Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Kí Ló Dé Tí N Kì Í Túra Ká?
“Jíjẹ́ onítìjú lè jẹ́ káyé súni. Ó máa ń fa ìbẹ̀rùbojo tí ń kóni lọ́kàn sókè. Nǹkan ńlá ni o.”—Richard.a
“Ojú máa ń tì mí gan-an nígbà tí mo wà ní kékeré. Ṣe ni mo kàn dá wà láyè ara mi.”—Elizabeth, ọmọ ọdún méjìdínlógún.
‘ṢÉ KÌ Í ṣe pé nǹkan kan ń ṣe mi ṣá? Kí ló dé tí n kì í túra ká?’ Ǹjẹ́ o máa ń bi ara rẹ ní ìbéèrè wọ̀nyí nígbà míì? Bíi ti Richard tó sọ ọ̀rọ̀ òkè yìí, àyà rẹ lè máa já tàbí kí ẹ̀rù máa bà ẹ́ nígbà tóo bá pàdé ẹnì kan tí o ò mọ̀ rí. O lè bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n jìnnìjìnnì tóo bá wà nítòsí àwọn èèyàn tó wà nípò àṣẹ. Tàbí kẹ̀, o lè máa dààmú gan-an nípa ohun táwọn míì ń rò nípa rẹ, débi pé nígbà tí wọ́n bá fún ẹ láǹfààní láti sọ èrò rẹ, ṣe ni wàá dákẹ́ lọ gbári. Ọ̀dọ́mọdé Tracey sọ pé: “Ó máa ń nira fún mi gan-an láti lọ bá àwọn tí mi ò mọ̀ dáadáa sọ̀rọ̀.”
Kí ló tilẹ̀ máa ń fa irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀? Ó jọ pé lílóye ìṣòro náà ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ fún ṣíṣẹ́pá rẹ̀. (Òwe 1:5) Obìnrin kan sọ pé: “Mi ò sáà mọ ìdí tí n kì í fi lè túra ká tí mo bá wà láàárín àwọn èèyàn. Àmọ́ nísinsìnyí tí mo ti mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro mi, àbùṣe ti bùṣe.” Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ohun díẹ̀ yẹ̀ wò tó lè mú kó nira fáwọn ọ̀dọ́ láti túra ká.
Ìṣòro Ìtìjú
Ó jọ pé ìtìjú ló sábà máa ń fà á. Nígbà tó ṣe pé ọ̀dọ́ tó túra ká sábà máa ń ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́, ọ̀dọ́ tó ń tijú, tí kì í yá mọ́ni lè máa nímọ̀lára pé òun dá wà àti pé wọ́n pa òun tì. Elizabeth, ẹni ọdún méjìdínlógún, sọ pé: “Ojú máa ń tì mí gan-an nígbà tí mo wà ní kékeré. Ṣe ni mo kàn dá wà láyè ara mi.” Diane rántí ìdààmú tó dé bá a lọ́dún tó bẹ̀rẹ̀ iléèwé gíga. Ó sọ pé: “N kì í fẹ́ kí ojú pé sí mi lára. Tíṣà wa kan ní ká sọ èrò wa lórí bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn gbajúmọ̀. Ó ní ká mú látorí òdo dórí aárùn-ún, òdo túmọ̀ sí pé kò ṣe pàtàkì rárá, aárùn-ún sì túmọ̀ sí pé ó ṣe pàtàkì. Gbogbo àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin tó gbajúmọ̀ níléèwé mú aárùn-ún. Òdo lèmi mú o. Lójú tèmi, títijú àti bíbẹ̀rù àtigbajúmọ̀, ọgbọọgba ni. O ò fẹ́ kí ojú àwọn èèyàn pé sí ẹ lára tàbí kí o di ẹni àpéwò, torí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ pé àwọn èèyàn lè má gba tìẹ.”
