ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 2-3
  • Ese Iwe Mimo Odun 2015

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ese Iwe Mimo Odun 2015
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà Kí O sì Gba Ìbùkún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • ‘Ẹ Fi Ara Yín Hàn Ní Ẹni Tí Ó Kún fún Ọpẹ́’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • “Ẹ Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, “Ọlọ́run Ìtùnú Gbogbo”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 2-3
Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 2, 3

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2015

“Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere.”​—Sáàmù 106:1

Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà lẹ́yìn tó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní Òkun Pupa. Ó yẹ káwa pẹ̀lú máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Òótọ́ ni pé a lè rẹ̀wẹ̀sì tí ìṣòro bá dé bá wa. Ohun tó máa fún wa lókun tó sì máa tù wá nínú nírú àkókò bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa.

Pàtàkì jù lọ lára àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa ni ìrètí tó dájú tá a ní pé ó máa mú gbogbo ohun tó ń fa ìrora àti ìbànújẹ́ kúrò. Ìṣòro yòówù ká ní, a mọ̀ pé Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀. Olùṣọ́ àgùntàn tó nífẹ̀ẹ́ wa ni Jèhófà, ó sì máa ń pèsè gbogbo ohun tá a nílò ká lè máa sìn ín tọkàntọkàn. Kì í já wa kulẹ̀ rárá torí pé òun ni “ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” (Sm. 46:1) Tá a bá ń ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, a ó lè fara da ìṣòro tó le jù lọ pàápàá. Jálẹ̀ ọdún 2015, ẹ jẹ́ ká kún fún ayọ̀ bá a ṣe ń ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ká sì máa tipa bẹ́ẹ̀ “fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere; nítorí tí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sm. 106:1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́