ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 105
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Tijú Mọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Tijú Mọ́?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù
  • Ohun tó o lè ṣe
  • Kí Ló Dé Tí N Kì Í Túra Ká?
    Jí!—1999
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Túra Ká?
    Jí!—1999
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ò Bá Rọrùn fún Mi Láti Máa Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Dá Wà?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 105
Ọ̀dọ́bìnrin kan dá jókòó níbi ìkórajọ kan, kò bá ẹnì kankan sọ̀rọ̀.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Tijú Mọ́?

Ohun tó jẹ́ ìṣòro: Tí ẹnì kan bá ń tijú, onítọ̀hún lè má ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ tàbí kó má fi bẹ́ẹ̀ ní ìrírí.

Ohun tó yẹ kó o mọ̀: Kéèyàn máa tijú ò fìgbà gbogbo burú. Torí nígbà míì, ó lè mú kéèyàn ronú kó tó sọ̀rọ̀, ó sì lè mú kéèyàn tẹ́tí sáwọn míì kó sì lákìíyèsí.

Òótọ́ ibẹ̀: Tó o bá ń tijú báyìí, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé bẹ́ẹ̀ láá ṣe máa rí títí lọ. O lè ṣe àwọn ohun tí ò ní jẹ́ kó o máa tijú. Àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.

  • Mọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù

  • Ohun tó o lè ṣe

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Mọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù

Ẹni tó bá ń tijú máa ń bẹ̀rù láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Ẹni náà tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í yẹra fáwọn èèyàn, kó máa ṣe é bíi pé ó dá wà nínú yàrá tó ṣókùnkùn. Ìyẹn sì léwu gan-an. Àmọ́ tó o bá mọ àwọn ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, wàá rí i pé kò sídìí tó fi yẹ kó o máa bẹ̀rù. Wo ohun mẹ́ta tó lè jẹ́ kẹ́rù máa bà ẹ́.

  • Àkọ́kọ́: “Mi ò mọ ohun tí màá sọ.”

    Òótọ́ ibẹ̀: Àwọn èèyàn kì í sábà rántí ohun tẹ́nì kan sọ, àmọ́ wọn ò lè gbàgbé ohun tẹ́ni náà ṣe sí wọn. Tẹ́rù bá ń bà ẹ́, o ò ṣe túbọ̀ máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀.

    Rò ó wò ná: Irú ọ̀rẹ́ wo ló wù ẹ́ kó o ní? Ṣé ẹlẹ́jọ́ ni, tí ò lè ṣe kó má rí nǹkan sọ, àbí ẹni tó máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn míì?

  • Ìkejì: “Àwọn èèyàn lè máa rò pé mi ò lọ́yàyà.”

    Òótọ́ ibẹ̀: Kò sí káwọn èèyàn má rí nǹkan sọ nípa ẹ, bóyá o máa ń tijú ni o àbí o kì í tijú. Tó o bá jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó o jẹ́, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n ní èrò tó dáa nípa ẹ, wàá sì lè borí ìbẹ̀rù.

    Rò ó wò ná: Tó o bá ń wò ó pé àwọn èèyàn ò gba tìẹ, èyí lè má jóòótọ́ torí ó lè jẹ́ pé ìwọ lò ń rò ó bẹ́ẹ̀

  • Ìkẹ́ta: “Tí mo bá sọ ohun tí kò yẹ kí n sọ, ojú á tì mí.”

    Òótọ́ ibẹ̀: Kò sẹ́ni tírú ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí, ó ṣe tán, a kì í mọ̀ ọ́n rìn kórí má mì. Torí náà, tó o bá ṣi ọ̀rọ̀ sọ, jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé aláìpé nìwọ náà, èyí á jẹ́ kó o lè borí ìbẹ̀rù.

    Rò ó wò ná: Ṣé ó má a ń wù ẹ́ kó o wà láàárín àwọn èèyàn tó gbà pé àwọn náà máa ń ṣàṣìṣe?

Ǹjẹ́ o mọ̀? Àwọn kan rò pé àwọn kì í tijú torí àtẹ̀jíṣẹ́ ni wọ́n sábà máa ń fi ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àmọ́ tó o bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tòótọ́, ó yẹ kó o máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Kódà, ọ̀gbẹ́nì Sherry Turkle tó jẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ àti afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá sọ pé: “Àwa èèyàn máa ń mọwọ́ ara wa dáadáa tá a bá ríra wa tàbí tá a gbóhùn ara wa.”a

Ọ̀dọ́bìnrin kan náà ń bá tọkọtaya kan sọ̀rọ̀ níbi ìkórajọ náà.

