ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 39
ORIN 54 “Èyí Ni Ọ̀nà”
Tètè Ran Àwọn Tó Fẹ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Lọ́wọ́
‘Gbogbo àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun di onígbàgbọ́.’—ÌṢE 13:48.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ká sì pè wọ́n wá sípàdé.
1. Kí làwọn kan ṣe nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run? (Ìṣe 13:47, 48; 16:14, 15)
NÍGBÀ ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló di Kristẹni lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù. (Ka Ìṣe 13:47, 48; 16:14, 15.) Bákan náà lónìí, inú àwọn kan dùn gan-an nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn kan ò kọ́kọ́ fẹ́ gbọ́, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Torí náà, kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí “àwọn olóòótọ́ ọkàn” nígbà tá à ń wàásù?
2. Báwo niṣẹ́ sísọni dọmọ ẹ̀yìn ṣe jọ iṣẹ́ àgbẹ̀?
2 Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí ná. A lè fi iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe wé ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀. Táwọn kan lára nǹkan tó gbìn bá ti tó kórè, ó máa kórè ẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó lè ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọbè síbòmíì kó lè gbin nǹkan síbẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá rẹ́ni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó yẹ ká tètè ràn án lọ́wọ́ kó lè dọmọ ẹ̀yìn Kristi. Àmọ́, àá ṣì máa ṣèrànwọ́ fáwọn tó jẹ́ pé ó máa pẹ́ díẹ̀ kí wọ́n tó mọyì ẹ̀kọ́ òtítọ́. (Jòh. 4:35, 36) Tá a bá lo ìfòyemọ̀, àá mọ ọ̀nà tó dáa jù láti bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀, ìyẹn á sì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe tá a bá kọ́kọ́ ráwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ Jèhófà.
BÁ A ṢE LÈ RAN ÀWỌN TÓ FẸ́ KẸ́KỌ̀Ọ́ ÒTÍTỌ́ LỌ́WỌ́
3. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ráwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà tá à ń wàásù? (1 Kọ́ríńtì 9:26)
3 Tá a bá rí àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà tá à ń wàásù, ojú ẹsẹ̀ ló yẹ ká ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà. Torí náà, ìgbà àkọ́kọ́ tá a bá wọn sọ̀rọ̀ ló yẹ ká bi wọ́n bóyá wọ́n máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì pè wọ́n wá sípàdé.—Ka 1 Kọ́ríńtì 9:26.
4. Sọ ìrírí obìnrin kan tó fẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
4 Bi wọ́n bóyá wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn kan tá a wàásù fún máa ń fẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ Thursday kan, obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Kánádà yà síbi tá a pàtẹ ìwé sí, ó sì mú ọ̀kan lára ìwé pẹlẹbẹ náà Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! Arábìnrin tó wà nídìí àtẹ ìwé náà sọ fún un pé a lè wá máa fi ìwé náà kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Obìnrin náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì gba nọ́ńbà tẹlifóònù ara wọn. Kílẹ̀ ọjọ́ yẹn tó ṣú, obìnrin náà fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí arábìnrin yẹn, ó sì sọ pé ìgbà wo làwọn máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Nígbà tí arábìnrin yẹn sọ fún un pé òun máa wá sọ́dọ̀ ẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀, obìnrin náà sọ pé: “Mo máa ráyè lọ́la, ṣẹ́ ẹ lè wá?” Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ obìnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ Friday nìyẹn. Ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn, obìnrin náà wá sípàdé nígbà àkọ́kọ́, ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ ń tẹ̀ síwájú, ó sì túbọ̀ ń sún mọ́ Jèhófà.
5. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kó wu ẹnì kan láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Ká sòótọ́, a ò retí pé kí gbogbo àwọn tó gbọ́rọ̀ wa gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ bí obìnrin yẹn. Ó lè gba pé ká pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn kan léraléra kí wọ́n tó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́. A lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa pẹ̀lú ohun tá a mọ̀ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Síbẹ̀, tá ò bá jẹ́ kó sú wa láti lọ sọ́dọ̀ ẹni náà, tá a sì ń ṣe ohun tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ó lè má pẹ́ rárá táá fi gbà ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí la lè sọ tá a bá fẹ́ bi àwọn èèyàn bóyá wọ́n máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́? Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó mọ bí wọ́n ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ.
