Aláàbọ̀ Ara Ni Síbẹ̀ Ó Fẹ́ Láti Ṣiṣẹ́ Ọlọ́run
TÉÈYÀN bá kọ́kọ́ rí Leonardo, kò jọ irú ẹni tó lè ṣiṣẹ́ ìkọ́lé. Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé ó ti pàdánù ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì nígbà tí jàǹbá kan ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ nígbà kan sẹ́yìn. Àmọ́, pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ aláàbọ̀ ara yẹn, ó fi ìtara ṣiṣẹ́ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé kan nílùú Acajutla, lórílẹ̀-èdè El Salvador. Àwòrán ibi tó ti ń bá wọn ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà ló wà lójú ewé yìí.
Ó ní kí wọ́n bá òun ṣe ohun èlò ìṣiṣẹ́ tó máa jẹ́ kóun lè kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Wọ́n wá bá a jó irin oníhò mọ́ ìdí ṣọ́bìrì. Á wá ki apá rẹ̀ ọ̀tún sáàárín irin oníhò tí wọ́n jó mọ́ ìdí ṣọ́bìrì yìí, á sì fọgbọ́n fi ṣọ́bìrì náà kó ilẹ̀ sínú bárò kan. Torí pé kò ní ọwọ́ tó máa fi di bárò náà mú, wọ́n bá a ṣe irin oníhò mọ́ ọwọ́ bárò náà kó lè máa ki apá rẹ̀ bọ̀ ọ́ láti fi tì í. Ṣùgbọ́n, kí ló sún un láti kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́lé náà?
Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn Leonardo pé kó wà lára àwọn tó máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ìyẹn orúkọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pe ibi tá a ti máa ń ṣe ìjọsìn. Ọ̀pọ̀ ìdí wà tó fi lè sọ pé òun ò ní lè ṣe nínú iṣẹ́ náà. Lára ẹ̀ ni pé, ó ní iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ń ṣe látàárọ̀ ṣúlẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì ti gé, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tún ni nínú ìjọ wọn. Àmọ́, ó fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe níbi iṣẹ́ ìkọ́lé náà láti ṣiṣẹ́ fún Ọlọ́run.
Ǹjẹ́ o ní irú ẹ̀mí tí arákùnrin yìí ní láti ṣiṣẹ́ Ọlọ́run? Kò fi jíjẹ́ tó jẹ́ aláàbọ̀ ara kẹ́wọ́, dípò ìyẹn, ńṣe ló ronú ọ̀nà tí wọ́n lè gbà bá a ṣe ohun èlò ìṣiṣẹ́ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ kó bàa lè ṣeé ṣe fún un láti ṣiṣẹ́ tí kì bá má lè ṣe. ‘Gbogbo èrò inú rẹ̀’ ló fi ń sin Ọlọ́run. (Mátíù 22:37) Kò sí àní-àní pé ńṣe làwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé yọ̀ǹda ara wọn tọkàntọkàn, yálà wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara tàbí wọn kì í ṣe aláàbọ̀ ara. Ẹnikẹ́ni ló lè wá síbi ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí. Torí náà, máa bọ̀.