Monday, July 14
Ó bọ́ síta, ó sì sunkún gidigidi.— Mát. 26:75.
Àpọ́sítélì Pétérù láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ń bá yí. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ kan. Nígbà tí Jésù sọ pé òun máa jìyà òun sì máa kú bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́ lẹ̀, ńṣe ni Pétérù sọ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní ṣẹlẹ̀ sí Jésù. (Máàkù 8:31-33) Yàtọ̀ síyẹn, léraléra ni Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù jiyàn nípa ẹni tó máa jẹ́ olórí láàárín wọn. (Máàkù 9:33, 34) Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, Pétérù gé etí ọkùnrin kan dà nù láìjáfara. (Jòh. 18:10) Ní alẹ́ ọjọ́ yẹn kan náà, ẹ̀rù ba Pétérù, ó sì sẹ́ Jésù ọ̀rẹ́ ẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta. (Máàkù 14:66-72) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kí Pétérù sunkún gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ti rẹ̀wẹ̀sì, Jésù ò jẹ́ kọ́rọ̀ ẹ̀ sú òun. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fún Pétérù láǹfààní láti fi hàn pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ òun. Torí náà, Jésù ní kí Pétérù máa fìrẹ̀lẹ̀ bójú tó àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. (Jòh. 21:15-17) Pétérù sì múra tán láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé fún un. Torí náà, ó wà lára àwọn tí Jèhófà kọ́kọ́ fi ẹ̀mí mímọ́ yàn ní Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. w23.09 22 ¶6-7
Tuesday, July 15
Máa bójú tó àwọn àgùntàn mi kéékèèké.—Jòh. 21:16.
Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn alàgbà nímọ̀ràn pé kí wọ́n “máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run.” (1 Pét. 5:1-4) Tó bá jẹ́ pé alàgbà ni ẹ́, ó dájú pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ẹ, ó sì wù ẹ́ kó o máa bójú tó wọn. Àmọ́ nígbà míì, ọwọ́ ẹ lè dí tàbí kó rẹ̀ ẹ́ débi pé o ò lè bójú tó àwọn ará. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe? Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún Jèhófà. Pétérù sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kó ṣe é bí ẹni tó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń fúnni.” (1 Pét. 4:11) Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin kan níṣòro tó jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ẹ̀. Àmọ́, máa rántí pé Jésù Kristi tó jẹ́ “olórí olùṣọ́ àgùntàn” máa ṣe ju ohun tó o lè ṣe fún wọn. Ó lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí, á sì tún ṣe bẹ́ẹ̀ nínú ayé tuntun. Ohun tí Jèhófà fẹ́ kẹ́yin alàgbà máa ṣe ni pé kẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, kẹ́ ẹ máa bójú tó wọn, kẹ́ ẹ sì “jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo.” w23.09 29-30 ¶13-14
Wednesday, July 16
Jèhófà mọ̀ pé èrò àwọn ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.—1 Kọ́r. 3:20.
Ó yẹ ká yẹra fún ọgbọ́n èèyàn tá a bá fẹ́ ṣe ohunkóhun. Tá a bá ń ronú bí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà ṣe ń ronú, ó lè jẹ́ ká pa Jèhófà àtàwọn ìlànà ẹ̀ tì. (1 Kọ́r. 3:19) “Ọgbọ́n ayé yìí” máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Àwọn Kristẹni kan tó wà nílùú Págámù àti Tíátírà ń bọ̀rìṣà, wọ́n sì ń ṣèṣekúṣe bíi tàwọn ará ìlú náà. Jésù bá ìjọ méjèèjì yìí wí lọ́nà tó le torí pé wọ́n gba ìṣekúṣe láyè. (Ìfi. 2:14, 20) Bákan náà lónìí, àwọn èèyàn ń fúngun mọ́ wa pé ká ṣàìgbọràn sí Jèhófà, àwọn ará ilé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa sì lè fẹ́ ká ṣe ohun tí Jèhófà ò fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé kò sóhun tó burú tá a bá ṣèṣekúṣe àti pé àwọn ìlànà Bíbélì ò bóde mu mọ́. Nígbà míì, a lè máa rò pé Jèhófà ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ohun tó fẹ́ ká ṣe. Kódà, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká kọjá àwọn ohun tó wà lákọsílẹ̀.—1 Kọ́r. 4:6. w23.07 16 ¶10-11