Tuesday, October 7
Ẹ máa rìn lọ́nà tó yẹ Jèhófà.—Kól. 1:10.
Lọ́dún 1919, àwọn èèyàn Ọlọ́run bọ́ lọ́wọ́ Bábílónì Ńlá. Lọ́dún yẹn gan-an ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” dé láti kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ káàbọ̀ sí “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí sílẹ̀. (Mát. 24:45-47; Àìsá. 35:8) A mọyì àwọn olóòótọ́ tó kọ́kọ́ tún ọ̀nà náà ṣe torí pé ohun tí wọ́n ṣe ti ran àwọn tó ń rin ọ̀nà náà lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fáráyé. (Òwe 4:18) Ó tún mú kí wọ́n máa ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Jèhófà ò retí pé kí àwọn èèyàn ẹ̀ ṣe gbogbo àyípadà náà lẹ́ẹ̀kan náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, díẹ̀díẹ̀ ló ń tọ́ àwọn èèyàn ẹ̀ sọ́nà. Ẹ wo bí inú gbogbo wa ṣe máa dùn tó nígbà tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́! Ó yẹ ká máa tún ọ̀nà kan ṣe déédéé kó má bàa bà jẹ́. Láti ọdún 1919 ni a ti ń ṣàtúnṣe “Ọ̀nà Ìjẹ́mímọ́” kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè kúrò nínú Bábílónì Ńlá. w23.05 17 ¶15; 19 ¶16
Wednesday, October 8
Mi ò ní fi ọ́ sílẹ̀ láé.—Héb. 13:5.
Ìgbìmọ̀ Olùdarí fúnra wọn máa ń dá àwọn arákùnrin tó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́kọ̀ọ́, àwọn arákùnrin yìí sì wà nínú onírúurú ìgbìmọ̀ tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò. Kódà ní báyìí, àwọn arákùnrin yìí ń fi òótọ́ inú bójú tó ọ̀pọ̀ ojúṣe nínú ètò Ọlọ́run. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí àwọn olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti gbà yìí ti múra wọn sílẹ̀ láti máa bójú tó àwọn àgùntàn Kristi nìṣó. Nígbà tí èyí tó kẹ́yìn lára àwọn ẹni àmì òróró bá ti lọ sọ́run ní apá ìparí ìpọ́njú ńlá, àwa èèyàn Jèhófà á ṣì máa bá ìjọsìn tòótọ́ lọ láyé. Torí pé Jésù ló ń darí wa, àwa èèyàn Ọlọ́run á ṣì máa sìn ín nìṣó, a ò ní pàdánù ohunkóhun. Òótọ́ ni pé nígbà yẹn, Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù, ìyẹn àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè á ti gbéjà kò wá torí pé wọ́n kórìíra wa. (Ìsík. 38:18-20) Àmọ́ àkókò tí wọ́n fi máa gbéjà kò wá ò ní pẹ́, kò sì ní dí àwa èèyàn Jèhófà lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn ẹ̀. Ó dájú pé ó máa gbà wá sílẹ̀! Nínú ìran kan, àpọ́sítélì Jòhánù rí “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jẹ́ ara àgùntàn mìíràn ti Kristi. Áńgẹ́lì kan sọ fún Jòhánù pé “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” yìí wá “látinú ìpọ́njú ńlá.” (Ìfi. 7:9, 14) Torí náà, ó dá wọn lójú pé Jèhófà máa gbà wọ́n là! w24.02 5-6 ¶13-14
Thursday, October 9
Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.—1 Tẹs. 5:19.
Kí ló yẹ ká ṣe kí Ọlọ́run lè fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀? Ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ká máa ka Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká sì wà nínú ètò rẹ̀ tí ẹ̀mí mímọ́ ń darí. Tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, a máa ní “èso ti ẹ̀mí.” (Gál. 5:22, 23) Àwọn tí ọkàn wọn mọ́ àtàwọn tí ìwà wọn mọ́ nìkan ni Ọlọ́run máa ń fún ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. Tá a bá ń ro èròkerò, tá a sì ṣe ohun tá à ń rò, Ọlọ́run ò ní fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ mọ́. (1 Tẹs. 4:7, 8) Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run máa fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, kò tún yẹ ká “kó àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ dà nù.” (1 Tẹs. 5:20) “Àsọtẹ́lẹ̀” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ nípa ẹ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà máa ń bá wa sọ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀. Lára àwọn ọ̀rọ̀ náà ni ọjọ́ Jèhófà tí ò ní pẹ́ dé àti bí àkókò tá a wà yìí ti ṣe pàtàkì tó. Kò yẹ ká máa rò pé ọjọ́ Jèhófà tàbí Amágẹ́dọ́nì ò ní dé lákòókò wa yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa ṣe àwọn ohun tó fi hàn pé ọjọ́ náà ò ní pẹ́ dé, ká máa hùwà tó dáa, ká sì máa ṣe “iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run.”—2 Pét. 3:11, 12. w23.06 12-13 ¶13-14