ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 160-ojú ìwé 161 ìpínrọ̀ 1
  • Jehofa Mu Ki Opo Eeyan Wa Kekoo

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Mu Ki Opo Eeyan Wa Kekoo
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jagunjagun Ti Ko Gba Pe Olorun Wa Di Iranse Olorun
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Aláàbọ̀ Ara Ni Síbẹ̀ Ó Fẹ́ Láti Ṣiṣẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Mo Rí “Ẹni Kékeré Kan” Tí Ó Di “Alágbára Orílẹ̀-èdè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 160-ojú ìwé 161 ìpínrọ̀ 1

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Jèhófà Mú Kí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Wá Kẹ́kọ̀ọ́

Leonardo Amor

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1943

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1961

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Ó sì ti lé ní àádọ́ta [50] ọdún báyìí tó ti ń sin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 160

MÒ Ń kẹ́kọ̀ọ́ òfin lọ́wọ́ ní yunifásítì nígbà tí wọ́n pa Trujillo lọ́dún 1961. Nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn náà ni mo ṣèrìbọmi. Iṣẹ́ amòfin ni bàbá mi fẹ́ kí n ṣe, àmọ́ mo rí i pé ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. Torí náà, láìka bí bàbá mi ṣe ń fúngun mọ́ mi sí, mo fi yunifásítì sílẹ̀. Kò sì pẹ́ rárá lẹ́yìn náà tí wọ́n fi ní kí n máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Ìlú La Vega wà lára àwọn ìlú tí wọ́n gbé mi lọ. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ti gbilẹ̀ níbẹ̀. Ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà níbẹ̀, kò sẹ́ni tó wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Tí mo bá ń sọ àsọyé, ẹni tá a jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà nìkan ló máa ń wà níbẹ̀ láti tẹ́tí gbọ́ mi. Síbẹ̀, Jèhófà fún mi lókun nípasẹ̀ àwọn àpéjọ tí mo máa ń lọ, àdúrà kíkankíkan àti bí mo ṣe máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tí mo bá ń gbàdúrà, mo máa ń bi Jèhófà bóyá ìjọ ṣì máa wà nílùú La Vega. Inú mi dùn láti sọ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti wà nílùú náà báyìí. Ìjọ ti di mẹ́rìnlá [14] níbẹ̀, iye akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà níbẹ̀ sì ti lé ní ẹgbẹ̀rin [800].

Ọdún 1965 ni mo fẹ́ Ángela, wọ́n sì pè wá sí Bẹ́tẹ́lì lọ́dún 1981. Nígbà tí mo ṣèrìbọmi, ẹgbẹ̀ta àti mọ́kànlélọ́gọ́rin [681] ni iye akéde tó wà ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Àmọ́ ní báyìí, iye akéde ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì [36,000], ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló sì máa ń kóra jọ láwọn àpéjọ wa. Tí n bá ronú pa dà sẹ́yìn, ó máa ń yà mí lẹ́nu láti rí bí Jèhófà ṣe mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 161

Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Reiner Thompson, Juan Crispín, Thomas Dean, Leonel Peguero, Leonardo Amor àti Richard Stoddard

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́