Kí la lè sọ táá jẹ́ kírú àwọn èèyàn yìí fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (Wo ìpínrọ̀ 5)a
6. Kí la lè sọ táá mú kó wu ẹni tá a wàásù fún láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
6 Àwọn akéde àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà tá a béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn sọ pé láwọn ilẹ̀ kan, tá a bá fẹ́ bi àwọn èèyàn bóyá wọ́n máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò yẹ ká sọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ṣẹ́ ẹ máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Tàbí ṣé kí n máa wá kọ́ yín lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Wọ́n sọ pé ohun tó máa ń wu àwọn èèyàn ni tá a bá sọ pé, “Ṣẹ́ ẹ máa fẹ́ ká jọ máa jíròrò nínú Bíbélì? Tàbí ṣẹ́ ẹ máa fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la?” Tó o bá fẹ́ kẹ́ni náà gbà kó o pa dà wá, o lè sọ pé, “Bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tó kan ìgbésí ayé yani lẹ́nu gan-an. Ṣẹ́ ẹ máa fẹ́ kí n pa dà wá ká jọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?” Tàbí kó o sọ pé, “Bíbélì sọ àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ayé wa dáa, ṣẹ́ ẹ máa fẹ́ kí n pa dà wá ká jọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀?” Jẹ́ kó mọ̀ pé ìjíròrò náà ò ní ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá (10) sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ, á sì kọ́ àwọn nǹkan tó máa ṣe é láǹfààní. Bákan náà, kò yẹ ká sọ fún un pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ làá máa wá sọ́dọ̀ ẹ̀ torí ẹ̀rù lè bà á, kó má sì fẹ́ gbọ́rọ̀ wa mọ́.
7. Ìgbà wo làwọn kan kọ́kọ́ mọ̀ pé àwọn ti rí òtítọ́? (1 Kọ́ríńtì 14:23-25)
7 Pè wọ́n wá sípàdé. Nígbà ayé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó jọ pé ìgbà táwọn kan kọ́kọ́ wá sípàdé ni wọ́n mọ̀ pé àwọn ti rí òtítọ́. (Ka 1 Kọ́ríńtì 14:23-25.) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń túbọ̀ tẹ̀ síwájú tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé. Torí náà, ìgbà wo ló yẹ kó o pè wọ́n wá sípàdé? Ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! ẹ̀kọ́ kẹwàá sọ bá a ṣe lè pe àwọn èèyàn wá sípàdé, àmọ́ kò yẹ kó o dúró dìgbà tó o bá dé ẹ̀kọ́ kẹwàá kó o tó pè wọ́n wá sípàdé. Lọ́jọ́ tó o kọ́kọ́ bá ẹni náà sọ̀rọ̀, o lè pè é wá sípàdé òpin ọ̀sẹ̀, kó o sọ àkòrí àsọyé tá a máa gbọ́ fún un tàbí ohun tá a máa kọ́ nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.
