ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 43
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó Àwọn Tí Kì í Ṣe Ẹ̀yà Kan Náà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó Àwọn Tí Kì í Ṣe Ẹ̀yà Kan Náà?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ọ̀dọ̀ ẹnì kan náà ní gbogbo ẹ̀yà pátá ti wá
  • Àwọn tó gbọ́n máa “ń fikùn lukùn”
  • Fífi Ẹ̀yà Ẹni Yangàn Ńkọ́?
    Jí!—1998
  • Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà
    Jí!—2014
  • Ǹjẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Gbé Ẹ̀yà Ìran Kan Ga Ju Òmíràn Lọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìgbéyàwó Jẹ́ Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Wa
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 43

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó Àwọn Tí Kì í Ṣe Ẹ̀yà Kan Náà?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ọlọ́run fọwọ́ sí ìgbéyàwó láàárín ọkùnrin àti obìnrin ti kì í ṣe ẹ̀yà kan náà torí pé bákan náà ni gbogbo ẹ̀yà rí lójú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú . . . , láìbeere orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́.”—Ìṣe 10:34, 35, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀.

Tún wo àwọn ìlànà Bíbélì míì tó ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀yà àti ìgbéyàwó.

Ọ̀dọ̀ ẹnì kan náà ní gbogbo ẹ̀yà pátá ti wá

Ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ádámù àti Éfà ìyàwó rẹ̀ tí Bíbélì pè ní “ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè,” ni gbogbo èèyàn ti wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:20) Torí ìdí èyí, Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run pé: “Láti ara ọkùnrin kan ni ó sì ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 17:26) Ẹ̀yà yòówù kí ẹnì kan jẹ́, ọmọ ìyá kan náà ni gbogbo wa pátá. Àmọ́, kí ló yẹ kó o ṣe tí ẹ̀tanú tàbí ìwà kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ bá gbilẹ̀ gan-an ní àdúgbò rẹ?

Àwọn tó gbọ́n máa “ń fikùn lukùn”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ìgbéyàwó àwọn tí kì í ṣe ẹ̀yà kan náà, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló fara mọ́ èrò Ọlọ́run. (Aísáyà 55:8, 9) Tó bá wù ọ́ kó o fẹ́ ẹ̀yà míì, kí ìwọ àti ẹni tó o fẹ́ fi ṣe ọkọ tàbí aya jọ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí lẹ máa ṣe tí àwọn tó wà ní àdúgbò yín tàbí àwọn ẹbí yín bá ń yọ yín lẹ́nu lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀yà?

  • Báwo lẹ ṣe máa ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kojú ìwà ẹ̀tanú tí wọ́n bá hù sí wọn?

Tí ẹ bá “fikùn lukùn” lọ́nà yìí, ìgbéyàwó yìn á yọrí sí rere.—Òwe 13:10; 21:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́