ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 69
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí là ń pè ní àdúrà?
  • Ṣé Ọlọ́run máa ń gbọ́ ẹ tó o bá gbàdúrà?
  • Kí ni mo lè sọ tí mo bá ń gbàdúrà?
  • Máa Gbàdúrà Kó O Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 69
Ọ̀dọ́bìnrin kan jókòó sétí omi

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PE

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?

Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìwádìí kan fi hàn pé ìdá mẹ́jọ nínú mẹ́wàá àwọn ọ̀dọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè náà ló máa ń gbàdúrà, àmọ́ ìdajì àwọn tó máa ń gbàdúrà yẹn ni kì í ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. Ó dájú pé àwọn kan nínú wọn á máa rò ó pé: ‘Ṣé torí kí ara kàn lè tuni léèyàn ṣe máa ń gbàdúrà ni, àbí ó kọjá ìyẹn?’

  • Kí là ń pè ní àdúrà?

  • Ṣé Ọlọ́run máa ń gbọ́ ẹ tó o bá gbàdúrà?

  • Kí ni mo lè sọ tí mo bá ń gbàdúrà?

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kí là ń pè ní àdúrà?

Ọ̀rọ̀ tá à ń bá Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run sọ là ń pè ní àdúrà. Tiẹ̀ rò ó wò ná! Jèhófà ju ọmọ aráyé lọ ní gbogbo ọ̀nà, síbẹ̀, “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ìṣe 17:27) Kódà, Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn tó wúni lórí, ó ní: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”​—Jákọ́bù 4:8.

Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run?

  • Ọ̀nà kan ni pé kó o máa gbàdúrà; bó o ṣe lè máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nìyẹn.

  • Ọ̀nà míì ni pé kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì; bí Ọlọ́run ṣe lè “bá ẹ sọ̀rọ̀” nìyẹn.

Tó o bá ń gbàdúrà, tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe lò ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, tí òun náà sì ń bá ẹ sọ̀rọ̀. Ìyẹn máa jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àti Ọlọ́run lágbára gan-an.

“Ọ̀kan lára àǹfààní tó ga jù táwa èèyàn ní ni pé ká máa bá Jèhófà, Ẹni Gíga Jù Lọ sọ̀rọ̀.”​—Jeremy.

“Tí mo bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, tí mò ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára mi fún un, ó máa ń jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ ọn.”​—Miranda.

Ṣé Ọlọ́run máa ń gbọ́ ẹ tó o bá gbàdúrà?

Tó o bá tiẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, tó o sì ń gbàdúrà sí i, ó lè fẹ́ ṣòro fún ẹ láti gbà pé òótọ́ ló ń gbọ́ ẹ. Síbẹ̀, “Olùgbọ́ àdúrà” ni Bíbélì pe Jèhófà. (Sáàmù 65:2) Bíbélì tiẹ̀ rọ̀ ẹ́ pé kó o “kó gbogbo àníyàn [rẹ] lé e.” Kí nìdí? “Nítorí ó bìkítà fún [ẹ].”​—1 Pétérù 5:7.

Rò ó wò ná: Ṣé o máa ń wáyè léraléra láti bá àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́ sọ̀rọ̀? O lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ náà sí Ọlọ́run. Máa gbàdúrà sí i léraléra, Jèhófà tó jẹ́ orúkọ rẹ̀ sì ni kó o máa lò. (Sáàmù 86:​5-7; 88:9) Kódà, Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o máa “gbàdúrà láìdabọ̀.”​—1 Tẹsalóníkà 5:​17.

“Tí mo bá ń gbàdúrà, tí mò ń bá Baba mi ọ̀run sọ̀rọ̀, gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi ni mo lè sọ fún un.”​—Moises.

“Mo máa ń bá Jèhófà sọ àwọn ohun tó wà nínú mi lọ́hùn-ún, bíi pé mọ́mì mi àbí ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ ni mò ń bá sọ̀rọ̀.”​—Karen.

Kí ni mo lè sọ tí mo bá ń gbàdúrà?

Bíbélì sọ pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”​—Fílípì 4:6.

Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé o lè sọ àwọn ìṣòro ẹ fún Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ ni o! Kódà, Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà . . . yóò sì gbé ọ ró.”​—Sáàmù 55:22.

Àmọ́ kì í ṣe ìṣòro ẹ nìkan ló yẹ kó o máa sọ tó o bá ń gbàdúrà. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Chantelle sọ pé, “Tó bá jẹ́ ìrànlọ́wọ́ nìkan ni mò ń wá lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, okùn ọ̀rẹ́ wa ò ní yi dáadáa. Èrò tèmi ni pé ṣe ló yẹ kí n kọ́kọ́ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, kí n ronú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tó ti ṣe fún mi, kí n sì sọ fún un pé mo mọrírì ẹ̀.”

Rò ó wò ná: Àwọn nǹkan wo ló ti ṣẹlẹ̀ láyé ẹ tó o mọrírì? Ṣé o lè ronú nǹkan mẹ́ta tí Jèhófà ṣe fún ẹ lónìí, tó o fi lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀?

“Kódà, nǹkan kékeré, bí òdòdó tó rẹwà tá a rí, lè mú ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.”​—Anita.

“O lè ronú nípa ohun kan tí Ọlọ́run dá tó o fẹ́ràn, tàbí kó o ronú nípa ẹsẹ Bíbélì kan tó wọ̀ ẹ́ lọ́kàn gan-an, kó o wá gbàdúrà sí Jèhófà, kó o dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”​—Brian.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Moises

“Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára wa ló yẹ ká máa sọ fún Jèhófà. Ó fẹ́ ràn wá lọ́wọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti mọ ohun tá a nílò ká tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, síbẹ̀ a lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá tá a bá ń sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún un.”​—Moises.

Miranda

“Ṣe ni àdúrà dà bí okùn téèyàn fi ń gun òkè. Jèhófà dì í mú lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, èmi náà sì dì í mú lẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì. Tí mo bá ń bá Jèhófà sọ ohun tó wà lọ́kàn mi, ṣe ló dà bíi pé mo di okùn yẹn mú dan-in dan-in bí mo ṣe rọ̀ mọ́ ọn, tí Jèhófà náà sì ń fà mí gùnkè. Ìyẹn á jẹ́ kí n túbọ̀ máa sún mọ́ ọn.”​—Miranda.

Jeremy

“Tá ò bá ṣọ́ra, ó lè jẹ́ ohun tá a fẹ́ nìkan làá máa sọ nínú àdúrà wa. Àmọ́ tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà, ó máa jẹ́ ká fi hàn pé a mọrírì ọ̀pọ̀ nǹkan tó fún wa, a ò sì ní máa ro tara wa nìkan nígbà tá a bá ń gbàdúrà.”​—Jeremy.

Shelby

“Bá a ṣe ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà làá túbọ̀ máa moore rẹ̀ láyé wa. Tá a bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nínú àdúrà wa, ó máa jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí bó ṣe ń bù kún wa dípò tí àá fi máa ronú nípa gbogbo ìṣòro tá a ní.”​—Shelby.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́