ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwfq àpilẹ̀kọ 61
  • Báwo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Lo Àwọn Ọrẹ Tá À Ń Rí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Lo Àwọn Ọrẹ Tá À Ń Rí?
  • Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Díẹ̀ Lára Àwọn Ohun Tá À Ń Ṣe
  • Báwo la ṣe ń rówó bójú tó iṣẹ́ wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • “Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fún Ẹni Tó Ni Ohun Gbogbo Ní Nǹkan?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Báwo La Ṣe Ń Rí Owó fún Iṣẹ́ Wa Kárí Ayé?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
Àwọn Míì
Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
ijwfq àpilẹ̀kọ 61
Fọ́tò: Ọrẹ táwọn èèyàn ń ṣe la fi ń bójú tó onírúurú iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe títí kan iṣẹ́ ìrànwọ́ tá à ń ṣe nígbà àjálù. 1. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. 2. Ẹlẹ́rìí kan tó yọ̀ǹda ara ẹ̀ láti ṣèrànwọ́ níbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ gbé omi fún obìnrin kan tí òùngbẹ ń gbẹ gan-an. 3. Níbi ìpàtẹ ìwé, Ẹlẹ́rìí kan ń jíròrò àkòrí kan nínú ìwé ‘Ìròyìn Ayọ̀’ pẹ̀lú ẹnì kan.

Báwo Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Ń Lo Àwọn Ọrẹ Tá À Ń Rí?

À ń lo àwọn ọrẹ tá à ń rí láti fi ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn wa títí kan àwọn ìrànwọ́ tá à ń ṣe kárí ayé. A máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà àjálù torí pé ó wà lára iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó yẹ ká ṣe, iṣẹ́ yẹn sì ni pé ká ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè di ọmọlẹ́yìn Kristi.​—Mátíù 28:19, 20.

A kì í fi àwọn ọrẹ wa sọ ẹnikẹ́ni di ọlọ́rọ̀. Kò sí alàgbà tàbí àwọn òjíṣẹ́ èyíkéyìí tá à ń san owó fún. Yàtọ̀ síyẹn, a kì í san owó fún Ẹlẹ́rìí Jèhófà èyíkéyìí láti lọ wàásù láti ilé dé ilé. Bákan náà, a kì í san owó oṣù fún àwọn tó ń sìn ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti oríléeṣẹ́ wa títí kan àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Díẹ̀ Lára Àwọn Ohun Tá À Ń Ṣe

  • Ìwé Títẹ̀: À ń túmọ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé míì tó ń ṣàlàyé Bíbélì sí onírúurú èdè, à ń tẹ̀ wọ́n, à ń pín ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù rẹ̀ fáwọn èèyàn, a sì ń kó wọn lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì. Kò sí èyí tá à ń gbówó fún nínú gbogbo nǹkan tá a mẹ́nu bà yìí. Bákan náà, orí ìkànnì jw.org àti ètò ìṣiṣẹ́ JW Library làwọn ìtẹ̀jáde wa wà lórí ẹ̀rọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé a kì í gba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti wa àwọn ìtẹ̀jáde tó wà níbẹ̀ jáde, kò sì sí ìpolówó ọjà kankan níbẹ̀.

    Ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí tó ń sìn níbi tá a ti ń tẹ̀wé ń ṣàyẹ̀wò Bíbélì tí wọ́n tẹ̀ bóyá ó dáa.
  • Iṣẹ́ Ìkọ́lé àti Àtúnṣe Rẹ̀: A máa ń kọ́ àwọn ilé ìjọsìn tó mọ níwọ̀n kárí ayé, a sì ń bójú tó wọn káwọn ìjọ lè ní ibi tó bójú mu láti pàdé pọ̀ fún ìjọsìn Ọlọ́run. Ohun kan náà là ń ṣe fún àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè wa. Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù lára iṣẹ́ yìí, ìyẹn sì máa ń dín ìnáwó náà kù gan-an.

    Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ń to irin táwọn òṣìṣẹ́ máa ń dúró lé ṣiṣẹ́ ní ìta ilé ìjọsìn wa kan.
  • Iṣẹ́ Àbójútó: Ọrẹ táwọn èèyàn ń ṣe fún iṣẹ́ wa kárí ayé la fi ń bójú tó gbogbo iṣẹ́ tá à ń ṣe ní orílé iṣẹ́ wa, àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àtàwọn ọ́fíìsì atúmọ̀ èdè wa títí kan iṣẹ́ táwọn alábòójútó arìnrìn àjò ń ṣe.

    Ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ń bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan.
  • Iṣẹ́ Ìwàásù: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gba owó fún iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí wọ́n ń ṣe tàbí fún kíkọ́ àwọn míì ní ẹ̀kọ́ “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 2:17) Àmọ́, bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, a máa ń pèsè ilé gbígbé àtàwọn ohun kòṣeémáàní fún àwọn òjíṣẹ́ kan tí wọ́n ti dá lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ń lo gbogbo àkókò wọn láti wàásù.​—Fílípì 4:​16, 17; 1 Tímótì 5:​17, 18.

    Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan wà lóde ẹ̀rí. Wọ́n ń fi fídíò tó ń ṣàlàyé Bíbélì han ọkùnrin kan.
  • Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́: Ọrẹ táwọn èèyàn ṣe la fi máa ń ṣe àwọn àpéjọ àyíká àti àwọn àpéjọ agbègbè wa. Yàtọ̀ síyẹn, à ń gbé àwọn ètò àtẹ́tísí àti àwọn fídíò tá a gbé karí Bíbélì jáde. A tún máa ń ṣètò àwọn ilé ẹ̀kọ́ tá a ti máa ń dá àwọn alàgbà àtàwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ àyànfúnni wọn.

    Àwọn tó wà ní àpéjọ agbègbè kan ń wo fídíò.
  • Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù: A máa ń pèsè oúnjẹ, omi àti ilé fáwọn tí àjálù dé bá. Àmọ́, kì í ṣe “àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́” nìkan ló máa ń jàǹfààní ìpèsè yìí, àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń jàǹfààní ẹ̀.​—Gálátíà 6:10.

    Àwọn Ẹlẹ́rìí kan ń kó ẹrù tí wọ́n fẹ́ kó lọ síbi tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ nínú ilé ìkẹ́rùsí kan.
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́