OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́
Máa Lo Atọ́ka Ẹsẹ Bíbélì
Àwọn atọ́ka ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun máa ń jẹ́ ká mọ ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì míì sọ nípa ọ̀rọ̀ kan, ohun tí wọ́n bá sọ sì máa ń bára mu. Tó o bá fẹ́ rí ẹsẹ Bíbélì míì tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ò ń kà, wàá rí atọ́ka kan, ìyẹn lẹ́tà kékeré tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ náà. Tó bá jẹ́ Bíbélì torí ìwé lò ń kà, wàá rí lẹ́tà kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ kan, lọ wo lẹ́tà náà ní àárín ojú ìwé tó o wà, ibẹ̀ ni wàá ti rí àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó sọ nípa ohun tó ò ń kà. Àmọ́ tó bá jẹ́ Bíbélì tó wà lórí jw.org tàbí JW Library® lò ń kà, tẹ lẹ́tà kékeré tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì náà, kó o lè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì míì tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ò ń kà.
Atọ́ka ẹsẹ Bíbélì máa jẹ́ kó o rí àwọn nǹkan tá a fẹ́ sọ yìí, o sì tún lè lò ó láwọn ọ̀nà míì:
Ẹsẹ Bíbélì míì tó sọ ohun kan náà nípa ẹsẹ tó ò ń kà: Atọ́ka yìí máa jẹ́ kó o rí ẹsẹ Bíbélì míì tó sọ ohun kan náà tó wà ní ẹsẹ tó ò ń kà. Bí àpẹẹrẹ, wo 2 Sámúẹ́lì 24:1 àti 1 Kíróníkà 21:1.
Àyọlò: Atọ́ka máa jẹ́ kó o mọ ibi tí ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn kan ti kọ́kọ́ fara hàn. Bí àpẹẹrẹ, wo Mátíù 4:4 àti Diutarónómì 8:3.
Àsọtẹ́lẹ̀ tó ti ṣẹ: Tí ẹsẹ Bíbélì kan bá sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan, atọ́ka máa jẹ́ kó o mọ ẹsẹ Bíbélì tó sọ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sẹ. Bí àpẹẹrẹ, wo Mátíù 21:5 àti Sekaráyà 9:9.