ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kíróníkà

      • Ìkànìyàn tí kò bófin mu tí Dáfídì ṣe (1-6)

      • Ìyà tí Jèhófà fi jẹ wọ́n (7-17)

      • Dáfídì mọ pẹpẹ (18-30)

1 Kíróníkà 21:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “alátakò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 24:1-3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1992, ojú ìwé 5

1 Kíróníkà 21:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 8:16
  • +Ond 18:29; 2Sa 17:11

1 Kíróníkà 21:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 24:4, 8

1 Kíróníkà 21:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 24:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1992, ojú ìwé 5

1 Kíróníkà 21:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:47
  • +1Kr 27:23, 24

1 Kíróníkà 21:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 12:13
  • +Sm 25:11; 51:1
  • +2Sa 24:10-14

1 Kíróníkà 21:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:29

1 Kíróníkà 21:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:26
  • +Le 26:14, 17
  • +Le 26:25
  • +2Ọb 19:35

1 Kíróníkà 21:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:6; Sm 51:1; Ais 55:7; Ida 3:22
  • +2Kr 28:9

1 Kíróníkà 21:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 16:46
  • +2Sa 24:15, 16

1 Kíróníkà 21:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kẹ́dùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:14; Di 32:36
  • +Sm 90:13
  • +2Kr 3:1
  • +2Sa 5:6

1 Kíróníkà 21:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:31; Joṣ 5:13
  • +2Ọb 19:1
  • +2Sa 24:17

1 Kíróníkà 21:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 51:4
  • +Ẹk 32:12; Nọ 16:22

1 Kíróníkà 21:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 24:11
  • +2Sa 24:18-23; 2Kr 3:1

1 Kíróníkà 21:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

1 Kíróníkà 21:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Fi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 25:8

1 Kíróníkà 21:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ohun tó bá dára lójú rẹ̀.”

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 28:27

1 Kíróníkà 21:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 24:24, 25

1 Kíróníkà 21:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ṣékélì kan jẹ́ gíráàmù 11.4. Wo Àfikún B14.

1 Kíróníkà 21:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:25
  • +Le 9:23, 24; 1Ọb 18:38; 2Kr 7:1

1 Kíróníkà 21:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 24:16; Sm 103:20

1 Kíróníkà 21:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:4; 1Kr 16:39; 2Kr 1:3

Àwọn míì

1 Kíró. 21:12Sa 24:1-3
1 Kíró. 21:22Sa 8:16
1 Kíró. 21:2Ond 18:29; 2Sa 17:11
1 Kíró. 21:42Sa 24:4, 8
1 Kíró. 21:52Sa 24:9
1 Kíró. 21:6Nọ 1:47
1 Kíró. 21:61Kr 27:23, 24
1 Kíró. 21:82Sa 12:13
1 Kíró. 21:8Sm 25:11; 51:1
1 Kíró. 21:82Sa 24:10-14
1 Kíró. 21:91Kr 29:29
1 Kíró. 21:12Le 26:26
1 Kíró. 21:12Le 26:14, 17
1 Kíró. 21:12Le 26:25
1 Kíró. 21:122Ọb 19:35
1 Kíró. 21:13Ẹk 34:6; Sm 51:1; Ais 55:7; Ida 3:22
1 Kíró. 21:132Kr 28:9
1 Kíró. 21:14Nọ 16:46
1 Kíró. 21:142Sa 24:15, 16
1 Kíró. 21:15Ẹk 32:14; Di 32:36
1 Kíró. 21:15Sm 90:13
1 Kíró. 21:152Kr 3:1
1 Kíró. 21:152Sa 5:6
1 Kíró. 21:16Nọ 22:31; Joṣ 5:13
1 Kíró. 21:162Ọb 19:1
1 Kíró. 21:162Sa 24:17
1 Kíró. 21:17Sm 51:4
1 Kíró. 21:17Ẹk 32:12; Nọ 16:22
1 Kíró. 21:182Sa 24:11
1 Kíró. 21:182Sa 24:18-23; 2Kr 3:1
1 Kíró. 21:22Nọ 25:8
1 Kíró. 21:23Ais 28:27
1 Kíró. 21:242Sa 24:24, 25
1 Kíró. 21:26Ẹk 20:25
1 Kíró. 21:26Le 9:23, 24; 1Ọb 18:38; 2Kr 7:1
1 Kíró. 21:272Sa 24:16; Sm 103:20
1 Kíró. 21:291Ọb 3:4; 1Kr 16:39; 2Kr 1:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kíróníkà 21:1-30

