Jèhófà Ń Kọ́ Wa
1 Lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kárí ayé ń lọ lọ́wọ́ ní ilẹ̀ igba ó lé mẹ́tàlélọ́gbọ̀n. Kò sóhun táyé yìí lè fi fúnni táa lè fi wé e. Atóbilọ́lá Olùfúnni-nítọ̀ọ́ni wa, Jèhófà, ń kọ́ wa bí a ṣe lè ṣe ara wa láǹfààní nísinsìnyí ní àfikún sí bó ṣe ń kọ́ wa fún ìyè ayérayé.—Aísá. 30:20; 48:17.
2 Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Tí Ọlọ́run Ti Ń Kọ́ni: Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí ń lọ lọ́wọ́ fún àǹfààní àwọn èèyàn Jèhófà. Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, táa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàdínláàdọ́rùn-ún [87,000] ìjọ, ń dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn akéde Ìjọba náà lẹ́kọ̀ọ́ láti jẹ́ ògbóṣáṣá òjíṣẹ́ ìhìn rere náà. Ṣé o ti forúkọ sílẹ̀ níbẹ̀? Ṣé o wà lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà tí wọ́n máa ń fi ọ̀sẹ̀ méjì ṣe? Bóyá dídín tí a dín wákàtí tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé kù yóò jẹ́ kí àwọn púpọ̀ sí i lè ṣe aṣáájú ọ̀nà kí wọ́n sì tóótun láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí. Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tí wọ́n máa ń fi oṣù méjì ṣe, tí a ń fi àwọn èdè pàtàkì ṣe kárí ayé báyìí, ń mú àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí kò tí ì ṣègbéyàwó gbára dì láti tẹ́wọ́ gba àwọn ẹrù iṣẹ́ tó túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Láti ìgbà dé ìgbà, gbogbo alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń gba ìtọ́ni pàtó ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba.
3 A ń lo ilé Watchtower Educational Center ní Patterson, New York, fún àwọn ilé ẹ̀kọ́ àkànṣe, tí ń pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ gíga ti ìṣàkóso Ọlọ́run. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù márùn-ún ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ń mú àwọn òjíṣẹ́ gbára dì fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní àwọn ilẹ̀ àjèjì. Àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka kárí ayé máa ń lọ fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù méjì láti kọ́ nípa ìṣètò ẹ̀ka. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló ń jàǹfààní dáadáa láti inú ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ń pèsè nípasẹ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ wọ̀nyí.
4 Kí Ni Ète Tí A Ṣe Ń Kọ́ Wa? Mẹ́ńbà kan nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ pé: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa tí ń lọ lọ́wọ́ la ṣe láti mú kí gbogbo àwọn ènìyàn Jèhófà níbi gbogbo dé ipò ìdàgbàdénú dáadáa tá ṣàpèjúwe ní Òwe 1:1-4.” Kí Jèhófà máa bá a nìṣó láti fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní “ahọ́n àwọn tí a kọ́.”—Aísá. 50:4.