Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower Ń rán Àwọn Míṣọ́nnárì Jáde
ILÉ ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ti darí kíláàsì púpọ̀ ní ibi púpọ̀. Láàárín 1943 sí 1960, ní ilé lílò ní South Lansing, New York, U.S.A., kíláàsì 35, tí ó ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ilẹ̀ 95 nínú, gba àkànṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, ilé ẹ̀kọ́ náà ṣí lọ sí orílé-iṣẹ́ àgbáyé ní Brooklyn, New York, níbi tí ó wà fún nǹkan bíi ọdún 28. Láti 1988 títí di ìbẹ̀rẹ̀ 1995, Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead darí kíláàsì ní Wallkill, New York.
Láàárín àwọn ọdún wọ̀nyí, ilé ẹ̀kọ́ náà mú ìlà iṣẹ́ rẹ̀ gbòòrò sí i. Lábẹ́ ìdarí rẹ̀, a pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́wàá fún kíláàsì mẹ́ta ní Mexico; a ṣe irú kíláàsì bẹ́ẹ̀ márùn-ún ní Germany; méjì ní India. Láti 1987, ilé ẹ̀kọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí a mọ̀ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, ti darí kíláàsì ní ilẹ̀ 34, ní pípèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́jọ fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n tóótun. Ṣùgbọ́n, ìtọ́ni tí a fún kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́rùn-ún ti Gilead, ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ní Patterson, New York, jẹ́ ìdálẹ́kọ̀ọ́ 20 ọ̀sẹ̀, ọ̀kan tí ó ní ìkẹ́kọ̀ọ́ odindi Bibeli jinlẹ̀jinlẹ̀, ìjíròrò ìtàn òde òní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa àti ètò àjọ wọn, àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìmọ̀ràn lórí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ àjèjì nínú.
Ní September 2, kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́rùn-ún yẹn kẹ́kọ̀ọ́ yege. A ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege oníwákàtí mẹ́ta náà ní gbọ̀ngàn ńlá tuntun ti Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower. Ó kún fọ́fọ́. Nípasẹ̀ ẹ̀rọ abánáṣiṣẹ́, a so àfikún àwùjọ tí ń bẹ ní ilé lílò Beteli ní Patterson, Wallkill, àti Brooklyn pọ̀ mọ́ ọn. Kì í ṣe kíláàsì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àti àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn wọn nìkan ni ọjọ́ yìí jẹ́ arùmọ̀lárasókè fún, ṣùgbọ́n fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tí wọ́n ti nípìn-ín nínú kíkọ́ ilé lílò tuntun ti ilé ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú.
Nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀, Carey Barber ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso darí àfiyèsí sórí ìjẹ́pàtàkì ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Ó wí pé: “Èyí ni yóò jẹ́ ibi ìkóríjọ ìgbòkègbodò ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kíkàmàmà jù lọ tí a tí ì ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé.” Ó ṣàlàyé pé, a ń sún mọ́ òtéńté ogun náà, láàárín irú ọmọ obìnrin náà, àti irú ọmọ ejò náà. (Genesisi 3:15) Ó fi hàn pé, kìkì àwọn tí yóò la ìkòlójú adániníjì nígbà ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀ já, yóò jẹ́ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i.
Ó polongo pé: “A wéwèé ètò ẹ̀kọ́ wa tí ń lọ lọ́wọ́, láti mú gbogbo ènìyàn Jehofa níbi gbogbo wá sí ipò pípinminrin ti ìdàgbàdénú tí a ṣàpèjúwe ní Owe 1:1-4—ti mímọ ọgbọ́n àti ìbáwí, jíjẹ́ ẹni tí ó lè mòye, gbígba ìbáwí tí ń fúnni ní òye inú, òdodo, ìfòyemọ̀, ìwà ìdúróṣinṣin, àti agbára ìrònú.” Ẹ wo irú ààbò tí ó jẹ́ láti ní irú ìtìlẹ́yìn tẹ̀mí bẹ́ẹ̀!
Ìmọ̀ràn fún Kíláàsì Tí Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Yege
Ọ̀wọ́ ìjíròrò ṣókí márùn-ún tí a darí wọn sí kíláàsì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà, tẹ̀ lé àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. Harold Jackson, olùkọ́ Gilead tẹ́lẹ̀, tí ó sì jẹ́ mẹ́ḿbà òṣìṣẹ́ orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn nísinsìyí, rọ kíláàsì náà pé, “Ẹ Rọ̀ Tímọ́tímọ́ Mọ́ Ìtẹ́lọ́rùn Oníwà-bí-Ọlọ́run Yín.” Lloyd Barry, míṣọ́nnárì ọlọ́jọ́ pípẹ́, tí ó sì jẹ́ mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso nísinsìnyí, sọ̀rọ̀ lórí “Ṣíṣiṣẹ́ Sin Jehofa Pẹ̀lú Ìrẹ̀lẹ̀.” Ó ṣàlàyé pé, ànímọ́ yìí ṣe pàtàkì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà nígbà tí wọ́n bá ń mú ara wọn bá ipò wọn tuntun mu, àti nínú àjọṣepọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wọn, pẹ̀lú àwọn ìjọ tí wọn yóò ti ṣiṣẹ́ sìn, àti pẹ̀lú àwọn ará àdúgbò.
