Mo Rí “Ẹni Kékeré Kan” Tí Ó Di “Alágbára Orílẹ̀-èdè”
GẸ́GẸ́ BÍ WILLIAM DINGMAN ṢE SỌ Ọ́
Ọdún 1936 ni; ní Salem, Oregon, U.S.A. Mo lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n béèrè ìbéèrè náà pé: “Ògìdìgbó ńláǹlà náà dà?” (Ìṣípayá 7:9, King James Version) Èmi nìkan ṣoṣo ni ẹni tuntun, nítorí náà, gbogbo wọ́n nawọ́ sí mi, wọ́n sì sọ pé, “Òun nìyẹn!”
NÍ ÀÁRÍN àwọn ọdún 1930, ìwọ̀nba kéréje láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó ní ìrètí inú Bíbélì ti gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé nínú Párádísè. (Orin Dáfídì 37:29; Lúùkù 23:43) Àwọn nǹkan ti yí pa dà gidigidi láti ìgbà náà. Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ kí n sọ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣamọ̀nà sí wíwà tí mo wà ní ìpàdé yẹn ní Salem, Oregon.
Bàbá mi máa ń san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn The Golden Age, orúkọ tí a ń pe ìwé ìròyìn Jí! nígbà náà. Nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́langba, mo máa ń gbádùn kíkà á, ó sì wá dá mi lójú pé òtítọ́ pàtàkì inú Bíbélì ni ó wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, ní ọjọ́ kan, mo gé ìwé ìpolówó tí ó fara hàn ní ẹ̀yìn ìwé ìròyìn Golden Age ránṣẹ́. Ó fi 20 ìwé kékeré, ìwé ńlá kan, àti orúkọ ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà nítòsí lọ ẹni tí ó bá kà á. Gbàrà tí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà tẹ̀ mí lọ́wọ́, mo lọ láti ilé dé ilé, mo sì fi gbogbo ìwé kékeré náà àti ìwé ńlá náà síta pátá.
Ẹnikẹ́ni kò tí ì bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà náà. Àní, n kò tí ì bá ọ̀kan nínú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ rí pàápàá. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, pẹ̀lú àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó sún mọ́ mi jù lọ lọ́wọ́ mi, mo wa ọkọ̀ lọ sí Salem, Oregon, nǹkan bí 40 kìlómítà, láti lọ sí ìpàdé. Níbẹ̀ ni a ti pè mí ní “ògìdìgbó ńláǹlà,” nígbà tí mo ṣì jẹ́ ẹni ọdún 18.
Bí n kò tilẹ̀ múra sílẹ̀ rárá fún iṣẹ́ òjíṣẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pẹ̀lú Ìjọ Salem. A fún mi níṣìírí láti fi kókó pàtàkì mẹ́ta kan kún ìjẹ́rìí mi. Àkọ́kọ́, pé Jèhófà ni Ọlọ́run; èkejì, pé Jésù Kristi ni Ọba rẹ̀ tí ó ti yàn; àti ẹ̀kẹta, pé Ìjọba náà nìkan ṣoṣo ni ìrètí fún aráyé. Mo gbìyànjú láti ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ yẹn ní gbogbo ẹnu ọ̀nà.
Lẹ́yìn dídarapọ̀ mọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Salem fún ọdún méjì, mo ṣe ìrìbọmi ní April 3, 1938. Inú àwọn ará ní Salem dùn láti rí àwa mélòó kan lára “ògìdìgbó ńláǹlà” náà tí ń ṣèrìbọmi. Ní February 1939, mo di aṣáájú ọ̀nà, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ní December ọdún yẹn, mo tẹ́wọ́ gba ìkésíni láti ṣí lọ sí Arizona, níbi tí a ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba.
Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà ní Arizona
Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ tuntun ní Arizona, ọ̀pọ̀ àṣìlóye sì wà nípa wa, nítorí náà, nígbà tí United States wọnú Ogun Àgbáyé Kejì, a ṣe inúnibíni sí wa gidigidi. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí mo ń sìn ní Stafford, Arizona, ní 1942, ẹgbẹ́ ìsìn Mormon ń sọ̀rọ̀ nípa kíkọlù wá. Ó ṣẹlẹ̀ pé èmi àti àwọn aṣáájú ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ mi ń gbé nítòsí bíṣọ́ọ̀bù Mormon kan, tí ó bọ̀wọ̀ fún wa, tí ó sì wí pé: “Bí àwọn míṣọ́nnárì Mormon bá jẹ́ aláápọn bí Àwọn Ẹlẹ́rìí ni, Ṣọ́ọ̀ṣì Mormon ì bá ti bí sí i.” Nítorí náà, ó ṣe kìlọ̀kìlọ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì, ó sì sọ pé: “Mo gbọ́ pé ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa àtikọlu àwọn ọmọkùnrin Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn. Toò, itòsí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyẹn ni mò ń gbé, bí ẹ bá kọlù wọ́n, ìbọn olójú méjì yóò dún lẹ́yìn ọgbà. N óò yin ìbọn olójú méjì yẹn—ṣùgbọ́n kò ní jẹ́ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí náà. Àwọn akọluni ni n óò yìn ín sí. Nítorí náà, bí ẹ bá ń ronú àtikọlù wọ́n, ẹ mọ ohun tí ń dúró dè yín.” Àwọn akọluni náà kò yọjú.
Láàárín ọdún mẹ́ta tí mo lò ní Arizona, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a fàṣẹ ọba mú wa, tí a sì jù wá sẹ́wọ̀n. Ìgbà kan wà tí a fi mí sẹ́wọ̀n fún 30 ọjọ́. Láti ṣẹ́pá fífòòró tí àwọn ọlọ́pàá ń fòòró wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, a bẹ̀rẹ̀ ohun tí a pè ní ẹgbẹ́ ayára-bí-àṣá. Ẹlẹ́rìí tí ó mú ipò iwájú nínú rẹ̀ sọ fún wa pé: “Ohun tí a ń pe ara wa gan-an náà ni a jẹ́. A óò bẹ̀rẹ̀ ní aago márùn-ún tàbí mẹ́fà òwúrọ̀, a óò fi ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé kékeré sí ẹnu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, a óò sì yára kúrò níbẹ̀.” “Ẹgbẹ́ ayára-bí-àṣà” wa kárí ọ̀pọ̀ ibi ní ìpínlẹ̀ Arizona. Ṣùgbọ́n, a tú u ká lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn nítorí irú ọ̀nà ìwàásù yẹn kò yọ̀ǹda fún wa láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tí ó fìfẹ́ hàn.
Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead àti Iṣẹ́ Ìsìn Àkànṣe
Ní December 1942, mo wà lára àwọn aṣáájú ọ̀nà mélòó kan ní Arizona tí ó gba lẹ́tà ìkésíni láti wá sí ilé ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì tuntun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá sílẹ̀. Ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible College of Gilead ni a sọ ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà, a yí orúkọ náà pa dà sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Nǹkan bí 4,800 kìlómítà, nítòsí ìlú Ithaca, ní àríwá New York ni ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà wà.
Lẹ́yìn ìbẹ̀wò ráńpẹ́ sí Oregon, ní January 1943, àwa aṣáájú ọ̀nà mélòó kan fi ooru gbígbóná Aṣálẹ̀ Arizona sílẹ̀ nígbà tí a wọ bọ́ọ̀sì Greyhound. Ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, a gúnlẹ̀ sí ibi tí a ń lọ, a sì rí òjò dídì ìgbà òtútù àríwá New York. Ilé ẹ̀kọ́ náà bẹ̀rẹ̀ ní February 1, 1943, nígbà tí ààrẹ rẹ̀, Nathan H. Knorr, sọ nínú ọ̀rọ̀ ìṣíléwèé tí ó sọ fún ọgọ́rùn-ún ọmọ ilé ẹ̀kọ́, pé: “Ète ilé ẹ̀kọ́ yìí KÌ Í ṢE láti mú yín gbára dì láti di òjíṣẹ́ tí a ti yàn. Òjíṣẹ́ ni yín tẹ́lẹ̀, ẹ sì ti ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ náà fún ọ̀pọ̀ ọdún. . . . Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ ilé ẹ̀kọ́ náà jẹ́ fún ètè kan ṣoṣo ti mímúra yín sílẹ̀ láti lè túbọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ tí ó tóótun nínú ìpínlẹ̀ tí ẹ ń lọ.”
