Ìyàsímímọ́ Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower—Ọjọ́ Àjọyọ̀ fún Jèhófà
ÀTAYÉBÁYÉ làwọn àjọyọ̀ tó mìrìngìndìn ti jẹ́ apá kan ìjọsìn tòótọ́. Àwọn kan lára àjọyọ̀ tó wáyé ní Ísírẹ́lì ìgbàanì gba ọ̀pọ̀ ọjọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùjọsìn Jèhófà ló sì máa ń péjú-pésẹ̀ síbẹ̀. Ọjọ́ méje gbáko ni wọ́n fi ṣayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, wọ́n sì fi odindi ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà. Èyí fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láǹfààní láti ronú lórí ọ̀nà àgbàyanu tí Jèhófà fi bá wọn lò. Wọ́n padà wálé, “wọ́n ń yọ̀, wọ́n sì ń ṣàríyá nínú ọkàn-àyà wọn lórí gbogbo oore tí Jèhófà ṣe.”—1 Àwọn Ọba 8:66.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower ní Patterson, nílùú New York, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, lọ́jọ́ kẹtàdínlógún sí ìkejìlélógún oṣù May, 1999, rán àwọn olùbẹ̀wò létí àwọn àjọyọ̀ ìgbàanì tó mìrìngìndìn. Èyí jẹ́ ọ̀sẹ̀ àkànṣe ìgbòkègbodò tó dá lé ìyàsímímọ́ ilé méjìdínlọ́gbọ̀n táa kọ́ fún gbígbé ẹ̀kọ́ Bíbélì lárugẹ kárí ayé. A ṣètò pé kí gbogbo òṣìṣẹ́ orílé iṣẹ́ wa tí iye wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún lé nírínwó [5,400] àwọn tó wà ní Brooklyn, Wallkill, àti Patterson rìn káàkiri gbogbo ilé táa kọ́ sí Patterson láàárín ọ̀sẹ̀ mánigbàgbé yìí. Lára àlejò wa ni àwọn tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta òṣìṣẹ́ wa tẹ́lẹ̀ rí, tó bá wa ṣiṣẹ́ nígbà táa ń kọ́ ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà, àti aṣojú mẹ́tàlélógún láti àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ Watch Tower Society, àtàwọn míì láti àwọn ìjọ itòsí—ó kéré tán, àpapọ̀ gbogbo wọn tó ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé lọ́gọ́rùn-ún.
Àwọn Àwòrán Táa Fi Hàn Ń Lani Lóye
Kí àwọn olùbẹ̀wò lè mọ bí ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe rí, a ṣètò àwọn àwòrán pàtàkì, àwọn fídíò tí ń lani lóye, àti béèyàn ṣe lè fúnra rẹ̀ rìn yí ká. Ní ibi ìgbàlejò téèyàn máa kọ́kọ́ dé, ohun tí àlejò máa kọ́kọ́ rí làwòrán tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn àwòrán míì dá lé ìtàn nípa ìbẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, àwọn àpéjọpọ̀ mánigbàgbé, àwọn ìpàdé ìjọ, báa ṣe bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóde òní—tó wá di pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ là ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ báyìí—àti iṣẹ́ tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ti mú ṣe, kí ọ̀nà lè là fún irú ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀, gbogbo èyí jẹ́ ìgbọràn sí àṣẹ Jésù.—Mátíù 28:19, 20.
Nínú gbọ̀ngàn àpéjọ tó wà nítòsí rẹ̀, tó gba ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] èèyàn dáadáa, làwọn àlejò tó wá nígbà àjọyọ̀ ìyàsímímọ́ ti wo fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́tàlélọ́gbọ̀n táa pe àkọlé rẹ̀ ní “Kì Í Ṣe Nípasẹ̀ Agbára—Nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mi Ni!” Fídíò yìí fi iṣẹ́ tó lọ lórí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower hàn. Àwọn táa fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ṣàlàyé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé ọwọ́ Jèhófà wà lára iṣẹ́ náà àti pé bíbùkún tó bù kún ìsapá àwọn ará ló jẹ́ kí iṣẹ́ tó gba ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yìí kẹ́sẹ járí. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ló kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Ní àkókò kan lọ́dún 1994, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé ní mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [526] òṣìṣẹ́ ló wà lẹ́nu iṣẹ́, èyíinì ni, àádọ́ta lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún [350] àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni alákòókò kíkún, àti òṣìṣẹ́ alákòókò ráńpẹ́ mẹ́tàléláàádọ́fà [113], àtàwọn mẹ́tàlélọ́gọ́ta tó ń ti ilé wọn wá síbi iṣẹ́ lójoojúmọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ náà. Gbogbo wọn ló mọ̀ pé èyí kì bá ṣeé ṣe láé bí kì í báá ṣe ẹ̀mí Jèhófà.—Sekaráyà 4:6.