Kíróníkà Kìíní

21 Nígbà náà, Sátánì* dìde sí Ísírẹ́lì, ó sì mú kí Dáfídì ka iye Ísírẹ́lì.+ 2 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Jóábù+ àti àwọn olórí àwọn èèyàn náà pé: “Lọ, ka Ísírẹ́lì láti Bíá-ṣébà dé Dánì;+ kí o sì wá jábọ̀ fún mi kí n lè mọ iye wọn.” 3 Ṣùgbọ́n Jóábù sọ pé: “Kí Jèhófà sọ àwọn èèyàn rẹ̀ di púpọ̀ ní ìlọ́po ọgọ́rùn-ún (100)! Olúwa mi ọba, ṣebí ìránṣẹ́ olúwa mi ni gbogbo wọn? Kí nìdí tí olúwa mi fi fẹ́ ṣe nǹkan yìí? Kí ló dé tí wàá fi mú kí Ísírẹ́lì jẹ̀bi?”

4 Àmọ́ ọ̀rọ̀ ọba borí ti Jóábù. Torí náà, Jóábù jáde lọ, ó sì rin gbogbo Ísírẹ́lì já, lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 5 Jóábù wá fún Dáfídì ní iye àwọn tó forúkọ wọn sílẹ̀. Gbogbo Ísírẹ́lì jẹ́ mílíọ̀nù kan ó lé ọ̀kẹ́ márùn-ún (1,100,000) àwọn ọkùnrin tó ní idà, Júdà sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (470,000) àwọn ọkùnrin tó ní idà.+ 6 Àmọ́ Léfì àti Bẹ́ńjámínì kò sí lára àwọn tí Jóábù forúkọ wọn sílẹ̀,+ torí ohun tí ọba sọ burú lójú rẹ̀.+

7 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí burú gan-an lójú Ọlọ́run tòótọ́, torí náà, ó kọ lu Ísírẹ́lì. 8 Dáfídì wá sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀+ ńlá nítorí ohun tí mo ṣe yìí. Ní báyìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì í,+ nítorí mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.”+ 9 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Gádì+ tó jẹ́ aríran Dáfídì sọ̀rọ̀, ó ní: 10 “Lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun mẹ́ta ni màá fi síwájú rẹ. Mú ọ̀kan tí o fẹ́ kí n ṣe sí ọ.”’” 11 Torí náà, Gádì wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Mú èyí tí o bá fẹ́, 12 bóyá kí ìyàn+ fi ọdún mẹ́ta mú tàbí kí àwọn ọ̀tá rẹ fi oṣù mẹ́ta gbá ọ dà nù bí idà àwọn ọ̀tá rẹ ti ń lé ọ bá+ tàbí kí idà Jèhófà, ìyẹn àjàkálẹ̀ àrùn ní ilẹ̀ yìí,+ fi ọjọ́ mẹ́ta jà, kí áńgẹ́lì Jèhófà sì máa pani run+ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì.’ Ní báyìí, ro ohun tí o fẹ́ kí n sọ fún Ẹni tó rán mi.” 13 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Gádì pé: “Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá mi gan-an. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Jèhófà, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi;+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ èèyàn.”+

14 Nígbà náà, Jèhófà rán àjàkálẹ̀ àrùn+ sí Ísírẹ́lì, tó fi jẹ́ pé ọ̀kẹ́ mẹ́ta ààbọ̀ (70,000) èèyàn lára Ísírẹ́lì kú.+ 15 Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run tòótọ́ rán áńgẹ́lì kan sí Jerúsálẹ́mù láti pa á run; àmọ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà rí i, ó sì pèrò dà* lórí àjálù náà,+ ó sọ fún áńgẹ́lì tó ń pani run náà pé: “Ó tó gẹ́ẹ́!+ Gbé ọwọ́ rẹ wálẹ̀.” Áńgẹ́lì Jèhófà dúró nítòsí ibi ìpakà Ọ́nánì+ ará Jébúsì.+