Níwọ̀n bí n kò ti kàwé púpọ̀, nǹkan kò rọrùn fún mi rárá ní Gilead ní ìbẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn olùkọ́ wa fi ojú àánú hàn sí mi, mo sì wá gbádùn ẹ̀kọ́ mi dáradára. Kíláàsì wa kẹ́kọ̀ọ́ yege lẹ́yìn oṣù márùn-ún ìdálẹ́kọ̀ọ́ jíjinlẹ̀. Lẹ́yìn náà, a rán díẹ̀ lára wa lọ sí orílé-iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, níbi tí a ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i láti múra wa sílẹ̀ fún sísìn nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Àríwá àti Gúúsù Carolina ni a kọ́kọ́ yàn mí sí.
Nígbà náà lọ́hùn-ún, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìgbà ni alábòójútó àyíká máa ń wà lórí ìrìn àjò. A óò lo ọjọ́ kan pẹ̀lú ìjọ kékeré tàbí kí a lo ọjọ́ méjì bí ó bá jẹ́ ìjọ ńlá. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ ìgbà náà ni ó kéré. Nítorí náà, lẹ́yìn lílo ọjọ́ kan ṣúlẹ̀, àti lọ́pọ̀ ìgbà, ṣíṣe ìbẹ̀wò àti dídáhùn ìbéèrè títí di ọ̀gànjọ́ òru, n óò ti jí ní aago márùn-ún àárọ̀ ọjọ́ kejì láti rìnrìn àjò lọ sí ìjọ tí ó tẹ̀ lé e. Mo ṣe alábòójútó àyíká fún nǹkan bí ọdún kan, lẹ́yìn náà, mo ṣe aṣáájú ọ̀nà fún ìgbà díẹ̀ ní Tennessee àti New York.
Sí Cuba àti sí Puerto Rico Lẹ́yìn Náà
Ní May 1945, pẹ̀lú àwọn mélòó kan, a rán mi lọ sí ibi iṣẹ́ àyànfúnni mi àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì, Cuba! Ní alẹ́ ọjọ́ tí a dé sí Havana, olú ìlú Cuba, a jáde lọ fún iṣẹ́ ìwé ìròyìn. A dúró sí Havana títí tí ó fi ṣeé ṣe fún wa láti rílé ní Santa Clara. Dọ́là 25 péré ni a ń fún wa lóṣooṣù láti fi gbọ́ gbogbo bùkátà, títí kan ti oúnjẹ àti owó ilé. A fi àwọn ohun èlò tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó kan bẹ́ẹ̀dì àti àga, a sì lo àwọn àpótí tí a ń kó ápù sí láti fi ṣe àwọn kọ́ńbọ́ọ̀dù wa.
A yàn mí sí iṣẹ́ àyíká ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e. Ní àkókò yẹn, àyíká kan ṣoṣo ni gbogbo Cuba jẹ́. Nítorí tí alábòójútó àyíká tí ó sìn ṣáájú mi ní ẹsẹ̀ gígùn, tí ó sì fẹ́ràn fífẹsẹ̀ rìn, ṣe ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin máa ń sáré tẹ̀lé e lẹ́yìn. Ó ṣe kedere pé wọ́n ronú pé, èmi náà yóò rí bẹ́ẹ̀, nítorí náà, wọ́n ti múra sílẹ̀ fún ìbẹ̀wò mi. Gbogbo wọn kò jáde fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọjọ́ kan náà, ṣùgbọ́n wọ́n pín ara wọn sí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́, wọ́n sì ń bá mi ṣiṣẹ́ lọ́kọ̀ọ̀kan. Ní ọjọ́ àkọ́kọ́, ẹgbẹ́ kan mú mi lọ sí ìpínlẹ̀ kan tí ó jìnnà; ní ọjọ́ kejì, ẹgbẹ́ mìíràn mú mi lọ sí ìpínlẹ̀ míràn tí ó jìnnà, bí gbogbo rẹ̀ ṣe lọ nìyẹn. Ó rẹ̀ mí gan-an lópin ìbẹ̀wò náà, ṣùgbọ́n mo gbádùn rẹ̀. Mo máa ń láyọ̀ nígbà tí mo bá rántí ìjọ yẹn.