Àwọn tó rìn yí ká ibẹ̀ lè rí i pé ìdí pàtàkì táa fi kọ́ ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà jẹ́ láti gbé ẹ̀kọ́ Ọlọ́run lárugẹ. Àwọn ohun táa fi hàn níbi ẹnu ọ̀nà Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead tó wà ní àjà àkọ́kọ́ ibi tí ilé ẹ̀kọ́ wà pe àfiyèsí sí ogún tẹ̀mí tó bùáyà àti ìtàn ilé ẹ̀kọ́ náà. Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méje akẹ́kọ̀ọ́ tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead láti ìgbà tí kíláàsì rẹ̀ àkọ́kọ́ wọlé lọ́dún 1943 ní ọgbà àkọ́kọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà ní South Lansing, New York. Àwọn ohun táa fi hàn ní àjà kejì ibi tí ilé ẹ̀kọ́ náà wà jẹ́ àwòrán Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka àti Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò, tó jẹ́ pé kíláàsì kan náà ni wọ́n ń lò. Látìgbà tí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀ka ti bẹ̀rẹ̀ ní November 1995, ó ti pèsè ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ fún òjì-dín-nírínwó [360] mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka láti ilẹ̀ mẹ́rìndínláàádọ́fà [106].
Bí àwọn olùbẹ̀wò ti ń fójú wọn lóúnjẹ, kò pẹ́ tí wọ́n fi rí i pé àwọn tilẹ̀ lè rí ju àwòrán nìkan. Wọ́n láǹfààní láti wọnú onírúurú ẹ̀ka ibi iṣẹ́, kí wọ́n wọ àwọn ọ́fíìsì kan àtàwọn ibi iṣẹ́ míì, kí wọ́n sì túbọ̀ rí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. Téèyàn bá wá dé ibi tí wọ́n ti ń ṣe Kásẹ́ẹ̀tì òun Fídíò, ìròyìn ò tó àfojúbà. Àní bẹ́ẹ bá rí àwọn ohun èlò tó wà níbẹ̀ táa fi ń gbé ẹ̀kọ́ Bíbélì lárugẹ, ẹdugbẹ ni! Wọ́n gbé àwọn ìsọfúnni kan síbẹ̀, àwọn olùbẹ̀wò sì lè wo àwọn fídíò ráńpẹ́, tó ṣàlàyé báa ṣe ń gba ohùn sílẹ̀ sórí kásẹ́ẹ̀tì àti báa ṣe ń ṣe fídíò. Wọ́n là wọ́n lóye nípa iṣẹ́ ribiribi táa ń ṣe nígbà táa bá ń ṣètò àwọn tí a ó ya àwòrán wọn, kí a tó gbé e jáde nínú ìwé. Wọ́n rí báa ti ń to àwọn ohun èlò orí ìtàgé pọ̀ láìsí ìnáwó rẹpẹtẹ, síbẹ̀ láìgbójúfo ohun tó kéré jù lọ dá. Wọ́n rí báa ti ń lo orin láti fi mú káwọn èèyàn nímọ̀lára pé àwọn alára wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ń wò. Láti 1990, Society ti ṣe fídíò mẹ́wàá jáde lédè mọ́kànlélógójì, tó ní onírúurú ẹṣin ọ̀rọ̀ látinú Bíbélì, yàtọ̀ sáwọn fídíò tó wà fáwọn tí ń sọ Èdè Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó rìn káàkiri ló dé Ibi Táa Ti Ń Fọ Fọ́tò, Ẹ̀ka Ìyàwòrán, Ẹ̀ka Tí Ń Pèsè Ìsọfúnni, èyí tó ń pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí lílo ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà àti títún un ṣe, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, tó ń mójú tó ìgbòkègbodò ìjọ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá ó lé igba àti méjìlélógójì [11,242] àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé méjìléláàádọ́rin [572] àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àti Ẹ̀ka Tí Ń Fèsì Lẹ́tà, níbi tí wọ́n ti ń dáhùn nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá ìbéèrè lọ́dọọdún. Inú wọ́n dùn gan-an sí ìwádìí jinlẹ̀ táa ń ṣe ká tó kọ lẹ́tà jáde, àti ìfẹ́ àtọkànwá táa ń fi hàn sáwọn tí ìbéèrè wọ́n fi hàn pé òkè ìṣòro tí wọ́n dojú kọ ń gbò wọ́n gan-an.