Ṣùgbọ́n ṣá o, kì í kúkú ṣe pé ó burú téèyàn bá ń tijú, tí ìtìjú ọ̀hún ò bá pọ̀ jù. Ìtìjú tan mọ́ ìmẹ̀tọ́mọ̀wà—tí í ṣe ìmọ̀wọ̀n ara ẹni. Kódà, Bíbélì pa á láṣẹ fún wa pé kí a ‘jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run wa rìn.’ (Míkà 6:8) Ara máa ń tù wá táa bá wà nítòsí ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà tàbí tó jẹ́ onítìjú pàápàá, ju táa bá wà nítòsí atẹnilóríba, onígìràgìrà, tàbí alámọ̀tán. Bí “ìgbà sísọ̀rọ̀” ti wà, bẹ́ẹ̀ náà ni “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” wà. (Oníwàásù 3:7) Kì í ṣòro fún onítìjú èèyàn láti dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorí pé wọ́n sábà máa ń “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, [wọ́n sì máa ń] lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ,” àwọn èèyàn máa ń mọyì wọn gan-an, torí pé wọ́n gbà pé wọ́n máa ń tẹ́tí sílẹ̀ láti gbọ́ni lágbọ̀ọ́yé.—Jákọ́bù 1:19.
Àmọ́ o, ó tún máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa, pé ọ̀dọ́ kan lè máa dákẹ́, tàbí kó máa tijú, tàbí kó lójo débi pé kì í bá ẹnikẹ́ni ṣọ̀rẹ́. Àní, nígbà míì ó lè burú débi pé ìtìjú lè fa ohun tí òǹkọ̀wé kan pè ní “bíbá ẹgbẹ́ yodì”—yíya ara ẹni láṣo.—Òwe 18:1.
Ìtìjú Jẹ́ Ìṣòro Tó Wọ́pọ̀
Bí ojú bá ń tì ẹ́, máa rántí pé ìṣòro tó wọ́pọ̀ gan-an ni. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láàárín àwọn ọmọ iléèwé gíga àtàwọn ti yunifásítì, “ìpín méjìlélọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọléèwé náà sọ pé àwọn máa ń tijú nígbà míì.” (Adolescence, látọwọ́ Eastwood Atwater) Kódà nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ onítìjú. Àwọn lóókọ-lóókọ, bíi Mósè àti Tímótì pàápàá, kò ṣàìní ìṣòro yẹn.—Ẹ́kísódù 3:11, 13; 4:1, 10, 13; 1 Tímótì 4:12; 2 Tímótì 1:6-8.
Ẹ tìẹ jẹ́ ká gbé ti Sọ́ọ̀lù yẹ̀ wò, ẹni tí í ṣe ọba àkọ́kọ́ tó jẹ ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì. Akíkanjú ẹ̀dá ni Sọ́ọ̀lù. Nígbà tí agbo ẹran bàbá rẹ̀ dàwátì, ṣe ni Sọ́ọ̀lù gbéra láìṣojo, láti wá wọn rí. (1 Sámúẹ́lì 9:3, 4) Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n fi í jẹ ọba orílẹ̀-èdè náà, ṣe ni ojú kàn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí tì í. Dípò kí Sọ́ọ̀lù dìde dúró láàárín ogunlọ́gọ̀ tí ń hó yèè, ṣe ló lọ sá pa mọ́ sáàárín ẹrù!—1 Sámúẹ́lì 10:20-24.
Ó lè yani lẹ́nu pé àyà Sọ́ọ̀lù tún lè máa já. Ṣebí Bíbélì sọ pé ọkùnrin gbọ̀ngbọ̀nrọ̀n ni, ọ̀dọ́kùnrin tó rẹwà sì ni. Àní, “láti èjìká rẹ̀ sókè, ó ga ju gbogbo àwọn ènìyàn náà”! (1 Sámúẹ́lì 9:2) Ìyẹn nìkan kọ́ o, wòlíì Ọlọ́run ti fi Sọ́ọ̀lù lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà ti sọ pé ìgbà ìjọba rẹ̀ á tùbà, á tùṣẹ. (1 Sámúẹ́lì 9:17, 20) Àṣé síbẹ̀síbẹ̀, ọkàn Sọ́ọ̀lù ò tíì balẹ̀. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé á jọba, ó fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé: “Èmi kì í ha ṣe ọmọ Bẹ́ńjámínì tí ó kéré jù lọ nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, tí ìdílé mi sì jẹ́ èyí tí ìjámọ́ pàtàkì rẹ̀ kéré jù lọ nínú gbogbo ìdílé ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì? Nítorí náà, èé ṣe tí o fi sọ irú ohun yìí fún mi?”—1 Sámúẹ́lì 9:21.
