Orílẹ̀-èdè Vietnam: Àwọn ọmọdé ń gbádùn fídíò Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O Sì Gba Ìbùkún lórí ìkànnì jw.org
ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Àwọn Fídíò Bèbí Wọ Àwọn Ọmọdé Lọ́kàn
Kárí ayé làwọn èèyàn ti mọ ọmọ kékeré tá a pè ní Kọ́lá nínú àwọn fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà. A túmọ̀ apá àkọ́kọ́ fídíò tó dá lórí ọmọ kékeré tó fani mọ́ra yìí sí èdè tó lé ní àádóje [130], a sì ti gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ lẹ́tà látọ̀dọ̀ àwọn tó wo fídíò alápá púpọ̀ yìí.
Nínú lẹ́tà tí ọmọ ọdún mọ́kànlá kan àti àbúrò rẹ̀ obìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ kọ, wọ́n sọ pé: “Ó wù wá láti fi owó yìí ti iṣẹ́ ìwàásù tó ń lọ kárí ayé lẹ́yìn. Ìgbà tí a ta ọmọ màlúù méjì tá a sìn la rí owó yìí. Orúkọ tá a sọ wọ́n ni Big Red àti Earl. A fẹ́ fún yín ní owó yìí torí a wò ó pé ẹ lè fi ṣe àwọn fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà púpọ̀ sí i. Ó wù wá kí Kọ́lá ní àbúrò obìnrin kan, ká wá wo ohun tó máa ṣe nígbà tí wọn ò bá tọ́jú rẹ̀ lójú méjèèjì bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Fídíò Kọ́lá yìí la fẹ́ràn jù!”
Ọ̀pọ̀ ọmọdé ló ti há ọ̀rọ̀ inú fídíò náà sórí látòkè délẹ̀, títí kan orin àti ọ̀rọ̀ asọ̀tàn. Arábìnrin kan sọ pé nínú ọgọ́rùn-ún [100] akéde tó wà nínú ìjọ òun, ogójì [40] jẹ́ ọmọdé, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ni kò sì tíì pé ọmọ ọdún mẹ́wàá. Ìlà kẹta ni arábìnrin náà jókòó sí lọ́jọ́ kan tí wọ́n fi orin ọgọ́fà [120] parí ìpàdé. Ṣe ni omijé ayọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú rẹ̀ bó ṣe ń gbọ́ táwọn ọmọ kéékèèké yẹn ń kọ “orin wọn” sókè lala.
Ìyá àgbà kan sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ọmọ-ọmọ rẹ̀ wo fídíò náà lẹ́ẹ̀méjì, ó ní ọmọ náà sọ pé: “Ó yẹ kí n lọ tún yàrá mi ṣe torí mi ò fẹ́ kí àwọn bèbí mi gbé èèyàn ṣubú tàbí kó ṣe wọ́n léṣe.” Yàrá tó fẹ́ tún ṣe yẹn ká a lára débi pé ìgbà tó parí rẹ̀ ló tó wá jẹun.
Ní abúlé kan lórílẹ̀-èdè South Africa, ojoojúmọ́ ni ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń rọ́ lọ sí ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Àwọn kan rò pé torí súìtì tí wọ́n ń tà níbẹ̀ ni. Àṣé fídíò Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O Sì Gba Ìbùkún lèdè Xhosa làwọn ọmọdé abúlé náà ń pera wọn wá wò. Ìgbà kan wà tí àwọn ọmọdé mọ́kànlá pé jọ síbẹ̀ lásìkò kan náà, gbogbo wọn ló sì ti há àwọn ọ̀rọ̀ orin inú fídíò náà sórí.
Ní orílẹ̀-èdè Ecuador, tẹ̀gbọ́n tàbúrò kan wà tó ń sọ èdè Quicha, Isaac àti Saul lorúkọ wọn. Ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ, ìkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún, wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n sábà máa ń tọ́jú owó oúnjẹ wọn láti fi ra ìbọn ìṣeré, idà àti àwọn bèbí tó dà bí àwọn tó ń ṣeré oníwà ipá. Lọ́jọ́ kan, màmá wọn sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ palẹ̀ yàrá wọn mọ́ kí wọ́n sì kó gbogbo bèbí wọn sínú páálí tó wà lábẹ́ bẹ́ẹ̀dì. Lọ́jọ́ kan, ẹnì kan fún wọn ní fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà, wọ́n sì jọ wò ó. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, nígbà tí ìyá àwọn ọmọ náà ń tún ilé ṣe, ó rí i pé mọ́tò ìṣeré nìkan ló kù sínú páálí náà. Ló bá béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ibo làwọn bèbí yòókù wà?” Wọ́n fèsì pé, “Jèhófà ò fẹ́ràn irú àwọn bèbí yẹn, torí náà a ti kó wọn dà nù.” Tí àwọn ọmọ tí wọ́n jọ wà ní àdúgbò bá ń fi àwọn bèbí tó lè mú wọn hùwà ipá ṣeré, Isaac máa ń sọ fún wọn pé: “Ẹ má firú nǹkan báyìí ṣeré mọ́, Jèhófà ò fẹ́ ẹ!”
Orílẹ̀-èdè Croatia: Àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run wọ àwọn ọmọ wa lọ́kàn