Ńṣe lèrò kàn ń wọ́ tìtì-rẹrẹ ní Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ìtumọ̀. Ó yà wọ́n lẹ́nu láti gbọ́ pé láàárín ọdún márùn-ún tó kọjá, èdè méjìlélọ́gọ́rùn-ún la fi kún iye èdè tí Society ti ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde. Kárí ayé, nǹkan bí ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ka àwọn ìtẹ̀jáde Society lédè míì, yàtọ̀ sí Gẹ̀ẹ́sì. Láti kájú àìní wọn, a ní ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ìtumọ̀ ní ọgọ́rùn-ún orílẹ̀-èdè. A rí àwòrán Ilé Ìṣọ́ ní àwọn èdè Amẹ́ríkà, Yúróòpù, Éṣíà, àti Áfíríkà. Àwọn olùbẹ̀wò rí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní èdè mọ́kànlélọ́gbọ̀n táa ti tẹ̀ ẹ́ jáde báyìí. A sọ fún wọn pé àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower ń jáde nísinsìnyí ní ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìlélọ́gbọ̀n èdè àti pé a ti tẹ ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ní igba ó lé mọ́kàndínlógún èdè lára ìwọ̀nyí.
Àwọn tó ṣèbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin rí ọ̀kan-kò-jọ̀kan ìgbòkègbodò tó la iṣẹ́ òfin lọ kárí ayé. Nínú fídíò kan, wọ́n rí ìgbẹ́jọ́ tí ń lọ lọ́wọ́ ní ilé ẹjọ́ níbi tí agbẹjọ́rò Ẹlẹ́rìí ti ń ro ẹjọ́ nípa ọ̀ràn ìfàjẹ̀sínilára. A tún sọ fún wọn nípa ohun táa ń ṣe láti rí sí i pé ọ̀nà iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ní gbangba kò dí. (Fílípì 1:7) A pe àfiyèsí sí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ ìjọba àpapọ̀ ṣe lóṣù March ọdún yìí, tó pàṣẹ fún Àdúgbò Oradell, nílùú New Jersey, ni Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, pé kí wọ́n fagi lé òfin tó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ́dọ̀ gbàṣẹ àti pé kí wọ́n máa lo káàdì ìdánimọ̀ bí wọ́n bá fẹ́ wàásù láti ilé dé ilé ládùúgbò yẹn.
Táa bá ní ká máa sọ gbogbo ohun táwọn olùbẹ̀wò rí, ẹnu á kọ̀ròyìn o. Wọn wo àwọn àwòrán táa fi hàn nípa Iléeṣẹ́ Tí Ń Mọ Ògiri Àgbélẹ̀mọ, wọ́n sì fojú kan Ẹ̀ka Iṣẹ́ Tí Ń Sọ Omi Ẹ̀gbin Di Omi Tó Dáa, Ilé Ẹ̀rọ Mànàmáná, Ẹ̀ka Tí Ń Pèsè Omi Tó Ṣeé Mu, àti ọ̀pọ̀ ibòmíràn táa ti ń ṣe àbójútó àwọn nǹkan èlò. Irú àǹfààní yẹn ṣọ̀wọ́n.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìyàsímímọ́ Dá Lé Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá
Ọjọ́ Wednesday, May 19, láago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́, la bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìyàsímímọ́ ní pẹrẹu. Àwọn ogunlọ́gọ̀ aláyọ̀ tí iye wọ́n jẹ́ 6,929, tó jẹ́ àpapọ̀ àwọn mẹ́ńbà òṣìṣẹ́ lórílé iṣẹ́, àwọn àlejò Society, àti ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìléláàádọ́rin tó pé jọ ní ẹ̀ka Kánádà, níbi tí wọ́n ti ń gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nípasẹ̀ ẹ̀rọ alátagbà.
Inú àwùjọ náà dùn gan-an láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwúrí tí Milton G. Henschel, ààrẹ Watch Tower Society, fi kí wọn káàbọ̀. Theodore Jaracz, mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso àti alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, wá ké sí William Malenfant tẹ̀ lé e. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “Àwọn Kókó Pàtàkì Nípa Ètò Ìkọ́lé Náà,” ó fọ̀rọ̀ wá àwọn arákùnrin mẹ́ta lẹ́nu wò, àwọn wọ̀nyí ṣe gudugudu méje nínú iṣẹ́ ìfilọ́lẹ̀, ìwéwèé, àti kíkọ́ Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower. Wọ́n sọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà pé láwọn ọdún tí wọ́n fi kọ́lé gan-an, ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin lé lẹ́gbàárin [8,700] àwọn òṣìṣẹ́ onígbà ráńpẹ́ tí wọ́n náwó nára kí wọ́n lè wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tó mú kí ìṣọ̀kan àti ìwà ọ̀làwọ́ yìí ṣeé ṣe!
