Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Túbọ̀ Túra Ká?
“N kì í lè bá èèyàn fọ̀rọ̀wérọ̀. Mo máa ń rò pé bí mo bá sọ nǹkan kan, wọ́n á gbé mi nídàáàmù ni. Onítìjú gbáà ni màmá mi, mo sì rò pé ohun tó mú kí èmi náà ya onítìjú nìyẹn.”—Artie.
ǸJẸ́ o máa ń ṣàníyàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pé ì bá dáa ká ní o kì í fi bẹ́ẹ̀ tijú—kí o túbọ̀ yára mọ́ni kí o sì túbọ̀ túra ká? Bí àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ṣe sọ, ó wọ́pọ̀ kí àwọn èèyàn máa tijú.a Nítorí náà, kì í ṣe pé nǹkan kan ń ṣe ọ́ tó bá jọ pé o máa ń ká jọ síbì kan, tí ẹnì kan kì í rójú rẹ nílẹ̀, tí o kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Ṣùgbọ́n ojú àtìjù lè jẹ́ ìṣòro ńlá kan. Ó kéré tán, ó lè máà jẹ́ kí o gbádùn ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ó sì tún lè máà jẹ́ kí ara rẹ balẹ̀ tàbí kí o má mọ bí o ṣe máa ṣe láàárín àwùjọ èèyàn.
Àwọn àgbàlagbà pàápàá máa ń bá ìṣòro ìtìjú jà. Alàgbà ni Barryb nínú ìjọ Kristẹni. Àmọ́, ó jọ pé kì í lè sọ̀rọ̀ láàárín èrò. Ó sọ pé: “Mi ò rò pé mo lè sọ nǹkan tó bọ́gbọ́n mu.” Ìṣòro kan náà ni Diane pàápàá tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ ní. Báwo ló ṣe wá yanjú ìṣòro náà? Ó sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ wà láàárín àwọn èèyàn tó yára mọ́ni nítorí mo máa ń ronú pé wọ́n lè gba ìjíròrò náà lẹ́nu mi.” Àwọn ohun wo ni ìwọ náà lè ṣe tí o fi lè túbọ̀ túra ká sí i?
Má Ṣe Máa Fojú Tẹ́ńbẹ́lú Ara Rẹ
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, o lè ní láti gbé ojú ìwòye ìwọ fúnra rẹ yẹ̀ wò. Ǹjẹ́ o sábà máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ara rẹ, tí o máa ń sọ lọ́kàn ara rẹ pé àwọn èèyàn ò ní fẹ́ràn rẹ tàbí pé kò sí nǹkan gidi tóo lè sọ? Ríronú lódì lódì nípa ara rẹ yóò wulẹ̀ máa dí ọ lọ́wọ́ láti túra ká ni. Ṣebí ohun tí Jésù sọ ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ”—kò sọ pé dípò ara rẹ! (Mátíù 19:19) Nítorí náà, ó bójú mu, ó sì tọ́ láti nífẹ̀ẹ́ ara rẹ dé àyè kan. Ó lè fún ọ ní ìdánilójú tí o lè nílò láti lè bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀.
Bí o bá ń nímọ̀lára pé o kò já mọ́ nǹkan, kíka orí kejìlá ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́c tó ní àkọlé “Eeṣe Ti Emi Kò Fi Fẹran Ara Mi?,” lè ràn ọ́ lọ́wọ́. Ìsọfúnni yẹn lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí i pé o ní ohun púpọ̀ láti sọ. Kódà, ti pé o jẹ́ Kristẹni pàápàá tilẹ̀ fi hàn pé Ọlọ́run rí ohun tó ṣeyebíye nínú rẹ! Ohun tí Jésù sáà sọ ni pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.”—Jòhánù 6:44.
