Pọ́tífárì tó fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́. Bákan náà, kí àdánwò tó dé ló yẹ kíwọ náà ti pinnu ohun tó o máa ṣe. Tí àdánwò bá dé, á rọrùn fún ẹ láti ṣe ohun tó tọ́.
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni kó o sá fún ìdẹwò bíi Jósẹ́fù! (Wo ìpínrọ̀ 17)
“Ẹ MÁA DÁN ARA YÍN WÒ”
18. Báwo lo ṣe lè borí èrò tí kò tọ́? (2 Kọ́ríńtì 13:5)
18 Tó o bá fẹ́ borí èrò tí kò tọ́, ó yẹ kó o ‘máa dán ara ẹ wò,’ ìyẹn ni pé kó o máa ṣàyẹ̀wò ohun tó ò ń ṣe déédéé. (Ka 2 Kọ́ríńtì 13:5.) Látìgbàdégbà, ó yẹ kó o máa kíyè sí ohun tó ò ń rò àtohun tó ò ń ṣe, kó o sì ṣàtúnṣe tó yẹ. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá borí ìdẹwò, ó ṣì yẹ kó o bi ara ẹ pé: ‘Ṣé ó pẹ́ kí n tó mọ ohun tó yẹ kí n ṣe?’ Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, má dá ara ẹ lẹ́bi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o túbọ̀ gbára dì. Bi ara ẹ pé: ‘Tí èrò tí kò tọ́ bá wá sí mi lọ́kàn, ṣé mo lè tètè gbé e kúrò lọ́kàn? Ṣé eré ìnàjú tí mò ń ṣe máa ń jẹ́ kó ṣòro fún mi láti borí ìdẹwò? Ṣé mo máa ń tètè gbé ojú mi kúrò tí mo bá rí àwòrán ìṣekúṣe? Ṣé mo gbà pé àwọn ìlànà Jèhófà ló dáa jù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo gbọ́dọ̀ kó ara mi níjàánu?’—Sm. 101:3.
19. Báwo làwọn ìpinnu kéékèèké tí ò dáa ṣe lè mú kó ṣòro fún wa láti borí èrò tí ò tọ́?
19 Má ṣàwáwí, má sì fojú kéré ìṣòro náà. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn ń tanni jẹ ju ohunkóhun lọ, kò sóhun tí kò lè ṣe.” (Jer. 17:9) Jésù sọ pé inú ọkàn ni “àwọn èrò burúkú” ti ń wá. (Mát. 15:19) Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè ti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán ìṣekúṣe, àmọ́ lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ ó lè rò pé kò sóhun tó burú tóun bá ń wo fọ́tò tó ń ru ìfẹ́ ìṣekúṣe sókè torí pé ẹni náà ò sí níhòòhò. Ó sì lè máa rò pé ‘Kò sóhun tó burú tí mo bá ń ronú nípa ìṣekúṣe tí mi ò bá ṣáà ti ṣe é.’ Tẹ́nì kan bá ń ronú bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń “gbèrò àwọn ìfẹ́ ti ara.” (Róòmù 13:14) Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa ro nǹkan tí ò dáa? Mọ àwọn nǹkan tó lè kó ẹ síṣòro, má sì ṣe àwọn ìpinnu kéékèèké tí ò dáa kó o má bàa ṣe àwọn ìpinnu ńlá tó lè mú kó o dẹ́ṣẹ̀.c Bákan náà, má fàyè gba “èrò burúkú” èyíkéyìí tó lè mú kó o ṣohun tí ò dáa.
20. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ nínú ayé tuntun, kí ni Jèhófà sì ń ṣe fún wa báyìí?
20 A ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí pé Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìdẹwò. Bákan náà, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ ẹ̀ kú nítorí wa, ó sì tún jẹ́ ká nírètí pé a máa wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun. Ẹ wo bínú wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá ń sin Jèhófà láìsí pé à ń ro èròkerò! Àmọ́ kó tó dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé a lè borí èrò tí ò tọ́, Jèhófà sì máa tẹ́wọ́ gbà wá. Tó o bá sì ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe, Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, wàá sì borí!
ORIN 122 Ẹ Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin!
a Nínú Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀, ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé: “Kò sí ìdánwò kan tí ó dé bá yín bíkòṣe irú èyí tí ó wọ́pọ̀ láàárín ènìyàn.”
b ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀: Nínú Bíbélì, tí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀,” ohun tí wọ́n ń sọ ni kéèyàn ṣe nǹkan tí ò dáa, bíi kó jalè, kó ṣèṣekúṣe tàbí kó pààyàn. (Ẹ́kís. 20:13-15; 1 Kọ́r. 6:18) Àmọ́ láwọn ibì kan nínú Bíbélì, “ẹ̀ṣẹ̀” ni àìpé tá a jogún nígbà tí wọ́n bí wa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò tíì dẹ́ṣẹ̀ kankan.
c Kíyè sí i pé ọ̀dọ́kùnrin tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú Òwe 7:7-23 ṣe àwọn ìpinnu kéékèèké tí ò dáa kó tó ṣe ìpinnu ńlá tó mú kó ṣèṣekúṣe.
d ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Apá Òsì: Nígbà tí arákùnrin kan wà níbi tí wọ́n ti ń mu kọfí, ó rí ọkùnrin méjì tó ń fìfẹ́ hàn síra wọn. Apá Ọ̀tún: Arábìnrin kan rí àwọn méjì tó ń mu sìgá.