Tuesday, September 30
Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, kò ní jẹ́ kí a dán yín wò kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n nínú àdánwò náà, yóò ṣe ọ̀nà àbáyọ kí ẹ lè fara dà á.—1 Kọ́r. 10:13.
Tó o bá ń ronú lórí àdúrà tó o gbà nígbà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, wàá nígboyà láti borí ìdẹwò èyíkéyìí. Bí àpẹẹrẹ, ṣé wàá tage pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹ? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀! Ìdí ni pé o ti pinnu tẹ́lẹ̀ pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Tí o ò bá jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ gbilẹ̀ lọ́kàn ẹ, kò ní sídìí fún ẹ láti máa wá bó o ṣe máa gbé e kúrò lọ́kàn tó bá yá. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní “gba ọ̀nà àwọn ẹni burúkú.” (Òwe 4:14, 15) Tó o bá rántí bí Jésù ṣe pinnu pé òun máa múnú Bàbá òun dùn, kíákíá lo máa kọ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá sì pinnu pé o ò ní ṣe ohunkóhun tó máa dun Jèhófà tó o ya ara ẹ sí mímọ́ fún. (Mát. 4:10; Jòh. 8:29) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé ìṣòro àti ìdẹwò máa fún ẹ láǹfààní láti fi hàn pé o ti pinnu láti máa tẹ̀ lé Jésù. Tó o bá pinnu láti máa tẹ̀ lé Jésù, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. w24.03 9-10 ¶8-10
Wednesday, October 1
Ọgbọ́n tó wá láti òkè . . . ṣe tán láti ṣègbọràn.—Jém. 3:17.
Nígbà míì, ṣé ó máa ń nira fún ẹ láti ṣègbọràn? Ó nira fún Ọba Dáfídì náà láti ṣègbọràn láwọn ìgbà kan, ìdí nìyẹn tó fi gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Jẹ́ kó máa wù mí láti ṣègbọràn sí ọ.” (Sm. 51:12) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa ń nira fún un láti ṣègbọràn, bọ́rọ̀ tiwa náà sì ṣe rí nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé àìpé tá a jogún ń mú ká ṣàìgbọràn. Ìkejì, Sátánì máa ń fẹ́ ká ṣọ̀tẹ̀ bíi tiẹ̀. (2 Kọ́r. 11:3) Ìkẹta, ìwà tinú mi ni màá ṣe ló pọ̀ nínú ayé lónìí, ìyẹn ni Bíbélì pè ní “ẹ̀mí tó ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ aláìgbọràn.” (Éfé. 2:2) Torí náà, a gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára láti borí àwọn nǹkan tó lè mú ká dẹ́ṣẹ̀, ká má sì jẹ́ kí Èṣù àti ayé burúkú yìí mú ká ṣàìgbọràn. Àmọ́, ó yẹ ká sapá gan-an láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tó wà nípò àṣẹ. w23.10 6 ¶1
Thursday, October 2
Wáìnì tó dáa lo gbé pa mọ́ títí di àkókò yìí.—Jòh. 2:10.
Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe sọ omi di wáìnì? Ó kọ́ wa pé ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀. Jésù ò fọ́nnu nítorí iṣẹ́ ìyanu yẹn. Kódà, kò sígbà kankan tí Jésù fọ́nnu nípa àwọn nǹkan tó ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní máa ń jẹ́ kó gbé gbogbo ògo fún Bàbá rẹ̀. (Jòh. 5:19, 30; 8:28) Táwa náà bá nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, a ò ní máa fọ́nnu nítorí àwọn nǹkan tá à ń gbé ṣe. Kò yẹ ká gbé ògo fún ara wa, kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run tá à ń sìn ló yẹ ká máa yìn torí òun lògo tọ́ sí. (Jer. 9:23, 24) Ká sòótọ́, kò sí àṣeyọrí tá a lè ṣe láìjẹ́ pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 1:26-31) Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní fọ́nnu tá a bá ṣe ohun kan láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà rí ohun tá a ṣe, ó sì mọyì ẹ̀. (Fi wé Mátíù 6:2-4; Héb. 13:16) Torí náà, tá a bá fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa.—1 Pét. 5:6. w23.04 4 ¶9; 5 ¶11-12