8. Kí la lè sọ fún ẹni tá a fẹ́ pè wá sípàdé? (Àìsáyà 54:13)
8 Tó o bá fẹ́ pe ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ wá sípàdé, jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tá à ń ṣe níbẹ̀ yàtọ̀ sí tàwọn ẹ̀sìn míì tó mọ̀. Nígbà tẹ́nì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ kọ́kọ́ wá sípàdé, ó bi arábìnrin tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ pé, “Ṣé ẹni tó ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ yìí mọ orúkọ gbogbo àwọn tó wà níbí ni?” Arábìnrin náà ṣàlàyé pé a máa ń sapá láti mọ orúkọ àwọn tó wà nínú ìjọ bá a ṣe mọ orúkọ àwọn ará ilé wa. Ó ya ẹni náà lẹ́nu torí kò rí bẹ́ẹ̀ rárá nínú ṣọ́ọ̀ṣì tó ń lọ. Bó sì ṣe rí fún ọ̀pọ̀ lónìí náà nìyẹn torí wọn ò mọ ohun tá à ń ṣe nípàdé wa. (Ka Àìsáyà 54:13.) A máa ń wá sípàdé ká lè jọ́sìn Jèhófà, kó lè kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, ká sì lè gba ara wa níyànjú. (Héb. 2:12; 10:24, 25) Torí náà, ìpàdé wa máa ń wà létòlétò, a kì í sì í ṣe ayẹyẹ ìsìn níbẹ̀. (1 Kọ́r. 14:40) Ilé Ìpàdé wa bójú mu, ó sì tuni lára, ìyẹn sì máa ń mú kó rọrùn fún wa láti kẹ́kọ̀ọ́ níbẹ̀. A kì í ti ẹgbẹ́ òṣèlú kankan lẹ́yìn torí a kì í dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Bákan náà, a kì í dá sí àríyànjiyàn tó ń lọ láàárín ìlú. Ó máa dáa kó o fi fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? han akẹ́kọ̀ọ́ náà kó tó wá sípàdé, ìyẹn á jẹ́ kó mọ ohun tá à ń ṣe níbẹ̀.
9-10. Tó o bá pe ẹnì kan wá sípàdé, kí lo lè ṣe kó lè mọ̀ pé a kì í fipá sọ àwọn èèyàn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Àwọn kan kì í fẹ́ wá sípàdé torí ẹ̀rù ń bà wọ́n pé wọ́n lè ní káwọn “di ọmọ ìjọ.” Jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé inú wa máa ń dùn tá a bá rí àlejò tó wá sípàdé, a kì í sì í fipá sọ wọ́n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí ká sọ fún wọn pé dandan ni kí wọ́n ṣe nǹkan kan tí wọ́n bá dé ìpàdé. O tún lè sọ fún un pé gbogbo èèyàn la pè, torí náà òun àtàwọn ará ilé ẹ̀ lè wá, títí kan àwọn ọmọ kéékèèké. Láwọn ìpàdé wa, àwọn ọmọdé kì í jókòó sọ́tọ̀ ká lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn òbí àtàwọn ọmọ máa ń jókòó pa pọ̀ kí wọ́n lè jọ kẹ́kọ̀ọ́. Ìyẹn máa ń jẹ́ kọ́kàn àwọn òbí balẹ̀ pé kò sóhun tó máa ṣe àwọn ọmọ wọn, wọ́n á sì mọ nǹkan tí wọ́n ń kọ́. (Diu. 31:12) A kì í gbégbá ọrẹ tàbí sọ pé kí wọ́n pín àpò ìwé táwọn èèyàn máa fowó sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jésù sọ là ń ṣe, ó sọ pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mát. 10:8) O tún lè sọ fẹ́ni náà pé kò pọn dandan kó ní aṣọ olówó ńlá kó tó lè wá sípàdé. Ìdí sì ni pé ọkàn ni Ọlọ́run máa ń wò, kì í ṣe ìrísí wa.—1 Sám. 16:7.
10 Tẹ́ni náà bá wá sípàdé, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti jẹ́ kára ẹ̀ balẹ̀. Fi ẹni náà han àwọn alàgbà àtàwọn ará ìjọ. Tó bá rí i pé àwọn ará ìjọ kí òun dáadáa, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ òun, á fẹ́ pa dà wá nígbà míì. Típàdé bá ń lọ lọ́wọ́, tó o bá rí i pé kò ní Bíbélì, ẹ jọ máa wo Bíbélì tìẹ, kó o sì sọ fún un pé kó máa fọkàn bá alásọyé lọ.
Tẹ́ni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé, á tètè mọ Jèhófà (Wo ìpínrò 9-10)
OHUN TÓ YẸ KÁ ṢE TÁ A BÁ BẸ̀RẸ̀ SÍ Í KỌ́ ẸNÌ KAN LẸ́KỌ̀Ọ́
11. Tẹ́nì kan bá sọ ìgbà tó o máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́, kí nìdí tí kò fi yẹ kó o yẹ àdéhùn?