Àpínsọ ọ̀rọ̀ ló tẹ̀ lé e, àkòrí rẹ̀ sì ni “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá Kárí Ayé.” Àwọn mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso mẹ́rin ló sọ ọ́. John E. Barr tẹnu mọ́ ọn pé ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ń rọ àwọn Kristẹni láti máa “bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo, tí ẹ sì ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” (Kólósè 1:10) Daniel Sydlik jíròrò bí a ṣe ṣètò ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run, láti orí ìjọ Kristẹni, Jésù Kristi, títí kan olúkúlùkù mẹ́ńbà ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé. (1 Kọ́ríńtì 12:12-27) Apá méjì yòókù lára àpínsọ ọ̀rọ̀ náà, tí Gerrit Lösch àti Carey Barber sọ, fi hàn bí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ti ń mú kí àwọn òjíṣẹ́ tóótun láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn níbi gbogbo, kí wọ́n sì máa fún wọn ní ìtọ́ni kí àwọn náà lè máa rìn ní ọ̀nà Ọlọ́run.—Aísáyà 2:1-4; 2 Kọ́ríńtì 3:5.
Kí àwùjọ lè mọ̀ nípa onírúurú ilé ẹ̀kọ́ tó wà ní ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí, a jíròrò pẹ̀lú àwọn olùkọ́ àtàwọn mí-ìn tó mọ̀ nípa ìgbòkègbodò ilé ẹ̀kọ́ wọnnì, a sì fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. A jẹ́ káwọn èèyàn rí ipa tí ilé ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ń kó nínú mímú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kẹ́sẹ járí kárí ayé. A tọ́ka sí i pé Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead dá lé kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì, àti ìtàn òde òní àwọn èèyàn Jèhófà, àti gbígbáradì fún iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Ilé ẹ̀kọ́ nípa ìṣètò ẹ̀ka jẹ́ ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ tó gbòòrò nípa onírúurú ẹrù iṣẹ́ tó wà lọ́rùn àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. A ṣètò Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò láti bójú tó àìní àwọn arákùnrin arìnrìn-àjò, ṣùgbọ́n ní àfikún sí i, ilé ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti pèsè irú ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí yóò wúlò gan-an fún ìjọ.
Láti mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà wá sópin, Lloyd Barry tí í ṣe ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ àsọyé ìyàsímímọ́ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Dídarapọ̀ Mọ́ Ẹlẹ́dàá Wa Atóbilọ́lá Láti Kọ́lé.” Ó sọ pé Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa, ní inú dídùn sí gbogbo ìṣẹ̀dá rẹ̀, ó sì ní kí a jẹ́ kí inú wa máa dùn bíi tòun. (Aísáyà 65:18) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run,” Jèhófà Ọlọ́run ló ni ògo tó ga jù lọ fún gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé yìí. (Hébérù 3:4) Lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ sọ èyí tán, ló wá gba àdúrà àtọkànwá, tó fi ya Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower sí mímọ́ fún Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá.a
Kò sí àní-àní pé àwọn tó wà níbi àjọyọ̀ gbogbo ọ̀sẹ̀ náà kò ní gbàgbé ohun tó ṣẹlẹ̀. O ò ṣe wá àyè wá ṣèbẹ̀wò sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower? Ó dá wa lójú pé ṣíṣèbẹ̀wò àti rírìn káàkiri ibùdó yìí yóò jẹ́ ìṣírí fún ẹ bí o ti ń sapá láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, tí o sì ń sapá láti máa gbé ìgbé-ayé tó bá ìlànà òdodo rẹ̀ mu.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Arákùnrin Barry jẹ́ olóòótọ́ títí tó fi parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ní July 2, 1999. Wo Ilé Ìṣọ́, October 1, 1999, ojú ìwé kẹrìndínlógún.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Gbọ̀ngàn àpéjọ kún dẹ́múdẹ́mú, gbọ̀ngàn ìjẹun pàápàá ò gbèrò
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Rírìn yí ká gbogbo ilé náà jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó kún fáyọ̀