Fi Ìfẹ́ Hàn Sáwọn Ẹlòmíràn
Òwe 18:1 kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan.” Bẹ́ẹ̀ ni, bí o kò bá túra ká, o lè máa pàfiyèsí jù sórí ara rẹ. Fílípì 2:4 gbà wá níyànjú láti ‘má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara wa nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ Nígbà tí o bá darí àfiyèsí rẹ sórí ire àti àìní àwọn ẹlòmíràn, o ò ní jẹ́ ẹni tí ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ nìkan ń jẹ lọ́kàn. Bí o bá sì ṣe ń bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn tó bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣeé ṣe kí ó yá ọ lára tó láti sapá láti mọ̀ wọ́n.
Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Lìdíà yẹ̀ wò, àwọn èèyàn mọ obìnrin náà bí ọ̀rẹ́ gbogbo èèyàn àti oníwà ọ̀làwọ́. Bíbélì sọ fún wa pé lẹ́yìn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sì ṣèrìbọmi, ó rọ Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá kà mí sí olùṣòtítọ́ sí Jèhófà, ẹ wọ ilé mi.” (Ìṣe 16:11-15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Lìdíà ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ni, ó lo ìdánúṣe láti mọ àwọn arákùnrin wọ̀nyí—kò sí iyè méjì pé ìbùkún ló yọrí sí fún un. Ibo ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà forí lé nígbà tí wọ́n jáde lẹ́wọ̀n? Ó dùn mọ́ni láti mọ̀ pé ilé Lìdíà ni wọ́n padà sí!—Ìṣe 16:35-40.
Bákan náà, wàá rí i pé inú ọ̀pọ̀ èèyàn á dùn nítorí ìfẹ́ tí o fi hàn sí wọn. Báwo lo ṣe wá lè bẹ̀rẹ̀ rẹ̀? Àwọn àbá díẹ̀ tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nìwọ̀nyí.
● Bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Kì í ṣe pé kí o wá di aláṣejù tàbí ẹni tí kì í gbélé mọ́ nítorí pé o fẹ́ jẹ́ ẹni tó túra ká o. Gbìyànjú láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. O lè fi ṣe góńgó rẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, ó kéré tán pẹ̀lú ẹnì kan, nígbàkigbà tí o bá lọ sí ìpàdé Kristẹni. Gbìyànjú láti rẹ́rìn-ín músẹ́. Gbìyànjú láti máa wo ojú ẹni náà bí ẹ ṣe ń sọ̀rọ̀.
● Kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. O lè béèrè pé, ‘Báwo ni mo ṣe lè ṣe é?’ Ní gidi, tí o bá nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn, kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣòro láti rí nǹkan sọ. Ọ̀dọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jorge láti Sípéènì sọ pé: “Mo ti ṣàkíyèsí pé kìkì bíbéèrè lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa bí nǹkan ṣe ń lọ tàbí bíbéèrè lọ́wọ́ wọn nípa iṣẹ́ wọn máa ń ranni lọ́wọ́ láti mọ̀ wọ́n dáadáa.” Ọ̀dọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fred dábàá pé: “Bí o ò bá mọ ohun tí o máa sọ, sáà bẹ̀rẹ̀ sí bi àwọn èèyàn níbèéèrè.” Àmọ́ ṣá o, máà jẹ́ kí àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí rò pé ńṣe lo ń fọ̀rọ̀ wá àwọn lẹ́nu wò. Bó bá jọ pé ẹnì kan ò fẹ́ dáhùn àwọn ohun tí o ń bi í, gbìyànjú láti sọ̀rọ̀ nípa ara rẹ fún un.