11 Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká rántí tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Ìgbà tẹ́ni náà bá ráyè, tó sì sọ pé kó o wá ni kó o lọ. Bí àpẹẹrẹ, tó bá sọ ìgbà tó fẹ́ kó o wá, rí i pé o lọ, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn tó wà lágbègbè yín kì í fi bẹ́ẹ̀ pa àdéhùn mọ́. Bákan náà, á dáa kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà má pẹ́ jù nígbà àkọ́kọ́. Àwọn ará kan tó nírìírí sọ pé á dáa ká má pẹ́ jù nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kódà tẹ́ni náà bá sọ pé ká ṣì máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ. Má sọ̀rọ̀ jù, jẹ́ kẹ́ni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ṣàlàyé bí ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ ṣe yé e àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀.—Òwe 10:19.
12. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
12 Ìgbà tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló yẹ kó o ti máa ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ Jèhófà àti Jésù, kó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. Bó o ṣe lè ṣe é ni pé kó o máa fi ohun tí Bíbélì sọ hàn án, má kàn fẹnu lásán sọ ọ́, má sì sọ èrò ara ẹ fún un. (Ìṣe 10:25, 26) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ó máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, ẹni tí Jèhófà rán wá ká lè mọ òun, ká sì nífẹ̀ẹ́ òun. (1 Kọ́r. 2:1, 2) Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù jẹ́ káwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ rí i pé ó ṣe pàtàkì kí wọ́n láwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye bíi wúrà, fàdákà àti òkúta iyebíye. (1 Kọ́r. 3:11-15) Ìgbàgbọ́, ọgbọ́n, òye àti ìbẹ̀rù Jèhófà wà lára àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye náà. (Sm. 19:9, 10; Òwe 3:13-15; 1 Pét. 1:7) Máa fara wé Pọ́ọ̀lù, kíwọ náà máa ran àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lè lágbára, kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.—2 Kọ́r. 1:24.
13. Báwo la ṣe lè ní sùúrù fáwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, ká sì gba tiwọn rò? (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
13 Máa fara wé Jésù, kíwọ náà máa ní sùúrù fáwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, kó o sì máa gba tiwọn rò. Má bi ẹni náà láwọn ìbéèrè tó máa kó ìtìjú bá a. Tó o bá rí i pé nǹkan kan ò yé e nígbà tẹ́ ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́, ẹ fi í sílẹ̀, kẹ́ ẹ wá pa dà sórí ẹ̀ tó bá yá. Má fipá mú un tí kò bá gba àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ kan, kàkà bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí àkókò díẹ̀ kọjá, káwọn nǹkan tó ń kọ́ lè túbọ̀ yé e. (Jòh. 16:12; Kól. 2:6, 7) Bíbélì fi ẹ̀kọ́ èké wé ògiri tó ga tá a fẹ́ wó lulẹ̀. (Ka 2 Kọ́ríńtì 10:4, 5; wo àlàyé ọ̀rọ̀ “overturning strongly entrenched things” nínú nwtsty-E.) Ó lè má rọrùn fẹ́ni náà láti jáwọ́ nínú ẹ̀kọ́ èké tó dà bí ògiri tó ga yẹn, torí ó ti gbà wọ́n gbọ́ tipẹ́tipẹ́. Torí náà, ṣe ló yẹ ká rọra fi ẹ̀kọ́ òtítọ́ kọ́ ọ kó lè fi Jèhófà ṣe Ibi Ààbò ẹ̀, ìyẹn á sì jẹ́ kó rọrùn fún un láti jáwọ́ nínú ẹ̀kọ́ èké.—Sm. 91:9.
