Ilé Ìwé Jẹ́lé-Ó-Sinmi Tí Kò Ní Ohun Ìṣeré Ọmọdé
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ JÁMÁNÌ
Láàárọ̀ ọjọ́ kan, nígbà táwọn ọmọ jẹ́lé-ó-sinmi wọ yàrá ìkàwé wọn, wọ́n rí i pé yàtọ̀ sáwọn ohun èlò ìkàwé tó máa ń wà níbẹ̀, ńṣe ni gbogbo ibẹ̀ mọ́ foo. Kò sí ibi tí wọn ò wá àwọn bèbí, àwọn ayò tàbí ohun ìṣeré mìíràn dé, ṣùgbọ́n pàbó ló já sí. Kò sí ìwé kankan, àwọn ohun ìṣeré tí wọ́n máa ń tò bíi búlọ́ọ̀kù náà sì ti di àfẹ́ẹ̀rí. Kódà wọn ò rí bébà àti sáàsì. Gbogbo nǹkan ìṣeré ọmọdé tó wà níbẹ̀ ni wọ́n ti kó kúrò, ó sì dẹ̀yìn oṣù mẹ́ta kí wọ́n tó dá wọn padà. Kí ló ṣẹlẹ̀?
Irú ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi báyìí ti ń pọ̀ lórílẹ̀-èdè Austria, Jámánì àti Switzerland. Àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ni wọ́n pawọ́ pọ̀ gbé ètò àràmàǹdà yìí tí wọ́n pè ní Ilé Ìwé Jẹ́lé-Ó-Sinmi Tí Kò Ní Ohun Ìṣeré Ọmọdé kalẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò yìí lè dà bí ohun tójú ò rí rí, síbẹ̀ nítorí káwọn ọmọ má bàa máa sọ nǹkan di bárakú ni wọ́n fi gbé e kalẹ̀, àwọn ògbógi lórí ọ̀ràn ìlera nínú àjọ ìlera àgbáyé sì ti gbóṣùbà bàǹbà fún wọn nítorí ẹ̀. Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn olùṣèwádìí ti wá rí i pé àwọn èèyàn kì í tètè dẹni tó sọ nǹkan di bárakú bí wọ́n bá kọ́ bí wọ́n ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn ṣeré láti ìgbà tí wọ́n ti wà lọ́mọdé. Ìwé ìròyìn kan sọ pé lára àwọn nǹkan téèyàn lè kọ́ láti kékeré ni, “mímọ bá a ṣe ń bá èèyàn sọ̀rọ̀ àti bá a ṣe ń yan ọ̀rẹ́ tìrọ̀rùntìrọ̀rùn, bá a ṣe ń yanjú aáwọ̀, bá a ṣe lè fara mọ́ ohun tó bá tìdí ìwà téèyàn hù jáde, béèyàn ṣe lè gbé nǹkan tá á máa lépa síwájú ara ẹ̀, bá a ṣe ń dá ìṣòro mọ̀, bá a ṣe lè wá ìrànlọ́wọ́, àti yíyanjú ìṣòro.” Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ṣagbátẹrù ètò yìí ṣe sọ, láti kékeré pínníṣín ló yẹ kéèyàn ti kọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ìdí tí wọ́n sì fi ṣètò láti kó àwọn ohun ìṣeré ọmọdé kúrò nílé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi fún àkókò kan nìyẹn, kó bàa lè kọ́ àwọn ògo wẹẹrẹ láti lè ní ọgbọ́n àtinúdá kí wọ́n sì máa fi ìdára-ẹni-lójú ṣe nǹkan.
Kí wọ́n tó ṣètò oṣù mẹ́ta tí kò fi ní sí àwọn ohun ìṣeré màjèṣín yìí, wọ́n ti múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa, wọ́n sì ti bá àwọn òbí àtàwọn ọmọ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, àwọn ọmọ kan ò mọ ohun tó yẹ káwọn ṣe nígbà tí wọn ò rí nǹkan ṣeré. Ìròyìn náà tẹ̀ síwájú pé: “Àwọn ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi kan wà táwọn ọmọ ti máa ń ya pòkíì láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́ tí wọ́n bá lò níbẹ̀,” àwọn tó ṣètò rẹ̀ ò sì mọ nǹkan tí wọn ì bá ṣe. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọdé ti wá ń mọ bí wọ́n á ṣe máa ṣe nípòkípò tí wọ́n bá bára wọn, wọ́n sì ti kọ́ láti mọ oríṣiríṣi nǹkan ṣe. Nígbà tí wọn ò rí àwọn nǹkan tí wọ́n á fi ṣeré, àwọn ọmọdé bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀, wọ́n ń gbèrò àtiṣe nǹkan wọ́n sì jọ ń ṣeré, wọ́n ń tipa báyìí kọ́ ẹ̀kọ́ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá àti èdè. Àwọn ọmọ tó jẹ́ pé tẹ́lẹ̀ ìdí àwọn nǹkan ìṣeré wọn ni wọ́n á jókòó sí ti wá ń lọ́rẹ̀ẹ́ báyìí. Àwọn òbí pẹ̀lú ti rí i pé ìyàtọ̀ ń dé bá àwọn ọmọ àwọn. Wọ́n sọ pé ìwà táwọn ọmọ àwọn ń hù tí wọ́n bá ń ṣeré ń sunwọ̀n sí i àti pé wọ́n ti ń mọ nǹkan ṣe ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.