ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Ìbẹ̀wò Táá Jẹ́ Kó O Mọ Ìtàn Amóríyá Nípa Wa
Ní oṣù October 2012, a ṣètò àfihàn kan tó dá lórí ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí ìlú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Àfihàn náà sọ nípa àwọn ohun tí ojú àwọn kan ti rí, títí kan àwọn ewu tí wọ́n ti là kọjá torí pé wọ́n fẹ́ ṣe ẹ̀sìn Kristẹni lọ́nà tí Jésù ní ká gbà ṣe é.
Lọ́sẹ̀ àkọ́kọ́ nìkan, iye èèyàn tó wá wo àfihàn náà lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti igba [4,200] látinú ìdílé Bẹ́tẹ́lì àti láti ìta. Kò pẹ́ sígbà táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wá wo àfihàn náà tí Arábìnrin Naomi pẹ̀lú wá, ilé rẹ̀ kò jìnnà síbẹ̀. Ó ní: “Bí wọ́n ṣe to àwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé jẹ́ kí n mọ ìgbà tí wọ́n ṣẹlẹ̀ àti ìdí tí wọ́n fi ṣẹlẹ̀. Mo kọ́ ohun púpọ̀ nípa ètò Ọlọ́run àti ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní.”
Àfihàn náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohun tó wáyé lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni títí di àkókò wà yìí. Apá mẹ́rin ló pín sí. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní àkọlé tó dá lórí Bíbélì àti fídíò kúkúrú kan lédè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ wọn, àmọ́ èèyàn lè rí ọ̀rọ̀ inú fídíò náà kà ní èdè méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Àkọlé apá àkọ́kọ́ ni ‘Àwọn Ènìyàn Nífẹ̀ẹ́ Òkùnkùn.’ Ó dá lórí ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Jòhánù 3:19. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì bá lọ tán, àwọn ènìyàn burúkú yóò “dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà.” (Ìṣe 20:30) Wọ́n sì fojú àwọn tí kò gba tiwọn rí màbo.
Àkọlé apá kejì jẹ́ òdìkejì ti àkọ́kọ́, ìyẹn ni ‘Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Tàn.’ Ó dá lórí 2 Kọ́ríńtì 4:6, ìtàn inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bí ọdún 1870, nígbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ lákọ̀tun. Wọ́n fi àwọn ẹ̀kọ́ àtayébáyé tó tako Bíbélì sílẹ̀, wọ́n sì wá ń fi ìgboyà wàásù ẹ̀kọ́ òtítọ́. Apá yìí ló sọ nípa bí wọ́n ṣe ń pọ̀ sí i àti bí ìmọ̀ wọn ṣe ń pọ̀ sí i ṣáájú Ogun Àgbáyé Kìíní.
Nínú yàrá kan tó tẹ̀ lé e, a ṣàfihàn ohun àrà ọ̀tọ̀ kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, tó sì ń dùn mọ́ wa nínú títí dòní olónìí. Lọ́dún 1914, Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (bí wọ́n ṣe mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn) bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwòkẹ́kọ̀ọ́ “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] han àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wo sinimá aláwọ̀ mèremère tó ní ohùn tí wọ́n ti gbà sílẹ̀ yìí. Ara àwọn nǹkan tí wọ́n ṣàfihàn rẹ̀ ni àwọn àwòrán tí wọ́n lò nígbà yẹn, díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi nasẹ̀ àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà àti àwọn àwòrán aláwọ̀ mèremère tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500].
Àkọlé apá kẹta ni ‘Dírágónì Náà Kún fún Ìrunú.’ Ó dá lórí inúnibíni tí Sátánì ṣe sí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, bó ṣe wà nínú Ìṣípayá 12:17. Ó sọ nípa bí àwọn Kristẹni ò ṣe lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ológun. Láfikún sí àfihàn àwọn ohun àtijọ́ àtàwọn fọ́tò, àwọn fídíò kúkúrú tún wà níbẹ̀ tí wọ́n fi ṣàfihàn bí ìjọba ṣe fẹ́ fipá mú àwọn tó kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ogun torí ẹ̀rí ọkàn wọn, irú bí Arákùnrin Remigio Cuminetti ti ilẹ̀ Ítálì, tó kọ̀ láti wọ aṣọ ológun, tí kò sì bá wọn lọ́wọ́ nínú Ogun Àgbáyé Kìíní. Fídíò míì tún sọ̀rọ̀ nípa Arákùnrin Alois Moser tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Austria. Ó kọ̀ láti sọ pé “Ti Hitler ni mo ṣe,” torí bẹ́ẹ̀ wọ́n lé e níbi iṣẹ́, wọ́n sì wá jù ú sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Dachau. A tún ṣe yàrá kótópó kan bíi yàrá ẹ̀wọ̀n tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀, èyí jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó ń wo àwọn fọ́tò tó wà níbẹ̀ láti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ṣẹ̀wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn nílẹ̀ Gíríìsì, Japan, Poland, ilẹ̀ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ àtàwọn ibòmíì.
Àkọlé apá tó kẹ́yìn ni ‘Ìhìn Rere fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè.’ A mú un látinú ìwé Ìṣípayá 14:6. Ó sọ nípa iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lásìkò wa yìí. Àwọn àwòrán tó wà lára ògiri ibẹ̀ jẹ́rìí sí ìfẹ́ tá a ní fún gbogbo ẹgbẹ́ ará, bí a ṣe ń wàásù láìdábọ̀ àti bí ìbísí tó kàmàmà ṣe ń wáyé. Àwọn kọ̀ǹpútà tá a gbé sára ògiri, tá a sì tò sọ́wọ́ ìparí àfihàn náà máa jẹ́ káwọn tó wá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ mọ bí Ilé Bíbélì àti ibi tá a pè ní Àgọ́ Ìjọsìn Ìlú Brooklyn ṣe rí. Ìyẹn àwọn ibi tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] ọdún sẹ́yìn.
Ojúlé kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], òpópónà Columbia Heights, ìlú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà la ti ń ṣe àfihàn yìí. A máa ń ṣí ibẹ̀ sílẹ̀ ní aago mẹ́jọ àárọ̀ sí márùn-ún ìrọ̀lẹ́ lọ́jọ́ Monday sí Friday. Ọ̀fẹ́ ni, a kì í gba owó ìwọlé. Tó o bá wà ní ìlú New York City, ṣé ìwọ náà á wá ṣe ìbẹ̀wò táá jẹ́ kó o mọ ìtàn amóríyá nípa wa?