Bí àyà irú èèyàn bí Sọ́ọ̀lù bá já, kò lè yani lẹ́nu rárá bí àyà ìwọ náà bá ń já nígbà míì. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, ìyípadà ńláǹlà ń dé bá ara rẹ lọ́wọ́ tóo wà yìí. Ṣe ni o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ ìwà àgbà. Fún ìdí yìí, kò sí bí àyà rẹ ò ṣe ní máa já, tí o ó sì máa bẹ̀rù nígbà míì. Ọ̀jọ̀gbọ́n David Elkind sọ nínú ìwé ìròyìn Parents pé: “Nígbà táwọn ọ̀dọ́ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, ṣe ni ojú máa ń ti ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn, nígbà tó máa dà bí ẹni pé wọ́n ń rí ohun tí èmi ń pè ní àwùjọ apélénilórí—èyíinì ni pé wọ́n á gbà gbọ́ pé àwọn èèyàn ń ṣọ́ àwọn lójú méjèèjì, àti pé ìrísí àwọn àti ìṣe àwọn ló gba àwọn èèyàn wọ̀nyí lọ́kàn.”
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló máa ń ka ìrísí wọn sí nǹkan bàbàrà nítorí pé ìrísí làwọn ojúgbà wọn fi ń pinnu irú ẹni tí wọ́n jẹ́. (Fi wé 2 Kọ́ríńtì 10:7.) Àmọ́, kò dáa kí ọ̀ràn ìrísí gba èèyàn lọ́kàn jù. Ọ̀dọ́bìnrin kan ní ilẹ̀ Faransé tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lilia rántí ohun tójú ẹ̀ rí nípa ọ̀ràn ìrísí, ó ní: “Mo ní ìṣòro kan tí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ní. Rorẹ́ wà lójú mi! O ò tẹ́rú tí ń yọjú sáwọn míì, torí pé àyà rẹ yóò máa já nípa bí ojú rẹ ṣe rí.”
Ìyà Ọ̀nà Méjì
Nítorí pé àwọn èèyàn kì í sábàá lóye àwọn onítìjú, ọ̀ràn ìdánìkanwà wọn á wá di ìyà ọ̀nà méjì. Ìwé Adolescence sọ pé: “Àwọn ọ̀dọ́langba tó ń tijú kì í sábàá lọ́rẹ̀ẹ́ nítorí pé ojú burúkú làwọn èèyàn fi ń wò wọ́n. Ojú táwọn èèyàn fi ń wo àwọn onítìjú ni ẹni tí kì í bẹ́gbẹ́ ṣe, tí kì í yá mọ́ni, tí kì í kani sí, tí kì í túra ká, tí kì í sì í hùwà bí ọ̀rẹ́. Bí wọ́n bá sì lọ ń fi ojú ìwòye yìí hùwà sí wọn, èyí á tún wá jẹ́ káwọn onítìjú túbọ̀ mọ̀ ọ́n lára pé àwọn ò rẹ́ni fojú jọ, pé àwọn dá nìkan wà, wọ́n á sì sorí kọ́.” Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, èyí gan-an ló máa ṣẹ̀ṣẹ̀ wá jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tijú, yóò wá kúkú jẹ́ káwọn èèyàn máa sọ pé àṣé òótọ́ lèrò àwọn pé onígbèéraga ni wọ́n tàbí pé wọ́n lẹ́mìí mo-tó-tán.
Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí o máa ronú nípa èrò tóo ń gbìn sáwọn èèyàn lọ́kàn, torí pé “ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé” ni ìwọ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kan. (1 Kọ́ríńtì 4:9) Ṣe o kì í gbójú sá nígbà tóo bá ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀? Ǹjẹ́ ìdúró rẹ àti ìṣarasíhùwà rẹ ń sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀ jọ̀ọ́? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, kí o mọ̀ pé àwọn èèyàn lè ṣì ẹ́ lóye, kí wọ́n sì máa yẹra fún ẹ. Ó lè wá jẹ́ kó túbọ̀ ṣòro gan-an láti lọ́rẹ̀ẹ́.
