Thursday, October 2
Wáìnì tó dáa lo gbé pa mọ́ títí di àkókò yìí.—Jòh. 2:10.
Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe sọ omi di wáìnì? Ó kọ́ wa pé ó yẹ ká nírẹ̀lẹ̀. Jésù ò fọ́nnu nítorí iṣẹ́ ìyanu yẹn. Kódà, kò sígbà kankan tí Jésù fọ́nnu nípa àwọn nǹkan tó ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù ní máa ń jẹ́ kó gbé gbogbo ògo fún Bàbá rẹ̀. (Jòh. 5:19, 30; 8:28) Táwa náà bá nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, a ò ní máa fọ́nnu nítorí àwọn nǹkan tá à ń gbé ṣe. Kò yẹ ká gbé ògo fún ara wa, kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run tá à ń sìn ló yẹ ká máa yìn torí òun lògo tọ́ sí. (Jer. 9:23, 24) Ká sòótọ́, kò sí àṣeyọrí tá a lè ṣe láìjẹ́ pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 1:26-31) Tá a bá nírẹ̀lẹ̀, a ò ní fọ́nnu tá a bá ṣe ohun kan láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ọkàn wa máa balẹ̀ torí a mọ̀ pé Jèhófà rí ohun tá a ṣe, ó sì mọyì ẹ̀. (Fi wé Mátíù 6:2-4; Héb. 13:16) Torí náà, tá a bá fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ bíi ti Jésù, ó dájú pé inú Jèhófà máa dùn sí wa.—1 Pét. 5:6. w23.04 4 ¶9; 5 ¶11-12
Friday, October 3
Ẹ máa wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.—Fílí. 2:4.
Ẹ̀mí Ọlọ́run darí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí tá a bá wà nípàdé? Bá a ṣe lè tẹ̀ lé e ni pé ká máa rántí pé àwa nìkan kọ́ ló máa dáhùn nípàdé, ká jẹ́ káwọn ẹlòmíì náà dáhùn. Rò ó wò ná. Tí ìwọ àti ọ̀rẹ́ ẹ kan bá jọ ń sọ̀rọ̀, ṣé ìwọ nìkan ni wàá máa sọ̀rọ̀ ṣáá àbí wàá fún òun náà láǹfààní láti sọ̀rọ̀? Rárá o, wàá jẹ́ kóun náà sọ̀rọ̀! Lọ́nà kan náà, tá a bá wà nípàdé, dípò ká máa nawọ́ ṣáá, á dáa ká jẹ́ káwọn ẹlòmíì náà dáhùn. Kódà, ọ̀kan lára ohun tá a lè ṣe láti gba àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa níyànjú ni pé, ká fún wọn láǹfààní láti dáhùn kí wọ́n lè sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. (1 Kọ́r. 10:24) Jẹ́ kí ìdáhùn ẹ ṣe ṣókí, káwọn ẹlòmíì lè dáhùn. Tí ìdáhùn ẹ bá tiẹ̀ ṣe ṣókí, má sọ kókó tó pọ̀. Tó o bá sọ gbogbo kókó tó wà nínú ìpínrọ̀ náà, àwọn ará ò ní rí nǹkan kan sọ mọ́. w23.04 22-23 ¶11-13
Saturday, October 4
Mò ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè sọ ọ́ fún àwọn ẹlòmíì.—1 Kọ́r. 9:23.
Ó yẹ ká rántí pé ó ṣe pàtàkì ká máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, pàápàá jù lọ ká máa wàásù fún wọn. Ó yẹ ká mọ bá a ṣe máa bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ tá a bá ń wàásù. Lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a máa ń pàdé àwọn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ìwà wọn àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ sì yàtọ̀ síra. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń bá onírúurú èèyàn sọ̀rọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, ó sì yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀. Jésù yàn án pé kó jẹ́ “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 11:13) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún un yìí, ó wàásù fáwọn Júù, àwọn Gíríìkì, àwọn ọ̀mọ̀wé, àwọn tálákà, àwọn èèyàn pàtàkì láwùjọ àtàwọn ọba. Kí Pọ́ọ̀lù lè wàásù fún gbogbo àwọn tá a sọ yìí, ó “di ohun gbogbo nítorí gbogbo èèyàn.” (1 Kọ́r. 9:19-22) Ó kíyè sí ibi tí wọ́n ti wá, àṣà ìbílẹ̀ wọn àtohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ìyẹn jẹ́ kó lè wàásù fún wọn lọ́nà tó wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Táwa náà bá jẹ́ kí ọ̀nà tá à ń gbà wàásù dáa sí i, àá lè wàásù fún onírúurú èèyàn. w23.07 23 ¶11-12