ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 79
  • Ṣé inú Ọkàn Rẹ ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé inú Ọkàn Rẹ ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ṣé Inú Ọkàn Ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìjọba Ọlọ́run
    Jí!—2013
  • Ohun Ti Ijọba Ọlọrun Lè Tumọsi Fun Ọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ṣé Inú Ọkàn Èèyàn Ni Ìjọba Ọlọ́run wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 79
Kò sí bí Ìjọba Ọlọ́run ṣe lè wà nínú ara èèyàn

Ṣé inú Ọkàn Rẹ ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?

Ohun tí Bíbélì sọ

Rárá, kì í ṣe inú ọkàn àwọn Kristẹni ni Ìjọba Ọlọ́run wà.a Bíbélì sọ ibi tí Ìjọba náà á ti máa ṣàkóso nígbà tó pè é ní “ìjọba ọ̀run.” (Mátíù 4:17) Wo bí Bíbélì ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba gidi tí yóò máa ṣàkóso láti ọ̀run.

  • Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn alákòóso, àwọn aráàlú àti òfin. Ohun tó sì fẹ́ ṣe ni pé kí ó mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lọ́run àti láyé.​—Mátíù 6:10; Ìṣípayá 5:10.

  • Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso lórí “gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè” tó wà kárí ayé. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló fún àwọn alákòóso náà láṣẹ kì í ṣe àwọn aráàlú.​—Sáàmù 2:4-6; Aísáyà 9:7.

  • Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn tó dúró tì í gbágbáágbá pé wọ́n máa “jókòó lórí ìtẹ́” pẹ̀lú òun nínú Ìjọba ọ̀run.”​—Lúùkù 22:28, 30.

  • Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn ọ̀tá tó máa pa run.​—Sáàmù 2:1, 2, 8, 9; 110:1, 2; 1 Kọ́ríńtì 15:25, 26.

Bíbélì ò kọ́ wa pé inú ọkàn ni Ìjọba Ọlọ́run wà bí ẹni pé ó ń jọba lọ́kàn ẹni. Síbẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí “ọ̀rọ̀ ìjọba náà” tàbí “ìhìn rere ìjọba yìí” wọ̀ wá lọ́kàn.​—Mátíù 13:19; 24:14.

Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínu yín” túmọ̀ sí?

Bí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan ṣe túmọ̀ Lúùkù 17:21 mú kó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti mọ̀ ibi tí Ìjọba náà wà. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì King James Version sọ pé “ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínu yín.” Ká tó lè lóye ẹsẹ Bíbélì yìí, a gbọ́dọ̀ mọ ohun tó mú kí Jésù sọ ọ̀rọ̀ náà.

Àwọn aṣáájú ìsìn tó ta ko Jésù

Ìjọba Ọlọ́run kò sí ní ọkàn àwọn ìkà tó pa Jésù

Àwọn Farisí ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀, ìyẹn ẹgbẹ́ àwọn aṣáájú ìsìn tó ta ko Jésù, tí wọ́n sì lọ́wọ́ sí ikú rẹ̀. (Mátíù 12:14; Lúùkù 17:20) Ṣé inú ọkàn àwọn ìkà bẹ́ẹ̀ ní Ìjọba Ọlọ́run máa wà? Jésù sọ fún wọn pé: “Ní inú, ẹ kún fún àgàbàgebè àti ìwà-àìlófin.”​—Mátíù 23:27, 28.

Àmọ́ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì túmọ̀ ẹsẹ Bíbélì yẹn lọ́nà tó péye tó sì yéni. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì Contemporary English Version sọ pé: “Ìjọba Ọlọ́run wà níbi pẹ̀lú yín.” Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sọ pé: “Ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.” Ìjọba ọ̀run wà “pẹ̀lú” tàbí ní “àárín” àwọn Farisí wọ̀nyẹn ni ti pé Jésù tí Ọlọ́run ti yàn láti jẹ́ Ọba Ìjọba náà wà láàárín wọn.​—Lúùkù 1:32, 33.

a Ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló ń kọni pé inú ọkàn wa ni Ìjọba Ọlọ́run wà. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìjọ Southern Baptist Convention polongo pé Ìjọba Ọlọ́run túmọ̀ sí pé kí “Ọlọ́run máa jọba lọ́kan èèyàn àti nínú ayé ẹni náà.” Póòpù Benedict XVI sọ ohun tó jọ èyí nínú ìwé rẹ̀ tó ń jẹ́ Jesus of Nazareth, ó ní “Ìjọba Ọlọ́run máa dé sínú ayé ẹnì tó bá gba Jésù tó sì ní ìgbàgbọ́.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́