ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb16 ojú ìwé 129
  • Mo La Rògbòdìyàn Àwọn Kọ́múníìsì Já

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mo La Rògbòdìyàn Àwọn Kọ́múníìsì Já
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀gá Àwọn Jàǹdùkú Di Ọmọlúwàbí
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
  • A Ya Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Sí Mímọ́
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
  • Mò Ń Wò Ó Pé Ayé Mi Ti Dáa
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2017
  • Ṣíṣiṣẹ́sìn Pẹ̀lú Òye Ìmọ̀lára Ìjẹ́kánjúkánjú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
yb16 ojú ìwé 129

INDONÉṢÍÀ

Mo La Rògbòdìyàn Àwọn Kọ́múníìsì Já

Ronald Jacka

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1928

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1941

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka Indonéṣíà fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25].

Ronald Jacka

LÁÀÁRỌ̀ kùtùkùtù October 1 ọdún 1965, àwọn kan lára Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì Ilẹ̀ Indonéṣíà (PKI) tó fẹ́ fipá gbàjọba pa mẹ́fà lára àwọn ọ̀gágun orílẹ̀-èdè náà. Kíá ni ìjọba ti gbé àwọn ọmọ ogun dìde sáwọn tó ṣọṣẹ́ náà, wọ́n sì fìjà pẹẹ́ta. Ogun náà gbóná débi pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500,000] ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ló ṣòfò ẹ̀mí nínú “ìjà àjàkú-akátá” náà.

Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ọ̀gá ológun kan ta mí lólobó pé orúkọ mi wà lára àwọn olórí ẹ̀sìn táwọn ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ń gbèrò láti pa. Ó tiẹ̀ ní kí n wá lọ wo sàréè tí wọ́n gbẹ́ sílẹ̀ fún mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ mo ní kó má ṣèyọnu. Ìlú ń gbóná nígbà yẹn, mi ò sì fẹ́ káwọn èèyàn rí mi pẹ̀lú ọ̀gágun yìí, kí wọ́n wá máa rò pé mò ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́