Nígbà tí yóò fi di 1950, akéde Ìjọba ní Cuba ti lé ní 7,000, nǹkan bí iye kan náà pẹ̀lú Mexico. Ní July ọdún yẹn, mo lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ti Ìbísí Ìṣàkóso Ọlọ́run ní Pápá Ìṣeré Yankee ní New York City. Lẹ́yìn náà, mo gba iṣẹ́ àyànfúnni míṣọ́nnárì tuntun, sí Puerto Rico. Estelle àti Thelma Weakley, tí wọ́n wà pẹ̀lú mi nínú ọkọ̀ òfuurufú sí Puerto Rico, wà lára àwọn míṣọ́nnárì tuntun láti inú kíláàsì kejìlá.
Ní ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, èmi àti Estelle ṣègbéyàwó nípa ṣíṣe ayẹyẹ ráńpẹ́ kan ní Bayamón, Puerto Rico, lórí pèpéle lákòókò ìsinmi nígbà àpéjọ àyíká wa. Mo sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ṣáájú àti lẹ́yìn ìgbéyàwó wa. Láàárín ohun tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá tí a lò ní Puerto Rico, èmi àti Estelle rí ìbísí ńlá—láti iye tí ó dín sí 500 akéde sí iye tí ó lé ní 2,000. Ó ṣeé ṣe fún wa láti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ dórí ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti batisí, a sì kópa nínú dídá àwọn ìjọ tuntun bíi mélòó kan sílẹ̀.
Ní December 1960, Milton Henschel láti orílé-iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, ṣèbẹ̀wò sí Puerto Rico, ó sì bá àwọn míṣọ́nnárì sọ̀rọ̀. Ó béèrè bí àwọn kan yóò bá yọ̀ǹda ara wọn nínú iṣẹ́ àyànfúnni mìíràn. Èmi àti Estelle wà lára àwọn tí ó yọ̀ǹda ara wọn.
Ilé Wa ní Dominican Republic
Dominican Republic ni iṣẹ́ àyànfúnni wa tuntun, a sì dá June 1, 1961, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a óò ṣí lọ. Ní May 30, wọ́n pa aláṣẹ bóofẹ́ bóokọ̀ ti ilẹ̀ Dominican náà, Rafael Trujillo, a sì fagi lé bíbá ọkọ̀ òfuurufú wọ orílẹ̀-èdè náà. Ṣùgbọ́n, kò pẹ́ tí a fi ṣínà bíbá ọkọ̀ òfuurufú wọlé, ó sì ṣeé ṣe fún wa láti wọkọ̀ òfuurufú lọ sí Dominican Republic ní June 1, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣètò.
Rúkèrúdò ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè náà nígbà tí a débẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò ológun sì ń lọ lọ́wọ́. Wọ́n bẹ̀rù pé ìyípadà tegbòtigaga yóò wáyé, àwọn sójà sì ń yẹ gbogbo ènìyàn wò lójú pópó. Wọ́n dá wa dúró ní ọ̀pọ̀ ibi ìyẹ-ọkọ̀-wò, wọ́n sì yẹ ẹrù wa wò ní gbogbo ibi tí wọ́n ti dá wa dúró. Wọ́n kó gbogbo ohun tí ó wà nínú àpò wa sílẹ̀, títí kan àwọn ohun kéékèèké pàápàá. Ohun tí a fi kí wa káàbọ̀ sí Dominican Republic nìyẹn.
