Sunday, October 5
Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́ sí gbogbo èèyàn.—2 Tím. 2:24.
Àwọn tó bá níwà tútù kì í ṣe ojo. Ó gba sùúrù gan-an ká tó lè hùwà jẹ́jẹ́ tí wọ́n bá múnú bí wa. Ìwà tútù jẹ́ ọ̀kan lára “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:22, 23) Nígbà míì, wọ́n sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìwà tútù” fún ẹṣin kan tó burú, àmọ́ tí wọ́n ti kápá ẹ̀. Fojú inú wo ẹṣin kan tó burú gan-an, àmọ́ tó ti wá ń ṣe jẹ́jẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹṣin náà ti ń ṣe jẹ́jẹ́, ó ṣì lágbára. Báwo làwa náà ṣe lè jẹ́ oníwà tútù, síbẹ̀ ká jẹ́ alágbára? Ká sòótọ́, kì í ṣe ohun tá a lè dá ṣe fúnra wa. Ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ká sì sọ fún un pé kó jẹ́ ká níwà tútù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti fi hàn pé èyí ṣeé ṣe. Ọ̀pọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ti fi hàn pé a níwà tútù nígbà táwọn èèyàn ta kò wá tàbí tí wọ́n múnú bí wa, ìyẹn sì ti jẹ́ káwọn èèyàn ní èrò tó tọ́ nípa wa.—2 Tím. 2:24, 25. w23.09 15 ¶3
Monday, October 6
Mo gbàdúrà nípa rẹ̀, Jèhófà sì fún mi ní ohun tí mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.—1 Sám. 1:27.
Nínú ìran àgbàyanu kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún (24) tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà lọ́run. Wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé òun ló tọ́ sí láti gba “ògo àti ọlá àti agbára.” (Ìfi. 4:10, 11) Bákan náà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń mú káwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa yin Jèhófà, kí wọ́n sì máa bọlá fún un. Ọ̀run làwọn áńgẹ́lì yìí ń gbé pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n mọ Jèhófà dáadáa. Wọ́n máa ń rí bí àwọn ànímọ́ Jèhófà ṣe ń hàn nínú gbogbo ohun tó ń ṣe. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe yìí ń mú kí wọ́n máa yìn ín. (Jóòbù 38:4-7) Ó yẹ káwa náà máa yin Jèhófà tá a bá ń gbàdúrà, ká jẹ́ kó mọ ìdí tá a fi nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ àti ìdí tá a fi mọyì àwọn ohun tó ṣe fún wa. Bó o ṣe ń ka Bíbélì tó o sì ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀, kíyè sí àwọn ànímọ́ Jèhófà tó wù ẹ́. (Jóòbù 37:23; Róòmù 11:33) Lẹ́yìn náà, sọ ìdí táwọn ànímọ́ náà fi wù ẹ́ fún Jèhófà. A tún lè yin Jèhófà torí pé ó ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ àti gbogbo àwọn ará wa kárí ayé.—1 Sám. 2:1, 2. w23.05 3-4 ¶6-7
Tuesday, October 7
Ẹ máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà.—Kól. 1:10.
Lọ́dún 1919, àwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá. Lọ́dún yẹn gan-an ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” dé láti kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ káàbọ̀ sí “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀. (Mát. 24:45-47; Àìsá. 35:8) A mọyì àwọn olóòótọ́ tó kọ́kọ́ tún ọ̀nà náà ṣe torí pé ohun tí wọ́n ṣe ti ran àwọn tó ń rin ọ̀nà náà lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. (Òwe 4:18) Ó tún mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Jèhófà ò retí pé kí àwọn èèyàn ẹ̀ ṣe gbogbo àyípadà náà lẹ́ẹ̀kan náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, díẹ̀díẹ̀ ló ń tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Ẹ wo bí inú gbogbo wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́! Ó yẹ ká máa tún ọ̀nà kan ṣe déédéé kó má bàa bà jẹ́. Láti ọdún 1919 ni a ti ń ṣàtúnṣe “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá. w23.05 17 ¶15; 19 ¶16