ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 24
  • Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà Ní Ayé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà Ní Ayé?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà Láyé?—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Nigba Wo ni Alaafia Pipẹtiti Yoo De Niti Gidi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 24
Ọkọ̀ òfúrufú tí wọ́n fi ń jagun

Kí Nìdí Tí Kò Fi Sí Àlàáfíà ní Ayé?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Gbogbo ìsapá àwọn èèyàn láti mú kí àlàáfíà wà ní ayé ló ń já sí pàbó, bí yóò sì ṣe máa rí nìyẹn torí pé:

  • “Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ọlọ́run kò dá àwọn èèyàn wọn pé kí wọ́n máa ṣàkóso ara wọn, torí náà, àlàáfíà tí wọ́n bá jàjà ní kò ní wà pẹ́ títí.

  • “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; Ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:3, 4) Tá a bá tiẹ̀ rí lára àwọn olórí ìjọba èèyàn tó fẹ́ ṣe ohun tó tọ́, wọ́n ò lè mú àwọn ohun tó ń fa ogun kúrò pátápátá.

  • “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ . . . òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:1–4) “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé búburú yìí la wà, àwọn ìwà tí àwọn èèyàn ń hù mú kó ṣòro láti ní àlàáfíà.

  • “Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.” (Ìṣípayá 12:12) Wọ́n ti lé Èṣù, tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́rún, wá sí sàkáání ilẹ̀ ayé. Òun ló ń mú kí àwọn èèyàn máa hùwà ìkà bíi tiẹ̀. A kò lè ní àlàáfíà níwọ̀n ìgbà tó bá jẹ́ òun ṣì ni “olùṣàkóso ayé yìí.”—Jòhánù 12:31.

  • “[Ìjọba Ọlọ́run] yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [tó ń ta ko Ọlọ́run] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba Ọlọ́run ló máa fún wa ní ohun táá tẹ́ wa lọ́rùn, ìyẹn àlàáfíà tí kò lópin kárí ayé, kì í ṣe ìjọba èèyàn.—Sáàmù 145:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́