A dúró sí olú ìlú, ní Santo Domingo, fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀, kí a tó lọ sí ibi iṣẹ́ àyànfúnni wa àkọ́kọ́ ní La Romana. Nígbà ìṣàkóso bóofẹ́ bóokọ̀ Trujillo, a sọ fún àwọn ará ìlú pé Kọ́múníìsì ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé kò sí àwọn ènìyàn tí ó burú tó wọn láyé. Nítorí èyí, a ṣe inúnibíni rírorò sí Àwọn Ẹlẹ́rìí. Ṣùgbọ́n, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti bẹ́gi ẹ̀tanú lulẹ̀.
Lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ ní La Romana fún àkókò díẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í sìn nínú iṣẹ́ àyíká lẹ́ẹ̀kan sí i. Lẹ́yìn náà, ní 1964, a yàn wá sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ìlú Santiago. Dominican Republic nírìírí ìyípadà tegbòtigaga ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, orílẹ̀-èdè náà sì bọ́ sínú pákáǹleke lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà ìforígbárí yẹn, a gbé wa lọ sí San Francisco de Macorís, ìlú kan tí a mọ̀ mọ ìgbòkègbodò olóṣèlú rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, a wàásù fàlàlà láìsí ìdílọ́wọ́. A tilẹ̀ dá ìjọ tuntun kan sílẹ̀ láìka rúkèrúdò ìṣèlú sí. Láàárín àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e, a nírìírí àwọn ìyípadà síwájú sí i nínú iṣẹ́ àyànfúnni wa, kí a tó yàn wá pa dà sí ilé wa tí a wà nísinsìnyí ní Santiago.
Dájúdájú, a ti rí ìbùkún Jèhófà lórí iṣẹ́ níhìn-ín ní Dominican Republic. Nígbà tí a dé síhìn-ín ní 1961, nǹkan bí 600 Ẹlẹ́rìí àti 20 ìjọ ni ó wà. Nísinsìnyí, nǹkan bí 20,000 akéde, tí ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní èyí tí ó lé ní 300 ìjọ, ní ń bẹ. Ìfojúsọ́nà fún ìbísí síwájú sí i pọ̀ rẹpẹtẹ, gẹ́gẹ́ bí àròpọ̀ 81,277 tí ó pé jọ síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ní 1997 ti fi hàn. Ìyẹn jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta àti ààbọ̀ iye akéde!
Alágbára Orílẹ̀-Èdè Nísinsìnyí
Bí ìran ayé tilẹ̀ ń bá a lọ láti yí pa dà, ìhìn iṣẹ́ Bíbélì tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù kò yí pa dà. (Kọ́ríńtì Kíní 7:31) Jèhófà ṣì ni Ọlọ́run, Kristi ṣì ni Ọba, ó sì ṣe kedere ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé Ìjọba náà ni ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé.
Lọ́wọ́ kan náà, ìyípadà àgbàyanu kan ti ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà láti ìgbà tí mo lọ sí ìpàdé ní Salem, Oregon, ní nǹkan bí 60 ọdún sẹ́yìn. Ògìdìgbó ńláǹlà, tàbí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ti di ńlá ní tòótọ́, wọ́n ti lé ní mílíọ̀nù márùn-ún. Bí Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ènìyàn rẹ̀ gan-an ni ó rí, pé: “Ẹni kékeré kan ni yóò di ẹgbẹ̀rún, àti kékeré kan di alágbára orílẹ̀-èdè: èmi Olúwa yóò ṣe é kánkán ní àkókò rẹ̀.”—Aísáyà 60:22.
Lẹ́yìn nǹkan bí 60 ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, mo láyọ̀ láti ní ìdùnnú bíbá a lọ láti wàásù àti láti kọ́ni nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí a yàn fún mi. Ẹ wo irú àǹfààní ńlá tí ó jẹ́ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ yẹn àti láti rí i tí “ẹni kékeré kan” di “alágbára orílẹ̀-èdè”!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Èmi pẹ̀lú aya mi, ní Dominican Republic