Tó o bá mọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù, ó máa rọrùn fún ẹ láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú, o ò sì ní máa tijú mọ́

Ohun tó o lè ṣe

  • Má ṣe fi ara ẹ wé ẹlòmíì. Kò di dandan kó o máa fi ara ẹ wé àwọn tó mọ̀rọ̀ sọ gan-an. Ohun tó o yẹ kó o máa wá ni bí wàá ṣe lè máa sọ̀rọ̀ nígbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, èyí á jẹ́ kó o láwọn ìrírí tó dáa kó o sì láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́.

    “Kò di dandan kó jẹ́ pé ìwọ ni wàá máa pa àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lẹ́rìn-ín. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ mọ níwọ̀n, tó o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé ẹni kan, o lè sọ orúkọ ẹ fún un kó o sì bi ẹni náà ní ìbéèrè díẹ̀, ìyẹn náà ti tó.”—Alicia.

    Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa yẹ ohun tó ń ṣe wò, nígbà náà, yóò láyọ̀ nítorí ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, kì í ṣe torí pé ó fi ara rẹ̀ wé ẹlòmíì.”​—Gálátíà 6:4.

  • Máa kíyè sí bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣe. Máa kíyè sí bí àwọn tí kì í tijú ṣe ń ṣe tí wọ́n bá wà láàárín àwọn èèyàn. Wo ohun tí wọ́n máa ń ṣe àti ohun tí wọn kì í ṣe tí wọ́n bá kọ́kọ́ pàdé ẹnì kan, irú ìwà wo ni wọ́n ní tó wu ìwọ náà kó o ní?

    “Kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn tó máa ń rọrùn fún láti lọ́rẹ̀ẹ́ tuntun. Tí wọ́n bá kọ́kọ́ pàdé ẹnì kan, kíyè sí ohun tí wọ́n ṣe àti bí wọ́n ṣe bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀.”​—Aaron.

    Ìlànà Bíbélì: “Bí irin ṣe ń pọ́n irin, bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ṣe ń pọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀.”​—Òwe 27:17.

  • Máa béèrè ìbéèrè. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ sọ èrò wọn lórí nǹkan, torí náà tó o bá bi ẹnì kan ní ìbéèrè, ìyẹn lè jẹ́ kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ dáadáa. Tẹ́ ẹ bá sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ, o ò ní máa dààmú jù nípa ohun tó o máa sọ.

    “Kó tó di pé o lọ síbi ìkórajọ kan, o lè múra ohun tó o fẹ́ sọ sílẹ̀ àbí kó o ti mọ àwọn ìbéèrè tó o lè bi ẹni tó ṣeé ṣe kó o bá pàdé, èyí á jẹ́ kó rọrùn fún ẹ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀.”—Alana.

    Ìlànà Bíbélì: ‘Ẹ máa wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.’—Fílípì 2:4.

a Látinú ìwé Reclaiming Conversation.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kelsey.

“O lè fi ẹ̀rín músẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ àbí kó o sọ pé ‘báwo ni o?’ Wàá rí i pé àwọn èèyàn máa rẹ́rìn-ín sí ẹ pa dà, ẹ̀rù ò sì ní bà ẹ́ mọ́ tó o bá fẹ́ bá ẹlòmíì sọ̀rọ̀ nígbà míì.”—Kelsey.

Robin.

“Gbogbo wa la ní ibi tá a dáa sí, tá a sì ní ìwà táwọn èèyàn máa mọyì. Àmọ́, tójú bá ń tì ẹ́, tó ò sọ̀rọ̀, kò sẹ́ni tó máa mọ irú ẹni tó o jẹ́, wọn ò sì ní mọ̀ pé o ní ìwà tó dáa.”—Robin.

Veronica.

“Tójú bá ń tì ẹ́ àmọ́ tó ò ń mára tu àwọn èèyàn, wọ́n máa fẹ́ràn ẹ. Ó tún máa ń dáa kéèyàn rẹ́rìn-ín músẹ́ tó ti ọkàn wá, kéèyàn sì tó lè ṣèyẹn, ó gbọ́dọ̀ máa wo ibi táwọn míì dáa sí”—Veronica.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́