Mary, tó jẹ́ ìyá fún ọ̀dọ́langba kan, sọ pé: “Mo ti wá rí i pé ọ̀nà tó dára jù láti mú kí ara tu àwọn èèyàn ni láti jẹ́ kí wọ́n sọ nípa ara wọn.” Ọ̀dọ́bìnrin tó ń jẹ́ Kate fi kún un pé: “Ó máa ń dáa ká sọ ohun tó dára nípa ìmúra àwọn èèyàn tàbí nǹkan mìíràn. Wàá jẹ́ kí wọ́n nímọ̀lára pé o fẹ́ràn wọn.” Àmọ́ ṣá o, jẹ́ kó tọkàn rẹ wá, má ṣe jẹ́ kó jẹ́ fífi ẹnu pọ́nni lásán. (1 Tẹsalóníkà 2:5) Inú àwọn èèyàn sábà máa ń dùn sí ọ̀rọ̀ rere, tó gbádùn mọ́ni, tí a sì sọ látọkànwá.—Òwe 16:24.
● Jẹ́ ẹni tó ń fetí sílẹ̀ dáadáa. Bíbélì sọ pé: ‘Kí ẹ yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, kí ẹ lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.’ (Jákọ́bù 1:19) Ṣebí àsọgbà ni ìfọ̀rọ̀wérọ̀ jẹ́—kì í ṣe ọ̀rọ̀ àdásọ. Nítorí náà, tó bá jọ pé ojú máa ń tì ọ́ láti sọ̀rọ̀, èyí lè ṣe ọ́ láǹfààní! Àwọn èèyàn máa ń mọrírì àwọn tó bá ń fetí sílẹ̀ dáadáa.
● Dá sọ́rọ̀ táwọn èèyàn ń sọ. Tí o bá ti ń ṣe dáadáa nínú bíbá ẹnì kan ṣoṣo sọ̀rọ̀, gbìyànjú sísọ̀rọ̀ láwùjọ. Bákan náà, àwọn ìpàdé Kristẹni ni ibi tó dára jù láti kọ́ bí a ṣe ń ṣe èyí. Nígbà mìíràn, ọ̀nà tó rọrùn jù láti bá àwọn èèyàn fọ̀rọ̀ wérọ̀ ni nípa dídá sí ọ̀rọ̀ tí ń lọ lọ́wọ́. Dájúdájú, agbára ìfòyemọ̀ àti ìmọ̀wàáhù ṣe pàtàkì nínú èyí. Má ṣe já lu ọ̀rọ̀ tó hàn gbangba pé ọ̀rọ̀ àṣírí ni. Ṣùgbọ́n tó bá hàn gbangba pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ àṣírí làwọn tí wọ́n péjọ ń sọ, gbìyànjú láti bá wọn dá sí i. Jẹ́ amẹ̀tọ́mẹ̀yẹ; má ṣe já lu ọ̀rọ̀, má sì gba ọ̀rọ̀ mọ́ àwọn èèyàn lẹ́nu. Fetí sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ láti gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Bí o bá ti ń gbádùn ìjíròrò náà, o lè fẹ́ láti dá sọ́rọ̀ náà.
● Má ṣe retí ìjẹ́pípé lọ́dọ̀ ara rẹ. Nígbà mìíràn, àwọn ọ̀dọ́ máa ń dààmú gan-an nípa kí àwọn má lọ máa sọ ọ̀rọ̀ tí ò bọ́ sí i. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Elisa láti Ítálì rántí pé: “Gbogbo ìgbà lẹ̀rù máa ń bà mí pé bí mo bá sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ mi lè máà bọ́ sí i.” Àmọ́, Bíbélì rán wa létí pé aláìpé ni gbogbo wa, nítorí náà a kò lè sọ̀rọ̀ láìṣàṣìṣe. (Róòmù 3:23; fi wé Jákọ́bù 3:2.) Elisa sọ pé: “Ohun tí mo máa ń rò lọ́kàn ni pé ọ̀rẹ́ mi làwọn tí mo ń bá sọ̀rọ̀. Nítorí náà, wọn ò ní kà á sí bí mo bá sọ ọ̀rọ̀ tí ò bọ́ sí i.”
