Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2016
Iye Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 89
Iye Orílẹ̀-Èdè Tó Ròyìn: 240
Àròpọ̀ Iye Ìjọ: 119,485
Àwọn Tó Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé: 20,085,142
Àwọn Tó Jẹ Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Kárí Ayé: 18,013
Góńgó Akéde: 8,340,847
Ìpíndọ́gba Akéde Tó Ń Wàásù Lóṣooṣù: 8,132,358
Iye Tá A Fi Pọ̀ Ju Ti Ọdún 2015: 145,079
Àròpọ̀ Iye Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 264,535
Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ Lóṣooṣù: 459,393
Ìpíndọ́gba Aṣáájú-Ọ̀nà Déédéé Lóṣooṣù: 1,157,017
Àròpọ̀ Wákàtí Tá A Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: 1,983,763,754
Ìpíndọ́gba Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lóṣooṣù: 10,115,264
Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2016, ó ju igba ó lé mẹ́tàlá [213] mílíọ̀nù owó dọ́là táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná láti bójú tó àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Bákan náà, kárí ayé, iye àwọn tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìdínlógún [19,818]. Gbogbo wọn wà lára Àwọn Tó Ń Ṣe Àkànṣe Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Lára Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.