Àwọn Kókó Mìíràn
Ìṣòro míì tó tún wọ́pọ̀ ni ìbẹ̀rù pé àwọn lè ṣàṣìṣe. Òtítọ́ ni pé kò sẹ́ni tí àyà rẹ̀ kì í já tàbí tí ọkàn rẹ̀ kì í ṣe kámi-kàmì-kámi nígbà tó bá ń ṣe ohun tí kò ṣe rí. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń ṣe èyí láṣejù. Nígbà tí Gail jẹ́ ọ̀dọ́, ó máa ń pe ara rẹ̀ ní abẹ́gbẹ́yodì. Ó ní: “N kì í dá sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ń sọ nínú kíláàsì. Ìgbà gbogbo sì ni wọ́n máa ń wá bá àwọn òbí mi, tí wọ́n ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ bíi, ‘Kì í nawọ́ sókè. Kì í sọ èrò inú rẹ̀.’ Ó máa ń ni mí lára gan-an ni, mi ò lẹ́mìí ẹ̀ rárá. Àní títí di bí mo ti ń sọ̀rọ̀ yìí pàápàá, ó kúkú ṣì ń ni mí lára.” Ìbẹ̀rù pé èèyàn lè gbé nǹkan gbági lè jẹ́ kí onítọ̀hún wọ̀ ṣin. Ọ̀dọ́ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Peter sọ pé: “Àyà mi máa ń já gan-an nígbà tí mo bá rántí pé mo mà lè ṣàṣìṣe. Mi ò tiẹ̀ ní wá mọ ohun tí mo ń ṣe mọ́.” Báwọn ojúgbà ẹni bá ń fòòró ẹni, tí wọ́n sì ń bẹnu àtẹ́ lu olúwarẹ̀ ṣáá, èyí lè tún dá kún ìjayà náà, kí ó sì ba ìgbẹ́kẹ̀lé tí ọ̀dọ́ kan ní nínú ara rẹ̀ jẹ́ pátápátá.
Ìṣòro míì tún ni pé kéèyàn má tiẹ̀ mọ báa ti fara mọ́ra láwùjọ. Bóyá kì í yá ẹ lára láti lọ bá ẹni tí o ò mọ̀ rí, kí o sì bá a sọ̀rọ̀ mọ̀-mí-n-mọ̀-ẹ́, kìkì nítorí pé o ò mọ ohun tí wàá sọ. Kí ó má yà ẹ́ lẹ́nu pé àwọn àgbàlagbà pàápàá máa ń tijú nígbà míì láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. Oníṣòwò kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Fred sọ pé: “Mi ò kẹ̀rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ajé mi rárá. Bó bá jẹ́ ọ̀ràn iṣẹ́ nìkan ni mo ń sọ, ọ̀rọ̀ mi yóò wọ̀ ẹ́ lọ́kàn ṣáá ni. Ṣùgbọ́n tí ọ̀rọ̀ bá wá di pé ká kàn fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀, pẹ̀lú àwọn èèyàn kan náà, ọ̀rọ̀ ò ní wù mí sọ mọ́. Màá wá máa tò kábakàba, tàbí kí n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ bí akadá, tàbí kí n bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹnà, màá wá di sùẹ̀gbẹ̀.”
Yálà o máa ń tijú, tàbí àyà ẹ máa ń já, tàbí kí ó kàn jẹ́ pé o ò bẹ́gbẹ́ mu, á dáa kóo yáa lọ kọ́ béèyàn ṣe ń túra ká. Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “gbòòrò síwájú,” kí wọ́n mọ àwọn èèyàn sí i! (2 Kọ́ríńtì 6:13) Ṣùgbọ́n báwo lo ṣe lè ṣe é? A óò jíròrò èyí nínú ìtẹ̀jáde kan lọ́jọ́ iwájú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ojú ẹni tí kì í bẹ́gbẹ́ ṣe làwọn èèyàn máa fi ń wo àwọn onítìjú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìbẹ̀rù pé àwọn lè ṣàṣìṣe máa ń mú káwọn ọ̀dọ́ kan wọ̀ ṣin láwùjọ