ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mrt àpilẹ̀kọ 103
  • Ṣé Ogun Àgbáyé Tún Máa Jà?—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ogun Àgbáyé Tún Máa Jà?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
  • Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò wa
  • Ogun tó ń bọ̀
  • Ìgbà Wo Ni Gbogbo Ogun Yìí Máa Dópin?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Wọ́n Ti Ná Ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ Owó Sórí Ogun—Kí Ni Àbárèbábọ̀ Ẹ̀?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ó Ti Lé Lọ́dún Kan Tí Ogun Ti Ń Jà ní Ukraine—Kí Ni Bíbélì Sọ Pé Ọlọ́run Máa Ṣe?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
mrt àpilẹ̀kọ 103
Ọkọ̀ ogun kan àti ọkọ̀ òfurufú kékeré tí wọ́n fi ń jagun.

Anton Petrus/Moment via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ṣé Ogun Àgbáyé Tún Máa Jà?​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Láti nǹkan bí ọgbọ̀n (30) ọdún sẹ́yìn lọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ronú pé àlàáfíà máa tó kárí ayé. Àmọ́ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti yí èrò yẹn pa dà.

  • “Ogun tó ń jà ní Gaza ti mú káwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èd Israel àti ẹgbẹ́ Hezbollah máa jà ní ààlà orílẹ̀-èdè Lebanon. Ẹ̀rù sì ń ba àwọn èèyàn pé àwọn orílẹ̀-èdè míì máa fẹ́ dá sí ogun tó ń jà ní Gaza.”​—Reuters, January 6, 2024.

  • “Àwọn ẹgbẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ fún orílẹ̀-èdè Iran ń fa wàhálà káàkiri àwọn agbègbè kan. Bákan náà, orílẹ̀-èdè náà ti ń ṣe àwọn bọ́ǹbù átọ́míìkì tó lè runlérùnnà. Kò tán síbẹ̀ o, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti Ṣáínà ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. Gbogbo èyí ń jẹ́ kẹ́rù máa ba àwọn tó ń gbé ní Amẹ́ríkà àti Yúróòpù.”​—The New York Times, January 7, 2024.

  • “Àwọn bọ́ǹbù tí Rọ́ṣíà ń jù túbọ̀ ń ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ lórílẹ̀-èdè Ukraine.”​—UN News, January 11, 2024.

  • “Orílẹ̀-èdè Ṣáínà túbọ̀ ń kó àwọn ohun ìjà jọ, ọrọ̀ ajé wọn sì ń gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Orílẹ̀-èdè Taiwan náà ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè wọn lárugẹ. Kò mọ síbẹ̀ o, ata àti ojú lọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè Ṣáínà àti Amẹ́ríkà báyìí. Bóyá ni ogun ò ní pa dà ṣẹlẹ̀ láàárín wọn.”​—The Japan Times, January 9, 2024.

Kí ni Bíbélì sọ nípa rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ayé lónìí? Ṣé gbogbo rògbòdìyàn yìí ò pa dà já sí ogún àgbáyé?

Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò wa

Bíbélì ò sọ tẹ́lẹ̀ nípa èyíkéyìí nínú àwọn ogun pàtó tó ń jà báyìí. Bó ti wù kó rí, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun á máa jà káàkiri lónìí, ìyẹn á sì “mú àlàáfíà kúrò ní ayé.”​—Ìfihàn 6:4.

Ìwé Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní àkókò òpin,” àwọn orílẹ̀-èdè alágbára á ‘máa kọ lu’ ara wọn tàbí bá ara wọn fà á kí wọ́n lè mọ ẹni táá jẹ́ ọ̀gá. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ “ìṣúra” tàbí òbítíbitì owó ní wọ́n á máa ná lórí ohun ìjà, wọ́n á sì máa fi ohun ìjà tí wọ́n kó jọ tahùn sí ara wọn.​—Dáníẹ́lì 11:40, 42, 43.

Ogun tó ń bọ̀

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ipò ayé yìí máa burú sí i kó tó di pé nǹkan dáa. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé “ìpọ́njú ńlá máa wà nígbà náà, irú èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé.” (Mátíù 24:21) “Ìpọ́njú’ńlá” yìí ló máa fa ogun Amágẹ́dọ́nì tí Bíbélì pè ní “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.”​—Ìfihàn 16:14, 16.

Àmọ́ ṣá o, ogun Amágẹ́dọ́nì kò ní pa ayé run, dípò bẹ́ẹ̀ ṣe ló máa gba aráyé là. Ọlọ́run máa lo ogun yẹn láti fòpin sí ìjọba èèyàn tó ti fa ọ̀pọ̀ ogun tó ba nǹkan jẹ́ gan-an. Tó o bá fẹ́ mọ bí ogun Amágẹ́dọ́nì ṣe máa mú kí àlàáfíà jọba láyé, ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí:

  • “Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?”

  • “Ìròyìn Ayọ̀ Ni Amágẹ́dọ́nì!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́