Karl Adams, tí ń ṣiṣẹ́ sìn lọ́wọ́lọ́wọ́ ní ẹ̀ka Gilead, bá àwọn kíláàsì náà sọ̀rọ̀ lórí ìbéèrè náà, “Kí Ni Ìgbàgbọ́ Yóò Sún Ọ Ṣe?” Ó fún wọn níṣìírí láti má ṣe dà bí àwọn ọmọ Israeli, tí wọ́n ráhùn nípa bí nǹkan ti rí nínú aginjù, tí wọ́n sì fẹ́ láti padà sí Egipti, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n dà bí Abrahamu, tí ó wo Ìjọba Ọlọrun dípò pípadà sí Uri ti Kaldea, gẹ́gẹ́ bí ojútùú sí ìṣòro. (Eksodu 16:2, 3; Heberu 11:10, 15, 16) Ulysses Glass, akọ̀wé ilé ẹ̀kọ́ náà, gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀, “Sọ Àwọn Ìbùkún Rẹ,” karí ìrírí Asafu, bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ ní Orin Dafidi 73, láti gba kíláàsì tí ń kẹ́kọ̀ọ́ yege náà níyànjú. Albert Schroeder, mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Jehofa Ń Pèsè.” Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí irú ìpèsè bẹ́ẹ̀, ó tọ́ka sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead fúnra rẹ̀, àti ipa tí ó ń kó nínú ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ bàǹtà-banta ti wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.
Lẹ́yìn náà, àwùjọ náà tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ nígbà tí Milton Henschel, ààrẹ Watch Tower Society, sọ̀rọ̀ nípa “Àwọn Ẹ̀yà Ara Tí Wọ́n Jẹ́ Ti Ara Wọn Lẹ́nì Kíní-Kejì.” Ó ka Romu orí 12, ó sì sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ jinlẹ̀jinlẹ̀. Lára àwọn ohun mìíràn tí ó sọ ni pé: “A ní láti ronú lórí rẹ̀ pé, a ní ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa nínú ìjọ.” Ó fi kún un pé: “Ó dára nígbà gbogbo, kí a máa ronú nípa ẹnì kíní kejì wa pé dúkìá Jehofa ni wá, kàkà tí a óò sì fi máa ṣe lámèyítọ́, kàkà tí a óò fi máa wẹ́sùn síni lẹ́sẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa ranni lọ́wọ́ nígbà gbogbo. Ara wa ni a ń ràn lọ́wọ́ nígbà tí a bá ń di ìṣọ̀kan tẹ̀mí ti ìjọ Kristian mú.” Ó fi hàn bí a ṣe lè fi irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ hàn nínú gbígbọ́ oúnjẹ nínú ilé àwọn míṣọ́nnárì, kíkíyè sí òtítọ́ náà pé, gbogbo ènìyàn kò lè jẹ ohun kan náà. Ó tún tẹnu mọ́ ìrànlọ́wọ́ dípò ṣíṣe lámèyítọ́, nígbà tí wọ́n bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wọn tí kò rí já jẹ. Ní tòótọ́, bí a bá ń ranni lọ́wọ́, tí a ń gbéni ró, tí a sì ń fún ara wa lẹ́nì kíní-kejì níṣìírí, Arákùnrin Henschel ṣàlàyé pé, “Jehofa yóò nífẹ̀ẹ́ wa nítorí èyí.” Ẹ wo irú ìṣílétí gbígbámúṣe tí èyí jẹ́ fún àwọn míṣọ́nnárì tí wọn yóò máa ṣiṣẹ́ sìn ní àwọn ilẹ̀ tí ó yàtọ̀ pátápátá sí tiwọn, tí wọ́n yóò fi sílẹ̀ lọ!
Títúbọ̀ Di Ojúlùmọ̀ Kíláàsì Náà Sí I
Ní ìpíndọ́gba, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 48 ti kíláàsì kọkàndínlọ́gọ́rùn-ún, jẹ́ ẹni ọdún 32, wọ́n sì ti lo ohun tí ó lé ní ọdún 11 nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.
Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí ó jẹ́ apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà fún àwùjọ náà láǹfààní láti túbọ̀ di ojúlùmọ̀ díẹ̀ lára wọn sí i. Nikki Liebl, láti United States, àti Simon Bolton, láti England, sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ti dán ìgbàgbọ́ wọn wò, pé Jehofa yóò pèsè fún àìní wọn nípa ti ara. Wọ́n nírìírí àbójútó Jehofa, bí wọ́n ṣe fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sí ipò kíní.
Isabelle Kazan, tí èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ Faransé, wí pé, òún ti kọ́ èdè Lárúbáwá láti lè jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè Lárúbáwá ní orílẹ̀-èdè òun. Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1987, àwùjọ kékeré tí ó wà ní Paris ní arákùnrin mẹ́rin péré tí ń sọ èdè Lárúbáwá, ní àfikún sí òun alára àti arábìnrin mìíràn tí ń kọ́ èdè náà. (Kò rọrùn. Wọn yóò lo wákàtí mẹ́jọ láti múra ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà wọn sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti baà lè lóhùn sí i.) Ìsapá náà ha yẹ fún un bí? Tóò, àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń sọ èdè Lárúbáwá wà lónìí, tí a ṣètò sí àyíká márùn-ún jákèjádò Faransé. Akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn, Miko Puro, sọ bí èdè Faransé tí ó ti kọ́ ni ilé ẹ̀kọ́ ṣe ràn án lọ́wọ́ láti lè wàásù fún àwọn olùwá ibi ìsádi, tí wọ́n jẹ́ ará Africa, ní ìlú rẹ̀, Finland, yóò sì tún wúlò fún un nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a yàn fún un ní Benin. Bonny Bowes ṣàlàyé ìjàkadì rẹ̀ láti lè sọ èdè Faransè lọ́nà tí ó já geere, kí ó baà lè ṣiṣẹ́ sìn lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ ní Quebec, Canada. Bjarki Rasmussen pẹ̀lú, láti Denmark, sọ àwọn ìrírí tí òun àti aya rẹ̀ ní, ní àwọn ọdún iṣẹ́ ìsìn ní àwọn Erékùṣù Faeroe. Kò sí àníàní, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún onírìírí ni àwọn míṣọ́nnárì tuntun wọ̀nyí.
A rán àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà lọ sí ilẹ̀ 19—ní Africa, Central àti South America, Eastern Europe, àti Ìlà Oòrùn Ayé. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ní àwọn kíláàsì ìṣáájú ti ṣiṣẹ́ sìn ní ilẹ̀ tí ó lé ní 200. Ọwọ́ púpọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà ṣì dí níbi iṣẹ́ àyànfúnni wọn. Àwọn míṣọ́nnárì tuntun wọ̀nyí ń dara pọ̀ mọ́ wọn nínú mímú ẹ̀rí Ìjọba náà gbòòrò sí i títí dé òpin ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 1:8.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ìran kíláàsì ní Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Watchtower
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Kíláàsì Kọkàndínlọ́gọ́rùn-ún ti Watchtower Bible School of Gilead
Nínú àkọsílẹ̀ tí ó wà nísàlẹ̀, a fi nọ́ḿbà sí àwọn ìlà láti iwájú lọ sí ẹ̀yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún ní ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Heffey, S.; Riley, E.; Mortensen, D.; Honable, A.; Bolton, J.; Poole, J.; Siimes, G.; Sousa, L. (2) Pashnitski, B.; Shepherd, D.; Pashnitski, W.; Järvinen, J.; Paulsen, K.; Rasmussen, E.; Schewe, C.; Olsson, L. (3) Paulsen, E.; Samsel, T.; Bowes, B.; Harris, E.; Kazan, I.; Liebl, N.; Sousa, P.; Puro, J. (4) Lager, K.; Lager, V.; Golden, K.; Bolton, S.; Johnson, M.; Johnson, S.; Liebl, A.; Rasmussen, B. (5) Harris, D.; Samsel, W.; Schewe, O.; Heffey, R.; Kazan, L; Riley, T.; Järvinen, O.; Puro, M. (6) Mortensen, D.; Golden, R.; Honable, L.; Shepherd, M.; Bowes, R.; Siimes, T.; Poole, E.; Olsson, J.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Wọ́n ṣì wà níbi iṣẹ́ àyànfúnni wọn: (apá òsì) Charles Leathco pẹ̀lú aya rẹ̀, Fern, ní Brazil, àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ní kíláàsì àkọ́kọ́ àti ìkẹfà ti Gilead; (nísàlẹ̀) Martha Hess, ní Japan, akẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì keje ti Gilead