INDONÉṢÍÀ
Ọ̀gá Àwọn Jàǹdùkú Di Ọmọlúwàbí
Hisar Sormin
WỌ́N BÍ I NÍ 1911
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1952
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀gá àwọn jàǹdùkú tó di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.
LỌ́JỌ́ kan, Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ pe Arákùnrin Sormin pé kó wá rí òun ní ọ́fíìsì adájọ́ àgbà ti orílẹ̀-èdè náà.
Ọ̀gá náà sọ pé: “Ọmọ ilẹ̀ Indonéṣíà ni ẹ́, àbí? Sòótọ́ fún mi, kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà gan-an?”
Arákùnrin Sormin dáhùn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ara mi fún un yín. Ṣé ẹ rí i, ọ̀gá àwọn jàǹdùkú ni mí tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, mò ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe níbí nìyẹn, wọ́n ń sọ àwọn èèyànkéèyàn bíi tèmi di ọmọlúwàbí.”
Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ yìí wá kéde pe: “Àìmọye ẹ̀sùn láwọn èèyàn máa fi ń kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ẹ̀sìn tòótọ́ lẹ̀sìn yìí nítorí ó jẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni Sormin yí pa dà.”