16 Nígbà tí Dáfídì gbójú sókè, ó rí áńgẹ́lì Jèhófà tó dúró láàárín ayé àti ọ̀run pẹ̀lú idà tó fà yọ+ ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó sì nà án sí Jerúsálẹ́mù. Ní kíá, Dáfídì àti àwọn àgbààgbà tí wọ́n fi aṣọ ọ̀fọ̀*+ bora wólẹ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀.+ 17 Dáfídì sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ṣebí èmi ni mo ní kí wọ́n lọ ka àwọn èèyàn náà! Èmi ni mo ṣẹ̀, èmi ni mo sì ṣe ohun tí kò dáa;+ àmọ́ kí ni àwọn àgùntàn yìí ṣe? Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀ọ́, èmi àti ilé bàbá mi ni kí o gbé ọwọ́ rẹ sókè sí; má ṣe mú àjàkálẹ̀ àrùn yìí wá sórí àwọn èèyàn rẹ.”+

18 Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì Jèhófà ní kí Gádì+ sọ fún Dáfídì pé kó lọ ṣé pẹpẹ kan fún Jèhófà ní ibi ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì.+ 19 Torí náà, Dáfídì lọ ṣe ohun tí Gádì sọ, èyí tó sọ fún un ní orúkọ Jèhófà. 20 Lákòókò yìí, Ọ́nánì bojú wẹ̀yìn, ó rí áńgẹ́lì náà, àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì fara pa mọ́. Nígbà yẹn, Ọ́nánì ń pa ọkà àlìkámà.* 21 Nígbà tí Dáfídì dé ọ̀dọ̀ Ọ́nánì, Ọ́nánì gbójú sókè, ó sì rí Dáfídì, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kúrò ní ibi ìpakà náà, ó tẹrí ba fún Dáfídì, ó sì dojú bolẹ̀. 22 Dáfídì sọ fún Ọ́nánì pé: “Ta* ilẹ̀ tó wá ní ibi ìpakà yìí fún mi, kí n lè mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà. Iye tó bá jẹ́ ni kí o tà á fún mi, kí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pa àwọn èèyàn yìí lè dáwọ́ dúró.”+ 23 Ṣùgbọ́n Ọ́nánì sọ fún Dáfídì pé: “Máa mú un, kí olúwa mi ọba ṣe ohun tó bá rí pé ó dára.* Mo tún fi màlúù sílẹ̀ fún àwọn ẹbọ sísun àti ohun èlò ìpakà+ láti fi ṣe igi ìdáná àti àlìkámà* fún ọrẹ ọkà. Gbogbo rẹ̀ ni mo fi sílẹ̀.”

24 Àmọ́, Ọba Dáfídì sọ fún Ọ́nánì pé: “Rárá o, iye tó bá jẹ́ ni màá rà á, torí mi ò ní gba ohun tó jẹ́ tìrẹ kì n sì fún Jèhófà tàbí kí n fi rú àwọn ẹbọ sísun láìná nǹkan kan.”+ 25 Nítorí náà, Dáfídì fún Ọ́nánì ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ṣékélì* wúrà fún ilẹ̀ náà. 26 Dáfídì mọ pẹpẹ kan+ síbẹ̀ fún Jèhófà, ó sì rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ó ké pe Jèhófà, ẹni tó wá fi iná dá a lóhùn+ láti ọ̀run sórí pẹpẹ ẹbọ sísun náà. 27 Lẹ́yìn náà, Jèhófà pàṣẹ fún áńgẹ́lì+ náà pé kí ó dá idà rẹ̀ pa dà sínú àkọ̀ rẹ̀. 28 Lákòókò yẹn, nígbà tí Dáfídì rí i pé Jèhófà ti dá òun lóhùn ní ibi ìpakà Ọ́nánì ará Jébúsì, ó ń rúbọ níbẹ̀ nìṣó. 29 Àgọ́ ìjọsìn Jèhófà tí Mósè ṣe ní aginjù àti pẹpẹ ẹbọ sísun ṣì wà ní ibi gíga Gíbíónì+ ní àkókò yẹn. 30 Àmọ́ Dáfídì kò tíì lọ síwájú rẹ̀ láti wádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ẹ̀rù idà áńgẹ́lì Jèhófà ń bà á.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́