ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | SÁÀMÙ 106-109
“Ẹ Fi Ọpẹ́ Fún Jèhófà”
Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi tètè gbàgbé bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n là?
Dípò kí wọ́n pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ Jèhófà, ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ àtàwọn nǹkan tara ní wọ́n gbájú mọ́
Báwo la ṣe lè fi hàn pé a moore, ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó?
Pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe tó fi yẹ kó o máa dúpẹ́
Máa ṣàṣàrò lórí ìrètí ọjọ́ ọ̀la
Tó o bá n gbàdúrà, máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àwọn nǹkan pàtó tó ti ṣe fún ẹ