Máa ní sùúrù fáwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kí ohun tí wọ́n ń kọ́ lè yé wọn (Wo ìpínrò 13)
BÁ A ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́ FÁWỌN TÓ ṢẸ̀ṢẸ̀ WÁ SÍPÀDÉ
14. Báwo ló ṣe yẹ ká ṣe sáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé?
14 Jèhófà kì í ṣojúsàájú, torí náà ó fẹ́ ká fìfẹ́ hàn sáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé. Lóòótọ́, ìlú àti àṣà ìbílẹ̀ wọn lè yàtọ̀ sí tiwa, wọ́n sì lè jẹ́ tálákà tàbí olówó. (Jém. 2:1-4, 9) Àmọ́, báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé?
15-16. Báwo la ṣe lè mára tu àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sípàdé?
15 Àwọn kan máa ń wá sípàdé wa torí pé wọ́n fẹ́ mọ nǹkan tá à ń ṣe níbẹ̀ tàbí kó jẹ́ pé ẹnì kan ló rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá. Torí náà, tá a bá rẹ́ni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sípàdé, ó yẹ ká lọ bá ẹni náà, ká sì kí i dáadáa. Àmọ́, má ṣàṣejù tó o bá ń kí i. O lè ní kẹ́ni náà wá jókòó sọ́dọ̀ ẹ. Ẹ jọ máa wo Bíbélì ẹ àtàwọn ìwé tá a fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípàdé tàbí kó o lọ gba tiẹ̀ fún un. Bákan náà, máa kíyè sí ẹni náà kó o lè mọ bó o ṣe máa mára tù ú. Ọkùnrin kan tó wá sí Ilé Ìpàdé sọ fún arákùnrin kan pé ara òun ò balẹ̀ torí pé aṣọ ìṣeré lòun wọ̀ wá sípàdé. Arákùnrin náà mára tù ú, ó sì sọ fún un pé èèyàn bíi tiẹ̀ làwa náà. Ọkùnrin náà tẹ̀ síwájú, ó sì ṣèrìbọmi, àmọ́ kò gbàgbé ohun tí arákùnrin yẹn sọ títí dòní. Torí náà, o lè bá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sípàdé sọ̀rọ̀ kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ àti lẹ́yìn ìpàdé kó o lè mọ̀ wọ́n dáadáa. Àmọ́ o, má tojú bọ̀rọ̀ wọn, má sì béèrè ìbéèrè tí ò kàn ẹ́.—1 Pét. 4:15.
16 Bákan náà, tá a bá fẹ́ mára tu àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sípàdé, àwọn nǹkan kan wà tí kò yẹ ká máa ṣe. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká kàn wọ́n lábùkù, kò sì yẹ ká dójú tì wọ́n tá a bá ń dáhùn tàbí tá à ń bójú tó àwọn iṣẹ́ míì pàápàá tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Kò yẹ ká sọ̀rọ̀ tí ò ní jẹ́ kí wọ́n wá sípàdé mọ́. (Títù 2:8; 3:2) Bí àpẹẹrẹ, a ò ní máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (2 Kọ́r. 6:3) Torí náà, àwọn arákùnrin tó ń sọ àsọyé gbọ́dọ̀ kíyè sára gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ó tún yẹ kí wọ́n ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ní yé àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nípàdé.
17. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí “àwọn olóòótọ́ ọkàn” nígbà tá à ń wàásù?
17 Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe láti sọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn ṣe pàtàkì gan-an, kò yẹ ká fi falẹ̀ rárá, ká má sì jẹ́ kó sú wa láti wá “àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 13:48) Torí náà, tá a bá ráwọn olóòótọ́ ọkàn, ó yẹ ká tètè bi wọ́n bóyá wọ́n máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì pè wọ́n wá sípàdé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn ní ‘ọ̀nà tó lọ sí ìyè.’—Mát. 7:14.
ORIN 64 À Ń Fayọ̀ Ṣe Iṣẹ́ Ìkórè Náà
a ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Àwọn arákùnrin méjì kan ń wàásù fún sójà kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn arábìnrin méjì kan ń wàásù fún obìnrin kan tó ń tọ́mọ, wọn ò sì pẹ́ lọ́dọ̀ ẹ̀.