● Fi ṣọ̀rọ̀ ẹ̀rín. Òótọ́ ni pé sísọ ọ̀rọ̀ tí kò bọ́ sí i máa ń dójú tini. Ṣùgbọ́n Fred sọ pé, “bí o bá fara balẹ̀ tí o sì fi ara rẹ rẹ́rìn-ín, àwọn èèyàn ò ní pẹ́ gbàgbé rẹ̀. Wàá wulẹ̀ máa sọ ohun tí kò tó nǹkan di bàbàrà ni bí o bá ń banú jẹ́, tí o ń jọ̀gọ̀ nù, tàbí tí o ń dara ẹ láàmú.”
● Ní sùúrù. Mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fèsì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bí o bá jó rẹ̀yìn nínú ìsapá rẹ nípa ìbánisọ̀rọ̀ kò fi dandan túmọ̀ sí pé ẹni tí o ń bá sọ̀rọ̀ kò fẹ́ràn rẹ tàbí pé kí o jọ̀gọ̀ nù, kí o má sì sọ̀rọ̀ mọ́. Nígbà mìíràn, ó kàn lè jẹ́ pé ọwọ́ àwọn èèyàn dí ni—tàbí kó jẹ́ pé onítìjú bí tìẹ ni wọ́n. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá dára kí o fún ẹni náà láyè díẹ̀ láti yá mọ́ ẹ.
● Gbìyànjú bíbá àwọn àgbàlagbà sọ̀rọ̀. Nígbà mìíràn, àwọn àgbàlagbà, pàápàá àwọn tó jẹ́ Kristẹni tó dàgbà dénú, máa ń gba ti àwọn èwe tí ìtìjú ń yọ lẹ́nu rò. Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù láti gbìyànjú láti kọ́kọ́ dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ẹni tó dàgbà jù ọ́ lọ. Kate sọ pé: “Ọkàn mi máa ń balẹ̀ tó bá jẹ́ àwọn àgbàlagbà ni mo ń bá sọ̀rọ̀ nítorí mo mọ̀ pé àwọn àgbàlagbà ò ní ṣòfíntótó mi tàbí kí wọ́n máa fi mí ṣẹ̀sín, tàbí kí wọ́n dójú tì mí bí àwọn èwe ẹlẹgbẹ́ mi ṣe máa ṣe.”
Fi Ìfẹ́ Ṣe É
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àbá wọ̀nyí lè ṣèrànwọ́, kò sí ọ̀nà àbùjá tí a lè gbà borí ìtìjú. Ní àbárèbábọ̀, kì í ṣe nítorí pé o gbọ́n féfé lo fi lè borí ìtìjú. Ohun tí o fi lè borí ìtìjú ni pé kí o “nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Jákọ́bù 2:8) Òtítọ́ ni, kọ́ bí o ṣe lè bìkítà nípa àwọn ẹlòmíràn—pàápàá àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin rẹ. (Gálátíà 6:10) Bí o bá ní ojúlówó ìfẹ́ lọ́kàn rẹ, wàá lè borí ìbẹ̀rù àti àìfọkànbalẹ̀, wàá sì lè gbìyànjú láti máa bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, “lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.”—Mátíù 12:34.
Barry, tí a sọ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, sọ pé: “Bí mo ṣe ń mọ àwọn èèyàn sí i ló ṣe ń rọrùn fún mi sí i láti bá wọn sọ̀rọ̀.” Lédè mìíràn, bí o bá ṣe ń gbìyànjú láti túra ká tó ni yóò ṣe máa rọrùn sí i fún ọ. Bí o sì ṣe ń ní àwọn ọ̀rẹ́ tuntun sí i, tí o sì ń nímọ̀lára pé àwọn èèyàn mìíràn ń gba tìẹ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni wàá máa nímọ̀lára pé làálàá rẹ ò já sásán!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Kí Ló Dé Tí N Kì Í Túra Ká?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti November 8, 1999.
b A yí orúkọ àwọn kan padà.
c Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Gbìyànjú láti dá sí ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń sọ!