ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Kí Ń Ṣe Tí Ọ̀rẹ́ Mi Bá Ṣe Nǹkan Tó Dùn Mí?
Ohun tó yẹ kó o mọ̀
Arẹ́májà kan ò sí. Torí pé aláìpé ni gbogbo wa, ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ lè ṣe nǹkan tó dùn ẹ́ gan-an. Má gbàgbé pé aláìpé ni ìwọ náà. Tíwọ náà bá rọ̀ ó dáadáa, wàá rántí pé nígbà kan rí, ìwọ náà ti ṣe nǹkan tó múnú bí ẹlòmíì.—Jákọ́bù 3:2.
Ohun tí ọ̀rẹ́ rẹ gbé sórí ìkànnì lè múnú bí ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ David sọ pé: “Tó o bá rí i pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ fi fọ́tò tí wọ́n yà níbi àpèjẹ kan sórí ìkànnì àjọlò, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í bínú sí wọn pé wọn ò pè ẹ́ wá síbi àpèjẹ náà. Á wá máa ṣe ẹ́ bíi pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti ṣe àìdáa sí ẹ, inú sì lè máa bí ẹ.”
Ìwọ fúnra rẹ lè yanjú ọ̀rọ̀ náà.
Ohun tó o lè ṣe
Yẹ ara rẹ wò. Bíbélì sọ pé: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn.”—Oníwàásù 7:9.
“Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wàá wá rí i pé nǹkan tí ò tó nǹkan lò ń bínú sí.”—Alyssa.
Bi ara rẹ pé: Ṣé gbogbo nǹkan ni mo máa ń bínú sí? Ṣé mo lè máa gbójú fo àìdáa táwọn míì bá ṣe sí mi?—Oníwàásù 7:21, 22.
Àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa dárí jini. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹwà ni ó jẹ́ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.’—Òwe 19:11.
“Kódà tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lẹnì kan ṣẹ̀ ẹ́, ohun tó dáa jù ni pé kó o dárí ji ẹni náà látọkànwá, kò ní dá a tó o bá ń rán ẹni yẹn létí ohun tó ṣe fún ẹ, kó lè máa bẹ̀ ẹ́ ní gbogbo ìgbà pé kó o má bínú. Tó o bá ti dárí ji ẹnì kan, gbàgbé ọ̀rọ̀ náà.”—Mallory.
Bi ara rẹ pé: Ṣé ọ̀rọ̀ yìí tó bí mo ṣe ń rò ó? Ṣé mo lè dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ mí kí àlàáfíà lè jọba?—Kólósè 3:13.
Tó ò bá kí ń gbàgbé ọ̀rọ̀ àná, ṣe ló dà bí ìgbà tóò ń ṣí ilẹ̀kùn sílẹ̀, tí òtútù sì ń fẹ́ wọ inú ilé
Má ṣe ro tara ẹ nìkan. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”—Fílípì 2:4.
“Tó o bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ, tó o sì bọ̀wọ̀ fún wọn, wàá rí ìdí tó fi yẹ kó o tètè máa yanjú èdèkòyédè tó bá yọjú kí àárín yín má bàa dàrú. Torí ó ti pẹ́ tẹ́ ẹ ti ń bá ọ̀rẹ́ yín bọ̀.”—Nicole.
Bi ara rẹ pé: Àwọn nǹkan tó dára wo ni mo rí nínú ohun táwọn míì sọ?—Fílípì 2:3.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ìsinsìnyí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́ ló yẹ kó o mọ nǹkan tó o lè ṣe tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé ẹnì kan ti ṣẹ̀ ẹ́. Tó o bá túbọ̀ dàgbà, àwọn nǹkan yẹn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an.