Àwọn Ohun Ìṣeré Tó Dáa Jù Lọ Fáwọn Ọmọdé
Irú ohun ìṣeré wo ló yẹ kí n rà fọ́mọ mi? Èló ló yẹ kí n ná lé e lórí? Bó o bá jẹ́ òbí, o lè ti bi ara ẹ láwọn ìbéèrè wọ̀nyí rí lọ́pọ̀ ìgbà. Ó dára, ìròyìn rere tá a ní fún ọ ni pé ó lè jẹ́ pé àwọn ohun ìṣeré tó dáa jù lọ lowó wọn rọjú jù lọ.
Ìwé náà, Motivated Minds—Raising Children to Love Learning, sọ pé: “Àwọn ọmọdé máa ń jàǹfààní púpọ̀ bí wọ́n bá ń fọwọ́ ara wọn ṣe nǹkan tí wọ́n sì ń ṣàwárí àwọn ohun tuntun ju kí wọ́n kàn máa wòran lọ, nítorí náà, àwọn ohun ìṣeré tá á mú kí wọ́n lo àtinúdá wọn sàn ju àwọn ọkọ oníbátìrì tó ń kọ mọ̀nà tàbí àwọn bèbí tí ń kọrin, tó jẹ́ pé ìwọ̀nba ni ohun tọmọ rẹ lè fi wọ́n ṣe.” Àwọn ọmọdé lè kọ́kọ́ “gbádùn àtimáa” fi irú ọkọ̀ tàbí bèbí bẹ́ẹ̀ ṣeré, “ṣùgbọ́n kò ní pẹ́ tá á fi sú wọn nítorí pé kò ní jẹ́ kí wọ́n ráyè ṣèwádìí, kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan, tàbí kí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe àwọn nǹkan.”
Ọjọ́ orí ọmọ kọ̀ọ̀kan ló tún máa ń pinnu ohun tó máa wù ú. Lára àwọn ohun ìṣeré tó lè ta ọpọlọ àwọn ọmọdé jí ni àwọn ohun ìṣeré tó ṣeé tò pọ̀, òfìfo páálí, bébà, àwọn nǹkan ìyàwòrán, iyẹ̀pẹ̀ àtomi náà sì tún wà ńbẹ̀. Ìwé Motivated Minds, sọ pé: “Àwọn ẹranko kéékèèké tí wọ́n fi ike ṣe táwọn ọmọdé lè fi ṣeré á fún [ọmọ] kan láǹfààní láti to àwọn tó jọra nínú wọn pọ̀, láti pín wọn sí onírúurú, kó fi wọ́n wéra, kó sì tún já fáfá nínú lílo èdè láti fi sọ ìtàn nípa wọn.” Ìwé náà tún dábàá lílo àwọn ohun èlò ìkọrin kékeré, nítorí pé èyí á mú káwọn ọmọ lè mọ onírúurú ohùn àti bí wọ́n ṣe máa ń dún, àmọ́ wàá ṣe tán láti fara mọ́ ariwo ẹ̀ o.
Àwọn ọmọdé kì í gbàgbé nǹkan bọ̀rọ̀, wọ́n máa ń fẹ́ láti kọ́ ohun tuntun kí wọ́n sì tún ṣeré. Nítorí náà, kí ló dé tó ò kúkú ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí nípa wíwá ohun ìṣeré tó dáa jù lọ fún wọn.